ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mímu Tábà
  • Àwọn Èwe àti Ìbọn
  • Ìlànà fún Ìṣekúpara-Ẹni
  • Kíkọ́ Ìwà Ipá
  • Àìtó Àlùfáà ní Ilẹ̀ Faransé Ń Pọ̀ Sí I
  • Agogo Tí Iṣẹ́ Rẹ̀ Péye Jú Lọ Lágbàáyé
  • Búrẹ́dì Ẹlẹ́ran Nínú Lásán Kẹ̀?
  • Òwò Bíbá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe ní Éṣíà
  • Ìbáradíje Tàbí Ìṣọ̀kan?
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Pípa Ara Ẹni—Ìṣòro Wíwọ́pọ̀ Láàárín Àwọn Ọ̀dọ́
    Jí!—1998
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 10/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Mímu Tábà

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mímú tábà ti dín kù gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ó hàn pé ńṣe ló ń pọ̀ sí i ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè ní àwọn ẹ̀wádún méjì tó kọjá. Fún àpẹẹrẹ, China ni wọ́n ṣì ti ń mu ún jù lọ lágbàáyé, ó sì fi ìpín 297 lórí ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. United States àti India ṣì wà ní ipò kejì àti ìkẹta bí ibi tí wọ́n ti ń mu ún jù lọ, ó sì fi ìpín 27 nínú ọgọ́rùn-ún àti ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí ó tún ti pọ̀ sí i gan-an ni Rwanda pẹ̀lú ìpín 388 lórí ọgọ́rùn-ún; Gíríìsì, ìpín 331 lórí ọgọ́rùn-ún; North Korea, ìpín 325 lórí ọgọ́rùn-ún; Tanzania, ìpín 227 lórí ọgọ́rùn-ún; Hong Kong, ìpín 214 lórí ọgọ́rùn-ún; Indonesia, ìpín 193 lórí ọgọ́rùn-ún; Singapore, ìpín 186 lórí ọgọ́rùn-ún; àti Turkey, ìpín 185 lórí ọgọ́rùn-ún. Àwọn nọ́ḿbà náà, tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Asiaweek, fi iye ìyípadà lórí ìpín ọgọ́rùn-ún láàárín 1970 sí 1993 hàn. Lára orílẹ̀-èdè 138 tí a kọ̀ sílẹ̀, kìkì ibi 26 péré ló hàn pé mímu tábà ti dín kù níbẹ̀.

Àwọn Èwe àti Ìbọn

Ẹgbẹ́ Owó Àkànlò fún Ìgbèjà Àwọn Ọmọdé sọ pé, àwọn tí a fi ìbọn pa ń yára pọ̀ sí i láàárín àwọn èwe America tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún 10 sí 19, ju láàárín àwọn àwùjọ èyíkéyìí mìíràn lọ. Ìbọn ti wáá di èkejì lára àwọn ohun tí ń fa ikú jù lọ. Ìjàm̀bá, pàápàá jù lọ, ti ọkọ̀ ìrìnnà, ni okùnfà àkọ́kọ́. Láàárín àwọn èwe America tí wọn kò tí ì pé 20 ọdún, a ń fi ìbọn pa ọ̀kan láàárín ìṣẹ́jú 92 ní 1993—ó fi ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i ju ti ọdún tó ṣáájú rẹ̀ lọ. Ní ìfiwéra, nínú gbogbo ìṣọ̀wọ́ ọjọ́ orí, ìwọ̀nba ìbísí ìpín 4.8 nínú ọgọ́rùn-ún ló wà. Ẹgbẹ́ agbèjà náà fẹ̀sùn kan ìjọba pé kò ṣe púpọ̀ tó láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọdé àti ilé ẹ̀kọ́ ní ìbọn. Ìṣirò tí Ẹ̀ka Ìdájọ́ ní United States ṣe ni a sọ pé ó bá ìyẹn mu. Iye àwọn màjèṣín apànìyàn ti di ìlọ́po mẹ́ta ní ẹ̀wádún tó kọjá, wọ́n sì lé ní 26,000 ní 1994. Iye àwọn tí ń lo ìbọn bí ohun ìṣọṣẹ́ ìṣìkàpànìyàn wọn ti di ìlọ́po mẹ́rin ní àkókò kan náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn tí ń lo àwọn ohun ìṣọṣẹ́ mìíràn wà ní iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Nọ́ḿbà náà tẹnu mọ́ ìbàjẹ́ tí níní ìbọn lárọ̀ọ́wọ́tó ń ṣe.

Ìlànà fún Ìṣekúpara-Ẹni

Ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “Nǹkan bí 30,000 àwọn ará America ní ń [pa] ara wọn lọ́dọọdún,” àti pé, “ó ṣeé ṣe kí àwọn ọkùnrin tí ń gbẹ̀mí ara wọn fi ìlọ́po mẹ́rin ju ti àwọn obìnrin lọ.” Ìwọ̀n ìṣekúpara-ẹni tún ti ń pọ̀ sí i pẹ̀lú ọjọ́ ogbó, tí ó sì ń ṣàgbéyọ másùnmáwo àìlera àti ìfojúsọ́nà tí ń dín kù. Iye ìṣekúpara-ẹni láàárín àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni ọdún 75 tàbí tí wọ́n dàgbà jù bẹ́ẹ̀ lọ fi ìlọ́po mẹ́rin pọ̀ ju ti àwọn ọ̀dọ́langba lọ. Àwọn kókó abájọ wo ló ń pinnu bóyá ẹnì kan yóò ṣekú pa ara rẹ̀ ní ti gidi? Àwọn tí ó ta yọ jù lọ lára àwọn ohun tí a ṣàkọsílẹ̀ ni àìsí ìtìlẹ́yìn ìdílé àti ti ẹgbẹ́ àwùjọ àti àìkópa nínú ìsìn lọ títí. Ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè míràn, ìwọ̀n ìṣekúpara-ẹni ní United States wà láàárín, pẹ̀lú ìwọ̀n nǹkan bí ìṣekúpara-ẹni 11 láàárín 100,000 ènìyàn.

Kíkọ́ Ìwà Ipá

◼ Ìwé agbéròyìnjáde The Washington Post sọ pé: “Ìwádìí nípa àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tí àwọn olùṣèwádìí fi ọdún kan ṣe ní àwọn yunifásítì mẹ́rin, fi hàn pé ìwà ipá ‘tí ń ṣèpalára fún èrò inú’ kún inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a ń gbé sáfẹ́fẹ́ àti ti orí tẹlifíṣọ̀n alátagbà.” Ìwádìí náà fi hàn pé kì í ṣe kìkì pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní àwọn ìwà ipá nínú ni, àmọ́, pé ọ̀nà tí wọ́n tún gbà fi í hàn lè ní ipa tí ó lè pa àwọn òǹwòran lára. Àwọn ipa náà “ní nínú, kíkọ́ láti hùwà ipá, dídi ẹni tí ìyọrísí ìwà ipá kì í dà láàmú páàpáà àti dídi ẹni tí ń bẹ̀rù gan-an pé kí a má kọ lu òun.” Ìdí kan ni pé àwọn ahùwà ipá nínú ìpín 73 nínú ọgọ́rùn-ún ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n ní ń mú un jẹ, ní gbígbé ìhìn iṣẹ́ náà jáde pé “ìwà ipá máa ń ní àṣeyọrí.” Bákan náà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àwòrán tí a fi hàn kì í fi àbáyọrí, bí ìpalára, ìrora, tàbí ìpalára èrò ìmọ̀lára tàbí ti ìṣúnná owó, tí ó ṣe fún àwọn òjìyà hàn. Ìwádìí náà tún sọ pé, lílo àwọn ìbọn ìléwọ́ léraléra nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ oníwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n lè “máa tanná ran àwọn èrò àti ìwà jàgídíjàgan.”

◼ Len Eron, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìfìṣemọ̀rònú-ẹ̀dà tí ó sì jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ aṣèwádìí ní Ẹ̀ka Ìṣèwádìí Nípa Àjọṣepọ̀ Ẹ̀dá ní Yunifásítì Michigan, sọ pé, nígbà tí àwọn tí ń wo ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n jù nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé bá fi máa pé ẹni 30 ọdún, “wọn óò ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí ìjẹ̀bi ìwà ipá, ọ̀pọ̀ ìfàṣẹmúni fún mímutí yó wakọ̀, wọn óò túbọ̀ ya oníjàgídíjàgan lábẹ́ ìdarí ọtí líle, wọn óò sì túbọ̀ ṣe àwọn ìyàwó wọn níṣekúṣe [àti] bákan náà wọn óò ní àwọn ọmọ tí wọ́n túbọ̀ ya oníjàgídíjàgan.” Àwọn eré àṣedárayá orí fídíò máa ń fa irú ìṣòro kan náà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star ṣe sọ, Eron sọ pé ewu tí ó so pọ̀ mọ́ eré àṣedárayá orí fídíò ni pé ó jẹ́ alápá méjì. Àwọn òṣèré “yóò fa ohun kan tàbí kí wọ́n tẹ bọ́tìnì kan, àwọn fúnra wọn sì ń ṣe eré oníwà ipá, tí ń bani lẹ́rù yìí—pípa ẹnì kan.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Eron nímọ̀lára pé a nílò àbójútó àwọn òbí lọ́nà púpọ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, ó kédàárò pé, “púpọ̀ àwọn òbí kò wulẹ̀ bìkítà.”

Àìtó Àlùfáà ní Ilẹ̀ Faransé Ń Pọ̀ Sí I

Àìtó àwọn àlùfáà Kátólíìkì ní ilẹ̀ Faransé ń pọ̀ sí i. Ìwé agbéròyìnjáde Paris náà, Le Monde, ròyìn pé ní 1995, àwọn àlùfáà 96 péré ni wọ́n fi joyè ní gbogbo ilẹ̀ Faransé àti kìkì 121 péré ní 1994. Àwọn ẹgbẹ́ Jesuit ní àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀ 7 péré, àwọn Dominican sì ní 25 ní 1995. Ipò ọ̀ràn náà dọ́gba nínú gbígba àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé Kátólíìkì síṣẹ́. Ìwé agbéròyìnjáde Le Monde sọ pé “láti àwọn ọdún 1970 ni iye àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tí bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, láti 92,326 ní 1977 sí 51,164 péré ní ọdún tó kọjá.” Pẹ̀lú pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àlùfáà náà ti ń darúgbó àti ìkùnà ṣọ́ọ̀ṣì náà láti lè fa àwọn mìíràn tí yóò wọṣẹ́ mọ́ra, àwọn ènìyàn tí wí àwítẹ́lẹ̀ pé tí yóò bá fi di ọdún 2005, nǹkan bí 9,000 àlùfáà pàríìṣì péré ni yóò wà ní ilẹ̀ Faransé. Ìwé agbéròyìnjáde Le Monde tọ́ka sí “dídín tí ipò àwọn àlùfáà ń dín kù láwùjọ, ìbẹ̀rù àwọn ènìyàn nípa wíwà lábẹ́ ẹ̀jẹ́ àdéhùn fún àkókò gígùn, ìfùsì aláìfanimọ́ra nípa àwọn àlùfáà, àti ṣíṣàìní ìgbọ́kànlé nínú àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì” gẹ́gẹ́ bí èrèdí ìfàsẹ́yìn náà.

Agogo Tí Iṣẹ́ Rẹ̀ Péye Jú Lọ Lágbàáyé

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní Perth, Ìwọ̀ Oòrùn Australia, ti ṣe agogo kan tí àkókò rẹ̀ fi ìgbà ẹgbẹ̀rún péye ju àwọn agogo tí ń lo agbára atọ́míìkì tí wọ́n ń lò ní England láti pinnu ìdíwọ̀n àkókò tí ó ṣètẹ́wọ́gbà lágbàáyé lọ. A mọ̀ ọ́n sí agogo sapphire, iye rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí 200,000 dọ́là, a sì ti ṣe àwọn bíi mélòó kan. Ó lè wọn ìṣẹ́jú àáyá femto ayárakánkán, tí ó jẹ́ ìpín mílíọ̀nù kan nínú ìpín bílíọ̀nù ìṣẹ́jú àáyá kan! Kí ló wúlò fún? Gẹ́gẹ́ bí àbá èrò orí gbogbogbòò ti ìṣiṣẹ́kanra ti Einstein, bí ènìyàn bá ṣe lọ sóde ilẹ̀ ayé tó ni àkókò ṣe ń yára sáré tó. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá, David Blair, tí ó lọ́wọ́ nínú ṣíṣe agogo náà, sọ pé: “Góńgó wa jẹ́ láti wọn bí ibi tó ga tó mítà kan ṣe jìnnà tó ní ìwọ̀n ìyára—ní ọ̀rọ̀ míràn láti ẹsẹ̀ rẹ dé orí rẹ.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìpéye rẹ̀ ní wíwọn àkókò lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ń pẹ́ tó ìṣẹ́jú márùn-ún péré.

Búrẹ́dì Ẹlẹ́ran Nínú Lásán Kẹ̀?

Ní 1762, Alàgbà Sandwich ọmọ ilẹ̀ Britain, tí ó ti jingírí nínú tẹ́tẹ́ títa, jókòó sídìí tábìlì tẹ́tẹ́ fún wákàtí 24. Láti lè pa ebi, ó béèrè fún awẹ́ búrẹ́dì méjì tí ègé ẹran kan wà láàárín wọn. Ìpápánu tuntun yìí—sandwich (búrẹ́dì ẹlẹ́ran nínú)—ni a bẹ̀rẹ̀ sí í fi orúkọ rẹ̀ pè ní kíá. Àwọn ará Britain ń ná mílíọ̀nù 7.9 dọ́là lójúmọ́ lórí búrẹ́dì ẹlẹ́ran nínú, tí ó fi ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju tí ọdún márùn-ún tó kọjá lọ. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé: “Búrẹ́dì ẹlẹ́ran nínú lé ní ìdá kan nínú mẹ́ta gbogbo oúnjẹ ìpápánu tí a ń tà,” láti orí 8,000 pẹpẹ ìtajà búrẹ́dì ẹlẹ́ran nínú ni a sì ti ń tà wọ́n. Nǹkan bíi bílíọ̀nù 1.3 búrẹ́dì ẹlẹ́ran nínú tí a ṣe sílẹ̀ ni àwọn ènìyàn ń jẹ́ ní ilẹ̀ Britain lọ́dọọdún. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn búrẹ́dì ẹlẹ́ran nínú yìí sábà máa ń yàtọ̀ gédégédé sí irú oúnjẹ lásán tí àwọn ìdílé máa ń kó dání nígbà tí wọ́n bá ń gba fàájì ní agbègbè àrọ́ko tàbí ní etí òkun. Àwọn ilé ìtajà kan ń pèsè àwọn oríṣi ṣíṣàrà ọ̀tọ̀, títí kan búrẹ́dì ẹlẹ́ran nínú tí a fi ẹran kangaroo tàbí ẹlẹ́gungùn sí tàbí búrẹ́dì oníṣokoléètì tí a fi strawberry àti wàrà sórí rẹ̀.

Òwò Bíbá Ọmọdé Ṣèṣekúṣe ní Éṣíà

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, àwọn ìjọba àti àwọn òṣìṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re fojú díwọ̀n pé àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin, ọlọ́dún 17 àti àwọn tí wọn kò dàgbà tó bẹ́ẹ̀, tí iye wọ́n lé ní mílíọ̀nù kan, ní ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó ní Éṣíà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ iye wọn gẹ́lẹ́, a tilẹ̀ ń rí àwọn ọmọdé tí wọn kò tí ì bàlágà ní àwọn ilé aṣẹ́wó ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Cambodia, China, India, Philippines, Taiwan, àti Thailand. Kí ló dé tí àwọn ènìyàn ń wọlé tọ àwọn ọmọdé tí wọ́n kéré bẹ́ẹ̀ lọ? Ìdí kan ni ìbẹ̀rù àrùn AIDS. Ìwé agbéròyìnjáde Times náà sọ pé: “Àwọn ọkùnrin jákèjádò Éṣíà ń yíjú sí àwọn ọmọdé tí wọ́n kéré gan-an, lápá kan, nítorí pé wọ́n ronú pé wọ́n lè máà ní fáírọ́ọ̀sì H.I.V., èyí tí ń fa àrùn AIDS.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, fáírọ́ọ̀sì àrùn AIDS ń yára tàn kálẹ̀ láàárín àwọn aṣẹ́wó ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, lápá kan, nítorí kíkó àwọn aṣẹ́wó láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn àti lápá kan nítorí pé àwọn oníbàárà, tí àwọn kan lára wọ́n wà ní ìrìn àjò nítorí ìbálòpọ̀, ń lọ láti ibì kan sí òmíràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń jí àwọn kan gbé sá lọ, àwọn òbí ló ta àwọn mìíràn nítorí èrè ohun ti ara.

Ìbáradíje Tàbí Ìṣọ̀kan?

Pépà ìròyìn ENI (Ìròyìn Ìgbìmọ̀ Ìkópọ̀ṣọ̀kan Ìsìn Yíká Ayé) Bulletin sọ pé: “Ayẹyẹ àyájọ́ 2000 ọdún tí a bí Kristi ti ń yára di ọ̀ràn arùmọ̀lára sókè láàárín àwọn ṣọ́ọ̀ṣì.” Konrad Raiser, akọ̀wé àpapọ̀ Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé, ti ké sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì láti ṣàgbéyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí “àkókó fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìṣọ̀kan—dípò ìbáradíje fún ìyọrí-ọlá.” Ó wí pé, bí ó ti wù kí ó rí, ó jọ pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ní ìtẹ̀sí ọkàn púpọ̀ lórí lílo ọdún náà gẹ́gẹ́ bí “àkókò fún ìjíhìnrere . . . láti borí kíkà wọ́n sí ipò aláìjámọ́ǹkankan ní gbangba.” Nígbà tí Raiser ń gbóríyìn fún póòpù fún ìpè rẹ̀ fún mímú kí ọdún 2000 “jẹ́ àkókò fún fífi ìdí ìṣọ̀kan Kristẹni múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in,” ó ṣàfikún pé: “Mélòó lára àwọn àlá wọ̀nyí ni a lè mú ṣẹ ní ọdún 2000 ló kù—àwọn ìrírí tó ti kọjá ń gbé iyè méjì dìde.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́