Wíwo Ayé
“Yóò Ṣe Wá Láǹfààní Bí A Bá Lè Ṣẹ̀dá Wọn”
Ọ̀jọ̀gbọ́n Anatoly P. Zilber, alága Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìtọ́jú Àkànṣe àti Àìmọ̀rora-Lára Fáwọn Aláìsàn, ní Yunifásítì ti Petrozavodsk àti Ilé Ìwòsàn Republican ní Karelia, ní Rọ́ṣíà, gbóríyìn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nípa sísọ pé: “Wọn kì í mutí ní ìmukúmu, wọn kì í mu sìgá, wọn ò lójú kòkòrò owó, wọn kì í yẹ àdéhùn wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í jẹ́rìí èké . . . Wọn kì í ṣe ẹ̀ya ìsìn àràmàǹdà kan, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ olùpa òfin ìlú mọ́.” Ó fi kún un pé: “[Wọ́n] lọ́wọ̀ lára, ènìyàn aláyọ̀ ni wọ́n, wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ nípa ìtàn, lítíréṣọ̀, iṣẹ́ ọnà, àti ìgbésí ayé pẹ̀lú gbogbo apá ìhà tó ní.” Lẹ́yìn tó ti sọ àwọn ìyípadà tó ṣàǹfààní tí àwọn Ẹlẹ́rìí ti mú wá nídìí iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n náà sọ pé: “Táa bá ní láti tún àwọn ọ̀rọ̀ Voltaire sọ, a lè sọ pé, ká ní kò sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, yóò ṣe wá láǹfààní bí a bá lè ṣẹ̀dá wọn.”
Ṣé Oge Àṣerégèé Kọ́ Lèyí?
Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé, àwọn bàtà àpólà, “tó jẹ́ ohun kòṣeémáàní fún àwọn ọ̀dọ́ tó bìkítà nípa oge,” àtàwọn bàtà gogoro ló ń fa nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá jàǹbá tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́dún kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Steve Tyler, tó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún Àjọ Tó Ń Gbé Ìlànà Kalẹ̀ ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Jàǹbá tó ṣì wọ́pọ̀ jù ni ti àwọn ọrùn ẹsẹ̀ tó rọ́ àti ẹsẹ̀ tó kán, ṣùgbọ́n àwọn bàtà wọ̀nyí tún lè fa ìṣòro ẹ̀yìn, pàápàá jù lọ fún àwọn ọmọdébìnrin tí ìyípadà ṣì ń ṣẹlẹ̀ ní ara wọn.” Lẹ́nu oṣù àìpẹ́ yìí, bàtà àpólà táwọn obìnrin méjì kan wọ̀ ló pa wọ́n ní Japan. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan, bàtà àpólà tó ga ní sẹ̀ǹtímítà méjìlá tí òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi kan, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, wọ̀, gbé e ṣubú, ló bá la orí mọ́lẹ̀, orí náà fọ́, obìnrin náà sì kú. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan náà tún kú nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó wọ̀ lọ forí sọ òpó oníkannkéré kan nítorí pé ẹni tó wakọ̀ náà kò lè tẹ bíréèkì dáadáa nítorí bàtà àpólà tó wọ́, èyí tó ga ní sẹ̀ǹtímítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Kí wọ́n má baà máa pe àwọn tó ń ṣe bàtà lẹ́jọ́, àwọn kan lára wọ́n ti wá ń lẹ ìkìlọ̀ sára àwọn bàtà wọn.
Iṣẹ́ Ilé fún Àwọn Ọmọ
Ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé: “Lóde òní, àwọn òbí tọ́wọ́ wọn ń dí kì í bìkítà, tó bá di ọ̀rọ̀ káwọn ọmọ wọ́n ṣiṣẹ́ ilé.” Jane Nelsen tó kọ ìwé Positive Discipline sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ilé “kọ́ ló gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ,” síbẹ̀, irú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni bẹ́ẹ̀ “máa ń mú ìdára-ẹni-lójú àti iyì ara ẹni dàgbà.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí kan tó fara hàn nínú ìwé ìròyìn Child, àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan wà táwọn ọmọ ọdún méjì sí mẹ́ta lè ṣe, irú bíi pípalẹ̀ ohun ìṣiré mọ́ àti kíkó àwọn aṣọ tó dọ̀tí síbi tí wọ́n á ti fọ̀ wọ́n. Àwọn ọmọ tó wà láàárín ọdún mẹ́ta sí márùn-ún lè palẹ̀ oúnjẹ mọ́, kí wọ́n kó àwọn àwo lọ síbi tí wọ́n ti ń fọ̀ wọ́n, wọ́n sì tún lè tún ibi ìṣeré wọn ṣe kó wà ní mímọ́ tónítóní. Àwọn tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí mẹ́sàn-án lè tẹ́ ibùsùn wọn, wọ́n lè gbálẹ̀, wọ́n sì lè tu koríko, nígbà tí àwọn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án sí méjìlá lè ṣe àwọn iṣẹ́ ilé bíi fífọ abọ́, dída ilẹ̀ nù, ṣíṣánko tó hù láyìíká ilé, àti gbígbálẹ̀. Nelsen fi kún un pé “wọ́n á túbọ̀ ṣe dáadáa sí i táa bá fún wọn ní àkókò kan pàtó tí wọn gbọ́dọ̀ parí iṣẹ́ wọn.”
Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Hùwà Ọ̀daràn
Ìwádìí kan tí Ẹ̀ka Ìjọba Scotland ṣe fi hàn pé ní Scotland, ìpín márùndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdékùnrin àti ìpín mẹ́tàdínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdébìnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìnlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n sọ pé àwọn hùwà ọ̀daràn kan láàárín ọdún tó kọjá lọ. Ìwé ìròyìn The Herald ti Glasgow sọ pé nínú ẹgbẹ̀rún ọmọ tí wọ́n wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn láti ilé ẹ̀kọ́ mẹ́fà, ìpín méjìlá péré nínú wọn ló sọ pé àwọn ò dáràn kankan rí. Nínú àwọn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n jẹ́wọ́ rẹ̀, ìpín mọ́kàndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdékùnrin àti ìpín mẹ́rìndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdébìnrin ló ti ba ohun ìní àwọn èèyàn jẹ́. Nǹkan bí ìpín mẹ́rìndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdékùnrin àti ìpín mẹ́tàléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdébìnrin ti jí nǹkan lórí igbá àwọn èèyàn, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì tó ti jí nǹkan ní ilé ẹ̀kọ́. Àwọn ìwà ọ̀daràn míì tí wọ́n ti hù ni, dídáná sun ohun ìní àti lílo ohun ìjà láti fi ṣe jàǹbá. Àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín ọjọ́ orí yìí sọ pé ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ló sún àwọn dédìí ìwà ọ̀daràn táwọn hù, nígbà tó jẹ́ pé ní tàwọn tó ti lé ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ohun tó jọ pé ó fa tiwọn ní láti lè rí owó ra oògùn líle tó ti di bárakú fún wọn.
Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Tó Ya Bàsèjẹ́
Nínú ìṣẹ̀dálẹ̀ Japan, ekukáká ni wọ́n fi ń rí i kí àwọn ọ̀dọ́langba ní ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ níbẹ̀. Àmọ́ o, àwọn olùkọ́ jákèjádò Japan ti ń sọ nísinsìnyí pé ńṣe ló túbọ̀ ń ṣòro sí i láti mú kí nǹkan wà létòlétò nínú kíláàsì nítorí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tára wọn ò balẹ̀ àtàwọn tó ya bàsèjẹ́. Ìjọba tó ń ṣàkóso ìlú ńlá Tokyo béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti lé lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án, àwọn tó ti lé lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, àtàwọn tó ti lé lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá láti mọ èrò wọn nípa àwọn ẹlòmíràn. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn The Daily Yomiuri sọ, ìpín márùndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún wọn sọ pé inú àwọn ọ̀rẹ́ àwọn ń bí àwọn, ọ̀rọ̀ wọn sì ti sú àwọn, ìpín ọgọ́ta lára wọn ní ìṣòro kan náà pẹ̀lú àwọn òbí wọn, nígbà tí ìpín àádọ́ta lára wọn ní ìṣòro pẹ̀lú àwọn olùkọ́ wọn. Ìpín ogójì lára wọn sọ pé àwọn kì í lè fi bẹ́ẹ̀ kápá ìbínú àwọn tàbí pé àwọn ò ti ẹ̀ lè kápá ẹ̀ rárá. Ìkan nínú márùn-ún wọn sọ pé káwọn máa ba nǹkan jẹ́ ni ọ̀nà táwọn ń gbà fìbínú àwọn hàn.
“Àràmàǹdà Fáírọ́ọ̀sì”
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Àràmàǹdà fáírọ́ọ̀sì kan ti ń kó bá ìpèsè ẹ̀jẹ̀ jákèjádò àgbáyé o. Kò sẹ́ni tó mọ̀ bóyá fáírọ́ọ̀sì ‘TT’ yìí léwu, ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù wà pé ó lè fa àrùn ẹ̀dọ̀ki.” Fáírọ́ọ̀sì ọ̀hún, tí wọ́n sọ ní TT tó jẹ́ àwọn lẹ́tà tó bẹ̀rẹ̀ orúkọ ọmọ ilẹ̀ Japan tí wọ́n kọ́kọ́ rí i nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ní wọ́n tún ti rí nínú “ẹ̀jẹ̀ àwọn afẹ̀jẹ̀tọrẹ àti àwọn aláìsàn tó ní àrùn ẹ̀dọ̀ki tí wọ́n ń fa ẹ̀jẹ̀ sí lára.” Ká sòótọ́, ìwádìí ti fi hàn pé fáírọ́ọ̀sì ọ̀hún wà nínú ẹ̀jẹ̀ mẹ́jọ lára àwọn afẹ̀jẹ̀tọrẹ méjìlélọ́gọ́rùn-ún ní ìlú California tí àyẹ̀wò ti kọ́kọ́ fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ wọn ò ní fáírọ́ọ̀sì kankan nínú, títí kan ti HIV tàbí ti àrùn mẹ́dọ̀wú onípele kejì àti ẹ̀kẹta. Wọ́n fojú bù ú pé ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn tó ti ràn jẹ́ ìpín méjì nínú ọgọ́rùn-ún, ti ilẹ̀ Faransé jẹ́ ìpín mẹ́rin sí mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún, ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà jẹ́ ìpín mẹ́jọ sí mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún, ti Japan sì jẹ́ ìpín mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ìdàníyàn àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń ṣèwádìí fáírọ́ọ̀sì TT yíká ayé ni láti má ṣe fi dá ìpayà sílẹ̀,” ṣùgbọ́n wọ́n ń “wá ọ̀nà láti mọ̀ bóyá fáírọ́ọ̀sì náà lè ṣe jàǹbá èyíkéyìí fún ìlera èèyàn.”
Ìkọ́rùn Gbẹ̀mí Là
Àwọn àgbẹ̀ ẹlẹ́ran ọ̀sìn ní àwọn àgbègbè kan ní Gúúsù Áfíríkà bára wọn nípò tó lè mú wọn pàdánù nǹkan tó tó ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ táwọn ẹran ọ̀sìn wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ní sáà kọ̀ọ̀kan nítorí àwọn akátá. Kì í ṣe pé eléyìí kó wọn sí gbèsè ńlá nìkan ni o, ṣùgbọ́n ńṣe ló tún mú kí iye àwọn akátá máa pọ̀ sí i. Pàbó ni gbogbo ìgbìyànjú wọn láti mú àwọn akátá wọ̀nyí kúrò ń já sí, kódà, ńṣe nìyẹn tún fi ẹ̀mí àwọn ẹranko ìgbẹ́ míì wewu. Bó ti wù kó rí, wọ́n ti wá hùmọ̀ ojútùú kan tó gbéṣẹ́ gan-an láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, wọn sì ti lò ó. Ìyẹn ni ìkọ́rùn kan tí kò ń fi bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgùntàn lára, tó lè bá ọrùn wọn mu, tí wọ́n sì tún lè tún wọn lò, bẹ́ẹ̀ ni kò dí ìrìn àwọn àgùntàn náà lọ́wọ́, kò sì pa àwọn akátá ọ̀hún lára. Kò wulẹ̀ ní jẹ́ káwọn akátá ráyè bù wọ́n jẹ ni. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé ìròyìn Natal Witness, àwọn àgbẹ̀ tó ti ń lo àwọn ìkọ́rùn náà “ti sọ nípa bó ṣe yára fòpin sí pípa tí àwọn akátá ń pa àwọn ẹran náà.” Àti pé, ní báyìí tó ti wá di dandan fáwọn akátá ọ̀hún láti máa jẹ oúnjẹ àdánidá wọn tó jẹ́ kòkòrò, eku, àti òkú ẹran, iye wọn tí ń dín kù.
Àwọn Agbọ́n Tó Jẹ́ Gbẹ́gigbẹ́gi
Ìwé ìròyìn National Geographic sọ pé agbọ́n ichneumon ní ẹ̀yà ara kan tó fi ń yé ẹyin, tó jẹ́ pé “èròjà manganese tàbí zinc ló mú un le.” Agbọ́n náà ń lo irinṣẹ́ onímẹ́táàlì láti fi gbẹ́ ihò sára igi kó lè yé ẹyin sórí àwọn ìdin tó wà níbẹ̀ tàbí sára wọn. Donald Quicke láti Yunifásítì Ìjọba Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Díẹ̀ nínú wọn lè gbẹ́ ihò tó jìn tó sẹ̀ǹtímítà méje sára igi tó le koko.” Nígbà tí àwọn agbọ́n náà bá pamọ tán, ńṣe ni wọn máa ń jẹ àwọn ìdin táwọn náà ń gbẹ́ igi, lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá tún jẹ igi náà kí wọ́n lè ráyè jáde nípa lílo apá kan ẹnu wọn tó ti le nítorí àwọn ìdin tí wọ́n jẹ.
“Ìṣòro Fífarasin” ti Íńdíà
Ìwé ìròyìn The Times of India sọ pé: “Láìka ti ìlera tí a túbọ̀ mú sunwọ̀n sí i àti ipò tó túbọ̀ dára ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí sí, àìjẹunre kánú ṣì jẹ́ ‘ìṣòro fífarasin’ síbẹ̀ ní Íńdíà.” Àìjẹunre kánú ń ná Íńdíà ní iye tó ju òjìlérúgba ó dín mẹ́wàá [230] mílíọ̀nù dọ́là fún bíbójú tó ìlera àti àìlèṣiṣẹ́ tó pójú owó. Ní ìbámu pẹ̀lú ìròyìn náà, ó lé ní ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ Íńdíà tí kò tíì pé ọdún mẹ́rin tí wọn kì í jẹunre kánú, ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ni “kò tẹ̀wọ̀n tó bó ṣe yẹ,” àti ìpín ọgọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ni ẹ̀jẹ̀ kò tó lára wọn. Meera Chatterjee, tó jẹ́ ògbógi nínú iṣẹ́ ìdàgbàsókè àwùjọ ẹ̀dá ní Báńkì Àgbáyé sọ pé, “kì í ṣe pé àìjẹunre kánú ń ba ìgbésí ayé ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ti ìdílé jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ńṣe ló tún ń jẹ owó ìdókòwò lórí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ run, tó sì ń bẹ́gi dínà ìtẹ̀síwájú àwùjọ ẹ̀dá àti ètò ìnáwó.”
Ṣé Àwọn Àlùfáà Ò Láyọ̀?
Láàárín ọdún mẹ́fà tó kọjá, ẹ̀ẹ̀mẹta ni wọ́n ti ṣèwádìí láti mọ̀ nípa èrò táwọn èèyàn ní nípa àwọn àlùfáà láwùjọ ilẹ̀ Faransé. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú ìwé ìròyìn Kátólíìkì náà, La Croix, ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìpín márùndínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn ilẹ̀ Faransé ni kò fojú wo àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tó láyọ̀ tàbí tó nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Àwọn ènìyàn níbi gbogbo ṣì ka àwọn àlùfáà sí ẹni tára wọn yọ̀ mọ́ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n sì ń gbọ́ tàwọn èèyàn. Bó ti wù kó rí, ìwé ìròyìn náà sọ pé, “ńṣe ni iye àwọn ará Faransé tó kà wọ́n sí ẹni tó wúlò fún àwùjọ túbọ̀ ń dín kù” àti pé kìkì ìpín mẹ́rìndínlọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún péré ló rí wọn bí “ẹlẹ́rìí Ọlọ́run ní ayé.” Kò tó ọ̀kan nínú mẹ́ta gbogbo ará ìlú lápapọ̀ àti ìpín mọ́kànléláàádọ́ta péré nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo àwọn tó ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì déédéé tó máa rọ ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ẹbí wọn kan láti lọ wọṣẹ́ àlùfáà.