ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Ń Wu Léwu
  • Dídáàbòbo Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́ Àwọn Gbọ́mọgbọ́mọ
  • Àwọn Èrò Oníjàgídíjàgan
  • Dídá Abẹ́ fún Obìnrin Ń Bá A Lọ
  • Ìrànlọ́wọ́ Tí Ajá Ń Ṣe fún Àwọn Alárùn Wárápá
  • Ìṣarasíhùwà Tuntun ní Japan
  • Àṣà Ìwakọ̀ Líléwu
  • Oúnjẹ Sísè —Iṣẹ́ Tí Ń Kógbá Sílé Kẹ̀?
  • Àwọn Ilé Onígbì-Ìtànṣán-Olóró
  • Àwọn Ìhùmọ̀ Ọlọ́gbọ́n Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Gíga fún Gbígbógunti Olè
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?
    Jí!—2002
Jí!—1997
g97 10/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Ń Wu Léwu

Ní Germany, Mínísítà Ìjọba Àpapọ̀ fún Àbójútó Àyíká, Angela Merkel, sọ àníyàn rẹ̀ jáde ní gbangba nípa bí àwọn irú ọ̀wọ́ tí a ń wu léwu ní ilẹ̀ náà ti pọ̀ tó. Nígbà tí ó ń kéde ìgbéjáde ìwé kan tí ó dá lórí ọ̀rọ̀ àyíká, tí ilé iṣẹ́ náà ṣe, Merkel ka àwọn nọ́ńbà kan jáde tí ó dani láàmú. Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung sọ pé, àwọn ògbóǹkangí fojú díwọ̀n pé lára àwọn ẹ̀dá elégungun-lẹ́yìn tí ó jẹ́ ti ilẹ̀ Germany, “ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo ẹranko afọ́mọlọ́mú, ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ẹranko afàyàfà, ìpín 58 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn jomijòkè, ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ẹja inú omi tí kò níyọ̀, àti ìpín 39 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ẹyẹ ló jẹ́ irú ọ̀wọ́ tí a ń wu léwu.” Nǹkan kò dára fún àwọn irúgbìn pẹ̀lú, a ń wu ìpín 26 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo irú ọ̀wọ́ wọn léwu. Àwọn ìsapá tí a ti ṣe sẹ́yìn láti dín ewu tí ń kojú àyíká àdánidá kù kò tó. Merkel béèrè fún “ìlànà tuntun kan fún ìdáàbòbò ìṣẹ̀dá.”

Dídáàbòbo Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́ Àwọn Gbọ́mọgbọ́mọ

Àwọn òbí ní Germany ti wá ń dàníyàn gan-an nípa ààbò àwọn ọmọ wọn, ní pàtàkì nítorí jíjí àwọn ọmọdébìnrin gbé tí ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ ní orílẹ̀-èdè náà láìpẹ́ yìí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà, Nassauische Neue Presse, ti sọ, Julius Niebergall, olùtọ́jú kan tí ń bá Àjọ Ìdáàbòbò Àwọn Ọmọdé ní Germany ṣiṣẹ́, dámọ̀ràn àwọn ìgbésẹ̀ ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ kan. Fún àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè fi àwọn ibì kan lójú ọ̀nà ilé ẹ̀kọ́ han àwọn ọmọ wọn—ilé ìtajà tàbí ilé kan—tí wọ́n ti lè béèrè fún ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá ní ìṣòro. A tún gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọdé láti má ṣe bá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn àjèjì fọwọ́ kàn wọ́n. Niebergall tẹnu mọ́ ọn pé, “àwọn ọmọdé ní láti kọ́ pé a gbà wọ́n láyè láti sọ bẹ́ẹ̀ kọ́,” kódà fún àwọn àgbàlagbà. Ní pàtàkì, nígbà tí àwọn ọmọdé bá wà lábẹ́ ìhalẹ̀mọ́ni ẹnì kan tí ó lè wá gbé wọn lọ, ó yẹ kí wọ́n ké sí àwọn àgbàlagbà míràn. A lè kọ́ wọn láti sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ràn mí lọ́wọ́. Ẹ̀rù ọkùnrin yìí ń bà mí.”

Àwọn Èrò Oníjàgídíjàgan

Àwọn ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú akérò ròyìn pé àwọn èrò tí inú ń bí ń hu ìwà jàgídíjàgan púpọ̀ sí i. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, àwọn èrò tí inú ń bí nítorí àwọn nǹkan bí àìgbéra ọkọ̀ òfuurufú lákòókò àti ẹrù tó sọ nù máa “ń tutọ́ lu àwọn olùtọ́jú èrò ọkọ̀, wọ́n ń ju àtẹ oúnjẹ fìrí, wọ́n sì máa ń lu àwọn òṣìṣẹ́ nígbà míràn. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n tilẹ̀ máa ń gbéjà ko awakọ̀ òfuurufú.” Ní pàtàkì ni irú ìkọlù bẹ́ẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ọkọ̀ lójú òfuurufú ń mú àwọn òṣìṣẹ́ dààmú, nítorí èyí lè yọrí sí ìjàǹbá ọkọ̀ òfuurufú. Ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú akérò kan ròyìn nǹkan bí 100 ìṣẹ̀lẹ̀ èébú, tàbí ìluni lóṣooṣù. Ìwé agbéròyìnjáde Times sọ pé, “àwọn èrò tí ń fàjọ̀gbàn máa ń jẹ́ yálà obìnrin tàbí ọkùnrin, onírúurú àwọ̀, ọjọ́ orí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì tún máa ń fa wàhálà ní ìṣọ̀wọ́ èrò olówó pọ́ọ́kú, ti àwọn oníṣòwò tàbí ti olówó gọbọi. Nǹkan bí ẹnì kan lára mẹ́ta wọn ló ti ń mutí yó.”

Dídá Abẹ́ fún Obìnrin Ń Bá A Lọ

Gẹ́gẹ́ bí ìtẹ̀jáde náà, The Progress of Nations 1996, ìròyìn ọdọọdún kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé jáde, ti sọ, dídá abẹ́ fún àwọn obìnrin (FGM) ṣì ń jẹ́ ìṣòro ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ní pàtàkì ní ilẹ̀ Áfíríkà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan ti gbé òfin jáde lòdì sí àṣà òkú òǹrorò yìí, àwọn ọmọdébìnrin tí iye wọn tó mílíọ̀nù méjì ni a ń dá abẹ́ fún lọ́dọọdún. Àwọn òjìyà ìpalára náà sábà máa ń wà láàárín ọdún 4 sí 12. Ìròyìn náà sọ pé: “Yàtọ̀ sí ìbẹ̀rù ojú ẹsẹ̀ àti ìrora, àwọn ìyọrísí rẹ̀ lè ní ìṣẹ̀jẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, àkóràn, àìlébímọ, àti ikú nínú.” (Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa FGM, wo ìtẹ̀jáde Jí!, April 8, 1993, ojú ìwé 20 sí 23.)

Ìrànlọ́wọ́ Tí Ajá Ń Ṣe fún Àwọn Alárùn Wárápá

Ní England, wọ́n ti ń dá àwọn ajá lẹ́kọ̀ọ́ láti kìlọ̀ nípa àkókò tí wárápá yóò gbé ẹnì kan tí àrùn náà ń ṣe. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, èyí yóò jẹ́ kí aláìsàn náà ní àkókò tí ó tó láti múra sílẹ̀ fún ìkọlù náà. Alábòójútó àjọ ọlọ́rẹ àánú tí ó mọ̀ dáradára nípa kíkọ́ àwọn ajá láti bójú tó àwọn aláàbọ̀ ara ṣàlàyé pé: “Gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí fífún ajá náà ní ẹ̀bùn fún gbígbó nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ wárápá kan, ó ti mọ àwọn àmì ìkìlọ̀ àti àmì àrùn tí a máa ń rí lára aláìsàn náà sáájú kí ó tó gbé e. Ní mímọ̀ pé irú ìhùwàpadà bẹ́ẹ̀ yóò mú kí òun gba ẹ̀bùn kan, ajá náà wá ń tètè fiyè sí irú àwọn àmì ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́nà akọ.”

Ìṣarasíhùwà Tuntun ní Japan

Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Yomiuri sọ pé, láìpẹ́ yìí, Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Japan lo 1,000 ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Japan fún ìwádìí kan. Ìwádìí náà fi hàn pé ìpín 65.2 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò rí ohun tó burú nínú pípa kíláàsì jẹ. Nǹkan bí ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ni èrò wọn dọ́gba nípa àìgbọràn sí àwọn olùkọ́, ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wo ṣíṣàìgbọràn sí àwọn òbí gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò tó pọ́n. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Daily Yomiuri ti sọ, ìwádìí kan náà fi hàn pé ìpín 25.3 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọdébìnrin ronú pé ó yẹ kí ọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe aṣẹ́wó nígbà tí wọ́n ṣì wà ní ilé ẹ̀kọ́ jẹ́ ìpinnu àdáṣe.

Àṣà Ìwakọ̀ Líléwu

● Ìwé agbéròyìnjáde Gazeta do Povo ti Curitiba, Brazil, sọ pé: “Ọtí àmupara ló ń fa ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún lára ikú tí ìjàǹbá mọ́tò ń fà ní Brazil.” Àwọn awakọ̀ tí wọ́n ti mutí yó ń ṣokùnfà “ikú àwọn tí iye wọn lé ní 26,000 lọ́dọọdún.” Àwọn ìjàǹbá wọ̀nyí “sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń lọ sí ibi tí kò jìnnà, tí ojú ọjọ́ sì dára.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé awakọ̀ tó ti mutí yó lè nímọ̀lára dídá ara rẹ̀ lójú, agbára rẹ̀ láti tètè ṣe nǹkan ti dín kù, èyí sì ń tipa bẹ́ẹ̀ wu ààbò tirẹ̀ àti ti àwọn mìíràn lójú ọ̀nà léwu. Àwọn àyẹ̀wò fi hàn pé lábẹ́ ìdarí ọtí líle, ó ṣòro, kò tilẹ̀ ṣeé ṣe, láti yanjú ìṣòro tí a kò rò tẹ́lẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà ti sọ, mímú ọtí líle kúrò nínú ara nípasẹ̀ ètò ìyíkẹ́míkà-padà lè gbà tó wákàtí mẹ́fà sí mẹ́jọ, kọfí líle tàbí fífi omi tútù wẹ̀ kò sì lè ran awakọ̀ kan tó ti mutí yó lọ́wọ́ láti wakọ̀ láìséwu.

● Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Britain ti fi hàn, awakọ̀ kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ ń ṣe 50 àṣìṣe líléwu láàárín ọ̀sẹ̀ kan. Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé, lápapọ̀, àwọn 300 awakọ̀ tí a lò fún ìwádìí náà jẹ́wọ́ pé, ó kéré tán, àwọn ti ṣe ohun tí ó fi ìwà àìbìkítà hàn lẹ́ẹ̀kan nínú ìpín 98 nínú ọgọ́rùn-ún lára ìrìn àjò kọ̀ọ̀kan tí àwọn ti rìn. Nínú ọ̀kan lára ìrìn àjò 2, wọ́n nírìírí ìmọ̀lára ìbínú. Ewu tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn awakọ̀ máa ń dán wò ni eré sísá, ìdajì lára wọn sì sọ pé àwọn ti ní ìjàǹbá kan. Ìwádìí tí wọ́n ṣe ní Toronto, Kánádà, fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn awakọ̀ tí ń lo tẹlifóònù inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ nígbà tí wọ́n ń wakọ̀ lọ́wọ́ ní ìjàǹbá ìlọ́po mẹ́rin. Ewu náà máa ń pọ̀ jù lọ láàárín ìṣẹ́jú mẹ́wàá àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí ìtẹniláago kan bá bẹ̀rẹ̀, bóyá nítorí pé ọkàn awakọ̀ náà ti pínyà tí àkókò tí ó fi ń fèsì sì falẹ̀ díẹ̀.

Oúnjẹ Sísè —Iṣẹ́ Tí Ń Kógbá Sílé Kẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí olóṣù 12 kan nípa àṣà ìjẹun ní ìpínlẹ̀ Queensland, ní Australia, ti fi hàn, oúnjẹ sísè lè di iṣẹ́ tí a kò ṣe mọ́. Ìwé agbéròyìnjáde The Courier Mail sọ pé, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn tí wọn kò tí ì pé ẹni ọdún 25 kò ní ìmọ̀ tí ó pọn dandan fún síse oúnjẹ tiwọn fúnra wọn. Olùkọ́ nínú ìmọ̀ ìlera ará ìlú náà, Margaret Wingett, tí ó ṣe ìwádìí náà, sọ pé, tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀dọ́—ní pàtàkì àwọn ọmọdébìnrin—máa ń kọ́ bí a ṣe ń se oúnjẹ bóyá ní ilé lọ́dọ̀ àwọn ìyá wọn tàbí ní ilé ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n ní báyìí, ó jọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́, títí kan àwọn ọmọdébìnrin, ni kò mọ oúnjẹ í sè, kò sì jọ pé wọ́n fẹ́ láti kọ́ ọ. Púpọ̀ wọn fẹ́ràn àwọn oúnjẹ tí a dì tàbí oúnjẹ rírọrùn láti sáré sè jù. Àwọn kan gbà gbọ́ pé irú àṣà oúnjẹ jíjẹ bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí kí àrùn ẹ̀jẹ̀ ríru, àtọ̀gbẹ, àti àrùn ọkàn àyà pọ̀ sí i.

Àwọn Ilé Onígbì-Ìtànṣán-Olóró

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Asiaweek ti sọ, ìgbì ìtànṣán olóró ti sọ “105 ilé tí ó ní iyàrá gbéetán 1,249 di èyí tó lábùkù” ní ìhà àríwá Taiwan. Òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ mànàmánà kan tó ń fi bí ẹ̀rọ atọpa ìtànṣán olóró ṣe ń ṣiṣẹ́ han ọmọkùnrin rẹ̀ ló rí èyí. Nígbà tí ó ń ka àkọsílẹ̀ ara ẹ̀rọ iyàrá ìgbọ́únjẹ wọn, ẹnu yà á láti rí i tí atọ́ka ẹ̀rọ náà yí lọ sí ìhà ibi tí ń kìlọ̀ ewu. Wọ́n ṣe ìwádìí síwájú sí i, tí ń fi dáni lójú pé ilé náà àti àwọn mìíràn ti lábùkù. Àwọn àyẹ̀wò fi hàn pé ìtànṣán olóró náà ń wá láti ara àwọn irin tí wọ́n fi fún ìgbéró àwọn ògiri ilé náà lágbára. Èrò àwọn aláṣẹ kò ṣọ̀kan nípa bí ìgbì ìtànṣán olóró náà ṣe dé inú àwọn irin náà.

Àwọn Ìhùmọ̀ Ọlọ́gbọ́n Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Gíga fún Gbígbógunti Olè

Wọ́n ti lo àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi àmì tóótòòtó tẹ̀, tí àwọn amí fọwọ́ sí fún fífi àwọn ìsọfúnni aláṣìírí ránṣẹ́ nígbà kan, láti fi ṣèdíwọ́ fún àwọn fọ́léfọ́lé ní ilẹ̀ Britain. Àwọn àmì tóótòòtó náà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò tóbi ju àmì ìdánudúró kan lọ, ní nọ́ńbà àgbègbè ìfìwéránṣẹ́ tí ilé kan wà nínú ní ìgbà 60 tàbí 70, wọ́n sì ń lò wọ́n láti sàmì sí àwọn ohun ìní tí ó lè fa àwọn olè wá. Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé àwọn àmì tóótòòtó náà ń “bá ohun ìlẹǹkan lílágbára kan tí ó wà nínú ìgò pẹ̀lú búrọ́ọ̀ṣì kan, tí ó jọ ìgò àpòpọ̀ olómi tí wọ́n fi ń ṣí ọ̀dà èékánná, wá. Ọ̀rọ̀ alámì tóótòòtó tó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tó 1,000, ẹni tó rà á sì lè fìṣọ́ra kán an sára ohun ìní rẹ̀ tàbí kí ó fi kùn ún bí ó bá ṣe fẹ́.” Lébẹ̀ẹ̀lì kan tí ó hàn kedere ń kìlọ̀ fún ẹni tó fẹ́ jalè náà, kò sì lè ní ìdánilójú pé òun ti ṣí gbogbo àwọn àmì tóótòòtó tí ó fara sin náà tán. Bákan náà, ìhùmọ̀ pẹlẹbẹ inú kọ̀ǹpútà kan, tí a ṣe láti fi mọ àwọn tí ọkọ̀ òfuurufú ológun pa nígbà Ogun Vietnam, ti wá ń dá iṣẹ́ ọnà tí a kùn, àwọn iṣẹ́ ọnà gbígbẹ́, tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ilé mọ̀. Tí a bá ki ìhùmọ̀ pẹlẹbẹ inú kọ̀ǹpútà tí kò tóbi ju hóró ìrẹsì lọ náà bọ̀ ọ́, yóò di àwátì, ó sì ń ní àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ẹni tó ni ín, àpèjúwe, àti orúkọ ẹni tí ó ni ín, tí ẹ̀rọ aṣẹ̀dà àwòrán kan lè kà. Ìwé ìròyìn The Times sọ pé, ìsọfúnni yìí lè ṣèrànwọ́ láti fi ẹni tí ó ni àwọn ohun kan tí a rí lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn hàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́