ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 1/15 ojú ìwé 7
  • Bawo Ni Iwọ Ṣe Mọ Bibeli Daradara To?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bawo Ni Iwọ Ṣe Mọ Bibeli Daradara To?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwé Tí Ọ̀pọ̀ Jù Lọ Àwọn Ọ̀dọ́ Kò Nífẹ̀ẹ́ Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 1/15 ojú ìwé 7

Bawo Ni Iwọ Ṣe Mọ Bibeli Daradara To?

‘Iwe Tomasi? Dajudaju, iyẹn wa ninu Bibeli. Ṣugbọn iwe Jona ko si nibẹ. Ibi ti a ti bí Kristi nkọ? Óò, Jerusalẹmu niyẹn—abi Nasarẹti ni? Emi ko mọ daju niti gidi boya iwe Aisaya wa ninu apa akọkọ Bibeli tabi ekeji. Iye awọn apọsteli nkọ? Emi ko mọ niti gidi.’

“AWỌN ìwádìíwò wọnyi le ti ṣàìwá gẹgẹ bi iyalẹnu bi a ba ti ko isọfunni naa jọ kiki laaarin awọn ti kii ṣe Kristian,” ni iwe-irohin naa Christianity Today wi. “Oun ti o nyanilẹnu—ti o si ndaniláàmú—ni iye aimọkan nipa Iwe Mimọ ti a ri laaarin awọn Kristian atunbi.”

Fun apẹẹrẹ, ipin 18 ninu ọgọrun-un awọn Kristian ajorukọ-lasan ti a wádìí ero wọn ronu pe iwe Tomasi kan wà ninu Bibeli nitootọ nigbati ipin 13 ninu ọgọrun-un ko ni idaniloju. Niti Jona, ipin 27 ninu ọgọrun-un wipe ko si ninu Bibeli, ipin 12 ninu ọgọrun-un ko si loye kankan. Ipin 6 ninu ọgọrun-un ko tilẹ le méfò ibi ti a ti bi Jesu, nigbati ipin 16 ninu ọgọrun-un darukọ Jerusalẹmu, ti ipin 8 ninu ọgọrun-un si wipe Nasarẹti ni. Aropọ ipin 13 ninu ọgọrun-un ko loye ibi ti a ti le ri iwe Aisaya ninu Bibeli, nigbati ipin 11 ninu ọgọrun-un sọ pe o wa ninu Iwe Mimọ lede Giriiki (“Majẹmu Titun”). Nigbati o si jẹ pe ọpọjulọ mọ pe awọn apọsteli 12 ni wọn wa, ipin 12 ninu ọgọrun-un funni ni iye miiran lati 2 si iye ti o ju ogun lọ, ti ipin 10 ninu ọgọrun-un ko si loye kankan rara.

Ibeere naa ti o funni ni wahala julọ ni boya gbolohun-ọrọ naa “Awọn wọnni ti wọn nran ara wọn lọwọ ni Ọlọrun ńràn lọwọ” wa ninu Bibeli tabi bẹẹkọ. Kiki ipin 38 ninu ọgọrun-un awọn Kristian ti a wadii nipa wọn ni wọn mọ pe a ko le rii nibi kankan ninu Bibeli, nigbati iye ti o pọju, ipin 42 ninu ọgọrun-un ronu rẹ sí ọrọ ti a fayọ lati inu Bibeli. Awọn ti wọn ṣẹku kò mọ.

“Eeṣe ti àìmọ̀kan ti o pọ tobẹẹ fi wa nipa Bibeli?” ni Christianity Today beere. “O ṣeeṣe julọ, ki o wa lati inu aisi ọpọ awọn ti nka Bibeli. Ilaji ninu gbogbo awọn ara America kii ka Bibeli. Iye ti o pọju ninu gbogbo awọn Kristian atunbi nka Bibeli lẹẹkan tabi lẹẹmeji lọsẹ tabi ṣai ka rara. Abajọ ti ọpọlọpọ Kristian fi mọ ohun ti o kere tobẹẹ nipa Iwe Mimọ!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́