ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/22 ojú ìwé 11-15
  • Ọlọrun Jẹ́ Kí A Rí Òun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun Jẹ́ Kí A Rí Òun
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Kìlọ̀ fún Wa Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa
  • A Pàdé Ọ̀kan Lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa
  • A Yó Nípa Tẹ̀mí
  • A Tẹ̀ Síwájú sí Ìdàgbàdénú Tẹ̀mí
  • Bí Steve Ṣe Di Èrò Moscow
  • Moscow—Ìlú Ńlá Tí Ń Wà Nìṣó
    Jí!—1997
  • Ilé Ẹjọ́ Dá Àwọn Èèyàn Jèhófà Láre!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Jí!—1996
g96 3/22 ojú ìwé 11-15

Ọlọrun Jẹ́ Kí A Rí Òun

NÍGBÀ tí Ọba Dafidi ṣe tán láti gbé ìṣàkóso kalẹ̀ fún ọmọ rẹ̀, Solomoni, ó fún un ní ìtọ́ni yìí: “Mọ Ọlọrun baba rẹ, kí o sì fi àyà pípé àti fífẹ́ ọkàn sìn ín: nítorí Oluwa a máa wá gbogbo àyà, ó sì mọ gbogbo ète ìrònú: bí ìwọ́ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀, ìwọ óò rí i; ṣùgbọ́n bí ìwọ́ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀ òun óò ta ọ́ nù títí láé.”—1 Kronika 28:9.

Òtítọ́ gan-an ni èyí jẹ́ nínú ọ̀ràn tiwa. A wá Ọlọrun, a sì rí i—àmọ́ ìyẹ́n jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti darí wa gba ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀nà èké. A gbà gbọ́ pé Jehofa fi òye mọ bí ìtẹ̀sí ìrònú wa ṣe fi tagbára tagbára kórí jọ sọ́dọ̀ òun àti iṣẹ́ ìsìn òun tó, ó sì jẹ́ kí a rí òun. Bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ nìyí.

Ọmọọ̀yá mẹ́rin, tí wọ́n tọ́ dàgbà ní Florida, U.S.A., ni wá. Bàbá wa ń ṣiṣẹ́ fún àkókò gígùn gẹ́gẹ́ bí agbọ́únjẹ láti gbọ́ bùkátà ìdílé, ìyá ni olùtọ́jú ilé, àwa ọmọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ń ṣiṣẹ́ gígé koríko, kíkó ìwé ìròyìn lọ fún àwọn ènìyàn—gbogbo ohun tí ó bá lè pa kún owó tí ń wọlé fún ìdílé. Ìyá jẹ́ onísìn Kátólíìkì, Bàbá sì jẹ́ onísìn ìjọ Onítẹ̀bọmi. Gbogbo wa ni a gbà gbọ́ nínú Ọlọrun àti nínú Bibeli, àmọ́ a kò ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀, a kì í sì í lọ sí ṣọ́ọ̀sì déédéé. Ní àwọn ọdún 1970 ni, nígbà tí àlàáfíà, ṣòkòtò ẹlẹ́nu kẹ̀m̀bẹ̀, irun gígùn, àti orin rọ́ọ̀kì ṣì gbòde kan. Gbogbo ìwọ̀nyí ló nípa lórí ìgbésí ayé wa.

Àfi ìgbà tí ó di ọdún 1982 ni àwa méjèèjì, Scott àti Steve—tí ẹni àkọ́kọ́ jẹ́ ọmọ ọdún 24, tí ẹnì kejì sì jẹ́ ọmọ ọdún 17—tó ní ìfẹ́ ọkàn tí ó gbóná nínú Bibeli, tí a sì mú ìdàníyàn tí ń pọ̀ sí i dàgbà nínú ipò ayé tí ń bàjẹ́ sí i. Scott ní iṣẹ́ ilé kíkọ́ tirẹ̀ lọ́wọ́. Nǹkan ń lọ déédéé fún un, nítorí náà, a jọ kó pa pọ̀ sínú ilé kan náà. Ìgbésí ayé ilé ọtí àti àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó jẹ mọ́ ọn ti sú wa, a sì mọ̀ pé ìgbésí ayé tí ó sàn kan gbọ́dọ̀ wà níbì kan. Ebi nǹkan tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ sí í pa wá. Kíkà tí à ń ka Bibeli wa déédéé ti ràn wá lọ́wọ́ láti fẹ́ ìmọ̀ àti òye tí ó pọ̀ sí i nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

A bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì ní ọjọ́ Sunday. Níbi àwọn kan tí a máa ń lọ nítòsí ilé wa ní Lake Worth, Florida, ìṣẹ́jú 25 tí wọ́n fi ń sọ ìwàásù lọ́jọ́ Sunday máa ń jẹ́ nípa ṣiṣètọrẹ owó. Bi ajíhìnrere náà bá ti tẹ̀ sórí àpótí ìbánisọ̀rọ̀ báyìí, yóò sọ pé: “Ẹ fi gbogbo ohun tí ẹ bá ni tọrẹ, ẹ tú gbogbo àpò yín yẹ́ríyẹ́rí.” Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń gbé igbá owó ní ẹ̀ẹ̀mẹta nígbà ìpàdé kan ṣoṣo, èyí ló sì máa ń fà á tí àwọn kan fi máa ń kúrò níbẹ̀ lẹ́yìn tí gbogbo àpò wọn bá ti gbẹ. Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ni a lọ, ṣùgbọ́n ohun tí à ń rí kò ju igbá owó tí wọ́n ń gbé káàkiri àti ìkẹ́gbẹ́jọ lọ.

Wọ́n Kìlọ̀ fún Wa Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa

Àwọn ohun tí a rò pé wọ́n jẹ́ ẹ̀kọ́ inú Bibeli ti wọ̀ wá lára, a sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n nítorí pé àwọn tí wọ́n kọ́ wa jẹ́ amọṣẹ́dunjú ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ wa ni nípa àwọn ẹgbẹ́ awo tí ó wà ní America, àwọn tí a sì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lé lórí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Wọ́n kìlọ̀ fún wa pé wọn kò gbà gbọ́ nínú Jesu, pé wọ́n ní Bibeli tiwọn, pé wọn kò ní lọ sọ́run, àti pé wọ́n gbà gbọ́ pé kò sí ọ̀run àpáàdì rárá. Gbogbo èyí dájúdájú ló mú kí a dé orí èrò náà pé àwọn Ẹlẹ́rìí kò tọ̀nà.

Ní gbogbo ìgbà yìí, a ní ìtara gbígbóná janjan, àmọ́ kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye. (Romu 10:2) A mọ ohun tí Jesu sọ nínú Matteu 28:19, 20—a gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere náà, kí a sì sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Nígbà yẹn, à ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kan, tí ó ní 2,000 mẹ́ḿbà, tí wọ́n ń pè ní Bible Town, níbi tí a ti jẹ́ ara àwùjọ àwọn èwe tí ó tó 100, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọmọ ọdún 17 sí 30. Scott gbìyànjú láti mú kí wọ́n máa wàásù lọ́nà kan tàbí òmíràn—àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí.

Nítorí náà, a bẹ̀rẹ̀ ìpolongo ìwàásù tiwa. Scott mú èrò náà wá pé kí a kan káńtà kan ní ibi ọjà bọ́síkọ̀rọ̀ kan tí ó wà ní àdúgbò, kí a sì máa fún àwọn ènìyàn ní àwọn ìwé kéékèèké àti Bibeli. Nítorí náà, ohun tí a ṣe nìyẹn. A lọ sí ilé tí wọ́n ti ń ta àwọn ìwé “Kristian” kan, a sì ra ọ̀pọ̀ yanturu ìwé kéékèèké àti Bibeli, a lọ sí ibi ọjà bọ́síkọ̀rọ̀ kan, a kan férémù kan, a sì gbé ẹ̀là fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan ka orí rẹ̀, a kó àwọn ìwé kéékèèké àti Bibeli wa sí orí rẹ̀, a sì gbìyànjú láti di “olùṣe ọ̀rọ̀ naa, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan.”—Jakọbu 1:22.

Bí ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ti ń kọjá lọ, iṣẹ́ òjíṣẹ́ pẹ́kúpẹ́kú ibi ọjà bọ́síkọ̀rọ̀ náà di ńlá, a sì ń fún àwọn ènìyàn ní àwọn ìwé lédè ìkẹ́kọ̀ọ́ Gẹ̀ẹ́sì àti Spanish. Bákan náà, a ní àwọn Bibeli, oríṣi 30 ìwé kéékèèké, àti àwọn nǹkan ìlẹ̀máṣọ tí wọ́n kọ “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ rẹ” sí. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, Scott ra ẹ̀rọ aṣàdàkọ kan tí a lè máa fi tẹ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bibeli kéékèèké sórí àwọn ẹ̀wù alápá péńpé—irú àwọn tí ó kà pé: “Ìwọ́ ha ti ka Bibeli rẹ lónìí bí?,” “Ìwọ́ ha ń ṣe kàyéfì ìdí tí mo fi ń rẹ́rìn-ín bí? Jesu wà nínú ọkàn mi ni,” àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn mìíràn. Ọ̀kan sọ pé “Ìṣípayá” ó sì ní àwòrán àwọn ẹlẹ́sin mẹ́rin.

A rò pé bí a bá ń wọ àwọn ẹ̀wù náà lọ síbi gbogbo, ńṣe ni a ń wàásù fún àwọn ènìyàn láìsọ̀rọ̀. Ní gbogbo ọjọ́ Saturday àti Sunday, láti agogo mẹ́jọ òwúrọ̀ sí agogo kan ọ̀sán, ènìyàn lè rí i pé a ti ṣí ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọjà bọ́síkọ̀rọ̀ wa. Bí o bá ń gba ibi tí wọ́n ń gbé àwọn ọkọ̀ sí kọjá, tí ó sì rí àwọn ìwé kéékèèké lára àwọn ọkọ̀—iṣẹ́ wa nìyẹn. Owó tí àwọn ènìyàn fi ń tọrẹ ni a fi ń ra ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tí wọ́n fi ń tọrẹ kò tó nǹkan. Lọ́dún kan, a ṣírò gbogbo owó tí a ná, ó sì lé ní 10,000 dọ́là.

A Pàdé Ọ̀kan Lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa

Lọ́jọ́ kan, nígbà tí à ń lúwẹ̀ẹ́ ní ọ̀kan lára àwọn etíkun tí ó wà ní Bonita Springs, ọkùnrin kan tí ó dàgbà jù wá tọ̀ wá wá, ó sì sọ̀rọ̀ pé òun rí àwọn ọ̀rọ̀ tí a lẹ̀ mọ́ ara ọkọ̀ wa, àti pé òún ṣàkíyèsí ẹ̀wù alápá péńpé wa. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa Bibeli, ó ń fi òye sọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́. Ó fa kókó tí ó wà nínú Ìṣe 2:31 jáde, nípa bíbèèrè pé: “Bí ọ̀run àpáàdì oníná kan bá wà, tí ó sì jẹ́ pé kìkì àwọn ènìyàn búburú ní ń lọ síbẹ̀, nígbà náà èé ṣe tí Bibeli yóò fi wá sọ pé Jesu lọ síbẹ̀?” Ó ń bá ọ̀rọ̀ náà lọ, ó sì ń ṣàlàyé ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ mìíràn. Nígbà tí ó yá, Scott sọ pé: “Ó ní láti jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ọ́.” Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀kan lára wọn ni mí.” Nígbà náà ni Scott sọ pé: “Ẹyin tí ẹ kò gbà gbọ́ nínú Jesu.” Fún gbogbo 20 ìṣẹ́jú tí ó tẹ̀ lé e, Ẹlẹ́rìí náà ń sọ̀rọ̀ nípa Jesu, àmọ́, lọ́nà kan ṣáá, kò wọ̀ wá létí.

À ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ ibi ọjà bọ́síkọ̀rọ̀ lọ ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀. A ti ń ṣe èyí fún ọdún mẹ́ta—a sì gbà gbọ́ ní gbogbo ìgbà náà pé a ti rí òtítọ́ àti pé ohun tí ó tọ́ ni à ń ṣe. A sì ń bẹ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wò, èyí tí a bá bẹ̀ wò ní alẹ́ Sunday yìí kọ́ ni a óò bẹ̀ wò ní èyí tí ń bọ̀, kò sì sí èyí tí ó tẹ́ wa lọ́rùn nínú gbogbo àwọn tí a lọ. Gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì ni a fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ̀ wò tán, nítorí náà, ní alẹ́ ọjọ́ kan, a pinnu láti lọ sí ọ̀kan lára “ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa,” gẹ́gẹ́ bí a ti pè é. A fẹ́ láti wàásù fún wọn nípa Jesu. A rí àdírẹ́sì wọn nínú ìwé tẹlifóònù, a sì lọ síbẹ̀ ní alẹ́ Sunday kan. Nígbà tí a gbọ́ pé wọn kì í pàdé ní alẹ́ Sunday bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yòókù ṣe ń ṣe, a parí èrò pé òtítọ́ ni pé wọn kò gbà gbọ́ nínú Jesu. A rí i lójú pátákó tí ń fi ìgbà tí wọ́n máa ń ṣe ìpàdé hàn pé alẹ́ Monday ni wọ́n máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé wọn. Nítorí náà, a padà wá pẹ̀lú Bibeli wa lọ́wọ́, a sì wọ ẹ̀wù alápá péńpé wa. A rántí pé ó gbà wá ní ìṣẹ́jú díẹ̀ láti pinnu èyí tí a óò wọ̀ lára àwọn ẹ̀wù alápá péńpé wa—èyí tí yóò fún wọn ní ẹ̀rí tí ó dára. A tètè débẹ̀, àwọn arákùnrin bíi mélòó kan sì tọ̀ wá wá. Ara wọ́n yá mọ́ni, wọ́n sì kó ènìyàn mọ́ra. Kíákíá ni a ti wọnú ìjíròrò tí ó jinlẹ̀ nípa Ìṣípayá. Wọ́n sọ pé kí a dúró fún ìpàdé náà. Wọ́n fún wa ní ìwé Isopọṣọkan ninu Ijọsin, ni a bá jókòó.a Arákùnrin kan bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pẹ̀lú àdúrà.

A tẹ́tí sílẹ̀ kínníkínní. Ní ìparí rẹ̀, ó sọ pé: “Ní orúkọ Jesu. Àmín.” À ń wo ara wa tìyanutìyanu. “Ǹjẹ́ a gbọ́ ohun tí ó sọ dáradára? Ó gbàdúrà ní orúkọ Jesu!” Nígbà yẹn, ńṣe ni ó dà bí ẹni pé ìpẹ́pẹ́ kan já bọ́ lójú wa. Bí ọkàn wa bá dára, ìgbà tí ó yẹ kí á tẹ́tí sílẹ̀ nìyí. Arákùnrin náà sọ fún gbogbo wọn láti ṣí ìwé Isopọṣọkan ninu Ijọsin sí orí 21, tí ó sọ̀rọ̀ nípa Jesu àti ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé. Kò tún sí ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tí a lè pésẹ̀ sí tí ó ju èyí lọ. Ó jẹ́ nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jesu, àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àti àìdásí tọ̀tún-tòsì. A gbọ́ tí àwọn ọmọ kéékèèké ń dáhùn ọ̀pọ̀ àwọn kókó tí a kò mọ̀ rárá. Yàtọ̀ sí ìyẹn, láti parí ìpàdé náà, arákùnrin náà gbàdúrà lórúkọ Jesu!

A Yó Nípa Tẹ̀mí

Nígbà tí a wọnú gbọ̀ngàn náà, òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ wá, ibẹ̀ ló sì wà, kò jìnnà rárá. A kúrò níbẹ̀ lẹ́yìn tí a ti yó nípa tẹ̀mí, a kò sì tẹ ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ láti ìgbà yẹn. Ní alẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, nígbà tí a ń fọ aṣọ wa ní ilé ìfọṣọ àdáni kan, a rí òkìtì gègèrè Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀rọ ọṣẹ sódà—ó kéré tán, wọ́n tó 150. Ká sọ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ni, a kò ní kà wọ́n, àmọ́ nísinsìnyí, a dì wọ́n pọ̀, níwọ̀n bí a ti ní ìfẹ́ ọkàn nínú ọ̀pọ̀ kókó ẹ̀kọ́.

Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà bèèrè pé, “Ìwọ ha gbà gbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan?” Òmíràn ni, “Ọ̀run àpáàdì ha wà ní tòótọ́ bí?” Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ère wà nínú Jí! kan. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, Steve ka èyí tí ó sọ nípa Mẹ́talọ́kan, ó ṣe ìwádìí lọ́pọ̀lọpọ̀, ó yẹ gbogbo ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó wà nínú rẹ̀ wò, ó sì jí Scott ní agogo 12:30 ọ̀gànjọ́ òru, nítorí ohun tí ó ti kọ́. Ní ọjọ́ kejì, Wednesday, lẹ́yìn iṣẹ́, Steve ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run àpáàdì. Ó ṣàlàyé lórí Johannu 11:11, níbi tí Jesu ti sọ pé Lasaru ń sùn. Nígbà tí Steve rí Scott, ó sọ pé: “Bibeli mi kò kọ́ni pé ọ̀run àpáàdì oníná wà.” Lẹ́yìn tí a ti ka Jí! tí ó sọ̀rọ̀ nípa ère àti onírúurú àwọn àgbélébùú tí ó wà, a kó àwọn tiwa dànù sínú ọkọ̀ akódọ̀tí, a sì ń wò ó bí ó ti ń gbé wọn lọ. À wo ara wa, a mi orí wa, a sì bú sẹ́rìn-ín. A mọ̀ pé a ti rí ohun kan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀—òtítọ́.

Ọjọ́ kan lẹ́yìn náà, àpótí méjì dé. Àwọn 5,000 ìwé kéékèèké tí ó sọ pé bí ènìyàn kò bá ronú pìwàdà, ọ̀run àpáàdì ni yóò lọ wà nínú wọn. A mọ̀ nísinsìnyí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé kéékèèké wọ̀nyí kò tọ̀nà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bibeli. Nítorí pé ọkàn wa dàrú díẹ̀, a tún lọ sí ibi ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé wọn ní alẹ́ ọjọ́ Monday, a sì kó ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìwé kéékèèké wa lọ. A bèèrè pé, “Èyí ha dára bí?” Ní alẹ́ ọjọ́ kan, a ṣàyẹ̀wò gbogbo wọn pátápátá. Kò pẹ́ tí òkìtì àwọn ìwé kéékèèké fi ga nílẹ̀; kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bibeli. A kó gbogbo wọn dà nù. A mọ̀ pé ìgbàgbọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà túmọ̀ sí ìwàláàyè wa àti ìwàláàyè àwọn tí a wàásù fún. A fẹ́ láti kó lọ kí a lè kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli láìsí ìdíwọ́.

A kó lọ sí Alaska. Nígbà ìpàdé tí a kọ́kọ́ ṣe níbẹ̀, a bèèrè lọ́wọ́ alàgbà kan bí yóò bá máa kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wa lójoojúmọ́. Mo rò pé gbogbo àwùjọ ló gbọ́ wa. A ní ìtẹ̀síwájú tí ó dára, a parí ìwé Walaaye Titilae, a sì fẹ́ láti ṣe ìrìbọmi nígbà ọ̀kan lára àwọn àpéjọ ọlọ́jọ́ méjì.* Àmọ́, ó di dandan pé kí a dúró díẹ̀. Góńgó wa ni láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Láìrò tẹ́lẹ̀, àìsàn kọ lu bàbá wa, ó sì di dandan pé kí a darí sí Florida láti ràn án lọ́wọ́.

A Tẹ̀ Síwájú sí Ìdàgbàdénú Tẹ̀mí

A ní ìtẹ̀síwájú tí ó dára ní Florida, a parí ìwé Isopọṣọkan ninu Ijọsin, a sì ṣe ìrìbọmi ní ọdún 1987. Ó ti pé oṣù 11 tí a bẹ̀rẹ̀. Lójú ẹsẹ̀ ni a ti di aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù mẹ́fà, tí a sì di aṣáájú ọ̀nà déédéé lẹ́yìn náà. Ní kìkì nǹkan bí ọdún kan àbọ̀ lẹ́yìn tí a bẹ̀rẹ̀, wọ́n yan àwa méjèèjì gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ọdún méjì lẹ́yìn tí a ṣe ìrìbọmi, a rí ara wa tí à ń ṣiṣẹ́ sìn ní Beteli Brooklyn, níbi tí Scott ti ń sìn títí di òní, tí ó sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Chinese láti ọdún méjì wá. Steve ń sìn nísinsìnyí ní Moscow, Rọ́ṣíà, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Àwa méjèèjì rí i pé òtítọ́ àti wíwá a kiri rí gan-an gẹ́gẹ́ bí Owe 2:1-5 ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀: “Ọmọ mi, bí ìwọ́ bá fẹ́ gba ọ̀rọ̀ mi, kí ìwọ́ sì pa òfin mi mọ́ pẹ̀lú rẹ. Tí ìwọ́ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí ìwọ́ sì fi ọkàn sí òye; àní bí ìwọ́ bá ń ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ́ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye; bí ìwọ́ bá ṣàfẹ́ẹ́rí rẹ̀ bíi fàdákà, tí ìwọ́ sì ń wá a kiri bí ìṣúra tí a pa mọ́; nígbà náà ni ìwọ óò mọ ìbẹ̀rù Oluwa, ìwọ óò sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.”

Bí Steve Ṣe Di Èrò Moscow

Níwọ̀n bí mo ti ń gbé ní New York, níbi tí mímọ èdè míràn yóò ti mú kí iṣẹ́ wíwàásù gbádùn mọ́ni sí i—tí mo sì ń ronú pé bóyá Jehofa yóò ṣí ìlẹ̀kùn ilẹ̀ Rọ́ṣíà láìpẹ́—mo pinnu láti kọ́ èdè Rọ́ṣíà. Ní àkókò yẹn, nígbà tí mò ń sìn ní Beteli Brooklyn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ibi tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé èdè Rọ́ṣíà. Kìkì àwùjọ tí ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé lédèe Rọ́ṣíà tí wọ́n ń pàdé ní gbogbo ọjọ́ Friday nìkan ló wà. Bí àkókò ti ń lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìfẹ́ ọkàn tí ó pọ̀ sí i nínú àwùjọ tí ń sọ èdè Rọ́ṣíà náà. Mò ń dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù, èyí tí ó gbádùn mọ́ mi gan-an nítorí pé ara àwọn ara Rọ́ṣíà yá mọ́ni. Mo kọ̀wé sí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn pé kí wọ́n gbé mi lọ sí àwùjọ àwọn ará Rọ́ṣíà. Ó dùn mọ́ mi pé wọ́n gbà bẹ́ẹ̀.

Ní ọjọ́ kan nígbà tí à ń ṣe ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ lọ́wọ́ ní Beteli, alága Watch Tower Bible and Tract Society, Milton G. Henschel, sọ fún ìdílé pé ìròyìn ayọ̀ kan yóò wà. Lẹ́yìn náà ni ó kéde pé a ti forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa múlẹ̀ lábẹ́ òfin ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà, àti pé àwọn arákùnrin wa yóò máa gbádùn òmìnira ìjọsìn nísinsìnyí. N kò rò pé ẹnì kan wà ní Beteli ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn tí yóò gbàgbé ayọ̀ tí a ní nígbà tí a gbọ́ irú ìròyìn àgbàyanu bẹ́ẹ̀. Nígbà yẹn, mo ronú pé àǹfààní ńláǹlà ni yóò jẹ́ láti lè jẹ́ apá kan ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ bàǹtàbanta tuntun yẹn.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé sí arákùnrin ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan tí ń jẹ́ Volodeya, tí ń gbé ní Krasnodar, Rọ́ṣíà. Ó ké sí mi láti wá ṣèbẹ̀wò sí ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Nítorí náà, nígbà tí ó dí oṣù June, ọdún 1992, mo kó ẹrù mi, mo sì mórí lé ọ̀nà Moscow. Nígbà tí mo débẹ̀, inú mí dùn láti rí Arákùnrin Volodeya tí ń dúró dè mí ní ibùdókọ̀ òfuurufú. Mò ń gbé pẹ̀lú Arákùnrin Stephan Levinski—tí ó ti wà nínú òtítọ́ fún ọdún 45. Òun ní Ẹlẹ́rìí àkọ́kọ́ tí mo bá pàdé ní Moscow, ó sì ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìdúró rẹ̀ fún òtítọ́. Ìfẹ́ àlejò tí àwọn ará ní pẹtẹrí nítòótọ́ gan-an ni.

Bí mo ṣe dé Moscow nìyẹn, n kò sì mọ èdè náà púpọ̀. Ní àkókò yẹn, kìkì ìjọ mẹ́rin ló wà, ó sì dà bí ẹni pé gbogbo àwa arákùnrin ni a mọ ara wa. Láti ìgbà náà, yóò-jẹ-kò-jẹ ni mo ṣe tí mo fi tiraka láti mú kí àkókò ìwé àṣẹ gbígbé orílẹ̀-èdè náà mi gùn sí i. Ó ṣeé ṣe fún mi láti máa ṣiṣẹ́ lóòrèkóòrè láti fi máa gbọ́ bùkátà ara mi. Kìkì ìṣòro títóbi jù lọ tí mo ní ni kíkọ́ èdè Rọ́ṣíà tí ó pọ̀ tó láti fi bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, kí n sì jẹ oúnjẹ tẹ̀mí ní ìpàdé. Díẹ̀díẹ̀ ni, ó sì dájú pé títí tí ó fi di ìsinsìnyí ni mò ń ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀.

Mo ti ní àǹfààní láti lọ sí ọ̀pọ̀ àpéjọpọ̀, àti ṣíṣẹlẹ́rìí ìbísí àti ìrìbọmi ọ̀pọ̀ yanturu. Rírí ìtara mímúná àwọn arákùnrin wa níhìn-ín ti jẹ́ ìrírí tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun lọ́nà tí ó gadabú. N kò rí ohun tí mo lè fi rọ́pò rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí mo débá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, tàbí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi nígbà tí mo dé ni wọ́n ń sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí òṣìṣẹ́ Beteli ní Solnechnoye, nítòsí St. Petersburg, Rọ́ṣíà.

Òjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó dín mẹ́wàá ènìyàn ní ń rọ́ sínú gbọ̀ngàn ìjọ tí mo wà ní gbogbo ọjọ́ Sunday, ní oṣooṣù ni a sì ń ní ìpíndọ́gba akéde tuntun tí kò tí ì ṣèrìbọmi 12. Iye tí ó kẹ́yìn jẹ́ 380 akéde, alàgbà 3, àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ 7. Ìjọ wa ń ròyìn ohun tí ó lé ní ìkẹ́kọ̀ọ́ 486 Bibeli. Ní oṣù February, ọdún 1995, mo ní àǹfààní ṣíṣèbẹ̀wò sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ 29 tí a ní, láti sọ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìsìn. Mò ń bẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ mẹ́rin wò lọ́sẹ̀. Ọwọ́ wa tún máa ń dí gan-an ṣaájú àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan ní bíbójú tó ìbéèrè tí ó wà fún àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Ní oṣù May, ọdún 1995, a ṣe àpéjọ àkànṣe kan, níbi tí 30 ènìyàn ti ṣe ìrìbọmi ní ìjọ wa. Iye gbogbo àwọn tí ó ṣe ìrìbọmi jẹ́ 607, gbogbo àwọn tí wọ́n sì pésẹ̀ jẹ́ 10,000. Nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè tí a ṣe ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ẹni 24 láti ìjọ wa wà lára àwọn 877 tí ó ṣe ìrìbọmi! A ní aṣáájú ọ̀nà 13 àti aṣáájú ọ̀nà àkànṣe 3 ní ìjọ wa. Gbogbo wọn ń ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ 110! Ní báyìí, àwọn akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi tí a ní jẹ́ 132.

Nígbà Ìṣe Ìrántí ọdún 1995, àwọn tí ó pésẹ̀ jẹ́ 1,012! Society ṣẹ̀ṣẹ̀ rán arákùnrin ọmọ Poland kan, Mateysh, sí ìjọ wa. Ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, ìrànwọ́ ńláǹlà ni yóò sì jẹ́. A ní alàgbà mẹ́ta nísinsìnyí. Nítorí náà, a óò dá ìjọ mìíràn sílẹ̀, tí a óò sì pín ìpínlẹ̀ wa—tí àwọn ènìyàn rẹ̀ sún mọ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ kan—sí méjì láìpẹ́. Ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò ní akéde bíi 200. Ìjọ kan yóò ní alàgbà méjì, èkejì yóò sì ní alàgbà kan. Àpéjọ mìíràn ń bọ̀ lọ́nà, nítorí náà, a ń ṣàyẹ̀wò ìbéèrè pẹ̀lú àwọn 44 tí wọn yóò ti ṣe tán láti ṣe ìrìbọmi tí ó bá di ìgbà náà. Ó dà bí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́! Ó jẹ́ párádísè tẹ̀mí ní tòótọ́! Ó jẹ́ àgbàyanu! Ọwọ́ Jehofa ń bẹ lẹ́nu iṣẹ́ ní tòótọ́. Ó dà bí ẹni pé ọkọ̀ kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ń yára kánkán lọ bíi mànàmáná ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní àkókò yìí. Títí tí ó fi dí oṣù October, ọdún 1995, nǹkan bí 40 ìjọ ló wà ní Moscow. Ó lè di ìlọ́po méjì dáadáa kí a sọ pé àwọn alàgbà tí ó pọ̀ tó wà ni.

Ìgbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ ibi ọjà bọ́síkọ̀rọ̀ tí kọjá lọ tipẹ́tipẹ́. Scott wà ní Beteli Brooklyn, Steve sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ tí ó wà ní Moscow—àwa méjèèjì dúpẹ́ pé Ọlọrun jẹ́ kí a rí òun. Àdúrà wa ni pé kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ṣì wá a rí, àti pé kí Ọlọrun jẹ́ kí wọ́n rí òun.—Gẹ́gẹ́ bí Scott àti Steve Davis ṣe sọ ọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Scott

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Steve

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ohun tí ó lé ní 530 ènìyàn ní ń pésẹ̀ sí ìjọ Moscow kan ní gbogbo ọjọ́ Sunday

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́