ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/22 ojú ìwé 13-18
  • Moscow—Ìlú Ńlá Tí Ń Wà Nìṣó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Moscow—Ìlú Ńlá Tí Ń Wà Nìṣó
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Ń Wà Nìṣó ní Àwọn Ọdún Ìjímìjí
  • Fífarada Ipò Lílekoko Kan Tí Kò Lẹ́gbẹ́
  • Moscow Gbérí Láti Inú Àwókù
  • Wíwànìṣó àti Ìníláárí
  • Wọ́n fún Ìlú Ńlá Náà Ní Ìrísí Tuntun
  • Ilé Ẹjọ́ Dá Àwọn Èèyàn Jèhófà Láre!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • ‘Ayé Yìí Ì Bá Yàtọ̀’
    Jí!—2000
  • Àwọn Ilé Iṣẹ́ Agbéròyìnjáde Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Yin Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Jí!—1998
  • Ọlọrun Jẹ́ Kí A Rí Òun
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 12/22 ojú ìwé 13-18

Moscow—Ìlú Ńlá Tí Ń Wà Nìṣó

Àjọ̀dún Àádọ́talélẹ́gbẹ̀rin rẹ̀

“Ọ̀RẸ́, wá sọ́dọ̀ mi ní Moscow.” Ó jọ pé ìkésíni yìí tí Yury Dolgoruky nawọ́ rẹ̀ sí ọba ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan ní 1147 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a mẹ́nu kan Moscow nínú àkọsílẹ̀ ìtàn. A ti tẹ́wọ́ gba déètì ọjọ́ náà—850 ọdún sẹ́yìn—gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n tẹ Moscow, olú ìlú Rọ́ṣíà, dó, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀rí tí a walẹ̀ kàn fi hàn pé abúlé kan ti wà níbẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò náà.

Ní ìfojúsọ́nà fún àjọ̀dún àádọ́talélẹ́gbẹ̀rin Moscow, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ohun èlò ìlú ńlá náà ni wọ́n tún ṣe tí wọ́n sì mú bọ̀ sípò—àwọn pápá ìṣeré ńláńlá, gbọ̀ngàn ìwòran, ṣọ́ọ̀ṣì, ibùdó ọkọ̀ ojú irin, ọgbà ìṣeré, àti àwọn ilé ìjọba. Ẹ wo irú ìyípadà àgbàyanu tí èyí jẹ́! Ọmọ ilẹ̀ Moscow kan sọ pé: “Gbogbo ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ilé ní àwọn àdúgbò ti yí pa dà débi tí a kò lè dá wọn mọ̀ mọ́.”

Nígbà tí a bẹ Moscow wò ní June tó kọjá, a rí ọ̀pọ̀ agbo àwọn òṣìṣẹ́ tí ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò jákèjádò àáríngbùngbùn ìlú ńlá náà, nítòsí Gbàgede Red. Tọ̀sántòru ni iṣẹ́ ń ṣe. Àwọn ìránnilétí nípa àjọ̀dún àádọ́talélẹ́gbẹ̀rin ọdún sì wà níbi gbogbo—lára fèrèsé àwọn ilé ìtajà, níbi ọkọ̀ ojú irin Metro, lára òpó iná, lára ọjà tí wọ́n ń tà—kódà eré kan tí a lọ wò, tí wọ́n ṣe níbi ìran àpéwò ìta gbangba Moscow tọ́ka sí i.

Ní September, tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àlejò jákèjádò àgbáyé wá fún àkànṣe ayẹyẹ àádọ́talélẹ́gbẹ̀rin ọdún Moscow, àrímáleèlọ ni ìrísí rẹ̀ tí a mú sunwọ̀n sí i jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Moscow ti la àwọn àkókò onípọ̀n-ọ́njú kọjá nínú ìtàn rẹ̀, ó ṣì ń wà nìṣó, ó sì ń gbèrú.

Ó dájú pé ọ̀kan lára irú àkókò bẹ́ẹ̀ nínú ìtàn Moscow ni akẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì kan ní lọ́kàn ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tó kọjá, tí ó fi sọ̀rọ̀ nípa “ogun” tí ó so pọ̀ mọ́ “Har-mageddoni” nínú Bíbélì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Ó sọ pé àwọn kan sọ pé Moscow ni ibi tí Har-mageddoni wà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ kò gbà pẹ̀lú èrò yẹn.a

Kí ló dé tí àwọn kan fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó dára, ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn Moscow tí ń gbádùn mọ́ni, tí ó sì sábà máa ń mú ìbànújẹ́ lọ́wọ́.

Ó Ń Wà Nìṣó ní Àwọn Ọdún Ìjímìjí

Moscow wà ní ìkòríta pàtàkì kan nítòsí àwọn odò pàtàkì-pàtàkì (Oka, Volga, Don, àti Dnieper) àti àwọn ọ̀nà pàtàkì-pàtàkì kan. Àkọsílẹ̀ ìtàn kan ní 1156 ròyìn pé, Ọba Dolgoruky “ló fi ìpìlẹ̀ ìlú Moscow lélẹ̀,” dájúdájú èyí túmọ̀ sí pé òun ni ó kọ́kọ́ mọ odi tí wọ́n fi ògiri alámọ̀, tí wọ́n fi pákó gbá òkè rẹ̀, ṣe. Kremlin, tàbí odi yìí, wà lórí ilẹ̀ onígun mẹ́ta kan láàárín Odò Moskva àti Neglinnaya, odò kékeré kan tí ń ṣàn sínú odò míràn.

Ó bani nínú jẹ́ pé ní ọdún 21 péré lẹ́yìn náà ni ọba ilẹ̀ Ryazan nítòsí wọn “gbógun ti Moscow, ó sì sun ìlú náà látòkèdélẹ̀.” Wọ́n ṣàtúnkọ́ Moscow, àmọ́ ní December 1237, àwọn ará Mongolia lábẹ́ àkóso Batu Khan, ọmọ-ọmọ Genghis Khan tí ó lókìkí gan-an, tún ṣẹ́gun Moscow, wọ́n sì tún sun ún látòkèdélẹ̀. Àwọn ará Mongolia tún ṣẹ́gun ìlú ńlá náà ní 1293.

Ó ha yà ọ́ lẹ́nu pé Moscow ṣì ń wà nìṣó lẹ́yìn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àjálù tí ń sọ ọ́ di ẹdun arinlẹ̀ bí? Ìlú ńlá náà tún di ibi ìjọsìn pàtàkì kan ní Rọ́ṣíà ní 1326, nígbà tí ọba Moscow, Ivan Kalita, rọ olórí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Rọ́ṣíà láti máa gbé Moscow.

Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, nígbà àkóso Ivan Ńlá (láti 1462 sí 1505), Moscow ti gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Mongolia. Ní 1453, ìlú ńlá Constantinople (tí ń jẹ́ Istanbul nísinsìnyí) bọ́ sọ́wọ́ àwọn Ottoman ti ilẹ̀ Turkey, tí ó mú kí ó jẹ́ àwọn alákòóso Rọ́ṣíà nìkan ni àwọn ọba Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì tó kù lágbàáyé. Ní àbáyọrí rẹ̀, a wá mọ Moscow sí “Róòmù Kẹta,” a sì pe àwọn alákòóso Rọ́ṣíà ní olú ọba, tàbí késárì.

Nígbà tí ìṣàkóso Ivan Ńlá ń lọ sópin—nígbà tí Christopher Columbus ń rìnrìn àjò lójú òkun lọ sí Amẹ́ríkà—wọ́n mú Kremlin tóbi sí i, wọ́n sì mọ ògiri àti ilé gogoro oníbíríkì tí ó ṣì wà di òní, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà yí pa dà. Ògiri náà gùn ju kìlómítà méjì lọ fíìfíì, ó nípọn tó mítà 6, ó sì ga ní mítà 18, wọ́n sì yí àgbègbè Kremlin tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30 hẹ́kítà po.

Ó lè yà ọ́ lẹ́nu pé nígbà tí ó fi di àárín àwọn ọdún 1500, àwọn ènìyàn sọ pé Moscow tóbi ju London lọ. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjábá bẹ́ sílẹ̀ ní June 21, 1547, nígbà tí iná ńlá kan sọ ìlú náà dahoro, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ gbogbo àwọn olùgbé ibẹ̀ di aláìnílé. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn akíkanjú ara Moscow tún ṣàtúnkọ́ rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yí, wọ́n tún kọ́ Kàtídírà Basil Mímọ́ mọ́ ọn, wọ́n kọ́ èyí láti ṣayẹyẹ ìjagunmólú wọn lórí àwọn ará Tatary, tàbí Mongolia, ní Kazan. Kódà lónìí, ilé tí wọ́n fi ọgbọ́n ọnà ìkọ́lé gígadabú kọ́ sí Gbàgede Red (tí wọ́n parí ní 1561) yìí jẹ́ àmì àpẹẹrẹ Moscow tí àwọn ènìyàn mọ̀ káàkiri.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, ní 1571, àwọn ará Mongolia ti Crimea fipá wọlé, wọ́n sì ṣẹ́gun Moscow, wọ́n sì ṣe ìpalára yíyanilẹ́nu gan-an. Gbogbo ibẹ̀ ni wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ sun tán àyàfi Kremlin. Àwọn àkọsílẹ̀ fi hàn pé 30,000 ènìyàn péré ló là á já lára àwọn 200,000 tí ń gbé ibẹ̀. Àwọn olùyẹ̀wòṣàtúnṣe àwọn ìwé Time-Life sọ nínú ìwé Rise of Russia pé: “Òkú ènìyàn kún inú Odò Moscow fọ́fọ́ débi pé ó ṣẹ́rí gba ibòmíràn, omi rẹ̀ sì pupa fún ẹ̀jẹ̀ tí ó ń ṣàn lọ fún ọ̀pọ̀ máìlì.”

Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n ní láti mú Moscow pa dà bọ̀ sípò. Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀! Bí àkókò ti ń lọ, ògo ìlú ńlá náà tún tàn wá láti Kremlin, pẹ̀lú ògiri títòtẹ̀léra tí ó yí àwọn apá ibi tí a pè ní Kitai Gorod, White City, àti Wooden City po. Irú ìrísí olóbìírípo kan náà tí Moscow ní yìí ṣì wà lónìí, pẹ̀lú àwọn títì tí a fi ṣodi yí i ká dípò ògiri tí ó yí Kremlin po.

Lákòókò náà, ìṣàkóso agbonimọ́lẹ̀ ti Ivan Adáyàfoni, ọmọ-ọmọ Ivan Ńlá, ń kó ìdààmú púpọ̀ bá àwọn ará Moscow. Lẹ́yìn náà ní 1598, Fyodor, ọmọkùnrin Ivan Adáyàfoni tí ó ṣàkóso lẹ́yìn rẹ̀, kú láìsí ajogún kankan. Ìyẹn bẹ̀rẹ̀ “Àkókò Wàhálà,” tí ìwé Rise of Russia pè ní “sáà tí ó kún fún ìdàrúdàpọ̀ jù lọ tí ó sì ń dani lọ́kàn rú jù lọ nínú gbogbo àkọsílẹ̀ ìtàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà.” Ó tó ọdún 15 tó fi wà bẹ́ẹ̀.

Fífarada Ipò Lílekoko Kan Tí Kò Lẹ́gbẹ́

Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí Boris Godunov, arákùnrin ìyàwó Fyodor, gorí àléfà, ọ̀dá àti ìyàn lílekoko kan pọ́n Moscow lójú. Láàárín sáà olóṣù méje kan ní 1602, a gbọ́ pé 50,000 ènìyàn ló kú. Lápapọ̀, ó lé ní 120,000 ènìyàn tó ṣègbé ní ìlú ńlá náà láàárín 1601 sí 1603.

Gbàrà lẹ́yìn àjálù yẹn, ọkùnrin kan tí ó sọ pé òun ni Ọba Dmitry, ọmọkùnrin Ivan Adáyàfoni, kógun ti Rọ́ṣíà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn jagunjagun ilẹ̀ Poland. Ní gidi, ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ti pa Dmitry gidi ní 1591. Nígbà tí Godunov kú láìròtẹ́lẹ̀ ní 1605, ẹni tí wọ́n pè ní Ayédèrú Dmitry náà wọ Moscow, wọ́n sì fi jẹ olú ọba. Lẹ́yìn oṣù 13 péré tí ó fi ṣàkóso, àwọn alátakò pa á.

Àwọn mìíràn tí wọ́n ń du oyè náà, títí kan Ayédèrú Dmitry kejì, tí ilẹ̀ Polland ran òun pẹ̀lú lọ́wọ́, yọjú. Ìwà jìbìtì, ogun abẹ́lé, àti ìṣìkàpànìyàn gbalẹ̀ kan. Ọba Sigismund Kẹta Vasa, ti ilẹ̀ Polland, kógun ti Rọ́ṣíà ní 1609, bí àkókò sì ti ń lọ, wọ́n fọwọ́ sí ìwé àdéhùn àlàáfíà kan tí ó fún ọmọkùnrin rẹ̀ Władysław Kẹrin Vasa ní ìdánimọ̀ lábẹ́ àṣẹ gẹ́gẹ́ bí olú ọba Rọ́ṣíà. Nígbà tí àwọn ará Polland rọ́nà wọlé sí Moscow ní 1610, ìlú ńlá náà bọ́ sábẹ́ ìṣàkóso àwọn ará Polland. Àmọ́, láìpẹ́, àwọn ará ilẹ̀ Rọ́ṣíà gbógun dìde sí àwọn ará Polland, wọ́n sì lé wọn kúrò ní Moscow ní òpin 1612.

Àwọn àkókò wàhálà lílekoko wọ̀nyí sọ Moscow di ‘aṣálẹ̀ rẹpẹtẹ tí ẹ̀gún òun ọ̀gàn kún bò, dípò àwọn òpópónà àtijọ́.’ Wọ́n ti sun ògiri Wooden City di eérú, àwọn ilé tí wọ́n wà ní Kremlin sì nílò àtúnṣe. Ikọ̀ ilẹ̀ Sweden kan tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ sọ pé: “Ìyẹn jẹ́ òpin bíbanilẹ́rù àti oníjàábá tí ó ṣẹlẹ̀ sí ìlú ńlá olókìkí náà, Moscow.” Ṣùgbọ́n, àṣìṣe ló ṣe.

Wọ́n dìbò yan olú ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan láti ìdílé Romanov ní 1613, àkókò ìṣàkóso tuntun tí àwọn Romanov fi ń jẹ olú ọba yìí sì lé ní 300 ọdún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbọ́ pé, ọ̀dọ́mọdé olú ọba tuntun náà, Michael, “kò ní ibi tí yóò gbé” nítorí ìsọdahoro náà, wọ́n ṣàtúnkọ́ Moscow, ó sì tún wá di ìlú ńlá pàtàkì kan lágbàáyé.

Ní 1712, olú ọba náà Peter Ńlá, ọmọ-ọmọ Michael, gbé olú ìlú Rọ́ṣíà kúrò ní Moscow lọ sí St. Petersburg, tí ó kọ́ sórí Òkun Baltic. Àmọ́ Moscow ṣì jẹ́ “oókan àyà” ọ̀wọ́n Rọ́ṣíà. Ní ti gidi, a gbọ́ pé, nígbà tí olú ọba ilẹ̀ Faransé náà, Napoléon Bonaparte, ń wá ìṣẹ́gun, ó sọ pé: ‘Bí mo bá ṣẹ́gun Petersburg, n óò gbá orí Rọ́ṣíà mú, bí mo bá sì ṣẹ́gun Moscow, n óò pa oókan àyà rẹ̀ run.’

Napoléon kógun ti Moscow, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìtàn ti fi hàn, oókan àyà tirẹ̀ ni wọ́n rún jégéjégé, kì í ṣe ti Moscow. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Moscow dẹ́rù bani gan-an tí ó fi hàn gbangba pé èyí ló mú kí àwọn kan sọ pé ìlú ńlá náà dà bíi Har-mageddoni.

Moscow Gbérí Láti Inú Àwókù

Ní ìgbà ìrúwé ọdún 1812, Napoléon lo ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó pọ̀ tó 600,000 láti kógun ti Rọ́ṣíà. Ní lílo ìlànà “rírun ilẹ̀ ìpèsè oúnjẹ ọ̀tá,” àwọn ará Rọ́ṣíà sá pa dà, wọn kò sì ṣẹ́ ohunkóhun kù fún àwọn ọ̀tá. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n pinnu láti fi àpatì ilẹ̀ Moscow sílẹ̀ fún àwọn ará Faransé!

Ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ sọ pé àwọn ará Moscow fúnra wọn ni wọ́n dáná sun ìlú wọn dípò kí àwọn ará Faransé gbà á. Ìtàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan sọ pé: “Afẹ́fẹ́ oníjì líle kan sọ iná náà di ọ̀run àpáàdì gidi kan.” Ó mú kí àwọn ará Faransé máà lóúnjẹ fúnra wọn tàbí fún ẹran wọn, bí ìtàn yí ṣe ṣàlàyé pé: “Àwọn ará Rọ́ṣíà kò gbé ẹyọ àpò ìyẹ̀fun kan péré fún àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kó koríko ẹ̀kún kẹ̀kẹ́ ẹrù kan fún wọn.” Níwọ̀n bí kò ti sí ohun mìíràn tí wọ́n lè ṣe, àwọn ará Faransé kò lò tó ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lẹ́yìn tí wọ́n wọ Moscow tí wọ́n fi fibẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdánù gbogbo ọmọ ogun wọn tán nígbà tí wọ́n ń sá pa dà.

Ìgboyà àwọn ará Moscow ti gba ìlú ńlá wọn olókìkí là, wọ́n sì gbé e dìde láti inú àwókù pẹ̀lú ìpinnu tọkàntara. Aleksandr Pushkin, tí a sábà máa ń kà sí akéwì pàtàkì jù lọ ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà, jẹ́ ọmọ́ ọdún 13 nígbà tí Napoléon kógun ti Moscow, ilẹ̀ ìbí ọ̀wọ́n ti Pushkin. Ó kọ̀wé nípa Moscow pé: “Ẹ wo irú èrò tí ń wá sọ́kàn olúkúlùkù ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà rere tí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn! Ẹ wo bí àdúntúndún ìró tí wọ́n ń gbọ́ níbẹ̀ ti rinlẹ̀ tó!”

Wíwànìṣó àti Ìníláárí

Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n wà láàyè lónìí ń rántí àwọn àkókò lílekoko tí Moscow là kọjá nígbà ìyípadà tegbòtigaga Rọ́ṣíà tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1917, yálà láti inú agbára ìrántí tàbí láti inú àwọn fíìmù. Síbẹ̀, kì í ṣe pé ìlú ńlá náà là á já nìkan ni—ó ní láárí. Wọ́n ṣe ọ̀nà ojú irin abẹ́lẹ̀ metro, àti Ọ̀nà Omi Abẹ́lẹ̀ Moscow-Volga láti pèsè omi fún ìlú ńlá náà. Ní pàtàkì jù lọ, wọ́n mú àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà kúrò, nígbà tí ó sì fi di ìparí àwọn ọdún 1930, Moscow ti ní ẹgbẹ̀rún kan ibi ìkówèésí.

Ní 1937, olórí ìlú Manchester, England, nígbà kan rí, kọ nínú ìwé náà, Moscow in the Making, pé: “Bí ogun ńlá kankan kò bá bẹ́ sílẹ̀, . . . ó dá mi lójú pé lẹ́yìn ìwéwèé ọlọ́dún mẹ́wàá náà, Moscow yóò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlú ńlá olókìkí tí a ṣètò dáradára jú lọ tí ayé tí ì mọ̀ rí ní ti ètò ìlera, ohun ìṣeyọ̀tọ̀mì, àti àwọn ohun amáyédẹrùn fún gbogbo àwọn ará ibẹ̀.”

Ṣùgbọ́n ní June 1941, láìròtẹ́lẹ̀ ni Germany kọ lu Rọ́ṣíà, alájọṣepọ̀ tí wọ́n jùmọ̀ fọwọ́ sí ìwé àdéhùn àlàáfíà ní ohun tí kò tó ọdún méjì sẹ́yìn. Ní October, àwọn ọmọ ogun Germany fi nǹkan bí 40 kìlómítà sún mọ́ Kremlin. Ó jọ pé Moscow yóò ṣubú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára àwọn mílíọ̀nù 4.5 tí ń gbé Moscow tí wọ́n ti kó jáde nílùú. Nǹkan bí 500 ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ti palẹ̀ àwọn ẹ̀rọ wọn mọ́, wọ́n sì ti kó wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn àyè ilẹ̀ tuntun ní ìhà ìlà oòrùn Rọ́ṣíà. Síbẹ̀, Moscow kọ̀, kò ṣubú. Ìlú ńlá náà wulẹ̀ gbẹ́ àwọn kòtò ààbò ńláńlá, ó mọdi ìdènà yí ara rẹ̀ ká, ó sì lé àwọn ará Germany pa dà.

Moscow jìyà gan-an, bí ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ńlá mìíràn ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti jìyà. Oníròyìn kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tí ń gbé ibẹ̀ ní àwọn ọdún 1930 àti 1940, kọ̀wé pé: “Moscow ti forí la ọ̀pọ̀ nǹkan kọjá ní ọ̀rúndún kan ṣoṣo, ẹnu sì yà mí pé ó ṣì ń wà nìṣó síbẹ̀.” Lótìítọ́, ohun àgbàyanu ló jẹ́ pé Moscow ṣì wà, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá títóbi jù lọ, tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ ní òde òní.

Lónìí, iye ènìyàn tí ń gbé Moscow lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án, ilẹ̀ rẹ̀ lápapọ̀ sì tó 1,000 kìlómítà níbùú lóròó, èyí sì mú kí ó tóbi ju New York City lọ, kí ó sì lókìkí jù ú lọ. Ọ̀wọ́ àwọn títì yí Kremlin po, pẹ̀lú Títì Yíyípo ti Moscow tí ó lé ní 100 kìlómítà, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ló yí ààlà ilẹ̀ Moscow po lápá ìta. Àwọn ọ̀nà àbùjá fífẹ̀ jáde síta láti àárín ìlú ńlá náà, bí àwọn wáyà táyà kẹ̀kẹ́.

Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Moscow ló jẹ́ pé ọkọ̀ ojú irin Metro, tí wọ́n ti fi ojú òpó mẹ́sàn-án àti 150 ibùdókọ̀ kún ibi tí ó máa ń dé, tí ń gbé àwọn ènìyàn dé ibi gbogbo ní ìlú ńlá náà, ni wọ́n máa ń wọ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ World Book Encyclopedia pe àwọn ibùdó ọkọ̀ ojú irin Metro ti Moscow ní “èyí tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ jù lọ lágbàáyé.” Àwọn ibùdókọ̀ kan dà bí ààfin tí wọ́n fi àwọn fìtílà alásorọ̀, ère, gíláàsì kíkùn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ mábìlì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. Ní ti gidi, àwọn ibùdókọ̀ 14 tí wọ́n kọ́kọ́ kọ́ gba àwọn mábìlì tó pọ̀ ju 70,000 mítà níbùú lóròó lọ, ó pọ̀ ju èyí tí wọ́n lò sí àwọn ààfin tí ìdílé Romanov kọ́ láàárín 300 ọdún lọ!

Wọ́n fún Ìlú Ńlá Náà Ní Ìrísí Tuntun

Nígbà tí a bẹ ibẹ̀ wò ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó kọjá, a wọ ọkọ̀ ojú irin Metro láti lọ wo ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ àtúnṣe títóbijùlọ tí wọ́n ṣe—Pápá Ìṣeré Ńlá Lenin tí ó ní àyè ìjókòó 103,000, tí wọ́n kọ́ sí gúúsù Moscow ní àwọn ọdún 1950. Wọ́n ń ṣe àwọn àga tuntun síbẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí a de ibẹ̀, a sì finú wòye òrùlé tí ó ṣeé ṣí tí yóò jẹ́ kí a lè máa lo ibẹ̀ jálẹ̀ ọdún.

Ilé ìtajà ńlá GUM lílókìkí, tí ó wà ní òdì kejì Gbàgede Red láti Kremlin, ní ìrísí tuntun tí ó jojú ní gbèsè. Ní ìhà míràn Kremlin, níbi tí odò Neglinnaya ń ṣàn lọ kí wọ́n tó darí rẹ̀ gba ìsàlẹ̀ ní ọ̀rúndún tó kọjá, ìṣètò ìrísí ojú ilẹ̀ wá ní odò tóóró kan tí yóò dà bí odò ti tẹ́lẹ̀. Ibùdó ìrajà ńlá tí àjà bíi mélòó kan lára rẹ̀ wà nínú ilẹ̀, títí kan àwọn ilé àrójẹ àti àwọn ìpèsè míràn, tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́, wà ní òdì kejì odò náà. Òǹkọ̀wé kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Moscow pè é ní “Ibùdó ìrajà tí ó tóbi jù lọ ní Yúróòpù,” àmọ́ ó fi kún un pé, “tàbí kí ó jẹ́ pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ní Ọ́fíìsì Olórí Ìlú nìyẹn.”

Ní apá ibòmíràn tí kò jìnnà sí Kremlin, ó jọ pé àwọn ẹ̀rọ ìkọ́lé agbẹ́rùlọ-sókè-sódò wà káàkiri, iṣẹ́ ìkọ́lé sì ń gbomi. Wọ́n rí àwọn ohun ìtàn ní àwọn ibi tí wọ́n ti walẹ̀, wọ́n rí ibi ìtọ́júǹkansí kan, wọ́n sì rí ohun tí ó lé ní 95,000 owó wẹ́wẹ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù tí wọ́n ti wà láti ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún sí ìkẹtàdínlógún níbẹ̀.

Wọ́n tún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣe, wọ́n sì tún àwọn kan kọ́. Wọ́n ti parí kíkọ́ Kàtídírà Màríà Mímọ́ ti Kazan, tí ó wà ní Gbàgede Red, tí wọ́n pa run ní 1936 tí wọ́n sì kọ́ ṣáláńgá gbogbogbòò síbi tí ó wà. Wọ́n fi bọ́ǹbù fọ́ Kàtídírà ńlá ti Kristi Olùgbàlà, tí wọ́n kọ́ láti ṣayẹyẹ ṣíṣẹ́gun Napoléon, ní 1931, nígbà ìgbétáásì ìgbógunti ìsìn tí Kọ́múníìsì ṣe. Nígbà tí a ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ́ ọ tán sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀, tí ó ti jẹ́ ibi tí ìkùdu ìlúwẹ̀ẹ́ ńlá olómi gbígbóná kan wà fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Lílọ wo àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé fani lọ́kàn mọ́ra, ní pàtàkì bí a ti ń ronú nípa ìrísí tí a mú sunwọ̀n tí Moscow yóò ní nígbà tí ọdún bá fi máa parí. Síbẹ̀, ohun tó mú wa nífẹ̀ẹ́ Moscow ni àwọn ènìyàn ibẹ̀. Aṣojúkọ̀ròyìn kan ní Moscow sọ nígbà kan pé: “Orí àlejò ń wú gan-an nítorí gbogbo ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí a mọ̀ mọ àwọn ará Moscow pé wọ́n tóótun fún.” A rí i pé èyí jẹ́ òtítọ́, ní pàtàkì bí a ti ṣù jọ sídìí tábìlì kékeré kan, tí a ń gbádùn ẹ̀mí ọ̀yàyà àti aájò àlejò tí ìdílé ará Rọ́ṣíà kan fi hàn.

Inú wa dùn láti mọ̀ pé púpọ̀ àwọn ará Moscow ti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Har-mageddoni túmọ̀ sí ní gidi, ogun kan tí Ẹlẹ́dàá wa yóò fi fọ gbogbo ilẹ̀ ayé mọ́. Èyí yóò mú àkókò kan wọlé tí gbogbo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní tòótọ́ yóò lè gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ń sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan, láìsí ẹ̀tanú àti ìfura, àmọ́ tòyetòye àti ìgbẹ́kẹ̀lé. (Jòhánù 13:34, 35; Jòhánù Kíní 2:17; Ìṣípayá 21:3, 4)—A kọ ọ́ ránṣẹ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé Commentary on the Holy Bible, tí Adam Clarke ṣe, Ẹ̀dà Onídìpọ̀ Kan, ojú ìwé 1349.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Kàtídírà Basil Mímọ́ àti ògiri Kremlin, àmì àpẹẹrẹ Moscow tí àwọn ènìyàn mọ̀ káàkiri

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwọn ìránnilétí nípa àjọ̀dún àádọ́talélẹ́gbẹ̀rin ọdún wà níbi gbogbo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ilé ìtajà ńlá GUM lílókìkí náà, pẹ̀lú ìrísí rẹ̀ tuntun

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ọ̀pọ̀ ibùdókọ̀ ọkọ̀ ojú irin Metro dà bí ààfin

[Credit Line]

Tass/Sovfoto

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ṣíṣàtúnṣe Pápá Ìṣeré Ńlá Lenin

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ṣíṣètò ìrísí ojú ilẹ̀ tuntun lóde Kremlin

[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ó jọ pé àwọn ẹ̀rọ ìkọ́lé agbẹ́rùlọ-sókè-sódò wà káàkiri, iṣẹ́ ìkọ́lé sì ń gbomi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́