ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 30
  • ‘Ayé Yìí Ì Bá Yàtọ̀’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ayé Yìí Ì Bá Yàtọ̀’
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Moscow—Ìlú Ńlá Tí Ń Wà Nìṣó
    Jí!—1997
  • Ilé Ẹjọ́ Dá Àwọn Èèyàn Jèhófà Láre!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà
    Jí!—1997
  • Àwọn Ilé Iṣẹ́ Agbéròyìnjáde Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Yin Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 30

‘Ayé Yìí Ì Bá Yàtọ̀’

Gbogbo kìràkìtà táwọn èèyàn ṣe láti fagi lé àpéjọpọ̀ kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ ṣe nílùú Moscow lóṣù August, ọdún tó kọjá kàn ń pe àfiyèsí lọ́tùn-ún lósì ni. (Wo ojú ìwé 27 àti 28 fún kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé.) Andrei Zolotov, Kékeré, sọ nínú ìwé ìròyìn The Moscow Times ti August 21, 1999, pé, “Vladimir Kozyrev, tí í ṣe igbá kejì gíwá ilé eré ìdárayá náà, sọ pé iléeṣẹ́ àwọn kò lòdì sí àpérò táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ ṣe náà. Ó lóun ò mọ ibi tí àṣẹ náà [láti fagi lé e] ti wá.”

Nínú lẹ́tà kan tí ìwé ìròyìn The Moscow Times gbé jáde lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ọ̀kan lára àwọn tó ka ìròyìn náà gbóríyìn fún ìwé ìròyìn náà nítorí pé ó tẹ àpilẹ̀kọ náà “tí ọ̀rọ̀ ẹ̀tanú ò sí nínú ẹ̀ rárá,” ó sì sọ pé ó “yẹ káwọn èèyàn fara balẹ̀ kà á dáadáa.” Ó tún sọ pé: “Ìròyìn tẹ́ẹ gbé jáde nípa òkè ìṣòro tí wọ́n gbé ko àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n ń múra sílẹ̀ fún àpéjọpọ̀ wọn ọdọọdún [ṣí aṣọ lójú] ìwà àìdáa tí wọ́n hù sí wọn.”

Ẹni tó kọ lẹ́tà náà wá sọ pé “kò síbi táwọn èèyàn ò ti mọ” àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “lágbàáyé (àti ní Rọ́ṣíà pẹ̀lú nísinsìnyí) . . . Gbogbo èèyàn . . . ló mọ̀ wọ́n sí ọmọlúwàbí, onínúure, àti èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí kì í bá ẹnikẹ́ni fa wàhálà, wọn kì í fipá mú ẹnikẹ́ni, ìgbà gbogbo ni wọ́n sì ń lépa àlàáfíà nínú àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn, láìka ẹ̀sìn wọn sí, wọn ì báà jẹ́ àwọn Kristẹni Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, tàbí àwọn Mùsùlùmí, tàbí àwọn ẹlẹ́sìn Búdà. Wọn kì í gba ẹ̀gúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀mùtípara tàbí ajoògùnyó láàárín wọn, ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ kò mù rárá: Wọ́n máa ń gbìyànjú láti rí i pé ìgbàgbọ́ wọn tó wá látinú Bíbélì ló ń darí wọn nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe tàbí tí wọ́n ń sọ. Ì bá ṣe pé gbogbo èèyàn tó wà láyé ń sapá láti máa gbé ìgbé-ayé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Bíbélì ni, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe, ayé burúkú yìí ì bá yàtọ̀ pátápátá.”

Àwọn alákòóso tó ti ṣèwádìí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì ti ní àjọṣe pẹ̀lú wọn mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí. Fún àpẹẹrẹ, irú àwọn alákòóso bẹ́ẹ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí láyè láti kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tuntun tó jojú ní gbèsè yìí sílùú St. Petersburg, ní Rọ́ṣíà. Nígbà tí wọ́n ń yà á sí mímọ́ ní September 18, ọdún tó kọjá, ẹgbọ̀kànlá ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [2,257] àwọn èèyàn aláyọ̀ tó wá wòran ló kún inú gbọ̀ngàn náà, ẹgbọ̀kànlá ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n [2,228] èèyàn sì tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba nílùú St. Petersburg àti ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Solnechnoye tí ń bẹ nítòsí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́