ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lábẹ́ Másùnmáwo
  • Ẹ̀kọ́ Nípa Ìbọ̀wọ̀ fún Ipò Àṣẹ
  • Ẹ̀rọ Ìgbohùnsílẹ̀ Níbi Tí Ẹran Ọ̀sìn Ti Ń Jẹun
  • Kíkọ Oògùn Eléwu Fúnni
  • Àwọn Oyin Mi Bá Adìyẹ Pamọ!
    Jí!—1998
  • Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Àwọn Ẹyẹ Ojú Ọ̀run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Àwọn Òbí Tó Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Tí Wọ́n sì Mọṣẹ́ Wọn Níṣẹ́
    Jí!—2009
  • Àníyàn Ṣíṣe Ohun Tó Ń Fà Á àti Ọṣẹ́ Tó Máa Ń Ṣe
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 29

Wíwo Ayé

Lábẹ́ Másùnmáwo

Ìwé ìròyìn Vancouver Sun sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì lára gbogbo àwọn ará Kánádà tó ń ṣàròyé pé ńṣe ni másùnmáwo ń yọ àwọn lẹ́nu ní fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tàbí ní kólekóle bí àwọ́n ṣe ń gbìyànjú láti kó ọ̀ràn iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àwọn àti ti ìgbésí ayé ìdílé pọ̀. Ìyẹn sì jẹ́ ìlọ́po méjì bó ṣe rí ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.” Kí ló mú kó pọ̀ sí i? Ìwádìí kan tí àjọ Conference Board ti Kánádà ṣe fi hàn pé iye àwọn òṣìṣẹ́ ará Kánádà tó ń di olùṣètọ́jú àwọn mẹ́ńbà ìdílé ń pọ̀ sí i. Púpọ̀ wọn ló ń bímọ lọ́wọ́ alẹ́ ìgbésí ayé wọn, àwọn wọ̀nyí sì sábà máa ń ko ìpèníjà “títọ́jú àwọn ọmọ àti àwọn òbí pọ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpín mẹ́rìnlélọ́gọ́rin lára àwọn tí wọ́n bi lọ́rọ̀ nígbà ìwádìí náà ló sọ pé iṣẹ́ àwọn ṣì tẹ́ àwọn lọ́rùn, ìròyìn náà sọ pé bí gbígbìyànjú láti ṣiṣẹ́ ilé kí wọ́n sì bójú tó iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn lákòókò kan náà bá nira, “ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kọ́kọ́ máa ń lò lára àkókò tí wọ́n fi ń gbọ́ tara wọn, títí kan àkókò tí wọ́n fi ń sùn.” Àjọ Conference Board sọ pé: “Ìyẹn á wá fa másùnmáwo, àìsàn á sì dé.”

Ẹ̀kọ́ Nípa Ìbọ̀wọ̀ fún Ipò Àṣẹ

Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé: “Àwọn òbí lóde òní kì í fi bẹ́ẹ̀ pàṣẹ fún àwọn ọmọ, èyí sì lè mú kí àwa òbí máa dín iyì àwọn ọmọ náà kù ní gidi.” Ronald Morrish, tó jẹ́ ògbógi nínú ọ̀ràn ìhùwà, sọ pé: “Bí àwọn ọmọ bá mọ ààlà wọn, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ní láti retí àti ààbò wọn—tí yóò wá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní iyì tó túbọ̀ pọ̀. Àwọn ọmọ tí wọn ò mọ ohun tó ń jẹ́ ìlànà àti ẹrù iṣẹ́ ló máa ń ní èrò pé ẹ̀mí àwọn ò dè, tí ọkàn wọn kì í sì í balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń dàgbà.” Ó fi kún un pé: “Mo ti rí àwọn ọmọ ọdún mẹ́fà tó jẹ́ àwọn fúnra wọn ni wọ́n ń pinnu àkókò tí wọ́n máa ń sùn. Mo sì ti rí àwọn ọmọ ọdún mẹ́ta tí ìyá wọ́n ń gbìyànjú láti rọ̀ wọ́n kí wọ́n yéé ṣe wọ́nranwọ̀nran nípa ṣíṣàlàyé pé Mọ́mì ò fẹ́ bẹ́ẹ̀.” Morrish sọ pé àwọn ọmọ ní láti kọ́ láti tẹ̀ lé òfin tí ìdílé fi lélẹ̀, bákan náà, èrò pé àbùdá wọn ni kí wọ́n máa ṣorí kunkun bí wọ́n ṣe ń dàgbà sí i kì í ṣe òótọ́. Ó ní: “A retí kí àwọn ọmọ máa mọ̀wé sí i bọ́dún ti ń gorí ọdún.” Ó wá béèrè pé: “Nítorí náà, kí ló dé tí a ò tún lè retí kí ìwà àwọn ọmọdé máa sunwọ̀n sí i lọ́dọọdún?” Ó wá fi kún un pé: “Tí o kò bá lè pàṣẹ fún ọmọ rẹ nígbà tó ṣì kéré pé kó mú ohun ìṣiré rẹ̀ kúrò nílẹ̀, nígbà tọ́mọ náà bá di ọ̀dọ́langba kò ní gbọ́ràn sí ẹ lẹ́nu tóo bá ní ìgbà báyìí ni kó máa wọlé lálẹ́.”

Ẹ̀rọ Ìgbohùnsílẹ̀ Níbi Tí Ẹran Ọ̀sìn Ti Ń Jẹun

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní Kánádà ti ṣàwárí pé èèyàn lè fún àwọn ọmọ ẹran ọ̀sìn níṣìírí láti jẹun nípa jíjẹ́ kí ohùn tí a gbà sílẹ̀ dún sétígbọ̀ọ́ wọn. Luis Bate, tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Prince Edward Island, sọ pé: “A gba ohùn àgbébọ̀ adìyẹ kan sílẹ̀ bó ṣe ń dún nígbà tó rí oúnjẹ kan tó fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ.” Nígbà tí àwọn òròmọdìyẹ gbọ́ ìró ohùn tí a gbà sílẹ̀ náà nínú àwọn gbohùngbohùn tí a gbé sẹ́gbẹ̀ẹ́ oúnjẹ, wọ́n jẹ oúnjẹ náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyá wọn ò sí níbẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ìró ohùn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó bá a mu. Ohun tí Bate tún kíyè sí ni pé: “Ìgbà tí a gbé ìró ohùn àgbébọ̀ adìyẹ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ pamọ sí i, èyí tó sì dún létí tèmi bí ìgbà tó ń pè wọ́n wá jẹun, ńṣe làwọn òròmọdìyẹ náà dúró sójú kan tí wọn ò ṣísẹ̀.” Ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà fẹ́ ṣe ni pé wọ́n fẹ́ kí àwọn ẹran ọ̀sìn náà tètè dàgbà. Nínú àyẹ̀wò tí wọ́n sì kọ́kọ́ ṣe, àwọn òròmọdìyẹ náà fi ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún dàgbà sí i ju bó ti yẹ kí wọ́n ṣe lọ ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta àkọ́kọ́ tí wọ́n dáyé. Nínú àwọn àyẹ̀wò míì tó jọ ìyẹn, èèyàn lè fún àwọn ọmọ tòlótòló àti ọmọ ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lú níṣìírí láti jẹun lọ́pọ̀ ìgbà sí i.

Kíkọ Oògùn Eléwu Fúnni

Ìwé ìròyìn Stuttgarter Nachrichten sọ pé: “Iye tí oògùn pa ní Jámánì lọ́dún tó kọjá pọ̀ ju iye tí jàǹbá pa lọ.” Wọ́n ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n èèyàn ló kú ní ọdún 1998 nítorí lílo oògùn tí wọ́n ṣì júwe fún wọn. Iye yìí jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta àwọn tó kú nínú ìjàǹbá mọ́tò lọ́dún yẹn. Wọ́n ní lájorí ohun tó fà á kọ́ ni lílo oògùn tí oníṣègùn ò júwe fúnni. Ó jọ pé olórí ìṣòro náà ni àìsí ìsọfúnni nípa àwọn oògùn ọ̀hún àti àìfún ọ̀pọ̀ dókítà ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn oògùn náà àti iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe lára. Ìròyìn náà fi yéni pé, Ingolf Cascorbi, tó jẹ́ apoògùn, sọ pé wọ́n fojú díwọ̀n pé “lọ́dọọdún, ní ilẹ̀ Jámánì, ì bá máà sí pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá èèyàn ń kú, tí ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ [250,000] èèyàn sì ń joró ìpalára burúkú tó tìdí rẹ̀ yọ, ká ní wọ́n ṣe ìwádìí àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó pójú owó.”

Bákan náà, ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, Sciences et avenir, sọ nípa ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Faransé lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó fi hàn pé lára ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ oògùn tí wọ́n kọ fáwọn èèyàn tí wọ́n ti ju ẹni àádọ́rin ọdún lọ, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ló jẹ́ àṣìkọ oògùn tàbí oògùn tí kò ní ṣiṣẹ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àádọ́ta ló léwu nínú nítorí pé ó lè gbòdì tó bá ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn oògùn míì tàbí kó ní àwọn ewu míì nínú. Ní ilẹ̀ Faransé, wọ́n fojú díwọ̀n rẹ̀ pé iye ọjọ́ tí àwọn arúgbó ń lò nílé ìwòsàn lọ́dún jẹ́ mílíọ̀nù kan nítorí pé oògùn gbòdì lára wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́