ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 8/22 ojú ìwé 22-27
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ***
  • ***
  • ***
  • ***
  • ***
  • Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láre
    Jí!—1998
  • Àwọn Èèyàn Àlàáfíà Gbèjà Orúkọ Rere Wọn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́—Rọ́ṣíà
    Wọ́n Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Ohun Tí Wọ́n Gbà Gbọ́
  • Ilé Ẹjọ́ Dá Àwọn Èèyàn Jèhófà Láre!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 8/22 ojú ìwé 22-27

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

Ojú Ìwòye Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ìsìn Kan

NÍ Róòmù, àwọn aṣáájú ìlú tí wọ́n jẹ́ Júù ní ọ̀rúndún kìíní sọ nípa ìsìn Kristẹni pé: “Ní ti ẹ̀ya ìsìn yí a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” Kí ni àwọn aṣáájú wọ̀nyẹn ṣe? Lọ́nà tó gboríyìn, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí ó wà ní àtìmọ́lé nígbà náà, wọ́n sì wí pé: “Àwa ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu láti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ohun tí àwọn ìrònú rẹ jẹ́.” (Ìṣe 28:22) Wọ́n fetí sí Kristẹni kan tí ó ní ìsọfúnni níkàáwọ́, kàkà kí wọ́n fetí sí àwọn tí ń sọ̀rọ̀ lòdì sí ìsìn Kristẹni.

Sergei Ivanenko, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ará Rọ́ṣíà kan tí a bọ̀wọ̀ fún, ṣe bákan náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó gba ọ̀pọ̀ lára àwọn ìròyìn búburú tí wọ́n ń gbé kiri Rọ́ṣíà nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ́, ó pinnu láti ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Àwọn Ẹlẹ́rìí, tí ó wà lẹ́yìn odi ìlú St. Petersburg, láti gba ìsọfúnni. Ó tẹ́wọ́ gba ìkésíni kan láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, kí ó béèrè ọ̀rọ̀, kí ó sì fúnra rẹ̀ ṣàkíyèsí Àwọn Ẹlẹ́rìí náà.

Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko débẹ̀ ní October 1996, ilé tí ó gba iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 200 àwọn mẹ́ńbà òṣìṣẹ́ ẹ̀ka ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ń parí lọ. Fún ọjọ́ mẹ́ta tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n fún un láǹfààní láti ṣàkíyèsí ibi iṣẹ́ ìkọ́lé náà, kí ó jẹun nílé oúnjẹ, kí ó sì fọ̀rọ̀ wá ẹnikẹ́ni tó bá wù ú lẹ́nu wò.

Àpilẹ̀kọ kan tí Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko kọ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí náà jáde nínú ìtẹ̀jáde ìwé agbéròyìnjáde ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tó gbajúmọ̀ ní Rọ́ṣíà náà, Moscow News, ti February 16 sí 23, 1997. Àpilẹ̀kọ náà tí ó ní àkọlé “A Ha Gbọ́dọ̀ Máa Bẹ̀rù Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Bí?,” tún jáde nínú ìtẹ̀jáde ìwé agbéròyìnjáde Moscow News lédè Gẹ̀ẹ́sì tí February 20 sí 26. Nítorí pé ọ̀pọ̀ òǹkàwé Jí! ní ìdàníyàn mímúná nínú ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, a ṣe àtúngbéjáde apá púpọ̀ jù lọ nínú àpilẹ̀kọ náà níhìn-ín, pẹ̀lú ìyọ̀ǹda. Ìrírí yìí, tí wọ́n kọ ní ìtẹ̀wé gàdàgbàgàdàgbà ni Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko fi bẹ̀rẹ̀:

“Ìwé àlẹ̀-fiṣèsọfúnni tí àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ òṣèlú LDPR ti Zhirinovsky ń jù síhìn-ín sọ́hùn-ún, tí ń fi ìpàdé kan tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe hàn, kà pé: ‘Ẹ̀yin oníyapa ìsìn, ẹ jáde kúrò ní Rọ́ṣíà!’ Mo béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn tí ń wọ́de náà pé: ‘Kí ni ohun tí o kò fẹ́ nípa àjọ yìí?’ Ó fún mi ní ẹ̀dà ìwé agbéròyìnjáde Megapolis-Express kan tí ó ní àkọlé ‘Ìbẹ́sílẹ̀ Rẹ́kórẹ́kó Ìsìn ní Kamchatka.’ Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè rówó kó jọ, wọ́n ń wá oníbàárà fún aṣẹ́wó, wọ́n sì ń ṣe òwò ẹgbẹ́ aṣẹ́wó, ní mímú kí àwọn àìsàn tí ìbálòpọ̀ takọtabo ń fà máa gbilẹ̀ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀. Mo béèrè lọ́nà ìbánikẹ́dùn pé: ‘Ṣé ìwọ pẹ̀lú wà lára àwọn tí ó kó sí pàkúté wọn ni? Ǹjẹ́ o gba ìsọfúnni yìí gbọ́?’ Ìdáhùn tó mú wá ni pé: ‘Ìyẹn kò ṣe nǹkan kan. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ẹ̀ya ìsìn America yí ń ba ipò tẹ̀mí àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Rọ́ṣíà jẹ́, a sì gbọ́dọ̀ fòpin sí i.’”

Àpilẹ̀kọ tí Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko kọ̀ tẹ̀ lé e lábẹ́ ìlà orúkọ òǹkọ̀wé náà: “Láti ọwọ́ Sergei Ivanenko, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, akẹ́kọ̀ọ́ oyè ìjìnlẹ̀ nínú ọgbọ́n èrò orí.”

“Ní gidi, àìlábòsí bí irú èyí ṣọ̀wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé ọ̀pọ̀ ará Rọ́ṣíà ni kì í ronú ohun rere nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí ẹnì kan bá fi lè dárúkọ àjọ yìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àròyé ni yóò wáyé nípa ìtara àìronújinlẹ̀ bíbanilẹ́rù rẹ̀, bí ó ṣe pilẹ̀ láti America, nípa bí àwọn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà lásán nínú wọn ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn aṣáájú àjọ náà láìláàlà, àti ìgbàgbọ́ pé òpin ayé ti sún mọ́lé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àpapọ̀ ìbẹ̀rù àti ìfẹ́ ìtọpinpin nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn.

“Kí Ni Ìsìn Yí, Ṣé A Sì Gbọ́dọ̀ Máa Bẹ̀rù Rẹ̀?

“Kí n lè fúnra mi ṣàwárí nípa rẹ̀, mo ṣèbẹ̀wò sí abúlé Solnechnoye ní àgbègbè Kururtnoye, St. Petersburg, níbi tí ibùdó ìṣàbójútó Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà wà.

***

“[Èyí wà] níbi ìpàgọ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn kan látijọ́. Nígbà tí ó fi di 1992, ilé [àkọ́kọ́] ti di àlàpà, àwọn asùnta tí kò nílé àti àwọn eku ló rọ́pò àwọn ọmọdé tí ń gbébẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó dájú pé ipò àìsí àbójútó àgbègbè náà ló mú kí ó ṣeé ṣe fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti gba ìpín ilẹ̀ hẹ́kítà méje náà fún lílò títí àkókò tí kò lópin kan. Wọ́n tún àwọn ògbólógbòó ilé náà ṣe, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ilé tuntun, tí ó ní ilé ìṣàbójútó alájà mẹ́rin kan, [Gbọ̀ngàn Ìjọba] kan tí ó gba 500 ènìyàn, àti gbọ̀ngàn ìjẹun kan. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń gbin ewéko tuntun (tí wọ́n pilẹ̀ kó wá láti Finland) àti onírúurú igi ṣíṣọ̀wọ́n. A retí pé wọn yóò parí iṣẹ́ náà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ń bọ̀ yí. Lájorí iṣẹ́ ibùdó ìṣàbójútó náà ni ṣíṣètò ìgbòkègbodò ìwàásù àti kíkó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ sí àwọn ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò. Kò sí àwọn èlò ìtẹ̀wé ní Solnechnoye, nítorí náà, Germany ni wọ́n ti ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè Rọ́ṣíà, tí wọ́n ń kó wá sí St. Petersburg, níbi tí wọ́n ti ń pín in lọ sí àwọn ẹkùn ilẹ̀ náà. Nǹkan bí 190 ènìyàn ní ń ṣiṣẹ́ ní ibùdó náà. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí ìpìlẹ̀ ìyọ̀ǹda ara ẹni, wọn kò sì ń gbowó oṣù, a ń pèsè gbogbo ohun kòṣeémánìí fún wọn, bí ibùgbé, oúnjẹ, àti aṣọ.

“Ìgbìmọ̀ kan tí ó ní alàgbà 18 nínú ní ń ṣe ìtọ́sọ́nà iṣẹ́ náà. Vasily Kalin ti jẹ́ olùṣekòkárí ibùdó ìṣàbójútó náà láti ọdún 1992. A bí i ní Ivano-Frankovsk. Ní 1951, nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin, wọ́n lé òun àti àwọn òbí rẹ̀ lọ sígbèkùn ní Siberia (ní 1949 àti 1951, àwọn aláṣẹ ṣenúnibíni sí nǹkan bí 5,000 ìdílé, nítorí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà). Ó ṣèrìbọmi ní 1965, ó sì gbé ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Irkutsk. Ó ṣiṣẹ́ bí ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ kan tí ń la pákó.

“Yàtọ̀ sí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ti ibùdó ìṣàbójútó náà, àwọn 200 olùyọ̀nda ara ẹni tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ìkọ́lé láti Rọ́ṣíà, Finland, Sweden àti Norway tún ń gbé ní Solnechnoye: Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn gba àyè àkókò díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ àmúṣe wọn. Ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti Ukraine, Moldova, Germany, United States, Finland, Poland àti àwọn orílẹ̀-èdè míràn tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. (Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní ẹ̀tanú ìran. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Georgia, ará Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Abkhaz, ará Azerbaijan àti ará Armenia ló jùmọ̀ ń gbé ní ibùdó náà, láti ọdún mẹ́rin tí wọ́n ti wà níbẹ̀, kò tí ì sí ìforígbárí kankan.)

“Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ohun èlò ìkọ́lé àti ohun èlò ìṣiṣẹ́ náà ni ó jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè Scandinavia ló pèsè rẹ̀, púpọ̀ sì ni àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn pèsè lọ́fẹ̀ẹ́. Wọ́n fi ẹ̀rọ ahúgihúlẹ̀ kan tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ará Sweden kan, gbé wá sí Solnechnoye ní 1993 hàn mí. Ó fi ṣiṣẹ́ ní gbogbo àkókò tí ó wà níbẹ̀, kí ó sì tó pa dà lọ sílé, ó fi fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tí ìsìn pa wọ́n pọ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ ìkọ́lé náà ń gbé inú àwọn ilé ọlọ́gban-anran àti àwọn ilé kéékèèké títura. Wọ́n máa ń lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan báyìí: Agogo méje àárọ̀—oúnjẹ àárọ̀ àti àdúrà; wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti agogo mẹ́jọ òwúrọ̀ di agogo márùn-ún ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ń lo wákàtí kan fún oúnjẹ ọ̀sán. Ní àwọn ọjọ́ Saturday, wọ́n ń ṣiṣẹ́ di àkókò oúnjẹ ọ̀sán, wọ́n sì ń fi Sunday sinmi.

“Wọ́n máa ń jẹun dáadáa, èso sì sábà máa ń wà nínú oúnjẹ wọn. Ìsìn náà kì í gbààwẹ̀, kò sì ka oúnjẹ léèwọ̀ lọ́nàkọnà. Lẹ́yìn iṣẹ́, púpọ̀ lára wọn ń lọ wẹ̀ nílé ìwẹ̀ olómi gbígbóná, lẹ́yìn náà, wọ́n ń mu ìgò bíà kan, wọ́n sì wulẹ̀ ń jókòó, tí wọ́n ń tẹ́tí sí orin. Kò sí ọ̀mùtípara nínú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò ka ọtí líle léèwọ̀ fún wọn. Wọ́n gba àwọn onígbàgbọ́ láyè láti mu wáìnì, ọtí cognac, ọtí vodka àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ níwọ̀nba. Bí ó ti wù kí ó rí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í mu sìgá.

***

“Ìgbà ìjókòó ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́ta, tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń pésẹ̀ síbẹ̀ máa ń jẹ́ ọ̀dọ́, ló wà lọ́sẹ̀. Síbẹ̀, a máa ń rí àwọn tí wọ́n ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún 30 sí 40 ọdún. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn àgbàlagbà náà ló ti lọ sí ẹ̀wọ̀n, àgọ́ ìkóniṣiṣẹ́ àti ìgbèkùn rí. Lẹ́yìn tí sáà ìtẹ̀rì náà kọjá, ọ̀pọ̀ dókítà, amòfin, onímọ̀ ẹ̀rọ, olùkọ́, oníṣòwò, àti akẹ́kọ̀ọ́ ló di ara Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

“Àwọn ìjọ ń gbìyànjú láti dáàbò bo ìmọ̀lára àparò-kan-ò-ga-jùkan-lọ láàárín àwọn mẹ́ńbà wọn. Fún àpẹẹrẹ, olùṣekòkárí ibùdó ìṣàbójútó náà pàápàá máa ń fọ àwo nírọ̀lẹ́ tí ó bá yí kàn án. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà ọlọ́rẹ̀ẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́, wọn yóò sì fi ‘arákùnrin’ tàbí ‘arábìnrin’ kún un bí wọ́n bá ń pe orúkọ ẹnì kan.

“Bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bá tẹ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lójú, tí ó sì kọ̀ láti ronú pìwà dà, ó máa ń gba ìjìyà tí ó le koko jù lọ—wọ́n ń yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ó ṣì lè máa lọ sí ìpàdé, ṣùgbọ́n àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kò ní kí i mọ́. Ìjìyà kan tí kò le tó bẹ́ẹ̀ ni ìbáwí àfitọ́nisọ́nà kan.

***

“Mo lo àkókò púpọ̀ láti ṣọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbígbìyànjú láti ṣàwárí ohun tí ó fa ọ̀pọ̀ ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ wá sínú àjọ onísìn yí. Bí ìyàtọ̀ ti pọ̀ tó nínú àkópọ̀ ìwà ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, ìwọ̀n ẹ̀kọ́ tí wọ́n ní àti ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan fẹ́ràn tàbí tí kò fẹ́ràn, [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ní àjọṣe ìjọsìn pẹ̀lú] àwọn ìsìn tí ń bá ayé ẹlẹ́ṣẹ̀ dọ́rẹ̀ẹ́. Kì í rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti wà níbi tí [àwọn ènìyàn] bá ti gbọ́dọ̀ ní èrò nípa ipò àṣẹ láìronúwò, níbi tí àyè bá ti wà fún ìgbàgbọ́ tí kò ní ìpìlẹ̀ yíyè kooro, níbi tí a bá ti pín àwọn ènìyàn sí ìsọ̀rí àwọn onípò àjùlọ àti àwọn gbáàtúù tí wọ́n ń tẹ̀ lórí ba.

“A dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ yàtọ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ fífìdímúlẹ̀ tí wọ́n ní nínú gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì. Wọ́n ń gbìyànjú láti fi ẹ̀rí ohun gbogbo tí wọ́n bá ṣe hàn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà kan tàbí òmíràn nínú Bíbélì, tàbí nípa títọ́ka sí àyọlò kan láti inú Májẹ̀mú Láéláé tàbí Tuntun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Bíbélì nìkan ṣoṣo péré ló ní ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè. Ní ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Bíbélì ni àkọsílẹ̀ òfin, ìlànà ìwà híhù ti gbogbogbòò àti àgbéjáde òtítọ́ gíga jù lọ.

“Nítorí ìdí yìí, a mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí ń pòfin mọ́ láìlábùkù, ní pàtàkì, a mọ̀ wọ́n fún ìṣarasíhùwà ṣíṣe ẹ̀tọ́ láìkùsíbìkan ní ti sísan owó orí. Ilé iṣẹ́ olówó orí máa ń yẹ̀ wọ́n wò déédéé, nígbà kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń jẹ́ ìyàlẹ́nu láti rí i pé kò sí ìrúfin lọ́nàkọnà. Dájúdájú, bí àwọn ẹlòmíràn ti ń ṣe, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè gbìyànjú láti rí ìdí kan láti má san owó orí, ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣòtítọ́ ní sísan owó orí, kò sì sí ohun kan tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

“Bí ó ti wù kí ó rí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń forí gbárí lọ́nà líléwu pẹ̀lú àwọn ìjọba nítorí ìṣarasíhùwà àìyẹhùn tí wọ́n ní fún Bíbélì. Ìdúró àìdásí-tọ̀túntòsì pátápátá tí wọ́n mú nínú ọ̀ràn ìṣèlú jẹ́ kókó àríyànjiyàn pàtàkì kan, ó sì ń fara hàn nínú kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti sìn nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun.

“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù nípa bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀ kò ṣe jẹ́ apá kan ayé yìí ní olówuuru, nítorí ìdí yìí ni wọ́n sì ṣe kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti ogun, láìka ibi yòó wù kí a ti máa jà á tàbí ohun yòó wù kí ó fà á sí. Nítorí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ láti ké pé ‘Heil Hitler’ kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hitler, a rán ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onígbàgbọ́ lọ sí àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi, ẹgbẹẹgbẹ̀rún sì kú. Ọ̀kọ̀ọ̀kan Ẹlẹ́rìí Jèhófà ará German tí ó kú nítorí pé ó kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ogun lòdì sí Soviet Union ni àwọn ará Rọ́ṣíà kà sí ẹni tí ó ṣe ojúṣe ìwà rere lọ́nà gíga. Nígbà kan náà, bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ àwọn ará Rọ́ṣíà kò ní ìtẹ̀sí láti ní ìyọ́nú fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà [ará Rọ́ṣíà] tí wọ́n pa nítorí pé wọ́n kọ̀ láti dìhámọ́ra kí wọ́n sì jà nínú Ogun Àgbáyé Kejì, tàbí àwọn tí a dá lẹ́bi nítorí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun láàárín àwọn àkókò àlàáfíà. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn méjèèjì, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ìsìn wọn, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìdánilójú ti ìṣèlú.

“Irú ìṣòro kan náà ṣẹlẹ̀ ní Japan láìpẹ́ yìí, níbi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mélòó kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ̀ láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìgbèjà ara ẹni, tí wọ́n sì bọ́ sínú ewu dídi ẹni tí a lé kúrò ní yunifásítì. Ní 1996, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Japan ṣe ìdájọ́ tí ó ti ẹ̀tọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí lẹ́yìn, tí ó sì fún wọn láyè láti lọ sí àwọn ìjókòó ẹ̀kọ́ àfirọ́pò.

***

“Kí ló ń ya àwọn ènìyàn onírònú òde òní lẹ́nu nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ju ohun gbogbo lọ, ó jẹ́ ìwàásù wọn láìdábọ̀ pé òpin ayé ti sún mọ́lé (wọ́n ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní àwọn òpópó àti láti ilé dé ilé). Láìpẹ́ yìí, àwọn alàgbà ti fún àwọn oníwàásù nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe tẹnu mọ́ ‘òpin ayé’ àti àgbákò onídàárò tí yóò dé bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n máa ṣàlàyé pé Jèhófà ń fún wọn ní àǹfààní láti ní ‘ìyè ayérayé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé.’

“Kókó amúnibínú mìíràn ni ìṣarasíhùwà ìlòdìsí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní sí àmúlùmálà ìsìn, àti sísẹ́ tí wọ́n sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú ìṣọ̀kan Kristẹni kárí ayé. Wọ́n gbà gbọ́ pé àwùjọ Kristẹni ti da Ọlọ́run àti Bíbélì, àti pé gbogbo ìsìn tó kù jẹ́ àṣìṣe oníjàábá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi àwọn ìsìn wọ̀nyí wé ‘aṣẹ́wó ti Bábílónì,’ wọ́n sì tẹnu mọ́ ọn pé ohun kan náà ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ìsìn wọ̀nyí. Ìtẹ̀jáde ‘Jí!’ kan ní lọ́ọ́lọ́ọ́ sọ pé òpin onírúurú ìsìn ti sún mọ́lé, àti pé ìsìn kan ṣoṣo tí yóò ṣẹ́ kù ni èyí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀.

“A kò ní ṣàìsọ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́wọ́ ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀rí ọkàn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní.

***

“Àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan ti sọ ìdàníyàn wọn jáde nípa bóyá àwọn ẹ̀kọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni jẹ́ ewu fún ẹgbẹ́ àwùjọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti ìpínlẹ̀ Connecticut, United States (1979) àti New South Wales, Australia (1972), Ilé Ẹjọ́ Ẹkùn Ìpínlẹ̀ British Columbia, Kánádà (1986) àti àwọn ilé ẹjọ́ mìíràn ti polongo pé kò sí ẹ̀rí kankan pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ewu sí ẹgbẹ́ àwùjọ, tàbí pé wọ́n jẹ́ ewu sí ìlera tàbí ìmọ̀lára àwọn ènìyàn. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Europe (1993) gbèjà ẹ̀tọ́ òmìnira ìsìn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní, tí a fòfin dè ní Gíríìsì àti Austria. Lónìí, a ń ṣenúnibíni sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè 25 . . .

“A lè ka Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àpẹẹrẹ fún àwọn aráàlú ẹlẹgbẹ́ wọn nítorí ìtòròpinpin wọn mọ́ òtítọ́ Bíbélì àti ìmúratán wọn láti dúró ti ìgbàgbọ́ wọn láìmọtara-wọn-nìkan tó bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ìbéèrè náà yọjú pé: Àwùjọ wa ha ṣe tán láti pèsè ìdánilójú òmìnira ẹ̀rí ọkàn tí ó bá àkọsílẹ̀ òfin mu fún àwọn àjọ tí ó fi ìtẹnumọ́ kéde ọ̀nà ìgbégbèésẹ̀ wọn tí ó bá Bíbélì mu lórí gbogbo ìhà ìgbésí ayé pátápátá, láìyẹhùn bẹ́ẹ̀?”

Nínú gbólóhùn tí ó kẹ́yìn yí, Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko béèrè ìbéèrè pàtàkì kan. Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tí Kristi yàn ní tààrà láti jẹ́ aṣojú rẹ̀, jìyà “àwọn ìdè ẹ̀wọ̀n” láìtọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nípa ìsapá rẹ̀ nínú “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.”—Fílípì 1:7; Ìṣe 9:3-16.

Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ yọ̀ǹda fún gbogbo ènìyàn láti baralẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbòkègbodò wọn bí Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko ti ṣe. Ó dá wa lójú pé bí àwọn ènìyàn bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò rí i pé àwọn ìròyìn òdì tí wọ́n ti gbọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí kì í ṣe òtítọ́, lọ́nà kan náà tí irú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀ nípa àwọn Kristẹni ìjímìjí kì í fi í ṣe òtítọ́ pẹ̀lú. Lọ́nà títayọ, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣègbọràn sí “àṣẹ tuntun” tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.”—Jòhánù 13:34, 35.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Àkọsílẹ̀ MN

(Wọ́n tẹ àwọn ìsọfúnni tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí láti inú àwọn àkójọ àkọsílẹ̀ ìwé agbéròyìnjáde Moscow News jáde pẹ̀lú àpilẹ̀kọ tí Sergei Ivanenko kọ yìí.)

“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ará Rọ́ṣíà jẹ ara àjọ àwọn Kristẹni kan tí ó wà kárí ayé, tí ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè 233, tí ó sì ní àwọn mẹ́ńbà tí ó jẹ́ mílíọ̀nù 5.4. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tí ó wà ní Brooklyn, New York. Àjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti òde òní bẹ̀rẹ̀ láti inú kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí Charles Taze Russell dá sílẹ̀ ní Pittsburgh, Pennsylvania, ní ọdún 1870. Àjọ náà dé Rọ́ṣíà ní ọdún 1887. Wọ́n lé ọ̀kan lára àwọn ará Rọ́ṣíà tí ó kọ́kọ́ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Semyon Kozlitsky, lọ sí ìgbèkùn láti Moscow sí Siberia ní ọdún 1891. Láìka inúnibíni tí ó kojú àjọ náà sí, ní ọdún 1956, 17,000 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó wà ní Soviet Union. A kò ka Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ní Rọ́ṣíà títí di March 1991, lẹ́yìn tí a gba òfin ‘Lórí Òmìnira Ìsìn’ wọlé. Lónìí, àwọn àwùjọ tí ó lé ní 500, tí ó ní nǹkan bí 70,000 mẹ́ńbà nínú ń gbéṣẹ́ ṣe ní Rọ́ṣíà. Àjọ náà ń pín àwọn ẹ̀dà ‘Ilé Ìṣọ́’ (tí a ń tẹ̀ ní èdè 125, ìpínkiri 20 mílíọ̀nù) àti ‘Jí!’ (ní èdè 81, ìpínkiri mílíọ̀nù 18) kiri.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Apá kan lára ilé ọ́fíìsì ẹ̀ka ní Rọ́ṣíà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, níbi tí ìdílé ẹ̀ka ní Rọ́ṣíà ti ń pàdé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn ìdílé Àwọn Ẹlẹ́rìí jùmọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì jùmọ̀ ń gbádùn eré ìtura

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Wọ́n ń bá àwọn ẹlòmíràn ṣàjọpín ìmọ̀ Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́