Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láre
ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ kò lòdì sí gbígbọ́ nípa ara wọn nínú ìròyìn, bí a bá fi òtítọ́ inú kọ irú ìròyìn bẹ́ẹ̀. Síwájú sí i, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fẹ́ láti pèsè ìsọfúnni tòótọ́ nípa ara wọn àti àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn àti ìgbòkègbodò wọn. Àmọ́, nígbà tí a bá tẹ àwọn àpilẹ̀kọ tí kì í ṣe òtítọ́ jáde, tí ó sì ń ba Àwọn Ẹlẹ́rìí lórúkọ jẹ́, wọ́n máa ń bẹ àwọn aláṣẹ ìjọba láti jẹ́ kí wọ́n gbèjà ẹ̀tọ́ ìjọsìn àti ẹ̀tọ́ òmìnira wọn gẹ́gẹ́ bí ará ìlú. Gbé àpẹẹrẹ kan tí ó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí yẹ̀ wò.
Ní August 1, 1997, Komsomolskaya pravda, ìwé ìròyìn Rọ́ṣíà kan tí ó gbajúmọ̀ tẹ àpilẹ̀kọ kan jáde, nínú àtẹ̀bọnú ẹlẹ́kùnjẹkùn rẹ̀ fún St. Petersburg, tí ó sọ ohun tí kì í ṣe òtítọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ náà, tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Ẹgbẹ́ Òkùnkùn ní Petersburg. Ìlú Ńlá-Tẹ́ńpìlì Kan Yóò Wà Níhìn-ín,” Oleg Zasorin tó kọ ọ́ sọ pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ìgbàgbọ́ wọn ṣe jàǹbá àti pé àwọn ìgbòkègbodò wọn ta ko Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Lájorí àtakò náà jẹ́ fífi èrú yí ìgbàgbọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí nínú Bíbélì po nínú àwọn ọ̀ràn bíi ti ìgbẹ̀jẹ̀sára àti àjọṣepọ̀ ìdílé. Síwájú sí i, àpilẹ̀kọ náà pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní “ẹgbẹ́ òkùnkùn,” ó sì sọ pé lójú àwọn kan, àwọn ni “ẹgbẹ́ òkùnkùn tó burú jù lọ nínú gbogbo ẹgbẹ́ òkùnkùn.”
Ibùjókòó Ìṣàkóso Ẹlẹ́kùnjẹkùn ti Àjọ Ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ Tí Ń Rí sí Àríyànjiyàn Nípa Ìròyìn ní Ilẹ̀ Rọ́ṣíà láti fojú ṣùnnùkùn wo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé ó jẹ́ irọ́. Nígbà ìjókòó Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ náà ní February 12, 1998, àwọn aṣojú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà níbẹ̀, wọ́n sì dáhùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè tí àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀, àwọn akọ̀ròyìn àti àwọn amòfin bi wọ́n. Láti rí àrídájú ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ ní gidi, tí wọ́n sì fi ń kọ́ni, àwọn ọmọ ilé Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ náà fẹ̀sọ̀ yẹ àwọn ìwé tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde wò, ní pàtàkì ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.
V. V. Borshchyov, ọmọ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ìjọba Àpapọ̀ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà, sọ pé ìtumọ̀ òdì pátápátá ni èrò tí ọ̀rọ̀ náà, “àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn,” fi síni lọ́kàn. Ọ̀gbẹ́ni Borshchyov sọ pé: “[Irú] àṣejù àti pípeni-lórúkọ-kórúkọ bẹ́ẹ̀ léwu gan-an. Gbígbà tí Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ gbà láti ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pè ṣe pàtàkì púpọ̀. A gbọ́dọ̀ fòpin sí irú ìdààmú àti àbùkù púpọ̀ tí a ń fi kan àwọn ìsìn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin.”
Lẹ́yìn tí Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ náà gbọ́ gbogbo ẹ̀rí tó wà, wọ́n sọ pé àpilẹ̀kọ tí a kọ sínú ìwé ìròyìn Komsomolskaya pravda náà kò bófin ìlànà ìwà híhù mu; ó tún sọ pé irọ́ ló kún inú rẹ̀ látòkè délẹ̀, kò sì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ náà sọ pé: “Ẹni tó kọ ìwé náà kò sọ òkodoro ọ̀rọ̀ rárá . . . Àhesọ ni ẹni tó kọ ìwé náà ń tàn kálẹ̀ tó ń pè ní ìròyìn tó ṣeé gbíyè lé, ó sì ṣi ẹ̀tọ́ àwọn akọ̀ròyìn lò.” Lòdì sí ohun tí àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn náà sọ, Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ náà rí i pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pòfin mọ́ àti pé wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn láti gbé lálàáfíà pẹ̀lú ìdílé àti àwọn mìíràn tí wọn kò jọ sí nínú ìsìn kan náà.
Wákàtí kan lẹ́yìn tí Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ náà gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹlẹ́rìí tó kẹ́yìn tán, wọ́n gbé ìpinnu wọn jáde pé:
“1. A ka títẹ àpilẹ̀kọ náà, ‘Ẹgbẹ́ Òkùnkùn ní Petersburg. Ìlú Ńlá-Tẹ́ńpìlì Kan Yóò Wà Níhìn-ín,’ sí rírú òfin ohun tí Ẹ̀ka 4, 49, àti 51 nínú Òfin Àpapọ̀ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà béèrè ‘Lọ́wọ́ Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn.’
“2. A dámọ̀ràn pé kí Ìgbìmọ̀ Ìjọba Àpapọ̀ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìtẹ̀ròyìnjáde ní Ìpínlẹ̀ náà tún gbé ọ̀ràn kíkìlọ̀ fún àjọ olóòtú ìwé ìròyìn Komsomolskaya pravda yẹ̀ wò.
“3. Kí a bá O. Zasorin tó kọ ìròyìn náà wí.
“4. A dámọ̀ràn pé kí àjọ olóòtú ìwé ìròyìn Komsomolskaya pravda kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ nítorí títẹ ohun tí kì í ṣe òtítọ́ jáde, èyí tí ń tẹ́ńbẹ́lú ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìnídìí.”
Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ ṣe yìí bára mu pẹ̀lú èrò ọ̀gbẹ́ni Sergei Ivanenko, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tí ó tún jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ oyè ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n èrò orí. Lẹ́yìn tí Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko, tí kì í ṣe ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fara balẹ̀ wádìí nípa ìgbàgbọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó sì rìn mọ́ wọn, ó kọ àpilẹ̀kọ kan tí ó jáde nínú ìwé ìròyìn Moscow News,a February 20 sí 26, 1997. Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko sọ pé: “A dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ yàtọ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ fífìdímúlẹ̀ tí wọ́n ní nínú gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì. . . . Ní ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Bíbélì ni àkọsílẹ̀ òfin, ìlànà ìwà híhù ti gbogbo gbòò àti àgbéjáde òtítọ́ gíga jù lọ. . . . A lè ka Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àpẹẹrẹ fún àwọn aráàlú ẹlẹgbẹ́ wọn nítorí bí ìtòròpinpin wọn mọ́ òtítọ́ Bíbélì àti ìmúratán wọn láti dúró ti ìgbàgbọ́ wọn láìmọtara wọn nìkan ti pọ̀ tó.”
Ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ ṣe àti ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko sọ tún fìdí ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìsìn Kristẹni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ewu fún àwùjọ rárá, àmọ́, ó ń ṣiṣẹ́ fún ire gbogbo ẹni tó bá lọ́kàn òtítọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ‘wà ní ìmúratán láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ wọn ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú wọn, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.’—1 Pétérù 3:15.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àpilẹ̀kọ Ọ̀gbẹ́ni Ivanenko, tí ó ní àkọlé náà, “A Ha Gbọ́dọ̀ Máa Bẹ̀rù Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Bí?,” ni a gba àṣẹ láti tún tẹ̀ jáde nínú ìtẹ̀jáde Jí!, August 22, 1997, ojú ìwé 22 sí 27.