Gbígbèjà Ìgbàgbọ́ Wa
“Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín.”—1 PÉTÉRÙ 3:15.
1, 2. Èé ṣe tí àtakò kò ya Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu, ṣùgbọ́n kí ni ìfẹ́ àtọkànwá wọn?
NÍ Ọ̀PỌ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni a mọ̀ sí olóòótọ́ àti onígbèé-ayé rere. Ọ̀pọ̀ kà wọ́n sí aládùúgbò rere tí kì í fa wàhálà. Ṣùgbọ́n, ó mà ṣe o, àwọn Kristẹni olùfẹ́ àlàáfíà wọ̀nyí ti fojú winá inúnibíni lọ́nà àìtọ́—ní àkókò ogun àti àlàáfíà. Irú àtakò bẹ́ẹ̀ kò yà wọ́n lẹ́nu. Kódà, ṣe ni wọ́n ń retí rẹ̀. Ó ṣe tán, wọ́n mọ̀ pé àwọn Kristẹni olóòótọ́ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa jẹ́ “ẹni ìkórìíra,” nítorí náà èé ṣe tí àwọn tí ń sapá láti jẹ́ ọmọlẹ́yìn tòótọ́ ti Kristi lónìí yóò fi retí pé kí tàwọn yàtọ̀? (Mátíù 10:22) Ìyẹn nìkan kọ́, Bíbélì sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.”—2 Tímótì 3:12.
2 Kì í kúkú ṣe pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wá inúnibíni, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbádùn àwọn ìnira tí ń bá a rìn, bí owó ìtanràn, ìfinisẹ́wọ̀n, tàbí ìfojú-ẹni-gbolẹ̀. Wọ́n fẹ́ láti máa ‘gbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́’ kí wọ́n lè máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láìsí ìdíwọ́. (1 Tímótì 2:1, 2) Wọ́n mọrírì òmìnira ẹ̀sìn tí wọ́n ní lọ́pọ̀ jù lọ ilẹ̀ láti lè máa bá ìjọsìn wọn nìṣó, wọ́n sì ń fi tọkàntọkàn ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn,” títí kan àwọn alákòóso ìjọba ènìyàn. (Róòmù 12:18; 13:1-7) Kí wá ni ìdí tí wọ́n fi jẹ́ “ẹni ìkórìíra”?
3. Kí ni ìdí kan tí a fi kórìíra Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́nà àìtọ́?
3 Ní pàtàkì, ìdí kan náà tí wọ́n fi ṣe inúnibíni sí àwọn Kristẹni ìjímìjí ló mú kí wọ́n kórìíra Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́nà àìtọ́. Èkíní, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ẹ̀sìn wọn ṣèwà hù lọ́nà tí ń mú kí àwọn kan fojú burúkú wò wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, pẹ̀lú ìtara ni wọ́n fi ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn sábà máa ń ṣi ìtara wọn lóye, tí wọ́n ń pe ìwàásù wọn ní “yíyíni lọ́kàn padà tipátipá.” (Fi wé Ìṣe 4:19, 20.) Wọn kì í dá sí tọ̀tún tòsì tó bá kan ọ̀ràn òṣèlú àti ogun àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn kan sì ti gba eléyìí sódì, wọ́n ní ọlọ̀tẹ̀ ni Àwọn Ẹlẹ́rìí.—Míkà 4:3, 4.
4, 5. (a) Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe di àwọn tí a ń fẹ̀sùn èké kàn? (b) Àwọn wo ni olórí alátakò tó sábà ń ru inúnibíni sókè sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà?
4 Ìkejì, wọ́n ti fi oríṣiríṣi ẹ̀sùn èké kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—irọ́ pátápátá àti lílọ́ àwọn ìgbàgbọ́ wọn po. Nítorí èyí, wọ́n ń dojúùjà kọ wọ́n láìnídìí. Síwájú sí i, nítorí pé wọ́n máa ń béèrè fún ìtọ́jú tí kò wé mọ́ lílo ẹ̀jẹ̀, èyí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ wọn láti ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì láti ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀,’ wọ́n ti fi ìṣìnà sọ wọ́n ní àwọn orúkọ bí “àwọn apọmọwẹ́wẹ́” àti “ẹgbẹ́ awo àwọn apara-ẹni.” (Ìṣe 15:29) Ṣùgbọ́n òtítọ́ náà gan-an ni pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka ìwàláàyè sí iyebíye, wọ́n sì ń wá bí àwọn yóò ṣe rí ìtọ́jú tó dára jù lọ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Irọ́ gbuu ni ẹ̀sùn náà pé àìmọye àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń kú lọ́dọọdún nítorí kíkọ̀ láti gbẹ̀jẹ̀ sára. Ní àfikún sí i, nítorí pé òtítọ́ Bíbélì kì í ní ipa kan náà lórí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé, a tún ti fẹ̀sùn kan Àwọn Ẹlẹ́rìí pé wọ́n ń tú ìdílé ká. Bẹ́ẹ̀ rèé, àwọn tó bá mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé wọn kò fọwọ́ kékeré mú ọ̀ràn ìdílé, wọ́n sì ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn àṣẹ Bíbélì pé kí tọkọtaya nífẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, àti pé kí àwọn ọmọ máa ṣègbọràn sí òbí wọn, yálà wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ tàbí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́.—Éfésù 5:21–6:3.
5 Àìmọye ìgbà ló ti jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́sìn ni olórí alátakò tó ti ń ru inúnibíni sókè sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, àwọn ló sì ti ń lo agbára wọn lórí àwọn olóṣèlú àti ilé iṣẹ́ ìròyìn láti gbìyànjú láti tẹ iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí rì. Kí ni kí àwa, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣe sí irú àtakò bẹ́ẹ̀—yálà ó jẹ yọ nítorí àwọn ìgbàgbọ́ àti ìṣarasíhùwà wa tàbí nítorí ẹ̀sùn èké?
“Ẹ Jẹ́ Kí Ìfòyebánilò Yín Di Mímọ̀ fún Gbogbo Ènìyàn”
6. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti ní ojú ìwòye tó wà déédéé nípa àwọn tó wà lóde ìjọ Kristẹni?
6 Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ ní ojú ìwòye títọ́—ojú ìwòye Jèhófà—nípa àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wa. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè máa fọwọ́ ara wa fa ẹ̀tanú àti ẹ̀gàn wá bá ara wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì rọ̀ wá láti ní ojú ìwòye tó wà déédéé nípa àwọn tó wà lóde ìjọ Kristẹni.
7. Kí ni ‘pípa ara wa mọ́ láìní èérí nínú ayé’ wé mọ́?
7 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Ìwé Mímọ́ ṣí wa létí lọ́nà tó yéni yéké pé kí a “pa ara [wa] mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.” (Jákọ́bù 1:27; 4:4) Ọ̀rọ̀ náà, “ayé” níhìn-ín, gẹ́gẹ́ bí a ti lò ó níbi púpọ̀ nínú Bíbélì, tọ́ka sí aráyé lápapọ̀ yàtọ̀ sí àwọn Kristẹni tòótọ́. Inú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà yìí là ń gbé; àwọn la jọ ń ṣiṣẹ́, ta jọ ń lọ iléèwé, ta jọ ń gbé ládùúgbò. (Jòhánù 17:11, 15; 1 Kọ́ríńtì 5:9, 10) Síbẹ̀síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ pa ara wa mọ́ láìní èérí nínú ayé nípa yíyàgò fún ẹ̀mí, ọ̀rọ̀, àti ìṣesí tó lòdì sí ọ̀nà òdodo Ọlọ́run. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí a mọ̀ pé ó léwu láti máa ṣe wọlé wọ̀de pẹ̀lú ayé yìí, ní pàtàkì pẹ̀lú àwọn tí kò ka àwọn ìlànà Jèhófà sí rárá.—Òwe 13:20.
8. Èé ṣe tí ìmọ̀ràn tí a fún wa láti pa ara wa mọ́ láìní èérí nínú ayé kò wá sọ pé kí a máa fojú pa àwọn yòókù rẹ́?
8 Àmọ́ ṣá o, ìmọ̀ràn náà pé kí a pa ara wa mọ́ láìní èérí nínú ayé kò wá sọ pé ká máa fojú pa àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà rẹ́. (Òwe 8:13) Rántí àpẹẹrẹ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù, tí a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú. Irú ẹ̀sìn tí wọ́n dá sílẹ̀ kò rí ojú rere Jèhófà; bẹ́ẹ̀ náà ni kò tún àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Júù ṣe. (Mátíù 21:43, 45) Nínú ipò ìjọra-ẹni-lójú tí wọ́n lé téńté sí, àwọn agbawèrèmẹ́sìn wọ̀nyí fojú kó àwọn Kèfèrí mọ́lẹ̀. A kì í ní irú ojú ìwòye aláìgbatẹnirò bẹ́ẹ̀, kí á wá máa ṣáátá àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìfẹ́ wa ni pé kí gbogbo àwọn tó bá gbọ́ ìhìn òtítọ́ Bíbélì jèrè ojú rere Ọlọ́run.—Ìṣe 26:29; 1 Tímótì 2:3, 4.
9. Ipa wo ló yẹ kí ojú ìwòye tó wà déédéé, tó sì bá Ìwé Mímọ́ mu ní lórí ọ̀rọ̀ tí a bá ń sọ nípa àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wa?
9 Ojú ìwòye tó wà déédéé, tó bá Ìwé Mímọ́ mu, ló yẹ kó máa pinnu ọ̀rọ̀ tí a bá ń sọ nípa àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù pé kí ó rán àwọn Kristẹni tó wà ní erékùṣù Kírétè létí “láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.” (Títù 3:2) Ṣàkíyèsí pé a ní kí àwọn Kristẹni má sọ̀rọ̀ “ẹnì kankan” lọ́nà ìbàjẹ́—kódà àwọn ará Kírétè tí kì í ṣe Kristẹni, bẹ́ẹ̀ rèé a mọ àwọn kan lára wọn sí òpùrọ́, alájẹkì, àti ọ̀lẹ. (Títù 1:12) Nítorí náà, yóò lòdì sí Ìwé Mímọ́ bí a bá ń lo èdè ẹ̀gàn nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wa. Kíka ara wa sí ẹni tó mọ́ ju àwọn yòókù lọ kò ní jẹ́ kí ìjọsìn Jèhófà wu àwọn ènìyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí a bá ń bá àwọn ènìyàn lò ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tó mọ́gbọ́n dání tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà, a ‘ń ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọ́run lọ́ṣọ̀ọ́.’—Títù 2:10.
Ìgbà Dídákẹ́ Jẹ́ẹ́, Ìgbà Sísọ̀rọ̀
10, 11. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ (a) “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́”? (b) “ìgbà sísọ̀rọ̀”?
10 Oníwàásù 3:7 sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. Ìṣòro náà gan-an nìyẹn: mímọ ìgbà tí kò yẹ kí a ṣú já àwọn alátakò àti ìgbà tó yẹ kí a gbèjà ìgbàgbọ́ wa. A lè rí ohun púpọ̀ kọ́ nínú àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ní ìfòyemọ̀ pípé—ẹni yìí ni Jésù. (1 Pétérù 2:21) Ó mọ “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́.” Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin fẹ̀sùn kàn án níwájú Pílátù, Jésù “kò dáhùn.” (Mátíù 27:11-14) Kò fẹ́ sọ nǹkan kan tó lè dí i lọ́wọ́ lẹ́nu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yàn láti jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ òun gbèjà òun. Ó mọ̀ pé òtítọ́ pàápàá kò lè yí èrò inú àti ọkàn-àyà wọn onígbèéraga padà. Nípa báyìí, ó dágunlá sí ẹ̀sùn wọn, ó dákẹ́, kò gbin.—Aísáyà 53:7.
11 Ṣùgbọ́n o, Jésù tún mọ “ìgbà sísọ̀rọ̀.” Nígbà kan, ó bá àwọn lámèyítọ́ fà á ní gbangba, ó jádìí àwọn ẹ̀sùn èké wọn. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn akọ̀wé òfin àti Farisí fẹ́ kàn án lábùkù lójú ogunlọ́gọ̀ kan nípa fífẹ̀sùnkàn án pé Béélísébúbù ló fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, Jésù yàn láti bi àwọn ẹ̀sùn èké wọn wó. Pẹ̀lú ọgbọ́n tó fakíki àti àpèjúwe tó múná dóko, ó dojú irọ́ náà bolẹ̀. (Máàkù 3:20-30; tún wo Mátíù 15:1-11; 22:17-21; Jòhánù 18:37) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, lẹ́yìn tí wọ́n da Jésù, tí wọ́n mú un, tí wọ́n sì wọ́ ọ lọ síwájú Sànhẹ́dírìn, Káyáfà Àlùfáà Àgbà fi ọgbọ́n àrékérekè béèrè pé: “Mo fi Ọlọ́run alààyè mú kí o wá sábẹ́ ìbúra láti sọ fún wa yálà ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run!” Èyí pẹ̀lú jẹ́ “ìgbà sísọ̀rọ̀,” nítorí pé dídákẹ́ lè túmọ̀ sí pé ó sẹ́ pé òun kọ́ ni Kristi. Nítorí náà, Jésù dáhùn pé: “Èmi ni.”—Mátíù 26:63, 64; Máàkù 14:61, 62.
12. Àwọn ipò wo ló mú kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi àìṣojo sọ̀rọ̀ ní Íkóníónì?
12 Tún gbé àpẹẹrẹ ti Pọ́ọ̀lù àti ti Bánábà yẹ̀ wò. Ìṣe 14:1, 2, sọ pé: “Ní Íkóníónì, wọ́n jùmọ̀ wọ sínágọ́gù àwọn Júù, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ní irúfẹ́ ọ̀nà tí ó fi jẹ́ pé ògìdìgbó ńlá àwọn Júù àti Gíríìkì di onígbàgbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn Júù tí kò gbà gbọ́ ru ọkàn àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè sókè, wọ́n sì ní ipa tí kò tọ́ lórí wọn lòdì sí àwọn arákùnrin.” The New English Bible kà pé: “Ṣùgbọ́n àwọn Júù aláìgbàgbọ́ ru àwọn Kèfèrí sókè, wọ́n fẹnu ba àwọn Kristẹni jẹ́ lọ́dọ̀ wọn.” Kíkọ̀ tí àwọn fúnra wọn kọ ìhìn náà sílẹ̀ kò tó àwọn Júù alátakò, ṣe ni wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí polongo ẹ̀sùn èké, tí wọ́n ń gbìyànjú láti gbin ẹ̀tanú sọ́kàn àwọn Kèfèrí lòdì sí àwọn Kristẹni.a Wọ́n mà kúkú kórìíra ẹ̀sìn Kristẹni o! (Fi wé Ìṣe 10:28.) Pọ́ọ̀lù àti Bánábà rí i pé “ìgbà sísọ̀rọ̀” nìyí, kí ẹ̀gàn ìtagbangba yìí má bàa sọ ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn tuntun domi. “Nítorí náà, wọ́n [Pọ́ọ̀lù àti Bánábà] lo àkókò gígùn ní sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà,” ẹni tó fọwọ́ sí ohun tí wọ́n ṣe nípa fífún wọn lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé àwọn kan “wà fún àwọn Júù ṣùgbọ́n àwọn mìíràn fún àwọn àpọ́sítélì.”—Ìṣe 14:3, 4.
13. Nígbà tí a bá pẹ̀gàn wa, ìgbà wo ló sábà máa ń jẹ́ “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́”?
13 Báwo wá ni ó ṣe yẹ ká dáhùn padà nígbà tí wọ́n bá pẹ̀gàn wa? Gbogbo rẹ̀ sinmi lórí ipò tó yí i ká. Àwọn ipò kan yóò béèrè pé kí a lo ìlànà “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́.” Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nígbà tí àwọn kìígbọ́-kìígbà alátakò bá ń gbìyànjú láti mú wa wọnú ìjiyàn tí kò wúlò. A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé àwọn kan wà tí kò wulẹ̀ fẹ́ mọ òtítọ́. (2 Tẹsalóníkà 2:9-12) Gbígbìyànjú láti fèròwérò pẹ̀lú àwọn ọlọ́kàn gíga tó ti jingíri sínú àìgbàgbọ́ kò lè sèso rere kankan. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bó bá jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹlẹ́sùn èké ni a ń bá fà á, a lè mú wa yà bàrá kúrò nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì tó sì lérè nínú jù lọ—iṣẹ́ ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn olóòótọ́ ọkàn tó ń fẹ́ gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì. Nítorí náà, nígbà tí àwọn aṣòdìsíni tí wọ́n ti fi í ṣe góńgó wọn láti tan irọ́ kálẹ̀ nípa wa bá kò wá lójú, ìmọ̀ràn onímìísí ni: “Yẹra fún wọn.”—Róòmù 16:17, 18; Mátíù 7:6.
14. Ní àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà gbèjà ìgbàgbọ́ wa níwájú àwọn ẹlòmíràn?
14 Èyí kò wá túmọ̀ sí pé a kò ní gbèjà ìgbàgbọ́ wa. Ó ṣe tán, “ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. Ó dùn wá pé wọ́n ti sọ̀rọ̀ wa ní búburú fún àwọn èèyàn kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn. Àwa yóò fẹ́ láti ṣe àlàyé tó ṣe kedere fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ìgbàgbọ́ wa àtọkànwá; ní tòótọ́, inú wa yóò dún bí àǹfàànì rẹ̀ bá yọ. Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Tí àwọn ojúlówó olùfìfẹ́hàn bá béèrè ẹ̀rí fún àwọn ohun tí a gbà gbọ́ tọkàntọkàn, tí wọ́n bá béèrè nípa àwọn ẹ̀sùn èké tí àwọn alátakò fi ń kàn wá, ojúṣe wa ni láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa, kí a pèsè àwọn ìdáhùn yíyèkooro tó bá Bíbélì mu. Ní àfikún, ẹ̀rí tí ìwà rere wa ń jẹ́ kò kéré. Bí àwọn alákìíyèsí tí wọ́n jẹ́ aláìlábòsí ti ń rí i pé lóòótọ́ ni a ń gbìyànjú láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Ọlọ́run, kíá ló máa hàn sí wọn pé irọ́ ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá.—1 Pétérù 2:12-15.
Nípa Àwọn Ìròyìn Tí Ń Bani Lórúkọ Jẹ́ Ńkọ́?
15. Kí ni àpẹẹrẹ kan nípa bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jẹ́ àwọn tí ilé iṣẹ́ ìròyìn fẹ́ bà lórúkọ jẹ́?
15 Nígbà mìíràn, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ti gbé ìsọfúnni èké jáde nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, ní August 1, 1997, ìwé ìròyìn ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan gbé àpilẹ̀kọ tí ń bani lórúkọ jẹ́ jáde, lára ohun tó sọ ni pé Àwọn Ẹlẹ́rìí dìídì máa ń pa á láṣẹ fún àwọn mẹ́ńbà wọn pé kí wọ́n ‘pa ìyàwó wọn, ọkọ wọn, àti àwọn òbí wọn tì, bí àwọn wọ̀nyí kò bá lóye ẹ̀sìn wọn, tí wọn kò sì ṣe ẹ̀sìn wọn.’ Ẹnikẹ́ni tó bá mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa mọ̀ pé ẹ̀sùn èké nìyí. Bíbélì fi hàn pé àwọn Kristẹni ní láti máa fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lò, Àwọn Ẹlẹ́rìí sì máa ń sapá láti tẹ̀ lé ìtọ́ni yẹn. (1 Kọ́ríńtì 7:12-16; 1 Pétérù 3:1-4) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, wọ́n tẹ àpilẹ̀kọ náà jáde, wọ́n sì tipa báyìí ṣi ọ̀pọ̀ àwọn tó kà á lọ́nà. Báwo la ṣe lè gbèjà ìgbàgbọ́ wa nígbà táa bá fẹ̀sùn èké kàn wá?
16, 17, àti àpótí tó wà lójú ìwé 16. (a) Kí ni Ilé Ìṣọ́ sọ nígbà kan rí nípa fífèsì sí ìsọfúnni èké láti ọ̀dọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn? (b) Àwọn ipò wo ló lè mú kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fèsì sí àwọn ìròyìn búburú láti ọ̀dọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn?
16 Lẹ́ẹ̀kan sí i, “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà. Nígbà kan rí, Ilé-Ìṣọ́nà sọ ọ́ báyìí: “Yálà a pa ìsọfúnni èké inú ìròyìn tì tàbí a gbèjà òtítọ́ lọ́nà tí ó yẹ sinmi lórí àyíká-ipò, ẹni tí ń súnná sí ìṣelámèyítọ́ náà, àti góńgó rẹ̀.” Nígbà mìíràn, ó sàn láti má ṣe ṣú já àwọn ìròyìn búburú nípa wa, kí a má bàa tún máa tan irọ́ ọ̀hún kálẹ̀.
17 Ní àwọn ìgbà mìíràn, ó lè jẹ́ “ìgbà sísọ̀rọ̀.” Wọ́n lè ti sọ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe òótọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún oníròyìn kan tó ní láárí, ó sì lè fẹ́ gbọ́ òótọ́ nípa wa. (Wo àpótí náà, “Ṣíṣàtúnṣe Ọ̀rọ̀ Ìbanilórúkọjẹ́.”) Bí àwọn ìròyìn búburú nípa wa láti ọ̀dọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn bá fa ẹ̀tanú tí ń ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìwàásù wa, àwọn aṣojú ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Watch Tower Society lè gbé ìgbésẹ̀ láti gbèjà òtítọ́ lọ́nà tó bójú mu.b Fún àpẹẹrẹ, bí ó bá jẹ́ pé ṣíṣàì sọ̀rọ̀ lè túmọ̀ sí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò rí nǹkan fi dáhùn, wọ́n lè yan àwọn alàgbà tó tóótun láti sọ bí ọ̀ràn náà ṣe jẹ́ gan-an, ó lè jẹ́ lórí ètò tẹlifíṣọ̀n kan. Yóò bọ́gbọ́n mu kí Àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́ni Watch Tower Society àti àwọn aṣojú rẹ̀ nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.—Hébérù 13:17.
Gbígbèjà Ìhìn Rere Lọ́nà Òfin
18. (a) Èé ṣe tí a kò nílò láti gbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn ìjọba ènìyàn láti wàásù? (b) Nígbà tí wọn kò bá gbà wá láyè láti wàásù, ìgbésẹ̀ wo ni a ń gbé?
18 Àtọ̀runwá ni a ti gbàṣẹ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. A ti fún Jésù, tó gbé iṣẹ́ yìí lé wa lọ́wọ́, ní ‘gbogbo ọlá àṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.’ (Mátíù 28:18-20; Fílípì 2:9-11) Fún ìdí yìí, a kò nílò láti gbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn ìjọba ènìyàn láti wàásù. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a mọ̀ pé níní òmìnira ẹ̀sìn ṣe pàtàkì fún títan ìhìn Ìjọba náà kálẹ̀. Ní àwọn ilẹ̀ tí a bá ti ní òmìnira láti máa jọ́sìn, a ó fi òfin dáàbò bò ó. Níbi tí wọ́n bá ti fi irúfẹ́ òmìnira bẹ́ẹ̀ dù wá, a ó sapá, lábẹ́ òfin, láti rí òmìnira ọ̀hún gbà. Góńgó wa kì í ṣe láti ṣàtúnṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, bí kò ṣe “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.”c—Fílípì 1:7.
19. (a) Kí ni ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìyọrísí ‘sísan tí a bá ń san àwọn ohun ti Ọlọ́run padà fún Ọlọ́run’? (b) Kí ni a ti pinnu láti ṣe?
19 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Jèhófà ni a mọ̀ sí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé. Òfin rẹ̀ ló ga jù lọ. A ń fi òtítọ́ inú ṣègbọràn sí àwọn ìjọba ènìyàn, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì.” Ṣùgbọ́n a ò ní jẹ́ kí nǹkan kan dí wa lọ́wọ́ ṣíṣe ojúṣe wa tó ṣe pàtàkì jù lọ—‘sísan àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.’ (Mátíù 22:21) Ó yé wa yékéyéké pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò sọ wá di “ẹni ìkórìíra” lọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n a ka èyí sí ara ohun tí dídi ọmọlẹ́yìn ń náni. Itú tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pa nínú àkọsílẹ̀ ìgbẹ́jọ́ ní ọ̀rúndún ogún yìí ń jẹ́ ẹ̀rí sí ìpinnu wa láti gbèjà ìgbàgbọ́ wa. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹyìn Jèhófà, a ó máa bá a lọ “láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere.”—Ìṣe 5:42.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé náà, Matthew Henry’s Commentary on the Whole Bible ṣàlàyé pé àwọn Júù alátakò “sọ ọ́ diṣẹ́ wọn láti dìídì lọ bá [àwọn Kèfèrí] tí wọ́n bá mọ̀, kí wọ́n sì sọ gbogbo ohun tí wọ́n bá lè fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tàbí inú burúkú hùmọ̀, kí wọ́n bàa lè gbin èrò játijàti, àní èrò ibi pàápàá sí wọn lọ́kàn nípa ẹ̀sìn Kristẹni.”
b Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́ yẹn jáde nínú ìwé ìròyìn Rọ́ṣíà náà (tí a mẹ́nu kàn ní ìpínrọ̀ 15), Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ké gbàjarè sí Ìgbìmọ̀ Amójútó Ọ̀ràn Ìdájọ́ Tí Ń Rí sí Àríyànjiyàn Nípa Ìròyìn ní Ilẹ̀ Rọ́ṣíà, pé kí wọ́n dákun ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀sùn èké tí àpilẹ̀kọ náà gbé jáde. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ilé ẹjọ́ náà gbé ìpinnu kan jáde tó na ìwé ìròyìn náà lẹ́gba ọ̀rọ̀ fún títẹ irú àpilẹ̀kọ burúkú bẹ́ẹ̀.—Wo Ji!, December 8, 1988, ojú ìwé 26 sí 27.
c Wo àpilẹ̀kọ náà, “Dídáàbò Bo Ìhìn Rere Lọ́nà Òfin,” lójú ìwé 19 sí 22.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Èé ṣe tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi jẹ́ “ẹni ìkórìíra”?
◻ Ojú wo ló yẹ kí a máa fi wo àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà ẹ̀sìn wa?
◻ Ní dídá àwọn alátakò lóhùn, àpẹẹrẹ tó wà déédéé wo ni Jésù fi lélẹ̀?
◻ Nígbà tí a bá pẹ̀gàn wa, báwo ni a ṣe lè lo ìlànà náà tó sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà sísọ̀rọ̀” wà?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ṣíṣàtúnṣe Ọ̀rọ̀ Ìbanilórúkọjẹ́
“Ní ìlú Yacuiba, Bolivia, ẹgbẹ́ ajíhìnrere kan ládùúgbò yẹn ṣètò pé kí ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan gbé fíìmù kan tí àwọn apẹ̀yìndà ṣe sáfẹ́fẹ́. Nítorí ipa búburú tí ètò náà ní, àwọn alàgbà pinnu láti ṣèbẹ̀wò sí ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n méjì, wọn sọ pé àwọn yóò sanwó fún wọn bí wọ́n bá lè gbé àwọn fídíò náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name àti The Bible—A Book of Fact and Prophecy sáfẹ́fẹ́ fún gbogbo ènìyàn. Lẹ́yìn wíwò fídíò Society, ẹnì kan tí ó ni ilé iṣẹ́ rédíò bínú gidigidi sí àwọn ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́ tó wà nínú ètò àwọn apẹ̀yìndà náà, ó sì fínnú fíndọ̀ yọ̀ǹda láti ṣètò àwọn ìfilọ̀ ráńpẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa àpéjọpọ̀ àgbègbè wọn tí ń bọ̀. Àwọn tó wá sí àpéjọpọ̀ ọ̀hún pọ̀, a ò rírú ẹ̀ rí níbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè àwọn ìbéèrè àtọkànwá nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀ wọ́n wò nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́.”—1997 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 61 sí 62.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Nígbà kan, Jésù jádìí ẹ̀sùn èké àwọn alátakò rẹ̀ ní gbangba