Bí Àwọn Kristian Ṣe Ń Kojú Ẹ̀gàn Ní Gbangba
IRÚ ìmọ̀lára wo ni o máa ń ní nígbà tí ẹnì kan bá kẹ́gàn rẹ tàbí tí ó tan irọ́ kálẹ̀ nípa rẹ? Lọ́nà ti ẹ̀dá yóò dùn ọ́ wọra. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń nímọ̀lára ohun tí ó jọ èyí nígbàkígbà tí wọ́n bá ti di àyànsọjú fún ìsọfúnni tí kò tọ̀nà tàbí tí a lọ́ lọ́rùn nínú ìròyìn. Ṣùgbọ́n bí Jesu ti sọ nínú Matteu 5:11, 12, wọ́n ṣì ní ìdí láti ní ìdùnnú-ayọ̀.
Fún àpẹẹrẹ, ìtẹ̀jáde ti Katoliki ní Germany sọ pé “ó pọndandan fún Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan láti dá láàárín ìpín 17 àti 28 lórí ọgọ́rùn ùn nínú owó tí ń wọlé fún un sí orílé-iṣẹ́ ẹ̀ya ìsìn náà.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, kì í ṣe ẹ̀ya ìsìn, iṣẹ́ wọn ni a sì ń tìlẹ́yìn látòkèdélẹ̀ pẹ̀lú owó tí ń wá láti inú àwọn ọrẹ àtinúwá. Ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé ni a ti ṣì lọ́nà nípa ìsọfúnni tí kò tọ̀nà yìí, tí ó dun àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn Kristian tòótọ́ ṣe níláti kojú ẹ̀gàn láti inú ìròyìn?
Àpẹẹrẹ fún Àwọn Kristian Lati Tẹ̀lé
Matteu orí 23 ṣàpèjúwe ketekete bí Jesu ṣe fi àwọn alátakò onísìn bú nítorí ìwà àgàbàgebè àti ẹ̀tàn wọn. Èyí ha fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn Kristian lónìí nípa bí wọ́n ṣe níláti kojú àwọn aṣelámèyítọ́ bí? Kì í ṣe níti gidi. Ọmọkùnrin Ọlọrun fi àwọn alátakò onísìn bú lórí ìpìlẹ̀ pé ó ní ọlá-àṣẹ aláìlẹ́gbẹ́ àti òye tí ó jinlẹ̀, ó ṣe èyí fún àǹfààní àwọn àwùjọ tí ń gbọ́ ọ.
Matteu 15:1-11 sọ pé Jesu ni a ṣe lámèyítọ́ sí nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni a sọ pé wọ́n ré àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù kọjá. Báwo ni Jesu ṣe hùwàpadà? Ó dúró láìyẹsẹ̀. Ní àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan, Jesu sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀bọpobọyọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣelámèyítọ́ rẹ̀, ó sì já àwọn èrò wọn tí kò tọ̀nà nírọ́. Ní gbogbogbòò, àwọn Kristian lónìí kò ṣe ohun tí kò tọ́ bí wọ́n bá gbìyànjú láti tún èrò tí kó tọ̀nà tí àwọn ènìyàn ní nípa iṣẹ́ wọn tàbí nípa ẹ̀kọ́ wọn ṣe, tí wọ́n bá ń gbìdánwò láti mú ipò náà ṣe kedere lọ́nà tí a gbékarí òtítọ́ gidi tí ó sì bọ́gbọ́nmu. Wọ́n ń ṣe èyí láti ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé kò sí ìdí kankan fún ṣíṣe lámèyítọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ó sì tún jẹ́ ìbanilórúkọjẹ́.
Ṣùgbọ́n ṣàkíyèsí bí Jesu ti hùwàpadà kété lẹ́yìn náà nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ tọ́ka sí i pé: “Iwọ ha mọ̀ pé awọn Farisi kọsẹ̀ ní gbígbọ́ ohun tí o wí?” Àwọn Farisi wọ̀nyí ti “kọsẹ̀”—kì í wulẹ̀ ṣe pé ọkàn wọn gbọgbẹ́ nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n di alátakò paraku tí Jesu ti kọ̀. Fún ìdí èyí ó dáhùn pé: “Ẹ jọ̀wọ́ wọn. Afọ́jú afinimọ̀nà ni wọ́n.” Ìjíròrò síwájú síi pẹ̀lú irú àwọn akóguntini abánirojọ́ báyìí kò mọ́gbọ́ndání, kò lè ṣàǹfààní fún ẹnikẹ́ni, yóò sì yọrí sí iyàn jíjà tí kò wúlò rárá. (Matteu 7:6; 15:12-14; fiwé 27:11-14.) Èsì tí Jesu fún wọn fi hàn pé “ìgbà dídákẹ́, àti ìgbà fífọhùn” wà.—Oniwasu 3:7.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò retí pé kí gbogbo ènìyàn sọ̀rọ̀ wọn ní rere. Wọ́n fi ọ̀rọ̀ Jesu sọ́kàn pé: “Ègbé, nígbàkígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní dáadáa, nitori awọn nǹkan bí iwọnyi ni awọn baba-ńlá wọn ṣe sí awọn wòlíì èké.” (Luku 6:26) C. T. Russell, ààrẹ Watch Tower Society àkọ́kọ́, ni a bi nígbà kan rí ìdí tí kò fi gbèjà ara rẹ̀ lòdì sí ẹ̀gàn. Ó dáhùn pé: “Bí o bá ń dúró láti ta gbogbo ajá tí ń gbó ọ ní ìpa, ìwọ kì yóò lè rìn jìnnà láé.”
Nítorí náà, a kò níláti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn alátakò tí wọ́n ti gbaradì sọ pín ọkàn wa níyà kúrò nínú ṣíṣe iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. (Orin Dafidi 119:69) Ẹ jẹ́ kí a pọkànpọ̀ sí iṣẹ́ àwọn Kristian tòótọ́, ìyẹn ni, jíjíhìnrere. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, a óò ní àǹfààní láti dáhùn àwọn ìbéèrè àti láti ṣàlàyé kókó pàtàkì iṣẹ́ wa, bíi kí á ṣàlékún ọ̀nà ìwàhíhù ẹnì kan àti kíkọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.—Matteu 24:14; 28:19, 20.
O Ha Níláti Dáhùnpadà sí Ìṣelámèyítọ́ Bí?
Jesu sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kì í ṣe apákan ayé . . . Nítìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.” (Johannu 15:19) Ọ̀pọ̀ àwọn ìròyìn tí ń kó ẹ̀gàn bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ìsọjáde ìkórìíra yìí, a sì níláti pa irú àwọn bẹ́ẹ̀ tì. Bí ó ti wù kí ó rí, ilé-iṣẹ́ ìròyìn nígbà mìíràn lè gbé ìsọfúnni tí ó fi àìní ìmọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí tàbí ti ń fi èrò-òdì tàbí òtítọ́ tí a sojú rẹ̀ dé hàn. Àwọn akọ̀ròyìn kan lè mú ìròyìn wọn láti orísun tí ó ní ẹ̀tanú. Yálà a pa ìsọfúnni èké inú ìròyìn tì tàbí a gbèjà òtítọ́ lọ́nà tí ó yẹ sinmi lórí àyíká-ipò, ẹni tí ń súnná sí ìṣelámèyítọ́ náà, àti góńgó rẹ̀.
Nígbà mìíràn ọ̀ràn náà ni a lè ṣàtúnṣe rẹ̀ nípa kíkọ lẹ́tà tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu sí olóòtú náà bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́tà náà ni a tẹ̀ jáde ní kíkún. Ṣùgbọ́n irú lẹ́tà báyìí lè yọrí sí òdìkejì ohun tí a ní lọ́kàn. Báwo? Irọ́ àkọ́kọ́ lè tipa báyìí di ohun tí gbogbo ayé gbọ́, tàbí àwọn alátakò ni a lè fún ní àǹfààní síi láti rí irọ́ tàbí ọ̀rọ̀ ìwọ̀sí láti tẹ̀jáde. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ó bọ́gbọ́n mu láti fi ọ̀ràn kíkọ lẹ́tà sí olóòtú sílẹ̀ fún àwọn alàgbà tí ọ̀rọ̀ kàn. Bí ìròyìn òdì tí ilé-iṣẹ́ ìròyìn tẹ̀ bá ru ẹ̀tanú sókè, ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society lè fi àwọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ìjọ ní orílẹ̀-èdè náà létí, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí gbogbo àwọn akéde fi àlàyé tí ó tẹ́nilọ́rùn fún àwọn olùwádìí.
Gbogbo yín lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ha níláti kówọnú àwọn ìfẹ̀sùnkanni tí a lọ́ lọ́rùn báyìí bí? Ìmọ̀ràn Jesu pé “ẹ jọ̀wọ́ wọn,” ẹ pa wọ́n tì, ní kedere ń tọ́kasí ẹgbẹ́ àwọn elénìní yìí. Àwọn Kristian adúróṣinṣin ní ìdí tí ó bá Bibeli mu láti yẹ àwọn apẹ̀yìndà àti àwọn èrò wọn sílẹ̀. (1 Korinti 5:11-13; Titu 3:10, 11; 1 Johannu 2:19; 2 Johannu 10, 11) Bí ẹnì kan bá fi pẹ̀lú òtítọ́-inú ní ọkàn-ìfẹ́ nínú bóyá ìṣelámèyítọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ni a gbéka orí òtítọ́ tàbí èké, ìmọ̀ tìrẹ tí ó péye ti tó láti fún wọn ní ìdáhùn.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti September 15, 1986, ojú-ìwé 24 àti 25.
Bí o bá dojúkọ ìsọfúnni tí a lọ́ lọ́rùn nínú ìwé ìròyìn, fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn Owe 14:15 pe: “Òpè ènìyàn gba ọ̀rọ̀ gbogbo gbọ́: ṣùgbọ́n amòye ènìyàn wo ọ̀nà ara rẹ̀ rere.” Ní Switzerland ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ìbínú hàn nígbà tí ìròyìn kan tí ń ru ìmọ̀lára sókè sọ pé ọ̀dọ́mọbìnrin kékeré kan tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí kú nítorí pé àwọn ìbátan rẹ̀ kọ̀ láti gbà kí òṣìṣẹ́ ìwòsàn kan fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nítòótọ́ ha nìyẹn bí? Bẹ́ẹ̀kọ́. Aláìsàn náà kọ ìfàjẹ̀sínilára nítorí ìsìn, ṣùgbọ́n ó tẹ́wọ́gba àbójútó ìṣègùn àfirọ́pò tí kò mú ìlò ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́. Èyí ni wọn ìbá ti bẹ̀rẹ̀ láìsí ìdádúró kankan ó sì ṣeé ṣe kí ó gba ẹ̀mí rẹ̀ là. Bí ó ti wù kí ó rí, ilé-ìwòsàn náà fi ọ̀ràn falẹ̀ láìnídìí títí ó fi bọ́ sórí. Ìròyìn yìí kò mẹ́nukan àwọn òtítọ́ wọ̀nyí.
Nítorí ìdí èyí, gbé bí ìròyìn náà ti jẹ́ òtítọ́ tó yẹ̀wò. A lè ṣàlàyé fún àwọn tí ń wádìí pé àwọn alàgbà ìjọ àdúgbò yóò rí sí irú àwọn ipò báyìí ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ àti ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìtọ́sọ́nà Bibeli. Dídìrọ̀mọ́ àwọn ìlànà nígbà tí a bá ń dáhùn ń yọ wá kúrò nínú fífi ìwàǹwára dé orí ìparí èrò.—Owe 18:13.
Ìsọfúnni Tí Ó Wá Tààràtà Ṣe Kókó
Ní ọ̀rúndún kìn-ínní, àwọn ènìyàn tan irọ́ kálẹ̀ nípa Jesu Kristi kí wọ́n baà lè ba orúkọ rere rẹ̀ jẹ́, àwọn kan tilẹ̀ fi í hàn bí ẹni tí ó fẹ́ dojú ìjọba dé. (Luku 7:34; 23:2; fiwé Matteu 22:21.) Lẹ́yìn náà, ìjọ Kristian tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà kojú àtakò tí ó gbilẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn onísìn àti àwọn ènìyàn ayé. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé “Ọlọrun yan awọn ohun òmùgọ̀ ayé,” ọ̀pọ̀ ń fojú tín-ínrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (1 Korinti 1:22-29) Àwọn Kristian tòótọ́ lónìí níláti gba ẹ̀gàn mọ́ra, èyí tí ó jẹ́ ọ̀nà inúnibíni kan.—Johannu 15:20.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọrírì rẹ̀ nígbà tí ẹni tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ pọ̀ bá jẹ́ aláìṣègbè tí ó sì fi irú ìwà kan náà bíi ti àwọn àlejò Paulu ní Romu hàn, àwọn tí wọ́n wí pé: “Àwa ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́mu lati gbọ́ lati ọ̀dọ̀ rẹ ohun tí awọn ìrònú rẹ jẹ́, nitori pé ní òótọ́ níti ẹ̀ya ìsìn yii a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”—Ìṣe 28:22.
Ṣàlàyé fún àwọn ènìyàn tí a ti sọ ohun tí kì í ṣe òtítọ́ fún, ṣe èyí pẹ̀lú ìwàtútù. (Romu 12:14; fiwé 2 Timoteu 2:25.) Késí wọn láti gba ìsọfúnni tí ó jẹ́ tààràtà nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, èyí tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máṣe di ẹni tí a fi ẹ̀sùn èké tàn jẹ. O tún lè lo àwọn àlàyé tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watch Tower Society tí ń fi kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni nípa ètò-àjọ náà, ìtàn rẹ̀, àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ fúnni.a Filipi nígbà kan dá Natanaeli lóhùn kìkì nípa sísọ pé: “Wá wò ó.” (Johannu 1:46) Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni a késí láti wá ṣe ìbẹ̀wò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò kí ó baà lè rí i fúnra rẹ̀ irú àwọn ẹni tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ àti ohun tí wọ́n gbàgbọ́.
Máṣe Jẹ́ Kí Àwọn Alátakò Dẹ́rùbà Ọ́
Ẹ wo bí ó ti fúnni ní ìṣírí tó láti mọ̀ pé ẹ̀gàn kò dí àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí! Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìjíròrò kan lórí tẹlifíṣọ̀n ní Germany, àwọn apẹ̀yìndà wé irọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́sẹ̀. Òǹwòran kan mọ̀ pé àwọn àsọdùn apẹ̀yìndà náà jẹ́ àlá-asán èyí sì sún un láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli padà pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí. Bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀gàn ní gbangba nígbà mìíràn lè yọrí sí àbájáde rere!—Fiwé Filippi 1:12, 13.
Aposteli Paulu mọ̀ pé àwọn kan yóò fetísílẹ̀ sí “ìtàn èké” ju òtítọ́ lọ. Nítorí náà ó kọ̀wé pé: “Máa pa agbára ìmòye rẹ mọ́ ninu ohun gbogbo, jìyà ibi, ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” (2 Timoteu 4:3-5) Nítorí náà máṣe jẹ́ kí a pín ọkàn rẹ níyà, kí àwọn alátakò ‘sì kó jìnnìjìnnì bá ọ lọ́nàkọnà.’ (Filippi 1:28) Ẹ séraró kí ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dààmú kí ẹ sì wàásù ìhìnrere náà pẹ̀lú ìdùnnú-ayọ̀, ẹ̀yin yóò sì kojú ẹ̀gàn ní gbangba pẹ̀lú ìdúróṣinṣin. Bẹ́ẹ̀ni, ẹ rántí ìlérí Jesu pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí awọn ènìyàn bá gàn yín tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nitori mi. Ẹ yọ̀ kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú-ayọ̀, níwọ̀n bí èrè-ẹ̀san yín ti pọ̀ ní awọn ọ̀run; nitori ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí awọn wòlíì tí wọ́n wà ṣáájú yín.”—Matteu 5:11, 12.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwọn ìtẹ̀jáde náà Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká Ayé, Jehovah’s Witnesses in the Twentieth Century, àti Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
Nígbà tí àwọn alátakò dojúkọ ọ́, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́ wọn.” Kí ni ohun tí ó ní lọ́kàn?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
“Aláyọ̀ ni yín nígbà tí awọn ènìyàn bá gàn yín tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nitori mi.”—Matteu 5:11