Wọ́n Ń ṣe Inúnibíni Sí Wa Síbẹ̀ À Ń láyọ̀
“Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi.”—MÁTÍÙ 5:11.
1. Kí ni Jésù mú dá àwọn ọmọlẹ́yìn lójú nípa ayọ̀ àti inúnibíni?
NÍGBÀ tí Jésù kọ́kọ́ rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ wàásù Ìjọba náà, ó kìlọ̀ fún wọn pé àwọn èèyàn máa ṣe inúnibíni sí wọn. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 10:5-18, 22) Àmọ́, ó tí kọ́kọ́ mú dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àtàwọn mìíràn lójú nígbà Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè pé kì í kúkú ṣe pé irú inúnibíni bẹ́ẹ̀ máa bá ayọ̀ wọn jẹ́. Jésù tiẹ̀ sọ pé ayọ̀ wà nínú inúnibíni táwọn Kristẹni máa fojú winá rẹ̀! Àmọ́, báwo ni inúnibíni ṣe lè fún èèyàn láyọ̀?
Ìyà Nítorí Òdodo
2. Gẹ́gẹ́ bí Jésù àti àpọ́sítélì Pétérù ṣe sọ, irú ìyà wo ló máa ń fún èèyàn láyọ̀?
2 Ohun kẹjọ tí Jésù sọ pé ó máa fún èèyàn láyọ̀ rèé, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:10) Àmọ́ o, kò sẹ́ni tí ìyà bá lára mu. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Iyì wo ni ó wà nínú rẹ̀ bí ẹ bá fara dà á nígbà tí ẹ ń dẹ́ṣẹ̀, tí a sì ń gbá yín lábàrá? Ṣùgbọ́n bí ẹ bá fara dà á nígbà tí ẹ bá ń ṣe rere, tí ẹ sì ń jìyà, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Ó tún wá sọ pé: “Àmọ́ ṣá o, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má jìyà gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn tàbí olè tàbí aṣebi tàbí gẹ́gẹ́ bí olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n bí òun bá jìyà gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, kí ó má ṣe tijú, ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní yíyin Ọlọ́run lógo ní orúkọ yìí.” (1 Pétérù 2:20; 4:15, 16) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jésù, èèyàn máa ń láyọ̀ nígbà tó bá fara da ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ nítorí òdodo.
3. (a) Tá a bá ní pé wọ́n ṣe inúnibíni séèyàn nítorí òdodo, kí ló túmọ̀ sí? (b) Ipa wo ni inúnibíni ní lórí àwọn Kristẹni ìjímìjí?
3 Ṣíṣe tẹ́nì kan bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ la máa fi mọ̀ lóòótọ́ pé olódodo lonítọ̀hún. Nítorí náà, tá a bá sọ pé ẹnì kan ń jìyà nítorí òdodo, ó túmọ̀ sí pé ẹni náà ń jìyà nítorí pé kò fàyè gba ohunkóhun tó lè mú kó rú òfin tàbí ìlànà Ọlọ́run. Àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe inúnibíni sáwọn àpọ́sítélì nítorí pé wọn ò yéé wàásù ní orúkọ Jésù. (Ìṣe 4:18-20; 5:27-29, 40) Ǹjẹ́ inúnibíni ọ̀hún ba ayọ̀ wọn jẹ́? Ǹjẹ́ wọ́n tìtorí èyí dá ìwàásù wọn dúró? Rárá o! “[Wọ́n] bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀. Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:41, 42) Ńṣe ni inúnibíni náà ń múnú wọn dùn, ó sì tún mú kí wọ́n túbọ̀ máa fi ìtara wàásù. Nígbà tó yá, àwọn ara Róòmù ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni ìjímìjí nítorí pé wọn ò jọ́sìn olú ọba.
4. Kí ni díẹ̀ lára ohun tó fà á táwọn èèyàn fi ń ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni?
4 Lóde òní, àwọn èèyàn máa ń ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé wọn ò yéé wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí.” (Mátíù 24:14) Nígbà tí ìjọba bá ṣòfin pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣèpàdé mọ́, wọ́n ṣe tán láti jìyà dípò tí wọn ò ní máa pé jọ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Bíbélì pa. (Hébérù 10:24, 25) Wọ́n máa ń ṣe inúnibíni sí wọn nítorí pé wọn kì í dá sí ọ̀ràn ìṣèlú àti nítorí pé wọn kì í lo ẹ̀jẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́. (Jòhánù 17:14; Ìṣe 15:28, 29) Síbẹ̀síbẹ̀, ìpinnu tí àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní ṣe nítorí òdodo mọ́kàn wọn balẹ̀, ó sì ń fún wọn láyọ̀.—1 Pétérù 3:14.
Àwọn Èèyàn Ń Gàn Wá Nítorí Kristi
5. Kí ni olórí ohun tó mú káwọn èèyàn máa ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn Jèhófà lóde òní?
5 Ohun kẹsàn-án tí Jésù sọ pé ó ń fún èèyàn láyọ̀ nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè tún kan ọ̀rọ̀ inúnibíni. Ó ní “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi.” (Mátíù 5:11) Olórí ohun tó mú káwọn èèyàn máa ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn Jèhófà ni pé wọn kì í ṣe apá kan ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.” (Jòhánù 15:19) Bákan náà, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Nítorí ẹ kò bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú wọn ní ipa ọ̀nà yìí sínú kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà, ó rú wọn lójú, wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.”—1 Pétérù 4:4.
6. (a) Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń gan àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn? (b) Ǹjẹ́ irú ẹ̀gàn bẹ́ẹ̀ ń dín ayọ̀ wa kù?
6 A ti wá rí i pé tìtorí pé àwọn Kristẹni ìjímìjí ò yéé wàásù ní orúkọ Jésù làwọn èèyàn ṣe ń ṣe inúnibíni sí wọn. Kristi sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun ṣe iṣẹ́ kan, ó ní: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Àwọn olóòótọ́ tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ náà, àwọn adúróṣinṣin alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” sì ń kọ́wọ́ tì wọ́n lẹ́yìn. (Ìṣípayá 7:9) Nítorí èyí, Sátánì wá ń “bá àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ rẹ̀ [irú ọmọ “obìnrin” náà, ìyẹn ètò àjọ Ọlọ́run ti ọ̀run] ja ogun, àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:9, 17) Àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́rìí Jésù, Ọba tí ń ṣàkóso lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí nínú Ìjọba náà tó máa fòpin sí ìjọba ènìyàn tó ń dènà ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 2:44; 2 Pétérù 3:13) Èyí ló mú káwọn èèyàn máa ṣe inúnibíni sí wa tí wọ́n sì ń gàn wa, àmọ́ inú wa ń dùn pé à ń jìyà nítorí orúkọ Kristi. —1 Pétérù 4:14.
7, 8. Irọ́ wo làwọn alátakò pa mọ́ àwọn Kristẹni ìjímìjí?
7 Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa yọ̀ bí àwọn èèyàn bá tilẹ̀ ń “fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú” sí wọn nítorí òun. (Mátíù 5:11) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ìjímìjí gan-an nìyẹn. Nígbà tí wọ́n ju àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù, ní nǹkan bí ọdún 59 sí 61 Sànmánì Tiwa, àwọn aṣáájú ìsìn Júù sọ nípa àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ pé: “Lóòótọ́, ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:22) Wọ́n fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù àti Sílà pé “wọ́n ti sojú ilẹ̀ ayé tí a ń gbé dé,” wọ́n tún sọ pé wọ́n ń “gbé ìgbésẹ̀ ní ìlòdìsí àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ Késárì.”—Ìṣe 17:6, 7.
8 Nínú ìwé tí òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ K. S. Latourette kọ nípa àwọn Kristẹni tó wà nígbà Ìjọba Róòmù, ó sọ pé: “Oríṣiríṣi ẹ̀sùn ni wọ́n fi kàn wọ́n. Wọ́n ní àwọn Kristẹni ò gbà pé Ọlọ́run wà, nítorí pé wọn ò lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà. Nítorí pé wọn ò kópa nínú ìgbòkègbodò ìlú, irú bíi ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà tàbí eré ìdárayá . . . wọ́n wá ń fi wọ́n ṣẹ̀sín pé ọ̀tá ọmọ aráyé ni wọ́n. . . . Wọ́n tún sọ pé tọkùnrin tobìnrin wọn máa ń pàdé lọ́wọ́ alẹ́ . . . tí wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn ṣèṣekúṣe. . . . Tìtorí pé àwọn Kristẹni nìkan ló máa ń wà níbi ayẹyẹ [Ìrántí Ikú Kristi], èyí ló mú káwọn èèyàn máa purọ́ kiri pé gbogbo ìgbà làwọn Kristẹni máa ń fi àwọn ọmọ ọwọ́ rúbọ, pé wọ́n ń mu ẹ̀jẹ̀ wọn, pé wọ́n sì ń jẹ ẹran ara wọn.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, tìtorí pé àwọn Kristẹni ìjímìjí ò bá wọn jọ́sìn olú ọba Róòmù, wọ́n wá fẹ̀sùn kàn wọ́n pé ọ̀tá Orílẹ̀-èdè ni wọ́n.
9. Kí ni àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe nígbà táwọn èèyàn fi ẹ̀sùn èké kàn wọ́n, báwo sì ni nǹkan ṣe rí lóde òní?
9 Gbogbo irọ́ táwọn èèyàn pa mọ́ àwọn Kristẹni ìjímìjí ò dí wọn lọ́wọ́ kí wọ́n má wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Ní ọdún 60 sí 61 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìhìn rere . . . ti ń so èso, tí ó sì ń bí sí i ní gbogbo ayé” ni a ti “wàásù [rẹ̀] nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:5, 6, 23) Irú nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní gan-an nìyẹn. Àwọn èèyàn ń fẹ̀sùn èké kan àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn èké kan àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Síbẹ̀, ńṣe ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà túbọ̀ ń gbèrú sí i, ó sì ń fún àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà láyọ̀ púpọ̀.
Inú Wa Dùn Pé Wọ́n Ń Ṣe Inúnibíni sí Wa Bíi Tàwọn Wòlíì
10, 11. (a) Kí ni ohun tí Jésù sọ kẹ́yìn pé ó máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀? (b) Kí nìdí táwọn èèyàn fi ṣe inúnibíni sáwọn wòlíì? Mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan.
10 Ohun kẹsàn-án tí Jésù sọ pé ó máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀ rèé, ó ní: “Ẹ yọ̀, . . . nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.” (Mátíù 5:12) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbọràn ò tẹ́wọ́ gba àwọn wòlíì tí Jèhófà ní kó lọ kìlọ̀ fún wọn, wọ́n sì tún ṣe inúnibíni sí wọn. (Jeremáyà 7:25, 26) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yẹn, ó sọ pé: “Kí ni kí n tún wí? Nítorí àkókò kì yóò tó fún mi bí mo bá ń bá a lọ láti ṣèròyìn nípa . . . àwọn wòlíì yòókù, àwọn tí ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, [wọ́n] rí àdánwò wọn gbà nípa ìfiṣẹlẹ́yà àti ìnàlọ́rẹ́, ní tòótọ́, ju èyíinì lọ, nípa àwọn ìdè àti ẹ̀wọ̀n.”—Hébérù 11:32-38.
11 Ọ̀pọ̀ lára àwọn wòlíì Jèhófà ni wọ́n fi idà pa nígbà ìjọba Áhábù, Ọba búburú yẹn àti ìyàwó rẹ̀, Jésíbẹ́lì. (1 Àwọn Ọba 18:4, 13; 19:10) Wọ́n fi wòlíì Jeremáyà sínú àbà, nígbà tó sì yá, wọ́n jù ú sínú ìkùdu tó ní ẹrẹ̀. (Jeremáyà 20:1, 2; 38:6) Wọ́n ju wòlíì Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún. (Dáníẹ́lì 6:16, 17) Gbogbo àwọn wòlíì wọ̀nyí tí wọ́n ti gbé ayé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé làwọn èèyàn ṣe inúnibíni sí nítorí pé wọ́n kọ́wọ́ ti ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà. Àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe inúnibíni sí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì. Jésù pe àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí wọ̀nyẹn ní “ọmọ àwọn tí wọ́n ṣìkà pa àwọn wòlíì.”—Mátíù 23:31.
12. Kí nìdí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gbà pé àǹfààní ni inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sí wa bíi tàwọn wòlíì ìgbàanì?
12 Lóde òní, àwọn èèyàn sábà máa ń ṣe inúnibíni sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé à ń fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Àwọn ọ̀tá wa fẹ̀sùn kàn wá pé “à ń fi tipátipá yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà,” àmọ́ a mọ̀ pé wọ́n ṣe irú inúnibíni yìí sáwọn olóòótọ́ olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n gbé láyé ṣáájú wa. (Jeremáyà 11:21; 20:8, 11) Àǹfààní ló jẹ́ pé à ń jìyà nítorí ohun kan náà tó mú káwọn èèyàn fìyà jẹ àwọn wòlíì olóòótọ́ ayé àtijọ́. Jákọ́bù, ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ fi àwọn wòlíì, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà ṣe àpẹẹrẹ jíjìyà ibi àti mímú sùúrù. Wò ó! Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀.”—Jákọ́bù 5:10, 11.
Olórí Ohun Tó Jẹ́ Ká Máa Láyọ̀
13. (a) Kí nìdí tá a kì í rẹ̀wẹ̀sì bí wọ́n tilẹ̀ ṣe inúnibíni sí wa? (b) Kí lohun tó jẹ́ ká lè dúró gbọn-in, kí sì ni èyí fi hàn?
13 Dípò tí inúnibíni á fi mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ńṣe ni mímọ̀ tá a mọ̀ pé à ń fara wé àwọn wòlíì, àwọn Kristẹni ìjímìjí àti Kristi Jésù fúnra rẹ̀, ń tù wá nínú. (1 Pétérù 2:21) À ń rí ìtùnú ńlá nínú Ìwé Mímọ́, irú bíi àwọn ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí iná tí ń jó láàárín yín rú yín lójú, èyí tí ń ṣẹlẹ̀ sí yín fún àdánwò, bí ẹni pé ohun àjèjì ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí yín. Bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀, nítorí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.” (1 Pétérù 4:12, 14) Àwọn nǹkan tójú wa ti rí sẹ́yìn jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí Jèhófà tó bà lé wa tó sì ń fún wa lágbára ni ohun kan ṣoṣo tó jẹ́ ká lè dúró gbọn-in lójú inúnibíni. Ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ tá à ń rí gbà fi hàn pé Jèhófà ń bù kún wa, ayọ̀ tí èyí sì ń fún wa kì í ṣe kékeré.—Sáàmù 5:12; Fílípì 1:27-29.
14. Kí làwọn ohun tó ń mú ká máa láyọ̀ bí wọ́n tilẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa nítorí òdodo?
14 Ìdí mìíràn tí àtakò àti inúnibíni táwọn èèyàn ń ṣe sí wa nítorí òdodo fi ń mú ká láyọ̀ ni pé, ó jẹ́ ẹ̀rí pé à ń gbé ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tòótọ́ tí a sì ń fọkàn sin Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Ayọ̀ wa tún pọ̀ gan-an bá a ṣe mọ̀ pé jíjẹ́ tá a bá jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò yóò túbọ̀ já irọ́ Sátánì tó sọ pé, ohun tó ń mú káwọn tí Jèhófà dá máa sìn ín jẹ́ nítorí ohun tí wọ́n ń rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀. (Jóòbù 1:9-11; 2:3, 4) Inú àwa náà dùn pé a ní ipa tá à ń kó, bó ti wù kó kéré mọ́, nínú dídá ipò ọba aláṣẹ òdodo tí Jèhófà wà láre.—Òwe 27:11.
Ẹ Fi Ìdùnnú Fò Sókè Nítorí Èrè Náà
15, 16. (a) Kí ni ohun tí Jésù sọ pé ó yẹ kó mú ká máa “fò sókè fún ìdùnnú”? (b) Kí ni èrè tá a tọ́jú sí ọ̀run dè àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, kí sì ni ohun tó máa jẹ́ èrè àwọn “àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn?
15 Jésù sọ ìdí mìíràn tó fi yẹ́ ká láyọ̀ bí àwọn èèyàn tilẹ̀ ń ṣèkà sí wa tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wa bíi tàwọn wòlíì ìgbàanì. Nígbà tí Jésù sọ ohun kẹsàn-án tó máa jẹ́ ká láyọ̀, ó wá sọ pé: “Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìyè àìnípẹ̀kun ni ‘èrè ńlá náà,’ àmọ́ kìí ṣe owó ọ̀yà iṣẹ́ tá a ṣe o. Ẹ̀bùn ni. Jésù sọ pé “ọ̀run” ni èrè náà wà nítorí pé àtọ̀dọ̀ Jèhófà ló ti wá.
16 Àwọn ẹni àmì òróró gba “adé ìyè,” ìyẹn ni pé, wọn yóò máa gbé lọ́dọ̀ Kristi ní ọ̀run, wọn ò sì ní lè kú mọ́. (Jákọ́bù 1:12, 17) Àwọn “àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n ń retí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé, ń wọ̀nà láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 21:3-5) “Èrè” tó wà fún ẹgbẹ́ méjèèjì kì í ṣe èyí tí wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí owó ọ̀yà. Àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” gba èrè wọn nípasẹ̀ “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [Jèhófà] títayọ ré kọjá,” tó mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.”—2 Kọ́ríńtì 9:14, 15.
17. Báwo ni inú wa ṣe lè máa dùn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa, báwo la sì ṣe lè máa “fò sókè fún ìdùnnú” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ?
17 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni kan, tí díẹ̀ nínú wọn wà lára àwọn tí Olú Ọba Róòmù máa tó ṣe inúnibíni rírorò sí, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá; ìfaradà, ní tirẹ̀, ipò ìtẹ́wọ́gbà; ipò ìtẹ́wọ́gbà, ní tirẹ̀, ìrètí, ìrètí náà kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí. Ẹ máa ní ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú.” (Róòmù 5:3-5; 12:12) Ì báà jẹ́ pé ọ̀run là ń lọ́ tàbí a fẹ́ gbé lórí ilẹ̀ ayé, èrè tá a máa ní tí a bá jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò á pọ̀ fíìfíì ju ohunkóhun tá a lẹ́tọ̀ọ́ sí lọ. Ayọ̀ wa ń pọ̀ sí i nítorí ìrètí tá a ní pé a ó wà láàyè títí láé, láti máa sin Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́, ká sì máa yìn ín, lábẹ́ Jésù Kristi Ọba. Ńṣe là ń “fò sókè fún ìdùnnú” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.
18. Kí ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa ṣe bí òpin ti ń sún mọ́lé, kí ni Jèhófà yóò wá ṣe?
18 Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn èèyàn ti ṣe inúnibíni sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn kan ṣì ń ṣe bẹ́ẹ̀ di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa òpin ètò àwọn nǹkan yìí, ó kìlọ̀ fáwọn Kristẹni tòótọ́ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 24:9) Bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí, Sátánì yóò sún àwọn orílẹ̀-èdè láti máa kórìíra àwọn èèyàn Jèhófà. (Ìsíkíẹ́lì 38:10-12, 14-16) Èyí ló máa mú kí Jèhófà jà fáwọn èèyàn rẹ̀. “Dájúdájú, èmi yóò sì gbé ara mi ga lọ́lá, èmi yóò sì sọ ara mi di mímọ́, èmi yóò sì sọ ara mi di mímọ̀ lójú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè; wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsíkíẹ́lì 38:23) Jèhófà yóò wá tipa báyìí sọ orúkọ ńlá rẹ̀ di mímọ́, yóò sì gba àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ inúnibíni. Nítorí náà, “aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò.”—Jákọ́bù 1:12.
19. Bá a ṣe ń dúró dé “ọjọ́ [ńlá] Jèhófà,” kí ló yẹ ká ṣe?
19 Bí “ọjọ́ [ńlá] Jèhófà” ti ń sún mọ́lé sí i, ẹ jẹ́ kí inú wa máa dùn nítorí pé “a ti kà [wá] yẹ fún títàbùkù sí” nítorí orúkọ Jésù. (2 Pétérù 3:10-13; Ìṣe 5:41) Bíi táwọn Kristẹni ìjímìjí, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó “láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà” àti Ìjọba rẹ̀, kí á sì tún máa dúró dé èrè wa ní ayé tuntun òdodo Jèhófà.—Ìṣe 5:42; Jákọ́bù 5:11.
Àtúnyẹ̀wò
• Tá a bá ní pé wọ́n ṣe inúnibíni séèyàn nítorí òdodo, kí ló túmọ̀ sí?
• Ipa wo ni inúnibíni ní lórí àwọn Kristẹni ìjímìjí?
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn èèyàn ń ṣe inúnibíni sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi táwọn wòlíì ìgbàanì?
• Kí ló lè mú ká máa “fò sókè fún ìdùnnú” nígbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
“Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín”
[Credit Line]
Àwùjọ tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n: Chicago Herald-American