MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Máa Yọ̀ Tẹ́ Ẹ Bá Ń Dojú Kọ Inúnibíni
Àwa Kristẹni mọ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa. (Jo 15:20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni máa ń fa àníyàn, ó sì lè fa ìrora nígbà míì, a máa láyọ̀ tá a bá fara dà á.—Mt 5:10-12; 1Pe 2:19, 20.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ A LÈ LÁYỌ̀ BÁ A TIẸ̀ Ń DOJÚ KỌ INÚNIBÍNI, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí lo rí kọ́ lára Arákùnrin Bazhenov tó bá di pé
ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́?
káwọn ará ràn wá lọ́wọ́?a
ká máa gbàdúrà déédéé?
ká máa kọ orin Ìjọba Ọlọ́run?
ká máa sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn míì?
a A lè gbàdúrà fáwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n, kódà a lè dárúkọ wọn nínú àdúrà wa. Àmọ́, ẹ̀ka ọ́fíìsì ò lè bá wa fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí wọn.