ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 January ojú ìwé 8
  • Máa Rántí Gbàdúrà Fáwọn Kristẹni Tí Wọ́n Ń Ṣe Inúnibíni Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Rántí Gbàdúrà Fáwọn Kristẹni Tí Wọ́n Ń Ṣe Inúnibíni Sí
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìròyìn Tó Ṣeé Gbára Lé Tó sì Ń Fún Ìgbàgbọ́ Ẹni Lókun
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Ẹ Máa Yọ̀ Tẹ́ Ẹ Bá Ń Dojú Kọ Inúnibíni
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Wọ́n Ń ṣe Inúnibíni Sí Wa Síbẹ̀ À Ń láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 January ojú ìwé 8

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Rántí Gbàdúrà Fáwọn Kristẹni Tí Wọ́n Ń Ṣe Inúnibíni Sí

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Sátánì máa ṣe inúnibíni sí wa, kó lè dá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa dúró. (Jo 15:20; Iṣi 12:17) Báwo la ṣe lè ran àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí láwọn orílẹ̀-èdè míì lọ́wọ́? A lè máa gbàdúrà fún wọn. “Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo, nígbà tí ó bá wà lẹ́nu iṣẹ́, ní ipá púpọ̀.”​—Jak 5:16.

Wọ́n ń mú arákùnrin kan tí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí lọ́wọ́ lọ sẹ́wọ̀n; àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin; arákùnrin kan ń gbàdúrà

Kí la lè sọ nínú àdúrà wa? A lè bẹ Jèhófà pé kó fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yìí ní ìgboyà, kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti má ṣe fòyà. (Ais 41:​10-13) A tún lè gbàdúrà pé kí àwọn aláṣẹ máa fi ojú tó tọ́ wo iṣẹ́ ìwàásù wa, “kí a lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́.”​—1Ti 2:​1, 2.

Nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí Pọ́ọ̀lù àti Pétérù, àwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dárúkọ wọn nínú àdúrà. (Iṣe 12:5; Ro 15:​30, 31) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò mọ orúkọ àwọn tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí lóde òní, ǹjẹ́ a lè dárúkọ ìjọ wọn, orílẹ̀-èdè tàbí àgbègbè tí wọ́n wà nínú àdúrà wa?

  • A lè rí ìsọfúnni tó dé kẹ́yìn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí lórí ìkànnì jw.org. (Wo abẹ́ ÌRÒYÌN > Ọ̀RÀN ẸJỌ́.)

  • Àpilẹ̀kọ kan lórí ìkànnì jw.org tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Wọ́n Fi Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sẹ́wọ̀n Torí Ohun tí Wọ́n Gbà Gbọ́​—Ibì Kọ̀ọ̀kan” sọ iye àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. (Wo abẹ́ ÌRÒYÌN > Ọ̀RÀN ẸJỌ́. Tẹ orúkọ orílẹ̀-èdè kan kó o lè mọ púpọ̀ sí i, kó o sì tún wo PDF tó máa jẹ́ kó o rí orúkọ gbogbo àwọn tó wà lẹ́wọ̀n níbẹ̀.)

Mo fẹ́ gbàdúrà fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí láwọn orílẹ̀-èdè yìí:

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́