ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • hdu àpilẹ̀kọ 19
  • Ìròyìn Tó Ṣeé Gbára Lé Tó sì Ń Fún Ìgbàgbọ́ Ẹni Lókun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìròyìn Tó Ṣeé Gbára Lé Tó sì Ń Fún Ìgbàgbọ́ Ẹni Lókun
  • Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Ń Ṣètò Àwọn Ìròyìn Tá À Ń Gbé Jáde
  • Ọ̀rọ̀ Ìmọrírì Táwọn Kan Sọ
  • Máa Rántí Gbàdúrà Fáwọn Kristẹni Tí Wọ́n Ń Ṣe Inúnibíni Sí
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà Torí Ìfẹ́ Tẹ́ Ẹ̀ Ń Fi Hàn
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
Àwọn Míì
Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
hdu àpilẹ̀kọ 19
Arákùnrin kan ń lo fóònù rẹ̀.

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Ìròyìn Tó Ṣeé Gbára Lé Tó sì Ń Fún Ìgbàgbọ́ Ẹni Lókun

DECEMBER 1, 2021

Ọ̀rọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà kárí ayé jẹ wá lógún gan-an. (1 Pétérù 2:17) Arábìnrin Tannis tó ń gbé ní Kẹ́ńyà sọ pé: “Ó máa ń wù mí láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa tó wà kárí ayé.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára ọ̀pọ̀ wa náà nìyẹn. Báwo ni Tannis àti ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń rí àwọn ìsọfúnni yíi? Láti ọdún 2013 lati ń gbé àwọn ìsọfúnni yìí sí apá tá a pè ní ìròyìn lórí Ìkànnì jw.org.

Ní apá yìí, a máa rí ìròyìn nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí àwọn ọ̀rọ̀ bíi, Bíbélì tá a mú jáde, bá a ṣe ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù, iṣẹ́ ìkọ́lé àtàwọn ìròyìn pàtàkì míì. Apá yìí tún jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa rí àwọn ìrírí tó ń wúni lórí nípa iṣẹ́ ìwàásù àti Ìrántí Ikú Kristi níbẹ̀. Àwọn wo ló ń kọ ìròyìn yìí, báwo sì ni wọ́n ṣe ń kó o jọ?

Bá A Ṣe Ń Ṣètò Àwọn Ìròyìn Tá À Ń Gbé Jáde

Ọ́fíìsì Tó Ń Gbé Ìròyìn Jáde (OPI) ló ń rí sí àwọn ìròyìn tó ń jáde lórí Ìkànnì wa. Oríléeṣẹ́ ni ọfíìsì yìí wà, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Ohun tó ju ọgọ́rùn-ún (100) àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì yìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ń ṣiṣẹ́ látilé. Àwọn kan lára wọn jẹ́ òǹkọ̀wé, àwọ́n kan ń ṣèwádìí, àwọn míì ń yàwòrán, àwọn kan sì jẹ́ atúmọ̀ èdè. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì nínú wọn máa ń kàn sí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n níléèwé àtàwọn oníròyìn. Láfikún sí i, láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kárí ayé, ó ju ọgọ́rin (80) Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde (PID) tó ń ṣèrànwọ́ fún ọ́fíìsì OPI.

Tá a bá fẹ́ kó ìròyìn kan jọ, ọ́fíìsì OPI máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka PID. Tí wọ́n bá rí i pé ìròyìn kan máa wọ àwọn ará lọ́kàn, wọ́n á ṣèwádìí nípa ẹ̀, wọ́n á sì kó àwọn ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé jọ. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tí ọ̀rọ̀ ṣojú wọn àtàwọn míì tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n. Lẹ́yìn tí wọ́n bá kó ìsọfúnni yẹn jọ, wọ́n á kọ ìròyìn náà, wọ́n á yẹ̀ ẹ́ wò, wọ́n á tún un kà, wọ́n á sì fi àwòrán sí i. Lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ránṣẹ́ sí Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí, kí wọ́n lè yẹ̀ ẹ́ wò, kí wọ́n sì fọwọ́ sí i.

Ọ̀rọ̀ Ìmọrírì Táwọn Kan Sọ

Kí ni àwọn ará wa kan sọ nípa apá tá a pè ní ìròyìn lórí Ìkànnì jw.org. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Chery lórílẹ̀-èdè Philippines sọ pé, “Kí n tó bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ó máa ń wù mí kí n kà nípa ètò Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀.”

Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka àwọn ìròyìn wa ló ti sọ̀rọ̀ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìròyìn orí jw àti àwọn ìròyìn míì tó ń jáde nínú ayé. Tatiana tó ń gbé ní Kazakhstan sọ pé: “Mi ò kí í ṣiyèméjì tí mo bá ń gbọ́ àwọn ìròyìn orí jw torí mo mọ̀ pé òótọ́ ló wà níbẹ̀, ó sì ṣeé gbára lé.” Arábìnrin Alma tó ń gbé ní Mẹ́síkò sọ pé: “Àwọn ìròyìn tó ń bani lọ́kàn jẹ́ ló pọ̀ jù nínú àwọn ìròyìn tó ń jáde nínú ayé, àmọ́ ìròyìn orí Ìkànnì jw máa ń gbéni ró.”

Kì í ṣe pé ìròyìn orí jw ṣeé gbára lé nìkan ni, ó tún máa ń fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun. Bernard tó ń gbé ní Kẹ́ńyà sọ pé: “Àwọn ìròyìn yìí ti jẹ́ kí n rí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin bí ọmọ ìyá mi láìka ibi tí wọ́n ti wá sí. Ní báyìí, mo lè fi orúkọ wọn àti ohun tí wọ́n ń dojú kọ sínú àdúrà mi.” Arábìnrin Bybron tóun náà ń gbé ní Kẹ́ńyà sọ pé: “Inú mi máa ń dùn tí mo bá rí àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe mú Bíbélì jáde ní èdè kan! Àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa ń jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú.”

Arákùnrin náà ń gbàdúrà. Nínú àwòrán tó wà lẹ́yìn, arábìnrin kan ń gba ohun tá a fi ṣèrànwọ́ nígbà àjálù, ilé kan tó bà jẹ́ lẹ́yìn tí àjálù kan ṣẹlẹ̀, arákùnrin kan tó wà lẹ́wọ̀n àti iná ńlá kan.

Ìròyìn orí Ìkànnì jw.org máa ń jẹ́ ká lè gbàdúrà tó ṣe pàtó nípa ìṣòro táwọn ará wa kárí ayé ń kojú

Kódà àwọn ìròyìn tó sọ bí àwọn ará wa ṣe ń kojú inúnibíni lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Arábìnrin Jackline tó ń gbé ní Kẹ́ńyà sọ pé: “Tí mo bá ń ronú nípa bí àwọn ará yìí ṣe nígboyà, ó máa ń fún ìgbàgbọ́ mi lókun. Mo kẹ́kọ̀ọ́ gan-an nípa ohun tó mú kí wọ́n fara dà á. Bákan náà, mo ti rí bí ohun táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí, irú bí àdúrà, Bíbélì kíkà àti kíkọ orin ṣe ń fún àwọn ará wa lókun.”

Arábìnrin Beatriz tó ń gbé ní Costa Rica mọyì àwọn ìròyìn tó dá lórí àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Ó ní: “Àwọn ìròyìn yìí máa ń jẹ́ kí n rí bí ètò Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ pèsè ohun táwọn ará nílò láìjáfara àti lọ́nà tó gbéṣẹ́. Èyí ti jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ló ń darí ètò yìí lóòótọ́.”

Inú wa dùn gan-an pé à ń rí àwọn ìròyìn tó ń jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe ń lọ fún àwọn ará wa kárí ayé. Ìtìlẹyìn táwọn ará wa ń ṣe ló ń mú kí èyí ṣeé ṣe, ọ̀pọ̀ lára ẹ̀ ló sì jẹ́ pé orí Ìkànnì donate.jw.org ni wọ́n ti fi ránṣẹ́. Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́