ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/22 ojú ìwé 18-19
  • Àwọn Ilé Iṣẹ́ Agbéròyìnjáde Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Yin Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ilé Iṣẹ́ Agbéròyìnjáde Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Yin Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà
    Jí!—1997
  • Moscow—Ìlú Ńlá Tí Ń Wà Nìṣó
    Jí!—1997
  • ‘Ayé Yìí Ì Bá Yàtọ̀’
    Jí!—2000
  • Ilé Ẹjọ́ Dá Àwọn Èèyàn Jèhófà Láre!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/22 ojú ìwé 18-19

Àwọn Ilé Iṣẹ́ Agbéròyìnjáde Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Yin Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

AṢE ìyàsímímọ́ àwọn ilé ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà ní June 21, 1997. Ọgbà náà ní ilé ibùgbé méje, Gbọ̀ngàn Ìjọba ńlá kan, iyàrá ìjẹun kan, àti ilé ńlá kan fún ọ́fíìsì àti ibi ìkẹ́rùsí, nínú. Ó wà ní nǹkan bí 40 kìlómítà sí ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá St. Petersburg, ní abúlé Solnechnoye.

A pòkìkí ìyàsímímọ́ náà káàkiri nípasẹ̀ àwọn oníròyìn tí a pè síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ọ̀kan lára wọn kọ nínú ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Moscow náà, Literaturnaya gazeta, ọ̀kan tí ìpíndọ́gba iye rẹ̀ tí a tà lé ní ìdá mẹ́rin mílíọ̀nù kan, pé: “Ohun tí yóò wá sọ́kàn ẹnì kan tí ó bá kọ́kọ́ rí i ni, Ẹ wo ojúlówó ilé!”—Wo àwòrán ojú ìwé 16 àti 17.

Òǹkọ̀wé náà, Sergey Sergiyenko, ṣàlàyé pé: “Àwọn ẹlẹ́sìn ni wọ́n fọwọ́ wọn ṣe gbogbo nǹkan tó wà níhìn-ín: Àwọn ará Finland, Sweden, Denmark, Norway, àti Germany ni wọ́n ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Àwọn ọ̀nà oníbíríkì mímọ́tónítóní; àwọn koríko tí a fẹ̀rọ gé; àwọn ilé tí a fi àwọn ègé amọ̀ ìṣọ̀ṣọ́ ṣe àjà wọn, tí wọ́n ní fèrèsé ńláńlá, àti ilẹ̀kùn onígíláàsì—ibí ni ibùjókòó ìṣàkóso ẹ̀ka ètò àjọ onísìn ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà.”

A pe àwọn oníròyìn láti Moscow, ibi tí ó lé ní 650 kìlómítà sí ìlà oòrùn gúúsù ẹ̀ka náà, síbi ìyàsímímọ́ náà, a sì pèsè ọkọ̀ láti lọ gbé wọn. A fún wọn ní ẹnì kan láti fi àyíká ilé náà hàn wọ́n, lẹ́yìn náà, a ṣètò àkókò ìbéèrè àti ìdáhùn kan, tí a sì fún wọn ní ìpápánu bí èyí ti ń lọ lọ́wọ́. Látàrí àkíyèsí Ọ̀gbẹ́ni Sergiyenko, ó kọ̀wé pé:

“Bí a ti sábà máa ń sọ, Àwọn Ẹlẹ́rìí wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, wọ́n kì í sì í ṣàṣehàn aláṣerégèé . . . Láti ṣàtúnsọ ọ̀rọ̀ èdè Rọ́ṣíà kan tí ó lókìkí pé, ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí ń gbé [ilé wọn] bíi pé wọ́n wà ní oókan àyà Jèhófà.’ . . . Bí wọ́n ti jẹ́ onínúure sí gbogbo ènìyàn nígbà gbogbo, ó dájú pé Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi ìbìkítà pàtàkì hàn fún àwọn arákùnrin wọn.”

Àpilẹ̀kọ kan tí S. Dmitriyev kọ fara hàn nínú ìwé agbéròyìnjáde Moskovskaya Pravda, ọ̀kan tí ìpíndọ́gba iye rẹ̀ tí a ń tà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 400,000. Nínú àpilẹ̀kọ rẹ̀ tí ó ní àkọlé náà, “O Lè Fi Ọwọ́ Ara Rẹ Gbé Irú Ayé Tí O Fẹ́ Kalẹ̀,” òǹkọ̀wé náà ṣàlàyé pé:

“Lẹ́yìn tí a fún àjọ onísìn ti Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìdánimọ̀ lábẹ́ òfin ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà [ní 1991], ìbéèrè dìde nípa ìkọ́lé orílé-iṣẹ́ wọn. Wọ́n ń wá ibì kan nítòsí Moscow lọ́wọ́ ni ìròyìn àìròtẹ́lẹ̀ náà fi dé pé wọ́n fẹ́ ta ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti àgọ́ àwọn ọ̀dọ́ kan tẹ́lẹ̀ rí nítòsí St. Pete[rsburg]. Wọ́n ra ilẹ̀ náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé. . . .

“Ní ọdún kan ààbọ̀ sẹ́yìn, ní January 1, 1996, ibùdó náà ní abúlé Solnechnoye di ẹ̀ka àfàṣẹsí ti ètò àjọ onísìn náà. Ní àárín oṣù June, nípa lílo àkókò díẹ̀ ní St. Pete[rsburg], ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn kan láti Moscow gbìyànjú láti ṣèwádìí pé, Ta ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀nyí?”

Kí ni ìdáhùn Ọ̀gbẹ́ni Dmitriyev? “Ènìyàn ni wọ́n, bíi ti àwọn ènìyàn mìíràn.” Síbẹ̀, wọ́n yàtọ̀, bí ó ti sọ ní ìparí àpilẹ̀kọ rẹ̀ pé: “Wọ́n wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wọn, àlàáfíà wà káàkiri. Àlá ha ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sì wà síbẹ̀.”

Nígbà tí oníròyìn mìíràn láti Moscow, Maksim Yerofeyev, ń kọ̀wé fún ìwé agbéròyìnjáde Sobesednik, ọ̀kan tí ìpíndọ́gba iye rẹ̀ lé ní 300,000, ó wí pé: “Gbogbo ipò ìbátan ní àwùjọ kékeré yìí ni a gbé karí ìlànà tí ó tẹ̀ lé e yìí: A kò fipá mú ẹnikẹ́ni láti ṣiṣẹ́, síbẹ̀ olúkúlùkù ní ń ṣiṣẹ́.”

Lẹ́yìn ṣíṣàpèjúwe ibùgbé Olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka náà, Vasily Kalin, Ọ̀gbẹ́ni Yerofeyev sọ pé: “Àwùjọ àwọn oníròyìn wa tí wọn kò gbà gbọ́ fẹ́ láti ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibùgbé mìíràn tí wọn ṣà yàn fúnra wọn. Ní pàtàkì jù lọ, ìwọ̀n iyàrá àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ inú àwọn iyàrá mìíràn kò yàtọ̀ sí èyí tí a ṣètò níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú iyàrá Vasily Kalin.”

Oníròyìn mìíràn, Anastasiya Nemets, kọ àpilẹ̀kọ náà, “Gbígbé Ní Ìfọ̀kànbalẹ̀.” Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tí àkọlé yẹn ní nínú ìwé agbéròyìnjáde Vechernyaya Moskva, kà pé “Èyí Ni Ohun Tí Àwọn Ènìyàn Ń Kọ́ ní Abúlé Àrà Ọ̀tọ̀ Kan Lóde St. Pete[rsburg].”

Nígbà tí obìnrin náà ń ṣàpèjúwe ibi tí àwọn ilé ẹ̀ka ọ́fíìsì náà wà àti ìrísí rẹ̀, ó wí pé: “Àwọn igbó àti pápá yí i ká. Ìyawọlẹ̀ Omi Finland kò jìnnà síbẹ̀. Àwọn ilé ṣúgúdúṣúgúdú tí ó mọ́ tónítóní tí a kọ́ bíi ti àwọn ará Yúróòpù, àwọn ọ̀nà tí a gbá mọ́ tónítóní tí a fi bíríkì gbá etí wọn, àti àwọn ebè tí a fi gbin àwọn òdòdó jíjojúnígbèsè wà níbẹ̀.

“Àwọn ilé iṣẹ́ olówò ń kọ́ irú ìlú ńlá kóńkó bẹ́ẹ̀ fún ‘àwọn ọlọ́rọ̀ Rọ́ṣíà.’ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ ló ń gbé abúlé yìí . . . Wọ́n ń gbádùn ayé wọn, ní pàtàkì jù lọ, wọ́n ń gbé bí ọ̀rẹ́. Nǹkan bí 350 ènìyàn péré, láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ló wà níbẹ̀; a gbọ́ tí wọ́n ń sọ onírúurú èdè—láti orí èdè Spanish àti Potogí sí èdè Finnish àti Swedish.

Ní pàtàkì, èyí jẹ́ àpẹẹrẹ kékeré ti ó jẹ́ ara ìṣọ̀kan ńlá kan: Abúlé náà ní àwọn ṣọ́ọ̀bù ìṣeǹkan àti ṣọ́ọ̀bù ìṣàtúnṣe nǹkan tirẹ̀, níbi tí ó ti ṣeé ṣe láti ṣe ohunkóhun tí ìdílé tí ń sọ onírúurú èdè náà nílò; wọ́n tilẹ̀ ní ibi ìtọ́jú aláìsàn tiwọn.”

Lótìítọ́, ó jẹ́ àkókò aláyọ̀ kan fún àwọn 1,492 ènìyàn láti orílẹ̀-èdè 42 tí wọ́n wà níbi ìyàsímímọ́ náà ní Solnechnoye. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́ àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ti sìn fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún nígbà tí iṣẹ́ ìwàásù náà wà lábẹ́ ìfòfindè. Ìwọ ha lè finú wòye ìyàlẹ́nu àti ayọ̀ ńláǹlà tí àwọn tí wọ́n ti pẹ́ nínú ètò wọ̀nyí ní bí a ti ń fi àwọn ilé ẹlẹ́wà tí ó wà lórí ilẹ̀ hẹ́kítà 6.9 tí ó dà bí ọgbà yìí hàn wọ́n? A lè lóye ìdí tí wọ́n fi ronú pé ńṣe ni àwọn ń lálàá.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn oníròyìn tí ń wo àwọn ilé ẹ̀ka ọ́fíìsì

Àkòókò ìbéèrè àti ìdáhùn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́