ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/22 ojú ìwé 25-27
  • Ẹ̀bùn Ìmúwàdéédéé Tí Ọlọrun Fún Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀bùn Ìmúwàdéédéé Tí Ọlọrun Fún Wa
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni? Báwo Ni Ó Ṣe Ń Ṣiṣẹ́?
  • Àìṣedéédéé Ìṣètò Ihò Etí
  • Okùnfà àti Ìtọ́jú Rẹ̀
  • Agbára Ìgbọ́ròó Rẹ—Ẹ̀bùn Tí Ó Yẹ Kí O Ṣìkẹ́
    Jí!—1997
Jí!—1996
g96 3/22 ojú ìwé 25-27

Ẹ̀bùn Ìmúwàdéédéé Tí Ọlọrun Fún Wa

“ÀWỌN ọ̀rẹ́ mi wí fún mi pé: “Ó wulẹ̀ jẹ́ ìtúnṣebọ̀sípò nínú ìgbì òkun, ó sì lè máa bá a lọ fún ọjọ́ bíi mélòó kan.” Ó jẹ́ ní October 1990, mo sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ gbígbẹ láti inú ọkọ̀ arìnrìn àjò ìnàjú lẹ́yìn ìrìn àjò ọlọ́jọ́ méje kan lórí òkun Caribbean ni. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí mo lérò pé yóò jẹ́ ìrírí ọjọ́ díẹ̀ péré wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Ńṣe ni ó jọ pé n kò tí ì bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ náà. Ohun kan ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìṣètò ihò etí mi, ìgbékalẹ̀ ìmúwàdéédéé etí-inú dídíjú tí àárín gbùngbùn ìsokọ́ra rẹ̀ wà nínú ọpọlọ.

Kí Ni? Báwo Ni Ó Ṣe Ń Ṣiṣẹ́?

Àárín gbùngbùn ìmúṣiṣẹ́ṣọ̀kan fún ìmúwàdéédéé rẹ wà ní ibi tí a ń pè ní ẹ̀ka ọpọlọ ní ìsàlẹ̀ ọpọlọ rẹ. Nígbà tí o bá lera, ìwàdéédéé rẹ̀ máa ń dára nítorí pé ojú rẹ, àwọn iṣan rẹ, àti ìṣètò ihò etí rẹ máa ń gbé àwọn ìmọ̀lára tí kò lóǹkà wá.

Ojú rẹ ń pèsè ìsọfúnni onímọ̀lára fún ẹ̀ka ọpọlọ náà nípa àwọn àyíká òde ara rẹ. Àwọn olùfaragba ìmọ̀lára nínú àwọn iṣan rẹ, tí a ń pè ní proprioceptor, ń gbé ìsọfúnni lọ sínú ọpọlọ rẹ nípa bí ibi tí o ń rìn tàbí tí o ń fọwọ́ kàn ṣe rí. Ṣùgbọ́n ìṣètò ihò etí rẹ tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ atọ́nà tí ń sọ fún ọpọlọ nípa ibi tí ara rẹ wà lófegè ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ayé àti agbára òòfàmọ́lẹ̀ rẹ̀.

Ìṣètò ihò etí ní apá márùn-ún tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìmúwàdéédéé: àwọn ihò títẹ̀ kọrọdọ mẹ́ta àti àpò méjì. Àwọn ihò títẹ̀ kọrọdọ náà ni a pè ní ihò òkè, ihò nínàró (ẹ̀gbẹ́), àti ihò dídábùú (ìsàlẹ̀). Àwọn àpò méjì náà ni a ń pè ní utricle àti saccule.

Àwọn ihò títẹ̀ kọrọdọ náà wà gbọọrọ-gbọọrọ ní ìforíkanra wọn, bíi ti ògiri àti ilẹ̀ tí ó pàdé ní igun iyàrá kan. Àwọn ihò náà jẹ́ ọ̀nà àbákọjá tí ó wá jẹ́ ètò ìgbékalẹ̀ dídíjú, tí ó sá pamọ́ sínú egungun líle agbárí, tí a ń pè ní egungun ẹ̀gbẹ́ agbárí. Ìgbékalẹ̀ dídíjú mìíràn tí a ń pè ní ìgbékalẹ̀ aláwọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ dídíjú wà nínú ìsokọ́ra eléegun dídíjú yìí. Ohun kan tí ó jọ ìyọgọọbu kan, tí a ń pè ní ampulla, wà ní ìsàlẹ̀ àpò aláwọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kọrọdọ kọ̀ọ̀kan. Omi pàtàkì kan, tí a ń pè ní endolymph, wà nínú ètò ìgbékalẹ̀ aláwọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ dídíjú náà. Omi mìíràn, tí ó jẹ́ ìgbékalẹ̀ kẹ́míkà míràn, tí a ń pè ní perilymph, sì wà ní ìta awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ náà.

Apá yíyọ gọọbu lára àpò náà, tí a ń pè ní ampulla, ní àwọn sẹ́ẹ̀lì irun pàtàkì títayọ tí ó rí bí ìdì tí ó fara sin sínú ìṣùjọ awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ń pè ní cupula. Bí o bá gbé orí rẹ sí ìhà èyíkéyìí, omi endolymph náà kì í yára tó bí àwọn ihò náà fúnra wọn ṣe ń lọ kiri; nítorí náà, omi náà máa ń tẹ cupula náà àti àwọn ìdì irun tí ó wà nínú rẹ̀. Ìlọkiri àwọn ìdì irun náà máa ń fa ìyípadà nínú ànímọ́ bíi ti ìgbọ̀ntìtì iná tí sẹ́ẹ̀lì irun náà ní, èyí pẹ̀lú yóò wá gbé àwọn ìsọfúnni gba inú sẹ́ẹ̀lì iṣan lọ sínú ọpọlọ rẹ. Kì í ṣe láti inú àwọn sẹ́ẹ̀lì irun kọ̀ọ̀kan wọ̀nyí nìkan ni ìsọfúnni tí ń gba inú àwọn ohun tí a ń pè ní iṣan agbésọfúnni-kiri ti máa ń lọ sínú ọpọlọ, àmọ́ ó tún máa ń gba inú iṣan agbésọfúnni-kiri padà láti inú ọpọlọ lọ sínú sẹ́ẹ̀lì irun kọ̀ọ̀kan láti lè fún sẹ́ẹ̀lì irun náà ní ìsọfúnni ìfèsìpadà nígbà tí èyí bá pọn dandan.

Àwọn ihò kọrọdọ náà máa ń mọ̀ nígbà tí o bá dagun orí rẹ tàbí tí o ń yí i kiri, irú bíi títẹ̀ ẹ́ síwájú tàbí sẹ́yìn, gbígbé e sí ẹ̀gbẹ́ kan tàbí èkejì, tàbí yíyí i sí apá òsì tàbí ọ̀tún.

Ní ọwọ́ kejì, utricle àti saccule máa ń mọ ìwọ̀n ìyára ọlọ́gbọn-ọnran; a sì ń torí èyí pè wọ́n ní awòye òòfàmọ́lẹ̀. Àwọn pẹ̀lú ní àwọn sẹ́ẹ̀lì irun nínú ohun kan tí a ń pè ní macula. Fún àpẹẹrẹ, saccule náà yóò fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sínú ọpọlọ rẹ tí yóò fún ọ ní ìmọ̀lára pé o ń lọ sókè nígbà tí ẹ̀rọ agbéniròkè kan bá ń gbé ọ lọ sókè. Utricle ni lájorí atúǹkanfó tí ó máa ń hùwà padà nígbà tí o bá wà nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí o sì yọsẹ̀ lójijì. Ó máa ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sínú ọpọlọ rẹ láti fún ọ ní ìmọ̀lára jíjẹ́ ẹni tí a fipá tì síwájú tàbí sẹ́yìn. Ọpọlọ rẹ yóò wá pa ìsọfúnni yìí pọ̀ mọ́ àwọn ìmọ̀lára mìíràn láti ṣe àwọn ìpinnu, irú bí ọ̀nà tí o ní láti gbà gbé ojú àti ẹsẹ̀ rẹ láti hùwà padà sí ìmọ̀lára ìgbékiri tí ó ń ní. Ó ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pa ìyípadà ipò rẹ mọ́.

Ó jẹ́ ìṣètò àgbàyanu tí ń fi ọlá fún Olùṣètò rẹ̀, Jehofa Ọlọrun. Ìṣètò rẹ̀ ń wú àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ aṣèwádìí pàápàá fúnra wọn lórí. A. J. Hudspeth, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nipa ohun alààyè àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìgbòkègbodò ẹ̀dá, kọ nínú ìwé ìròyìn Scientific American pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, iṣẹ́ ìṣèwádìí síwájú sí i nípa rẹ̀ yóò wulẹ̀ mú kí ẹnu yà wá sí i nípa bí ohun èèlò bín-ń-tín ara ìṣẹ̀dá yìí ṣe tètè máa ń mọ nǹkan lára sí àti bí ó ṣe díjú tó.”

Àìṣedéédéé Ìṣètò Ihò Etí

Nínú ọ̀ran tèmi, ìṣòro etí-inú mi ni wọ́n ti ṣàwárí pé ó jẹ́ àrùn otospongiosis tàbí otosclerosis. Ó jẹ́ ipò kan nínú èyí tí egungun tí ìṣètò ihò etí ẹnì kan wà ti rọ̀ fùkọ̀fùkọ̀ tàbí kí ó ṣe bùtẹ̀bùtẹ̀. Egungun yìí sábà máa ń le gbandi ni, tí ó tilẹ̀ máa ń le ju àwọn èròjà egungun inú ara rẹ yòókù lọ. A ronú pé, nígbà tí ó bá ń rọ̀, èròjà enzyme kan máa ń jáde tí ó máa ń yọ̀ tẹ̀rẹ́ wọnú omi etí-inú náà, tí ó sì máa ń ṣèdíwọ́ fún ìṣiṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi kẹ́míkà tàbí kí ó tilẹ̀ sọ omi náà di onímájèlé. Èyí lè ṣokùnfà ìmọ̀lára ìyíkiri aláìdáwọ́dúró ṣíṣàjèjì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wà ní ìdúró tàbí ìdùbúlẹ̀.

Nínú ọ̀ràn tèmi, ó ń jẹ́ kí ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ẹsẹ̀ mi dà bí èyí tí ìgbì tí ó máa ń ga tó ìlàta mítà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ń gbé kiri. Nígbà tí mo bá wà ní ìdùbúlẹ̀, mo máa ń nímọ̀lára bíi pé mo dùbúlẹ̀ sábẹ́ ọkọ̀ òbèlè láàárín ìgbì òkun tí ó ga tó mítà kan. Ìmọ̀lára náà kì í wá kí ó sì lọ bí ó ti ń rí nínú ọ̀ràn àrùn ojú ṣíṣú, ṣùgbọ́n ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí mi fún gbogbo wákàtí 24 tí ó wà nínú ọjọ́ kan fún ọ̀pọ̀ oṣù, láìdábọ̀. Ìdásílẹ̀ kan ṣoṣo tí mo ní wá nígbà tí ń kò bá mọ nǹkan kan tí mo bá wà lójú oorun.

Okùnfà àti Ìtọ́jú Rẹ̀

A kò tí ì mọ àwọn okùnfà àrùn otospongiosis tàbí otosclerosis síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ní àwọn ìsopọ̀ pẹ̀lú okùnfà àjogúnbá kan nínú. Ipò náà ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn láti ṣèwádìí nípa rẹ̀ nítorí ó jọ pé ẹ̀dá ènìyàn nìkan ni nǹkan náà máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Bí ó bá tilẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹranko, kò wọ́pọ̀. Àrùn otospongiosis lè fa ìmọ̀lára ariwo (ìhangooro nínú etí), ìmọ̀lára bíi pé orí ń tóbi sí i, kí orí máa fúyẹ́, ìmọ̀lára àìlèdádúró, tàbí onírúurú ìmọ̀lára ìlọ́ọ̀yì (ojú ṣíṣú). Ipò kan náà lè fa ìdúró gbandi àwọn egungun inú àárín etí, kí ó sì fa àìgbọ́rọ̀ nítorí ìṣèdíwọ́ fún ìgbékiri ohùn. Bí àrùn otospongiosis bá dé ọ̀dọ̀ cochlea, ó tún lè fa àìgbọ́rọ̀ nítorí ìlèwòye ọpọlọ nípa bíba ìṣiṣẹ́ iṣan jẹ́.

Àwọn ìtọ́jú wà fún ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Àwọn kan máa ń la iṣẹ́ abẹ́ lọ (wo Jí!, July 8, 1988, ojú ewé 19, Gẹ̀ẹ́sì); àwọn mìíràn gbìyànjú láti ṣèkáwọ́ àbùkù egungun náà nípasẹ̀ fífi èròjà calcium àti fluoride kún un. Wọ́n máa ń dámọ̀ràn àwọn oúnjẹ tí kò ní ṣúgà nínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí pé etí-inú ń yán hànhàn gan-an fún ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀. Ní tòótọ́, etí-inú nílò ṣúgà tí ó pọ̀ tó ìlọ́po mẹ́ta iye tí ọpọlọ tí ó bá a dọ́gba nílò láti fún un lágbára. Etí tí ó jí pépé máa ń ṣiṣẹ́ dáradára lórí ìlọsókè-sódò wíwà déédéé ṣúgà inú ẹ̀jẹ̀; ṣùgbọ́n níwọ̀n bí etí bá ti lábùkù, àwọn ìlọsókè-sódò yìí lè mú kí o nímọ̀lára ìlọ́ọ̀yì. Ó jọ pé èròjà kaféènì àti ọtí líle pẹ̀lú léwu gbàrà tí etí-inú rẹ kò bá ṣiṣẹ́ dáradára mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wíwọ ọkọ̀ arìnrìn àjò ìnàjú, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí, kọ́ ló fa ìṣòro náà ní ti gidi, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìyípadà nínú ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù, ọ̀rinrin, àti àṣà ìjẹun ni ó tanná ran ìpàdánù ipò ìmúwàdéédéé náà.

Etí-inú rẹ ń ṣe ju gbígbọ́ ọ̀rọ̀ lọ. Lọ́nà àgbàyanu, tí ó sì ń ṣeni ní kàyéfì, ó ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí ìmúwàdéédéé rẹ wà gẹ́gẹ́. Ó yẹ kí ìṣètò rẹ̀ mú wa kún fún ìyanu nípa iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá wa, ó sì yẹ kí ó mú kí ìmọrírì wa túbọ̀ jinlẹ̀ nípa ipò jíjẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àgbàyanu Ìṣètò Ihò Etí Rẹ

Ọwọ́ Ẹ̀yìn

IHÒ ÒKÈ

ÀLÀFO ROGODO

“COCHLEA”

EGUNGUN Ẹ̀GBẸ́ AGBÁRÍ

ÌGBÉKALẸ̀ ALÁWỌ FẸ́LẸ́FẸ́LẸ́ DÍDÍJÚ

Ọwọ́ Inú

“AMPULLA”

“SACCULE”

Èyí ń mọ̀ bí a bá nàró

“CRISTA”

IHÒ NÍNÀRÓ

IHÒ DÍDÁBÙÚ

ÀLÀFO ROBOTO

“COCHLEA”

Ẹ̀yà ìgbọ́rọ̀

“MACULA”

“UTRICLE”

“CRISTA”

Èyí ń mọ̀ bí a bá dagun

Èyí ń mọ̀ bí a bá dábùú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́