Agbára Ìgbọ́ròó Rẹ—Ẹ̀bùn Tí Ó Yẹ Kí O Ṣìkẹ́
ÌRỌ̀LẸ́ píparọ́rọ́ kan ní àrọko, tí kò ti sí ariwo tí ọ̀làjú ń mú wọ inú ìlú ńlá, ń pèsè àǹfààní láti jẹ̀gbádùn àwọn ìró jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ti òru. Afẹ́fẹ́ tó rọra ń fẹ́ lẹ́lẹ́ ń fẹ́ àwọn ewé. Àwọn kòkòrò, ẹyẹ, àti ẹranko ń dún látòkèèrè wá. Ẹ wo irú ìmọ̀lára àgbàyanu tó jẹ́ láti máa gbọ́ irú àwọn ìró jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bẹ́ẹ̀! Ǹjẹ́ o lè gbọ́ wọn?
Ohun tí ìgbékalẹ̀ agbára ìgbọ́ròó ènìyàn lè ṣe jẹ́ àgbàyanu. Lo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú nínú iyàrá àìgbọ́ròó—iyàrá kan tí a dá kọ́ lọ́nà tí yóò fi gba gbogbo ìró mọ́ra—agbára ìgbọ́ròó rẹ yóò sì ti rọra ‘yí ohùn sókè’ tó pé kí o máa gbọ́ ìró ṣíṣàjèjì tí ń wá láti inú ara ìwọ fúnra rẹ. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìró náà, F. Alton Everest, ṣàpèjúwe ìrírí náà nínú ìwé The Master Handbook of Acoustics. Lákọ̀ọ́kọ́, ìlùkìkì ọkàn àyà tìrẹ fúnra rẹ ṣeé gbọ́ ketekete. Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí kan nínú iyàrá náà, o ń gbọ́ bí ẹ̀jẹ̀ rẹ ṣe ń lọ nínú àwọn òpó rẹ̀. Níkẹyìn, bí agbára ìgbọ́ròó rẹ bá múná dáradára, “a ń san èrè sùúrù rẹ nípa ìró ìpòṣé ṣíṣàjèjì kan láàárín ìlùkìkì ọkàn àyà àti ìtújáde ẹ̀jẹ̀. Kí ni?” Everest ṣàlàyé pé: “Ó jẹ́ ìró afẹ́fẹ́ tí ń gbá ọmọlétí rẹ. Bí ìró ìpòṣé yìí ṣe ń gbọn ọmọlétí tó kéré tó bẹ́ẹ̀ tí kò ṣeé gbà gbọ́—kìkì ìpín 1/100 lára ìpín mílíọ̀nù nínú sẹ̀ǹtímítà kan!” Èyí ni “ọ̀nà àbáwọlé ìgbọ́ròó” ìwọ̀n tí ó kéré jù nínú agbára rẹ láti gbọ́ròó. Agbára ìgbọ́ròó tí ó bá jù bẹ́ẹ̀ lọ kò ní wúlò fún ọ nítorí pé ariwo híhó afẹ́fẹ́ náà yóò bo gbogbo ìró tí kò bá tó bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.
Ó ṣeé ṣe láti gbọ́ròó nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ etí òde, etí àárín, àti etí inú pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn agbára ìmòye àti ìṣètumọ̀ tí ìgbékalẹ̀ iṣan ara àti ọpọlọ wa ní. Àwọn ìró ń gba inú afẹ́fẹ́ kọjá bí ìgbì ìgbọ̀nrìrì. Àwọn ìgbì wọ̀nyí ń ti ọmọlétí wa síwá sẹ́yìn, tí etí àárín sì ń tàtaré ìtìlọtìbọ̀ yí sí etí inú. Níbẹ̀ ni a ti ń yí ìtìlọtìbọ̀ náà pa dà sí ìsọkúlúkúlú iṣan, tí ọpọlọ ń túmọ̀ sí ìró.a
Etí Òde Rẹ Tó Ṣe Pàtàkì
Apá oníṣẹ̀ẹ́po, tí ó ṣeé tẹ̀ nínú etí rẹ, tí ó hàn níta, ni a ń pè ní pinna. Pinnae máa ń gba ìró, àmọ́ ó ń ṣe púpọ̀ sí i ju ìyẹn lọ. Ǹjẹ́ o tí ì ṣe kàyéfì rí nípa ìdí tí etí rẹ fi ní gbogbo àwọn ìṣẹ́po kéékèèké wọ̀nyẹn bí? Àwọn ìgbì ìró tí ń gba ara pinna kọjá ni a ń tún rọ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀gbẹ́ tí wọ́n gbà dé. Ó ṣeé ṣe fún ọpọlọ láti ṣàtúpalẹ̀ àwọn ìyàtọ̀ kéékèèké wọ̀nyí, kí ó sì pinnu ìhà ibi tí ìró náà ti wá. Ọpọlọ ń ṣe èyí ní àfikún sí ṣíṣe àfiwéra àkókò tí ìró kan wọ etí rẹ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú bí ó ṣe le tó.
Láti ṣàfihàn èyí, máa tàka rẹ bí o ti ń mú ọwọ́ rẹ lọ sókè, tí o sì ń mú un wá sílẹ̀ ní tààràtà níwájú ẹnì kan tí ó dijú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bákan náà ni ọwọ́ rẹ ṣe jìnnà sí etí rẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó, síbẹ̀, ó lè mọ̀ yálà ìró náà ń wá látòkè, látìsàlẹ̀, tàbí látibikíbi láàárín. Ní gidi, ẹnì kan tí ó ní etí kan ṣoṣo tí ń ṣiṣẹ́ lè mọ ibi tí ìró ti wá dáradára.
Etí Rẹ Àárín—Àgbàyanu Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Kan
Lájorí iṣẹ́ etí rẹ àárín ni láti tàtaré ìsúnlọsúnbọ̀ ọmọlétí rẹ sínú ohun ṣíṣàn tó wà nínú etí inú rẹ. Ohun ṣíṣàn yẹn wúwo gan-an ju afẹ́fẹ́ lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ó ti rí ní ti agunkẹ̀kẹ́ kan tí ń pọ́nkè, ó yẹ kí ó lo ‘ìwọ̀n jíà’ yíyẹ kí ó lè gbé agbára náà yọ lọ́nà jíjáfáfá tó bí ó bá ti lè ṣeé ṣe. Nínú etí àárín, àwọn egungun tíntìntín mẹ́ta, tí a sábà ń pè ní òòlù, owú, àti arùdìdesókè nítorí ìrísí wọn, ní ń tàtaré agbára náà. Ìsopọ̀ ọlọ́nà ẹ̀rọ kékeré yìí ń ṣàṣeyọrí ‘ìwọ̀n jíà’ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kógo já pátápátá fún etí inú. A ṣírò rẹ̀ pé láìsí i, ìpín 97 nínú ọgọ́rùn-ún agbára ìró ni à bá máa pàdánù!
Àwọn ìṣù ẹran ara méjì tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ wà ní ìsopọ̀ mọ́ ìfarakanra inú etí rẹ àárín. Láàárín ìpín ọgọ́rùn-ún ìṣẹ́jú àáyá kan tí ìró aláriwo bá ń wọ etí rẹ, àwọn ìṣù ẹran wọ̀nyí yóò fún pọ̀ fúnra wọn, tí ń tipa bẹ́ẹ̀ pààlà sí ìtìlọtìbọ̀ ìfarakanra náà, tí ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣèdíwọ́ fún ìpalára èyíkéyìí tí ó ṣeé ṣe. Ìmárabápòmu yìí yára kánkán tó láti dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìró aláriwo inú ìṣẹ̀dá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kì í ṣe lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ẹ̀rọ àti ohun èlò oníná mànàmáná ń mú wá. Ní àfikún sí i, ìṣẹ́jú mẹ́wàá péré ni àwọn ìṣù ẹran náà fi lè wà ní ipò ìdáàbòbò yí. Ṣùgbọ́n èyí fún ọ láǹfààní láti sá fún ìró amúnibínú náà. Lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, ọpọlọ rẹ ń fún àwọn ìṣù ẹran wọ̀nyí ní ìsọfúnni pé kí wọ́n dín agbára ìgbọ́ròó rẹ kù, ki ohùn ìwọ fúnra rẹ má baà pariwo jù fún ọ.
Àgbàyanu Etí Inú Rẹ
Apá tí ń nípa nínú agbára ìgbọ́ròó nínú etí inú rẹ wà láàárín cochlea, tí a pè bẹ́ẹ̀ nítorí ìrísí ìkarahun ìgbín tó ní. Egungun tó nípọn jù lọ nínú ara rẹ ní ń dáàbò bo ìgbékalẹ̀ ẹlẹgẹ́ rẹ̀. Láàárín ìlọ́kọ́lọkọ̀lọ rẹ̀ ni awọ fẹ́lẹ́fẹ́fẹ́ basilar, ọ̀kan lára àwọn iṣu ẹran mélòó kan tí ó pín cochlea sí ipa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní gígùn rẹ̀, wà. Lára awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ basilar náà ni ẹ̀yà ara Corti wà, tí ń gbé ẹgbẹẹgbẹ̀rún sẹ́ẹ̀lì irun ró—àwọn sẹ́ẹ̀lì iṣan tí o ní góńgó bí irun tí ó wọnú ohun ṣíṣàn tó kún inú cochlea.
Nígbà tí ìsúnlọsúnbọ̀ àwọn egungun etí àárín bá gbọn àlàfo rogodo ti cochlea, ó ń fa ìgbì nínú ohun ṣíṣàn náà. Àwọn ìgbì wọ̀nyí ń ti àwọn awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ náà, lọ́nà kan náà tí ìgbì omi kékeré nínú adágún ń gbà ti àwọn ewé ojú omi sókè àti sódò. Àwọn ìgbì náà ń tẹ awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ basilar ní àwọn ibi tí ó bá iye ìgbì tí ń jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan mu. Àwọn sẹ́ẹ̀lì irun tó wà ní àwọn ibi wọ̀nyẹn wá ń fara nu awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó dà bí ìbòrí lókè rẹ̀. Ìfarakanra yìí ń ta àwọn sẹ́ẹ̀lì irun jí, àwọn náà wá ń mú ìsọkúlúkúlú kan jáde, wọ́n sì ń fi ránṣẹ́ sí ọpọlọ rẹ. Bí ìró náà bá ṣe le tó ni ó ṣe ń fún àwọn sẹ́ẹ̀lì irun náà lágbára tó, tí ó sì ń yára ṣe bẹ́ẹ̀ tó. Nípa bẹ́ẹ̀, ọpọlọ ń gbọ́ ìró tí ó túbọ̀ ròkè.
Ọpọlọ Rẹ àti Agbára Ìgbọ́ròó Rẹ
Ọpọlọ rẹ ni apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbékalẹ̀ agbára ìgbọ́ròó rẹ. Ó ní agbára ìṣeǹkan kíkàmàmà láti yí omilẹngbẹ ìsọfúnni tí ó ń rí gbà gẹ́gẹ́ bí ìsọkúlúkúlú iṣan pa dà di ìmòye ìró nínú ọpọlọ. Iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ yí ń tọ́ka àkànṣe ìsopọ̀ tó wà láàárín èrò àti ìgbọ́ròó jáde, ìsopọ̀ kan tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí a ń pè ní psychoacoustics. Bí àpẹẹrẹ, ọpọlọ rẹ mú kí o lè máa gbọ́ ìjíròrò kan nínú ọ̀pọ̀ ìjíròrò tí ń lọ nínú iyàrá ọlọ́pọ̀ èrò kan. Ẹ̀rọ gbohùngbohùn kan kò ní agbára ìṣeǹkan yìí, nítorí náà, ohùn tí a gbà sílẹ̀ nínú iyàrá kan náà lè fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé gbọ́.
A ń ṣàfihàn apá mìíràn kan nínú ìsokọ́ra yìí nípa ìbínú tí ariwo tí a kò fẹ́ ń fà. Bí ó ti wù kí ìró kan kéré tó, bí o bá ti lè gbọ́ ọ nígbà tí ó kò fẹ́ ẹ, ó lè bí ọ nínú. Bí àpẹẹrẹ, ìró tí ń jáde nígbà tí omi bá ń jò lẹ́nu ẹ̀rọ kéré púpọ̀. Àmọ́ o lè rí i pé kò bá ọ lára mu rárá, bí ó bá jí ọ sílẹ̀ láàárín òru!
Láìṣe àní-àní, ìmọ̀lára wa ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú agbára ìgbọ́ròó wa. Wulẹ̀ ronú lórí ipa tí ń ranni tí ẹ̀rín kèékèé ń ní, tàbí ti ọ̀yàyà tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìfẹ́ni tàbí ìyìn àtọkànwá. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ lára ohun tí a mọ̀ nínú ọpọlọ ni ó gba etí wọlé.
Ẹ̀bùn Tí Ó Yẹ Kí A Ṣìkẹ́
A kò ì rídìí ọ̀pọ̀ lára àwọn àṣírí fífani-lọ́kànmọ́ra tí agbára ìgbọ́ròó wa ní. Àmọ́ ìwọ̀n òye tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti fún wa mú kí a túbọ̀ mọrírì làákàyè àti ìfẹ́ tí a fi hàn nípasẹ rẹ̀. Olùwádìí nípa ìró náà, F. Alton Everest, kọ̀wé pé: “Dé ìwọ̀n èyíkéyìí tí a bá ń ṣàyẹ̀wò agbára ìgbọ́ròó ẹ̀dá ènìyàn, ìpinnu tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ náà ni pé àwọn iṣẹ́ àti ìrísí rẹ̀ dídíjú ń tọ́ka sí i pé ẹni ọlọ́làwọ́ kan ló ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀.”
Ọba Dáfídì ti Ísírẹ́lì ìgbàanì kò ní ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní nípa bí agbára ìgbọ́ròó wa ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú lọ́hùn-ún. Síbẹ̀, ó ronú lórí ara òun tìkára rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn tí ó ní, ó sì kọrin sí Olùṣe rẹ̀ pé: “Tẹ̀rùtẹ̀rù àti tìyanutìyanu ni a dá mi: ìyanu ni iṣẹ́ rẹ.” (Orin Dáfídì 139:14) Ìwádìí lọ́nà ti sáyẹ́ǹsì nípa àwọn ohun àgbàyanu àti àdììtú inú ara, títí kan agbára ìgbọ́ròó, ń ṣàfikún ẹ̀rí pé Dáfídì tọ̀nà—Ẹlẹ́dàá kan tó gbọ́n tó sì nífẹ̀ẹ́ ló ṣàgbékalẹ̀ wa!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí!, July 22, 1990, ojú ìwé 18 sí 21.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tí Agbára Ìgbọ́ròó Wọn Bà Jẹ́
Gbígbọ́ ariwo fún àkókò gígùn ń fa ìpalára tí kò ṣeé wò sàn fún agbára ìgbọ́ròó. Irú àdánù bẹ́ẹ̀ níye lórí ju títẹ́tí sí ohùn orin aláriwo tàbí ṣíṣiṣẹ́ nídìí ohun èlò aláriwo láìdáàbò bo etí lọ. Àwọn ohun èlò ìgbọ́ròó lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí agbára ìgbọ́ròó wọn bá lábùkù, kódà, fún àwọn kan tí a bí ní adití. Ní ti àwọn ènìyàn púpọ̀, irú àwọn ìhùmọ̀ bẹ́ẹ̀ ń dá agbára ìgbọ́ròó wọn pa dà. Lẹ́yìn tí a fún obìnrin kan ní àwọn ohun èlò ìgbọ́ròó fún ìgbà àkọ́kọ́, ó gbọ́ ìró ṣíṣàjèjì láti ìta fèrèsé ilé ìdáná rẹ̀. Ó f ìyanu sọ pé: “Àwọn ẹyẹ ni! N kò gbọ́ ohùn ẹyẹ láti ọdún mélòó kan wá!”
Kódà, láìsí ìbàjẹ́ tí kò ṣeé tún ṣe, ọjọ́ orí máa ń dín agbára wa láti mọ ìró híhan yàtọ̀ kù. Ó bani nínú jẹ́ pé èyí kan bí àwọn ìró kọ́ńsónáǹtì—ìró tí ó sábà ṣe kókó jù láti lè lóye ọ̀rọ̀—ti lọ sókè tó. Nítorí náà, àwọn ènìyàn tí wọ́n túbọ̀ dàgbà lè rí i pé àwọn ìró abẹ́lé wíwọ́pọ̀, bí ìró tí ń jáde nígbà tí omi bá ń jáde lẹ́nu ẹ̀rọ tàbí nígbà tí a bá rún pépà pọ̀, lè dí wọn lọ́wọ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀, nítorí pé ìró wọn lè lọ sókè kí ó sì dí ìró kọ́ńsónáǹtì lọ́wọ́. Àwọn ohun èlò ìgbọ́ròó lè pèsè ìtura díẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ní àwọn ìṣòro tiwọn. Lọ́nà kan, àwọn ojúlówó ohun èlò ìgbọ́ròó máa ń wọ́n—apá kòlàkòṣagbe kan ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kò sì lè ká a. Lọ́nàkọnà pẹ̀lú, kò sí ohun èlò ìgbọ́ròó tí ó lè dá agbára ìgbọ́ròó rẹ pa dà pátápátá. Nítorí náà, kí ni o lè ṣe?
Gbígba tẹlòmíràn rò ṣàǹfààní gidigidi. Kí o tó sọ̀rọ̀ sí ẹnì kan tí ó pàdánù agbára ìgbọ́ròó rẹ̀, rí i dájú pé ó mọ̀ pé o fẹ́ sọ̀rọ̀. Gbìyànjú láti kọjú sí ẹni náà. Èyí mú kí ó lè rí bí o ṣe ń gbé ara àti ètè, kí ó sì mọ ohun tí ìró kọ́ńsónáǹtì inú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́. Bí ó bá ṣeé ṣe, sún mọ́ ẹni náà pẹ́kípẹ́kí, kí o sì rọra sọ̀rọ̀ ketekete; má pariwo. Ariwo máa ń ro ọ̀pọ̀ ènìyàn tí agbára ìgbọ́ròó wọn lábùkù lára. Bí wọn kò bá lóye gbólóhùn kan, gbìyànjú láti sọ ọ́ lọ́nà rírọrùn dípò kí o wulẹ̀ tún un sọ. Bákan náà, bí agbára ìgbọ́ròó tìrẹ kò bá rí bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ mọ́, o lè mú kí ó rọrùn fún àwọn ẹlòmíràn láti bá ọ jíròrò nípa sísún mọ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ náà pẹ́kípẹ́kí sí i, kí o sì mú sùúrù. Àfikún ìsapá wọ̀nyí yóò yọrí sí àjọṣe tí ó sunwọ̀n sí i, ó sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àyíká rẹ dunjú.
[Àwòrán]
Nígbà tí o bá ń bá ẹnì kan tí ó pàdánù agbára ìgbọ́ròó rẹ̀ sọ̀rọ̀, kọjú sí i, kí o sì rọra sọ̀rọ̀ ketekete
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Etí Rẹ
Pinna
Àlàfo rogodo
Iṣan ìgbọ́ròó
Òòlù (malleus)
Owú (incus)
Arùdìdesókè (stapes)
Ihò ìgbọ́ròó
Ọmọlétí
Cochlea
Ẹ̀yà ara Corti
Ihò roboto
Iṣan ìgbọ́ròó
Àwọn sẹ́ẹ̀lì irun
Awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó dà bí ìbòrí lókè
Àwọn fọ́nrán iṣan
Awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ basilar