ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/8 ojú ìwé 26-27
  • Àwọn Kristian Tòótọ́ Ha Lè Retí Ààbò Àtọ̀runwá Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kristian Tòótọ́ Ha Lè Retí Ààbò Àtọ̀runwá Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ète Ààbò Àtọ̀runwá
  • A Lò Ó Láti Mú Ète Ọlọrun Ṣẹ
  • Ṣé Ọlọrun Kò Láàánú Ni?
  • Agbára Ààbò—“Ọlọ́run Ni Ibi Ààbò Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Retí Pé Kí Ọlọ́run Yọ Wọ́n Nínú Gbogbo Ewu?
    Jí!—2002
  • Jehofa Ọlọrun Ète
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • ‘Àwọn Èèyàn Tí Ò Kàwé àti Gbáàtúù’
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 4/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bibeli

Àwọn Kristian Tòótọ́ Ha Lè Retí Ààbò Àtọ̀runwá Bí?

KÍ ÀWỌN Kristian baà lè kó àwọn ìpèsè ìtìlẹ́yìn lọ fún àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn, lẹ́yìn tí wọ́n gbàdúrà tán, wọ́n rìnrìn àjò pa pọ̀ kọjá ní agbègbè kan tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ níbi tí wọ́n ti lè pàdé ikú. Wọ́n débẹ̀ láìséwu, sí ìyàlẹ́nu ńlá lójú àwọn jagunjagun tí ń bá ara wọn jà. Áńgẹ́lì Ọlọrun ló ha dáàbò bò wọ́n bí?

Nígbà tí ọkọ̀ òfuurufú kan já lulẹ̀, ó pa àwọn Kristian tọkọtaya kan, tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, níbi tí wọ́n ti ń jíhìn rere láti ilé dé ilé. Kí ló dé tí áńgẹ́lì Ọlọrun kò darí àwọn tàbí ọkọ̀ òfuurufú náà sí ibòmíràn ní àkókò yẹn gan-an?—Fi wé Ìṣe 8:26.

Bí a bá fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wéra, a lè béèrè pé: Kí ló dé tí àwọn Kristian kan ṣe máa ń kú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun lọ́wọ́, nígbà tí ó sì jẹ́ pé àwọn ẹlòmíràn, tí wọ́n wà nínú ipò tí ó léwu gan-an lọ́pọ̀ ìgbà, máa ń yè bọ́? Àwọn Kristian ha lè retí ààbò àtọ̀runwá, ní pàtàkì ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí ó le koko yìí?—2 Timoteu 3:1.

Ète Ààbò Àtọ̀runwá

Jehofa Ọlọrun ti ṣèlérí láti bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀, kí ó sì dáàbò bò wọ́n. (Eksodu 19:3-6; Isaiah 54:17) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ó ta yọ ní ọ̀rúndún kìíní, nígbà tí ìjọ Kristian ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Iṣẹ́ ìyanu pọ̀ gan-an lóríṣiríṣi. Jesu sọ oúnjẹ di púpọ̀ láti bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn; òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wo onírúurú àrùn àti àmódi sàn; wọ́n lé àwọn ẹ̀mí tí agbára wọn ju ti ènìyàn lọ jáde lára àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí èṣù, wọ́n sì jí àwọn òkú dìde pàápàá. Lábẹ́ ìdarísọ́nà àtọ̀runwa, ìjọ tuntun náà ń dàgbà, ó sì ń fìdí múlẹ̀ ṣinṣin. Síbẹ̀, láìka gbogbo ìtìlẹ́yìn Ọlọrun tí ó fara hàn gbangba yẹn sí, ọ̀pọ̀ àwọn Kristian olùṣòtítọ́ jìyà ohun tí a lè pè ní ikú àìtọ́jọ́.—Fi wé Orin Dafidi 90:10.

Ronú nípa ọ̀ràn Jakọbu àti Johannu, àwọn ọmọkùnrin Sebede. A yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí aposteli, àwọn, pa pọ̀ pẹ̀lú Peteru, wà lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Kristi.a Ṣùgbọ́n Jakọbu kú ikú ajẹ́rìíkú ní ọdún 44 Sànmánì Tiwa, nígbà tí arákùnrin rẹ̀, Johannu, gbé ayé títí di òpin ọ̀rúndún kìíní. Ó hàn kedere pé iṣẹ́ Ọlọrun ni àwọn méjèèjì ń ṣe. Kí ló dé tí a fi jẹ́ kí Jakọbu kú, tí Johannu sì wà láàyè?

Ó dájú pé Ọlọrun Olódùmarè ní agbára láti dáàbò bo ẹ̀mí Jakọbu. Ní tòótọ́, ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ikú ajẹ́rìíkú Jakọbu, áńgẹ́lì Jehofa gba Peteru sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ikú. Kí ló dé tí áńgẹ́lì náà kò gba Jakọbu sílẹ̀?—Ìṣe 12:1-11.

A Lò Ó Láti Mú Ète Ọlọrun Ṣẹ

Láti lóye ìdí tí a fi ń pèsè ààbò àtọ̀runwá, a gbọ́dọ̀ lóye pé a kò fi í fúnni kìkì láti jẹ́ kí ẹnì kan pẹ́ láyé, ṣùgbọ́n láti dáàbò bo ohun kan tí ó ṣe pàtàkì gan-an, mímú ète Ọlọrun ṣẹ. Fún àpẹẹrẹ, wíwà nìṣó ìjọ Kristian lódiidi ni Ọlọrun mú dájú nítorí pé ó kan mímú ète yẹn ṣẹ pẹ́kípẹ́kí. Bí ó ti wù kí ó rí, Kristi sọ ní gbangbagbàǹgbà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n lè dojú kọ ikú lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Lẹ́yìn tí Jesu sọ èyí tán, ó tẹnu mọ́ ‘ìforítì títí dé òpin’ kì í ṣe ìgbàlà lọ́nà ìyanu. (Matteu 24:9, 13) Òtítọ́ náà pé a dáàbò bo àwọn ènìyàn kan, tí a kò sì dáàbò bo àwọn mìíràn, kò tọ́ka pé Ọlọrun ń ṣojúsàájú. Ọlọrun wulẹ̀ lo ẹni tí ó wà ní ipò tí ó dára jù lọ láti ṣàṣeparí ète rẹ̀ ni, èyí tí yóò wá ṣàǹfààní fún gbogbo aráyé níkẹyìn.

Níwọ̀n bí ikú àìtọ́jọ́ nídìí iṣẹ́ ìsìn Ọlọrun ti jẹ́ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, ó yẹ kí àwọn Kristian ní ẹ̀mí ìrònú wíwà déédéé bíi ti àwọn ọmọ Heberu olùṣòtítọ́ mẹ́ta tí wọ́n dájọ́ ikú fún nítorí jíjọ́sìn Ọlọrun. Wọ́n wí fún ọba Babiloni pé: “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọrun wa tí àwá ń sìn, lè gbà wá lọ́wọ́ iná ìleru náà tí ń jó, òun óò sì gbà wá lọ́wọ́ rẹ, ọba. Ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó yé ọ, ọba pé, àwa kì yóò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwa kì yóò sì tẹrí ba fún ère wúrà tí ìwọ́ gbé kalẹ̀.”—Danieli 3:17, 18.

Jehofa dá ẹ̀mí Peteru àti Johannu sí nítorí ipa pàtàkì tí wọ́n kó nínú mímú ète rẹ̀ ṣẹ. Peteru ni a lò láti ‘fún ìjọ lókun’ nípa ṣíṣe iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, tí ó ní kíkọ méjì lára àwọn ìwé Bibeli tí ó ní ìmísí nínú. (Luku 22:32) Johannu kọ ìwé márùn-ún nínú Bibeli, ó sì jẹ́ “ọwọ̀n” kan nínú ìjọ ìjímìjí náà.—Galatia 2:9; Johannu 21:15-23.

Kò ṣeé ṣe láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí Jehofa yóò ṣe pinnu àkókò àti ọ̀nà pàtó tí òun yóò gbà dá sí ọ̀ràn nínú ìgbésí ayé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Gbogbo ohun ti a wulẹ̀ lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú ni pé Kristi ṣèlérí àtiwà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ “ní gbogbo awọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” (Matteu 28:20) Ní pàtàkì, yóò wà ‘pẹ̀lú wa’ nípasẹ̀ ìtọ́sọ́nà áńgẹ́lì nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. (Matteu 13:36-43; Ìṣípayá 14:6) Yàtọ̀ sí àwọn ìtọ́kasí ti gbogbogbòò yìí, a kò lè fojú sọ́nà ní pàtó nípa bí a óò ṣe rí ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá gbà tàbí ẹni tí ó lè rí ààbò àtọ̀runwá. Bí Kristian kan bá nímọ̀lára pé òún ti rí ààbò àti ìtọ́sọ́nà Ọlọrun gbà ńkọ́? Níwọ̀n bí kò ti lè fi ẹ̀rí èyí hàn délẹ̀délẹ̀ tàbí tí a kò lè já a pátápátá, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ ṣèdájọ́ ohun tí irú ẹnì bẹ́ẹ̀ bá fi òtítọ́ inú sọ.

Ṣé Ọlọrun Kò Láàánú Ni?

Ǹjẹ́ òtítọ́ náà pé Ọlọrun máa ń fàyè gba ikú àwọn Kristian fi hàn pé kò láàánú lọ́nà kan ni? Kí a má rí i. (Oniwasu 9:11) Jehofa ń ṣiṣẹ́ láti dáàbò bo ẹ̀mí wa, kì í ṣe fún kìkì ọdún bíi mélòó kan tàbí fún àwọn ẹ̀wádún pàápàá àmọ́ títí ayérayé. Ní ìhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ gíga lọ́lá jù lọ, ó máa ń yí nǹkan padà fún ire ayérayé ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tàbí tí ó fà sún mọ́ ọ́n. (Fi wé Matteu 18:14.) Ìmúṣẹ ète rẹ̀ yóò túmọ̀ sí mímú ohunkóhun tí a bá jìyà nínú ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan yìí kúrò pátápátá—kódà ikú pàápàá. Àwọn ọ̀nà ìbálò Ọlọrun díjú, wọ́n sì pé gan-an débi pé a sún aposteli Paulu láti pòkìkí pé: “Óò ìjìnlẹ̀ awọn ọrọ̀ ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ Ọlọrun! Awọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó awọn ọ̀nà rẹ̀ sì rékọjá àwákàn!”—Romu 11:33.

Níwọ̀n bí kò ti sí ohunkóhun tí ó lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọrun, ìbéèrè tí ó yẹ kí Kristian kọ̀ọ̀kan béèrè kì í ṣe ‘Èmi yóò ha rí ààbò àtọ̀runwá bí?’ ṣùgbọ́n ‘Mo ha ní ìbùkún Jehofa bí?’ Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, òun yóò fún wa ní ìyè ayérayé—láìka ohunkóhun tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí wa nínú ètò ìgbékalẹ̀ yìí sí. Tí a bá fi ìjìyà èyíkéyìí—kódà ikú pàápàá—nínú ètò ìgbékalẹ̀ yìí wéra pẹ̀lú ìyè ayérayé nínú ipò pípé, yóò wulẹ̀ dà bíi “fún ìgbà díẹ̀ tí ó sì fúyẹ́” ni.—2 Korinti 4:17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Peteru, Jakọbu, àti Johannu ṣe ẹlẹ́rìí ìyípadà ológo Jesu (Marku 9:2) àti àjínde ọmọdébìnrin Jairu (Marku 5:22-24, 35-42); wọ́n wà nítòsí ní Ọgbà Getsemane nígbà ìdánwò Jesu fúnra rẹ̀ (Marku 14:32-42); àwọn kan náà, pa pọ̀ pẹ̀lú Anderu, béèrè lọ́wọ́ Jesu nípa ìparun Jerusalemu, wíwà níhìn-ín rẹ̀ ọjọ́ iwájú, àti òpin èto ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.—Matteu 24:3; Marku 13:1-3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́