Bíbá Àwọn Ènìyàn Sọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Ọwọ́ Tí Ń Ṣàpèjúwe
BẸ̀RẸ̀ láti June 1995 jálẹ̀ ìgbà ẹ̀rùn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ ẹ̀ka United States ṣe àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè 181 pẹ̀lú àkọlé náà “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn.” Ní méjì lára àwọn àpéjọpọ̀ náà—ọ̀kan ní ìhà ìlà oòrùn àti èkejì ní ìhà ìwọ̀ oòrùn—gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni a gbé jáde tààràtà ní Èdè Àwọn Adití. Nípa bẹ́ẹ̀ ìmúṣekedere ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni a mú sunwọ̀n sí i—nítorí pé gbígbé e jáde tààràtà fún àwọn adití ní èdè adití túbọ̀ ṣeé lóye dáradára ju títúmọ̀ rẹ̀ láti inú ọ̀rọ̀ tí a ń sọ.
Àwọn àyànṣaṣojú wá láti ìjọ 11 tí wọ́n ti ń lo èdè àwọn adití àti nǹkan bí 30 àwùjọ àwọn tí wọ́n gbọ́ èdè àwọn aditi káàkiri United States. Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn ti wọ́n tún wà níbẹ̀ ni àwọn àyànṣaṣojú láti Britain, Denmark, Dominican Republic, Ecuador, Germany, Japan, Kánádà Mexico, Norway, Puerto Rico, àti Rọ́ṣíà. Nípa bẹ́ẹ̀, àyíká náà jẹ́ tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.
A gbé àwọn gọgọwú fídíò káàkiri kí àwọn ènìyàn baà lè máa rí ohun tí ń lọ lórí tẹlifíṣọ̀n díẹ̀ tí a so kọ́ra. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àyànṣaṣojú bíi mélòó kan jẹ́ adití, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ríran. Báwo ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe jàǹfààní láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà? Ó jẹ́ ohun tí ń ru ìmọ̀lára sókè ní tòótọ́ láti rí àwọn olùyọ̀ọ̀da ara ẹni tí iye wọn lé ní ọgọ́rùn-ún tí wọ́n ń pààrọ̀ ara wọn láti ṣàpèjúwe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ojoojúmọ̀ fún wọn nípasẹ̀ (ìfọwọ́kàn) àfòyemọ̀.
Ní àwọn àpéjọpọ̀ méjèèjì yìí, àwọn ènìyàn 36 ni wọ́n fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn sí Jehofa Ọlọrun nípasẹ̀ ìrìbọmi. Kókó pàtàkì míràn ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, Bíbọlá fún Àwọn Ẹni Yíyẹ ní Ọjọ́ Ogbó Wọn. Ẹ wo bí ó ti gbádùn mọ́ni tó láti gbé àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí kalẹ̀ pátápátá ní èdè àwọn adití, tí èyí sì jẹ́ kí àwọn mẹ́ḿbà tí wọ́n jẹ́ adití lè ní àjọpín pàtàkì nínú ìgbékalẹ̀ náà!
Lẹ́yìn náà ni ó kan gbígbé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tuntun náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, jáde. Ní pàtàkì inú àwọn onípàdé dùn láti mọ̀ pé a ti mú ẹ̀dà ìwé náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè àwọn adití lórí téèpù fídíò! Ìdìpọ̀ Kíní, tí a gbé jáde ní àpéjọpọ̀ náà, ní àkòrí mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú. Àwọn ìdìpọ̀ márùn-ún mìíràn ṣì ń bọ̀ lọ́nà. Àyànṣaṣojú kan láti Ohio sọ pé: “Ẹ wo bí ọpẹ́ wa ti pọ̀ tó fún fídíò tuntun yìí. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí iṣẹ́ wa túbọ̀ yára kánkán ní ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ àwọn odi.”
Àwọn 2,621 tí wọ́n wà níbi àpéjọpọ̀ méjèèjì yìí darí sílé pẹ̀lú ìtura tẹ̀mí. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, wọ́n pinnu láti ṣàsọtúnsọ àwọn ọ̀rọ̀ olórin náà pé: “Jẹ́ kí ohun gbogbo tí ó ní ẹ̀mí kí ó yin Oluwa. Ẹ fi ìyìn fún Oluwa.”—Orin Dafidi 150:6.