ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/22 ojú ìwé 24
  • O Ha Rí Ìbùyẹ̀rì Aláwọ̀ Ewéko Rí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Ha Rí Ìbùyẹ̀rì Aláwọ̀ Ewéko Rí Bí?
  • Jí!—1996
Jí!—1996
g96 5/22 ojú ìwé 24

O Ha Rí Ìbùyẹ̀rì Aláwọ̀ Ewéko Rí Bí?

Ẹ WO bí ó ti ń dùn mọ́ni tó láti dá gbére fún ọjọ́ mìíràn nípa wíwo wíwọ̀ oòrùn rírẹwà kan! Ríràn yẹ́ríyẹ́rí oòrùn náà ń mú onírúurú àwọ̀ àfiṣèranwò jáde bí ìmọ́lẹ̀ ṣe ń kọjá nínú afẹ́fẹ́ àyíká ayé. Ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu yìí ń rí bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ohun àràmàǹdà kan tí ń jẹ́ ìbùyẹ̀rì aláwọ̀ ewéko. Bí nǹkan bá rí bí ó ṣe yẹ, ìtújáde ìmọ́lẹ̀ òkúta émírádì máa ń wáyé ní apá ìgbẹ̀yìn wíwọ̀ oòrùn. Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó túbọ̀ ṣọ̀wọ́n, tí a ń pè ní ìbùyẹ̀rì aláwọ̀ búlúù máa ń lẹ́wà jù ú lọ.

Kí ní ń fa àwọn ìbùyẹ̀rì aláwọ̀ mèremère wọ̀nyí? Èé ṣe tí wọn kì í pẹ́? Èé sì ti ṣe tí wọ́n fi ṣọ̀wọ́n tó bẹ́ẹ̀? Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní ìpìlẹ̀ òye nípa àjọṣepọ̀ láàárín ìmọ́lẹ̀ oòrùn àti afẹ́fẹ́ àyíká ayé.

Ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí ń tan ìtànṣán sí ilẹ̀ ayé ní gbogbo àwọ̀ ara òṣùmàrè. Nígbà tí ìmọ́lẹ̀ yìí bá gba àárín afẹ́fẹ́ àyíká ayé kọjá, afẹ́fẹ́ àyíká náà máa ń ṣe bíi nǹkan ńlá kan, tí ó sì máa ń fọ́n ìmọ́lẹ̀ náà ká, tàbí pín in yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Àmọ́, bí ìgbì ìmọ́lẹ̀ kan ṣe ń pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tó sinmi lórí ìwọ̀n ìgbì rẹ̀.

Ìgbì ìmọ́lẹ̀ aláwọ̀ búlúù ní ìwọ̀n ìgbì kékeré, ó sì fọ́n ká inú afẹ́fẹ́ àyíká púpọ̀púpọ̀. Ìdí nìyẹn tí òfuurufú fi ń ní àwọ̀ búlúù nígbà tí oòrùn bá yẹ̀ kúrò níbi ìpàdé ilẹ̀ òun òfuurufú lọ́jọ́ tí kò bá sí kùrukùru. Ṣùgbọ́n bí oòrùn bá ń sún mọ́ ibi ìpàdé ilẹ̀ òun òfuurufú—irú bíi nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀—ìmọ́lẹ̀ oòrùn náà gbọ́dọ̀ la ọ̀pọ̀ afẹ́fẹ́ àyíká kọjá kí ó tó dé ojú wa. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ìmọ́lẹ̀ aláwọ̀ búlúù tí ó fọ́n ká gan-an náà kì í dé ọ̀dọ̀ wa. Lọ́nà míràn, àwọn ìgbì tí ó gùn jù ú lọ, bíi pupa, lè túbọ̀ fìrọ̀rùn la afẹ́fẹ́ àyíká dídíjú náà já. Èyí ló ń mú kí wíwọ̀ oòrùn máa ni àwọ̀ pupa tàbí àwọ̀ olómi ọsàn rẹ̀ tí a mọ̀ dunjú.a

Bí ó ti wù kí ó rí, lábẹ́ àwọn ipò kan, a lè rí ìtànṣán oòrùn aláwọ̀ ewéko tàbí aláwọ̀ búlúù nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀. Báwo ni èyí ṣe ń ṣẹlẹ̀? Bí apá tí ó kẹ́yìn tí a lè rí lára oòrùn ti ń pò ó rá mọ́ni lójú, ìmọ́lẹ̀ oòrùn ń pín sí ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ bíi ti òṣùmàrè. Ìmọ́lẹ̀ pupa ń fara hàn nísàlẹ̀ ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ aláwọ̀ búlúù sì ń wà lókè. Bí oòrùn ti ń mòòkùn sí i, apá aláwọ̀ pupa ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ náà bọ́ sábẹ́ ibi ìpàdé ilẹ̀ òun òfuurufú, afẹ́fẹ́ àyíká sì máa ń fọ́n apá aláwọ̀ búlúù náà ká. Nígbà yìí gan-an ni apá tí ó kẹ́yìn lára ìmọ́lẹ̀ tí a lè rí náà máa ń ní àwọ̀ ewéko. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí ó fi jẹ́ àwọ̀ ewéko? Nítorí àwọ̀ ewéko ni àwọ̀ ìpìlẹ̀ kejì tí ìmọ́lẹ̀ ní.

Nígbà tí ojú òfuurufú bá ní ìdọ̀tí púpọ̀, a kì í sábà rí ìbùyẹ̀rì aláwọ̀ ewéko náà, ìbùyẹ̀rì aláwọ̀ búlúù sì máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí afẹ́fẹ́ àyíká bá mọ́ ta yọ, tí ìwọ̀n ìmọ́lẹ̀ aláwọ̀ búlúù púpọ̀ tó láti mú kí ìbùyẹ̀rì mímọ́lẹ̀ yòò fara hàn sì la òfuurufú já.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí!, June 8, 1988, ojú ìwé 16, fún àfikún ìsọfúnni nípa wíwọ̀ oòrùn.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Wíwọ̀ oòrùn: ©Pekka Parviainen/SPL/Photo Researchers

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́