ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/22 ojú ìwé 22-23
  • A Dá Wa Nídè Kúrò Nínú Lahar!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Dá Wa Nídè Kúrò Nínú Lahar!
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Làásìgbò Náà Bẹ̀rẹ̀
  • Ìdáǹdè—Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
  • Lahar—Àtubọ̀tán Òkè Ńlá Pinatubo
    Jí!—1996
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Mi Ò Ṣi Iṣẹ́ Tí Màá Ṣe Láyé Mi Yàn
    Jí!—2007
  • Ǹjẹ́ O Ti Ríbi Tí Ẹja Ti Ń Rìn Rí?
    Jí!—1999
Jí!—1996
g96 5/22 ojú ìwé 22-23

A Dá Wa Nídè Kúrò Nínú Lahar!

OCTOBER 1, 1995, já sí ọjọ́ aláìlẹ́gbẹ́ kan nínú ìgbé ayé ìdílé Garcia. Ìdílé Garcia jẹ́ àwọn ọ̀jáfáfá Ẹlẹ́rìí Jehofa, ilé wọ́n sì wà ní ìhà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́lé sí ní Cabalantian, Bacolor, ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Pampanga, Philippines. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọ́n wà ní agbègbè tí ń nírìírí ìtújáde lahar láti Òkè Ńlá Pinatubo, kò kàn wọ́n ní tààrà rí. Ọ̀nà ìṣàn omi tí ìjọba ń gbẹ́ láti dá ìṣàn lahar dúró ń dáàbò bo Cabalantian. Ṣùgbọ́n nǹkan ń fẹ́ yí padà ní kíákíá.

Ìjì ńlá kan rọ òjò tí ó wọlẹ̀ ní 216 mìlímítà sórí Òkè Ńlá Pinatubo. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ẹ̀rọ tẹlifóònù ilé Garcia han gan-anran. Ẹni náà ṣi nọ́ḿbà ẹ̀rọ tẹ̀ ni, ṣùgbọ́n ó sọ pé ọ̀nà ìṣàn omi kan ti ya, ìdílé náà sì gbọdọ̀ múra láti kojú àkúnya kan.

Làásìgbò Náà Bẹ̀rẹ̀

Nonato Garcia, olórí ìdílé náà, tí ó tún jẹ́ alábòójútó olùṣalága Ìjọ Villa Rosemarie, ṣàlàyé pé: “Ṣáájú aago márùn-ún òwúrọ̀ Sunday, omí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ya bo ilé wa.

“Mo rò pé àkúnya omi lásán ni yóò ṣẹlẹ̀, nítorí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹrù wa gòkè ilé. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn agogo mẹ́wàá òwúrọ̀, mo rí i pé ẹrẹ̀ lahar wà nínú omi náà. Ìṣàn omi náà ń ga sí i, ó sì ń lágbára sí i títí ó fi pọ̀ gan-an tí ó sì ń kó àfọ́kù àpáta mọ́ra. A gòkè lọ sí òkè ilé.

“Lẹ́yìn náà, ìṣàn omi náà bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ ọkọ̀ àti ilé pàápàá lọ. Ilé kan tí àfọ́kù àpáta kọ lù wó lulẹ̀, omí sì gbé e lọ. Lahar náà gbé òrùlé rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ ilé wa. Àwọn ènìyàn wà lórí òrùlé náà. Mo ké sí wọn, mo sì fún wọn níṣìírí láti wá sórí òrùlé ilé tiwa. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n rọ̀ mọ́ wáyà kan tí a jù sí wọn. Mo so ó mọ́ ara mi, mo sì fà wọ́n kọjá lọ́kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣí wá láti àwọn òrùlé tí ẹrẹ̀ lahar ń bò mọ́lẹ̀. Ní gbogbo ìgbà wọ̀nyí, òjò náà ṣì ń rọ̀.

“Ní ọ̀sán, àwọn hẹlikọ́pítà bẹ̀rẹ̀ sí í fò kọjá. Ṣùgbọ́n kò sí èyí tí ó wá gbà wá sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé taratara ni a ń wawọ́ sí wọn. A rò pé àwọn ènìyàn míràn wà nínú ewu jù wá lọ, àwọn yẹn ni wọ́n sì kọ́kọ́ ń kó. N kò rò pé a óò tètè kó wa kíákíá, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ló wà lórí àwọn òrùlé ilé lọ.

“Ní irú ipò bẹ́ẹ̀, àdúrà ṣe pàtàkì gan-an. Àní nígbà tí o bá wà nínú ewu ńlá gan-an, lẹ́yìn tí o bá ti gbàdúrà, ẹ̀rù kò ní bà ọ́ mọ́. A kò gbàdúrà pé kí Jehofa ṣe iṣẹ́ ìyanu, ṣùgbọ́n a béèrè fún ohunkóhun tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ inú rẹ̀, ní mímọ̀ pé kò sí ẹni tí ìjábá kò lè kàn. Ṣùgbọ́n mo béèrè fún okun, ìgboyà, àti ọgbọ́n. Gbogbo èyí ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ipò tí ó dojú kọ wá.”

Ìyàwó Nonato, Carmen, fara mọ́ ọn ní sísọ pé: “Òtítọ́ gidi ni ohun tí ọkọ mí sọ nípa àdúrà. Ojora máa ń ṣe mí nígbà tí mo bá dojú kọ ipò tí ẹ̀mí àwọn olólùfẹ́ mi ti wà nínú ewu. Nígbà tí mo rí i pé ẹrẹ̀ lahar àti àfọ́kù àpáta ń bo òrùlé, mo sọ fún ọkọ mi pé: ‘Ó jọ pé a kò nírètí kankan mọ́.’ Ṣùgbọ́n ó fún mi níṣìírí, ní sísọ pé: ‘Jẹ́ kí á gbàdúrà.’”

Nonato ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Láago mẹ́rin ọ̀sán, ìṣàn lahar náà ṣì lágbára gan-an. Àwọn àpáta ńlá ń kọ lu ilé. Àwọn pàǹtírí lahar ti bo nǹkan bí ìdajì òrùlé náà. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ilẹ̀ ń ṣú lọ, yóò sì ṣòro gan-an láti rìnrìn àjò. Nítorí náà, a pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí lọ lójú mọmọ.

“Mo gbìyànjú jíju àga kan sínu ẹrẹ̀ lahar náà láti mọ̀ bóyá yóò rì, mo tilẹ̀ gun orí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò rì. Nítorí náà, mo wá ọ̀pá gbọọrọ kan tí mo lè fi tẹ ẹrẹ̀ náà. Mo ṣe èyí láti mọ àwọn ìhà tí ó le tó láti rìn. Lọ́nà yìí, àwa àti àwọn aládùúgbò díẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ ìrìn wa lórí ẹrẹ̀ náà. A jẹ́ 26 lápapọ̀.

“A forí lé òrùlé kan tí ó tún ga díẹ̀ sí i lókèèrè. A ń fi ọ̀pá gbọọrọ náà tẹ ẹrẹ̀ láti mọ ibi tí a lè gbẹ́sẹ̀ lé. A ń rákòrò ní àwọn ibi tí ó bá ti rọ̀ jù.”

Pẹ̀lú omijé lójú, Carmen ṣàlàyé pé: “Ní àwọn ibì kan, a wà ní etí bèbè ìṣàn lahar náà, a sì ní láti dẹ̀gbẹ́ rìn lórí ilẹ̀ tí kò fẹ̀ rárá. Ó dé ibì kan tí mo rì dé àyà, mo sì sọ fún ọkọ mi pé: ‘N kò lè lọ mọ́. N óò kú.’ Ṣùgbọ́n ó sọ pé: ‘Rárá, o lè ṣe é. Dìde.’ Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa, a ń bá a lọ.”

Nora Mengullo, ìbátan ìdílé náà kan, fi kún un pé: “Ní àwọn ibi tí ilẹ̀ ti rọ̀ jù láti rákòrò, a ń fẹ̀yìn lélẹ̀, tí a óò sì fẹsẹ̀ talẹ̀ ti ara wa síwájú. Nígbà míràn, a ń rì jù, ṣùgbọ́n, a ń ṣèrànwọ́ láti fa ara wa, ní pàtàkì àwọn ọmọ kéékèèké.”

Ìdáǹdè—Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!

Nonato ń bá a lọ pé: “Nígbà tí a ń fi làálàá rákòrò ní etí bèbè lahar náà, hẹlikọ́pítà kan ń fò kọjá, wọ́n sì rí ipò eléwu tí a wà—kì í ṣe lórí òrùlé kankan, bí kò ṣe láàárín pàǹtírí lahar. Ọ̀kan lára àwọn tí a jọ ń lọ gbé ọmọ rẹ̀ olóṣù mẹ́jọ péré sókè, nírètí pé àwọn olùdáǹdè náà yóò rí ìṣòro wa. Wọ́n wá sísàlẹ̀ láti gbà wá. Àwọn ọmọdé àti obìnrin ni wọ́n kọ́kọ́ lọ, nítorí kò lè gba gbogbo wa.

“Níkẹyìn, wọ́n wá kó àwa náà, wọ́n sì kó wa lọ sí ibùdó àwọn tí ń ṣípò padà. Àwọn ènìyàn tí ń bẹ níbẹ̀ kò lè fún wa ní aṣọ wọ̀, bí àwọn aṣọ wá tilẹ̀ kún fún ẹrẹ̀ láti inú lahar náà. Mo sọ fún wọn pé ìdílé mi kì yóò bá àwọn yòókù lọ sí ibùdó àwọn tí ń ṣípò padà, níwọ̀n bí a ti fẹ́ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Nígbà tí a débẹ̀, wọ́n fún wa ní aṣọ, oúnjẹ, àti àwọn ìrànlọ́wọ́ mìíràn lọ́gán. Àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i nínú ìjọ náà dé, àwọn pẹ̀lú sì ràn wá lọ́wọ́.”

Carmen fi kún un pé: “Àní bí a kò tilẹ̀ lè retí ìrànwọ́ láti àwọn orísun mìíràn, a ní ìbùkún ẹgbẹ́ ará Kristian wa.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lahar náà bo ilé alájà méjì ti Garcia, ó dùn mọ́ni nínú láti mọ̀ pé àwọn àti àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, Lovely, Charmy, àti Charly, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ní agbègbè náà la làásìgbò náà já.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àjà kejì ilé Garcia tí a hú dààbọ̀

Agbo ìdílé Nonato Garcia níwájú ilé wọn tí ó rì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́