Mi Ò Ṣi Iṣẹ́ Tí Màá Ṣe Láyé Mi Yàn
Gẹ́gẹ́ Bí Sonia Acuña Quevedo Ṣe Sọ Ọ́
Wọ́n fún mi ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ ní báńkì tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Ipò iyì ni ìgbéga náà máa fi mí sí, owó rẹpẹtẹ lá á sì máa wọlé fún mi. Àmọ́, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kí n wá máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún ní ìjọ kan tó jìn sí ibi tí mò ń gbé ni. Nígbà tí mo padà ronú lórí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mo ti fi ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ṣe, ó dá mi lójú gbangba pé mi ò ṣi iṣẹ́ yàn.
INÚ ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n bí màmá mi sí, àmọ́ wọ́n máa ń ṣiyè méjì nípa ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ wọ́n ní ṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n máa ń ṣe kàyéfì pé, etí wo ló ń gbọ́ ọ pé à ń jọ́sìn ère, tó jẹ́ pé èèyàn ló gbẹ́ ẹ? Torí pé ọwọ́ pàtàkì ni màmá mi fi mú ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tó bá bá Bíbélì mu, wọ́n ń ti ṣọ́ọ̀ṣì kan lọ sí òmíràn láti wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ń jà gùdù lọ́kàn wọn, àmọ́ pàbó ni gbogbo ẹ̀ ń já sí.
Lọ́jọ́ kan, Màmá jókòó síwájú ilé wa nílùú Tuxtla, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, wọ́n ń gbafẹ́fẹ́ tútù sára. Bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe wàásù délé wa nìyẹn. Ọ̀nà tó gbà fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè màmá mi dùn mọ́ wọn nínú gan-an débi tí wọ́n fi gbà pé kó padà wá. Nígbà tó fi máa dé, ó rí i pé màmá mi nìkan kọ́ ló ń dúró de òun, òjíṣẹ́ ìjọ Adventist kan, àlùfáà Kátólíìkì kan àti oníwàásù kan tó jẹ́ ọmọ ìjọ Nazarene ti wà lọ́dọ̀ wọn. Màmá mi béèrè ìbéèrè kan nípa Sábáàtì, Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn nìkan ṣoṣo ló sì fi Ìwé Mímọ́ dáhùn ìbéèrè náà lọ́nà tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Kódà, òun nìkan ṣoṣo ló ní Bíbélì lọ́wọ́! Lọ́dún 1956, oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn tí màmá mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n ṣèrìbọmi, wọ́n sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí nígbà yẹn.
Bàbá Mi Fìfẹ́ Tòótọ́ Hàn sí Mi
Bàbá mi ò ta ko màmá mi nítorí pé wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣùgbọ́n nígbà tí màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwa ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì, lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ń kó wa lọ sípàdé, bàbá mi fa gbogbo ìwé màmá mi ya. Bàbá mi gbà pé ọ̀nà tó lòdì là ń tọ̀, nítorí náà wọ́n gbìyànjú láti fi Bíbélì àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ṣàlàyé pé ọ̀nà ẹ̀tàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà fi orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, sínú ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ń lò. Àmọ́ nígbà tí màmá mi forúkọ náà hàn wọ́n nínú Bíbélì Kátólíìkì táwọn fúnra wọn ń lò, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wọn, bí wọ́n ṣe yíwà padà sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn o.—Sáàmù 83:18.
Ohun àkànṣe gbáà làwọn èèyàn ka àṣeyẹ ọjọ́ ìbí ọmọ tó bá pé ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Níwọ̀n bí àṣeyẹ ọjọ́ ìbí ò sì ti bá Ìwé Mímọ́ mu, mi ò wulẹ̀ ṣe àṣeyẹ ọjọ́ ìbí tèmi nígbà tí mo pọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.a Síbẹ̀, bàbá mi ni àfi dandan káwọn ṣe ohun àkànṣe kan fún mi. Mo da ọ̀rọ̀ náà rò, mo sì sọ pé: “Ẹ̀yin gan-an ni mo fẹ́ kẹ́ ẹ jẹ́ ẹ̀bùn mi. Mo fẹ́ kẹ́ ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ nípa bíbá mi lọ sí àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bọ̀ lọ́nà.” Wọ́n gbà láti bá mi lọ, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Bíbélì wá ń pọ̀ sí i.
Lálẹ́ ọjọ́ kan báyìí, tí ìjì ńlá kan ṣẹ̀ṣẹ̀ jà tán, bàbá mi fara pa yánnayànna nígbà tí wọ́n kọ lu wáyà iná tó já lulẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń gbàtọ́jú nílé ìwòsàn, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò bójú tó wọn lójú méjèèjì. Bàbá mi ò gbàgbé báwọn ará ṣe fìfẹ́ tòótọ́ hàn sí wọn yìí. Nígbà tó ṣe, bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ láti máa ṣèfẹ́ Jèhófà. Rẹ́rẹ́ rún ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹsàn-án, ọdún 1975, nítorí pé bàbá mi ṣaláìsí nígbà tí ìrìbọmi wọn ku oṣù kan. Inú wa máa dùn gan-an láti gbá bàbá mi mọ́ra ká sì tún kí wọn káàbọ̀ nígbà àjíǹde!—Ìṣe 24:15.
Mo Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àǹtí Mi
Ó ti pẹ́ tí àǹtí mi, ìyẹn Àǹtí Carmen, ti máa ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Kété lẹ́yìn tí àǹtí mi ṣèrìbọmi lọ́dún 1967, wọ́n di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, wọ́n sì ń fi nǹkan bí ọgọ́rùn-ún wákàtí wàásù lóṣooṣù. Nígbà tó ṣe, wọ́n kó lọ sí ìlú Toluca, ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Àmọ́ nígbà témi jáde ilé ẹ̀kọ́ mo ríṣẹ́ sí báńkì kan, mo sì ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù keje, ọdún 1970.
Iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún máa ń mú kí Àǹtí Carmen láyọ̀ gan-an ni, wọ́n sì rọ̀ mí pé kémi náà kó wá sí ìlú Toluca. Mo ṣì ń ronú lórí ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ títí di ọjọ́ kan báyìí tí mò ń tẹ́tí sí àsọyé kan tó fi hàn pé ńṣe ló yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa lo ìgbàgbọ́ àti òye òtítọ́ ṣíṣeyebíye tí wọ́n ní láti máa fògo fún Ọlọ́run. (Mátíù 25:14-30) Mo wá bi ara mi pé, ‘Ṣé lóòótọ́ ni mò ń ṣiṣẹ́ kára kí n bàa lè lo òye òtítọ́ tí Jèhófà fi jíǹkí mi?’ Irú èrò báyìí ló ta mí jí tí mo fi fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Jèhófà.
Bí Mo Ṣe Yan Ohun Tí Màá Ṣe Láyé Mi
Lọ́dún 1974, mo kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé kí wọ́n fún mi láǹfààní láti lọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù mìíràn. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí alàgbà kan láti ìlú Toluca fi fóònù pè mí lẹ́nu iṣẹ́. Ó bi mí léèrè pé: “A ti ń retí rẹ. Ṣé kò sí tá ò tíì rí ẹ?” Kàyéfì ló jẹ́ fún mi, àṣé wọ́n ti rán mi lọ sílùú Toluca pé kí n lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe níbẹ̀, àmọ́ lẹ́tà tí wọ́n kọ sí mi ti sọ nù lójú ọ̀nà! (Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe gbà láti fi àkókò kíkún sin Jèhófà níbikíbi tí ètò rẹ̀ bá rán wọn lọ.)
Mo yára kọ̀wé pé mo fẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀. Bí ọ̀gá mi ṣe ń ju ìwé pélébé kan fìrìfìrì níwájú mi, bẹ́ẹ̀ ló ń bi mí pé: “Dúró ná, Sonia. Ìròyìn ṣẹ̀ṣẹ̀ tó wa létí ni pé o wà lára àwọn obìnrin méje tí wọ́n yàn pé kí wọ́n jẹ́ igbá kejì fáwọn máníjà báńkì yìí. Kò sí obìnrin tó tíì jẹ igbá kejì máníjà rí nílé iṣẹ́ wa yìí. Àbí inú ẹ ò dùn sí i ni?” Bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ipò iyì ni ìgbéga náà máa fi mí sí, owó rẹpẹtẹ lá á sì máa wọlé fún mi. Síbẹ̀, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá mi mo sì sọ fún un pé mo ti pinnu láti túbọ̀ jára mọ́ sísin Ọlọ́run. Ó wá sọ fún mi pé: “Ọwọ́ ẹ ló kù sí. Àmọ́, kó o má ṣe gbàgbé pé nígbàkigbà tó o bá ń wáṣẹ́, báńkì wa ṣe tán láti gbà ẹ́ padà o.” Ọjọ́ kẹta sígbà yẹn ni mo wọ ìlú Toluca.
Mo Ṣiṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Àkànṣe Lórílẹ̀-Èdè Mẹ́síkò
Nígbà tí mo dé sọ́dọ̀ Àǹtí Carmen, ó ti pé ọdún méjì tí wọ́n ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Toluca. Inú wa mà dùn pó tún ṣeé ṣe fún wa láti jọ máa gbé pọ̀ o! Àmọ́, kò tún pẹ́ tá a fi ya ara wa. Ìdí ni pé lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tá a ti jọ ń gbé, jàǹbá ọkọ̀ ṣẹlẹ̀ sí màmá wa, ó sì di dandan kí ẹnì kan máa bójú tó wọn tọ̀sán tòru. Lẹ́yìn tá a ti kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́, Àǹtí Carmen gbà pé àwọn á padà relé láti lọ máa tọ́jú màmá wa, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ fọ́dún mẹ́tàdínlógún. Bí wọ́n ṣe ń tọ́jú Màmá, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé nìṣó. Wọ́n tún máa ń ní káwọn táwọn ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa wá bá àwọn nílé, kí wọ́n má bàa fi màmá wa sílẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan.
Lọ́dún 1976, wọ́n gbé mi lọ sí ìlú Tecamachalco. Onírúurú èèyàn ló wà nílùú náà; àwọn òtòṣì ń gbé lápá ibì kan nínú ìlú náà, àwọn ọlọ́rọ̀ sì ń gbé lápá ibòmíì. Mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú obìnrin àgbàlagbà kan báyìí tí ò tíì lọ́kọ àmọ́ tó ń gbé lọ́dọ̀ àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọlọ́rọ̀. Nígbà tóbìnrin náà sọ fún àbúrò ẹ̀ pé òun fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àbúrò ẹ̀ ní lílé lòun á lé e jáde nílé òun. Síbẹ̀, obìnrin tó níwà ìrẹ̀lẹ̀ yìí ò tìtorí ìyẹn jẹ́ kẹ́rù ba òun, kí ló sì ṣèrìbọmi tán sí, ńṣe ni àbúrò ẹ̀ lé e jáde bó ṣe sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pọ́mọ ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nígbà yẹn, ó ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà. Ìjọ gbà láti máa bójú tó o, ó sì ṣe olóòótọ́ títí tó fi kú.
Mo Relé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, Lẹ́yìn Náà Wọ́n Rán Mi Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Bolivia
Ọdún márùn-ún ti mo lò nílùú Tecamachalco lárinrin gan-an ni. Lẹ́yìn náà ni wọ́n ké sí mi láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìyẹn Gilead Extension School, tí wọ́n ṣe nígbà àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ yìí ṣe fi hàn, ìlú New York ló yẹ kí ilé ẹ̀kọ́ náà ti wáyé, àmọ́ wọ́n wá ṣe é lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Màmá mi àti Àǹtí Carmen fi dandan lé e pé kí n lọ sílé ẹ̀kọ́ náà, ni mo bá gba ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Mexico City lọ fún ilé ẹ̀kọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́wàá, àbùsí ire tẹ̀mí gbáà nìyẹn jẹ́ nígbèésí ayé mi. Kíláàsì wa kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ́jọ́ kìíní oṣù kejì, ọdún 1981, wọ́n sì rán èmi, Enriqueta àti Ayala (tó ti di Fernández báyìí) lọ sí ìlú La Paz, lórílẹ̀-èdè Bolivia.
Nígbà tá a wọ̀lúu La Paz, àwọn arákùnrin tó yẹ kí wọ́n wá pàdé wa ò tíì dé. La bá sọ pé: “Kí la tún ń dúró ṣe?” Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn èèyàn ní ibùdókọ̀ òfuurufú nìyẹn. Lẹ́yìn tá a ti gbádùn ṣíṣe bẹ́ẹ̀ fún wákàtí mẹ́ta, àwọn arákùnrin tí wọ́n rán láti ẹ̀ka ọ́fíìsì dé. Lẹ́yìn tí wọ́n tọrọ àforíjì, wọ́n ní ọdún táwọn èèyàn ń ṣe nígboro tó mú kójú ọ̀nà lọ́lù ló fà á táwọn fi pẹ́.
A Máa Ń Wo Kùrukùru Nísàlẹ̀ Bá A Bá Ń Wàásù
Èyí tí ìlú La Paz fi ga ju ibi tójú ilẹ̀ ti bá òkun dọ́gba tó nǹkan bí egbèjìdínlógún lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [3,625] mítà, ìyẹn nǹkan bí ẹgbàafà [12,000] ẹsẹ̀ bàtà, nítorí náà ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń wo kùrukùru nísàlẹ̀. Afẹ́fẹ́ tí ò tó nǹkan lókè téńté tá a wà sábà máa ń mú kó nira fún wa láti mí, ká má sì tíì bẹ̀rẹ̀ ìwàásù ní, á ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tó ọdún kan kí gbígbé níbi gíga fíofío tó mọ́ mi lára, ńṣe lòjò ìbùkún Jèhófà ń gbá gbogbo ìnira mi lọ. Bí àpẹẹrẹ, lówùúrọ̀ ọjọ́ kan lọ́dún 1984, mo pọ́nkè lọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè págunpàgun kan, mo lọ bẹ ilé kan tí wọ́n kọ́ síbi tí àpáta ti yọ gọnbu wò. Nígbà tí mo fi máa débẹ̀ ó ti rẹ̀ mí tẹnutẹnu. Mo kànlẹ̀kùn, obìnrin kan sì jáde sí mi. Ó gbádùn ọ̀rọ̀ tá a jọ sọ gan-an, mo sì sọ fún un pé mi ò ní pẹ́ padà wá.
Ó fèsì pé: “Òun ò rò pé màá lè padà wá.” Mo padà lọ ṣá o, obìnrin náà sì ní kí n máa kọ́ àwọn ọmọbìnrin òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo sọ fún un pé: “Ojúṣe tìẹ gẹ́gẹ́ bí òbí nìyẹn. Àmọ́, mo lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o bá fẹ́.” Ó gbà pé kí n ran òun lọ́wọ́, ó sì tún gbà pé kí n máa kọ́ òun náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nítorí pé kò mọ̀wé, a kúkú bẹ̀rẹ̀ látorí ìwé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń kọ́ àwọn èèyàn láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, ìyẹn Learn to Read and Write.
Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn ọmọ obìnrin náà di mẹ́jọ. Bí mo bá lọ síbẹ̀, díẹ̀ lára àwọn ọmọ náà á fọwọ́ kọ́ ọwọ́, wọ́n á sì fi fà mí gòkè. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo ìdílé náà pátá, bàbá, ìyá, àtàwọn ọmọ wọn mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ, di olùjọsìn Jèhófà. Aṣáájú-ọ̀nà ni mẹ́ta lára àwọn ọmọ wọn obìnrin, ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọn ọkùnrin sì ti di alàgbà ìjọ. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni bàbá wọn nínú ìjọ kó tó kú lọ́dún 2000. Inú mi máa ń dùn gan-an ni bí mo bá rántí ìdílé àrà ọ̀tọ̀ yìí àti bí wọ́n ṣe dúró nínú òtítọ́! Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó lò mí láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Èmi àti Àǹtí Carmen Tún Ń Padà Gbé Pọ̀
Lẹ́yìn tí màmá wa kú lọ́dún 1997, wọ́n tún yan Àǹtí Carmen gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Lọ́dún 1998, wọ́n gbé wọn wá sí ìlú Cochabamba, lórílẹ̀-èdè Bolivia, níbi tí mo wà. Bó ṣe di pé a tún jọ ń gbé pọ̀ lẹ́yìn ọdún méjìdínlógún nìyẹn o, ètò Ọlọ́run sì gbà kí Àǹtí Carmen máa sìn gẹ́gẹ́ bíi mísọ́nnárì. A gbádùn ara wa gan-an nílùú Cochabamba, ojú ọjọ́ sì dáa níbẹ̀ débi pé ẹyẹ alápàáǹdẹ̀dẹ̀ kì í kúrò níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń sọ ọ́! Ní báyìí, a wà nílùú Sucre, lórílẹ̀-èdè Bolivia, ìlú rírẹwà tó wà nínú àfonífojì gíga, táwọn olùgbé ibẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mọ́kànlá [220,000]. Vatican Kékeré ni wọ́n máa ń pe ìlú náà tẹ́lẹ̀, nítorí pé ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ló kún ibẹ̀, ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú náà báyìí sì jẹ́ márùn-ún.
Bá a bá ro iye ọdún témi àti Àǹtí Carmen ti jọ lò lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà pọ̀, ó ti lé lọ́gọ́ta ọdún báyìí, a sì ti gbádùn àǹfààní ti kò láfiwé ní ti pé Jèhófà ti lò wá láti ran àwọn èèyàn tó lé lọ́gọ́rùn-ún lọ́wọ́ débi tí wọ́n fi ṣèrìbọmi. Dájúdájú, kò sí iyè méjì níbẹ̀ pé fífi tọkàn tara sin Jèhófà, ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó ń ṣeni láǹfààní jù lọ!—Máàkù 12:30.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn abọ̀rìṣà ló ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjì péré tá a lè rí kà nínú Ìwé Mímọ́, ọ̀rọ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa wọn ò sì dáa. (Jẹ́nẹ́sísì 40:20-22; Máàkù 6:21-28) Àmọ́ ṣá o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò sọ pé ká má máa fáwọn èèyàn lẹ́bùn o. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí ẹ̀bùn náà ti ọkàn wá, kó má ṣe jẹ́ torí pé a fẹ́ ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe tàbí pé à ń bẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa sọ.—Òwe 11:25; Lúùkù 6:38; Ìṣe 20:35; 2 Kọ́ríńtì 9:7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Mo pọ́nkè lọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè págunpàgun kan, kí n lè bá ìdílé yìí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Èmi àti àǹtí mi Carmen (lápá ọ̀tún) nìyí lóde ẹ̀rí