ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 2/1 ojú ìwé 20-25
  • A Ti Wá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ti Wá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọrírì fún Òtítọ́ Bibeli
  • Wíwọnú Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà
  • Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Wa ní Àwọn Ọdún Ogun
  • Àwọn Ìgbòkègbodò Ẹ̀yìn Ogun​—⁠Lẹ́yìn náà Gileadi
  • Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Wa ní Brazil
  • Ìgbésí-Ayé Dídọ́ṣọ̀, Tí Ó Lérè
  • Ṣé Owó Ni Orísun Ayọ̀ Tòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Mi Ò Ṣi Iṣẹ́ Tí Màá Ṣe Láyé Mi Yàn
    Jí!—2007
  • Jèhófà Jẹ́ Kọ́wọ́ Mi Tẹ Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Tó Wù Mí Gan-an
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ohun Dídára Jùlọ Tí Mo Lè Lo Ìgbésí-Ayé Mi Fún
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 2/1 ojú ìwé 20-25

A Ti Wá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́

GẸ́GẸ́ BÍ OLIVE SPRINGATE TI SỌ Ọ́

Màmá ṣẹ̀ṣẹ̀ paná àbẹ́là ni ó sì ti kúrò nínú iyàrá lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ àdúrà wa tán. Àbúrò mi ọkùnrin bi mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Olive, báwo ni Ọlọrun ṣe lè rí wa kí ó sì gbọ́ wa kọjá inú ògiri oníbíríkì?”

MO FÈSÌ pé: “Màmá sọ pé ó lè ríran gba inú ohunkóhun kọjá, kódà dé inú ọkàn-àyà wa.” Màmá jẹ́ obìnrin kan tí ó ní ìbẹ̀rù Ọlọrun àti olùfìháragàgà ka Bibeli, ó sì gbin ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọlọrun àti fún àwọn ìlànà Bibeli sínú àwa ọmọ rẹ̀.

Àwọn òbí wa jẹ́ mẹ́ḿbà Ṣọ́ọ̀ṣì Anglican ní ìlú kékeré Chatham, Ẹ̀ka ìjọba ìbílẹ̀ títóbi jùlọ Kent, England. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Màmá ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé, ó ní ìgbàgbọ́ pé jíjẹ́ Kristian kan túmọ̀sí ju mímú ìjókòó gbóná lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì lọ. Ó tún dá a lójú pé Ọlọrun gbọ́dọ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì òtítọ́ kanṣoṣo.

Ìmọrírì fún Òtítọ́ Bibeli

Ní 1918, nígbà tí mo jẹ́ nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-⁠ún, Màmá ra àwọn ìdìpọ̀ tí a fún ní àkọlé náà Studies in the Scriptures, tí Charles T. Russell kọ, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society. Ní ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí ó ń gbé ni ibi kékeré kan tí a ń pè ní Wigmore, Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan, bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sí nígbà náà, kàn sí Màmá. Ó gba àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli náà Duru Ọlọrun, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí rí àwọn ìdáhùn láti inú rẹ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè rẹ̀ lórí Bibeli. Káàdì aláwọ̀ pupa-bàrébàré kan ń wá nípasẹ̀ ìfìwéránsẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìbéèrè títẹ̀ tí a gbékarí ọ̀kọ̀ọ̀kan orí-ìwé náà. Káàdì náà tún fi ibi tí a ti lè rí ìdáhùn nínú ìwé náà hàn.

Ní 1926 àwọn òbí mi, Beryl àbúrò mi obìnrin, àti èmi, fi Ṣọ́ọ̀ṣì Anglican sílẹ̀ nítorí ìlọ́wọ́sí ṣọ́ọ̀ṣì náà nínú òṣèlú, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí kò lọ́gbọ́n-nínú ti mú kí ó sú wa. Ẹ̀kọ́ kan tí ó gba iwájú jùlọ ni pé Ọlọrun yóò dá àwọn ènìyàn lóró títí ayérayé nínú iná ọ̀run àpáàdì. Ó dá màmá mi tí ó ti ń wá òtítọ́ Bibeli kiri lójú níti tòótọ́, pé Ṣọ́ọ̀ṣì Anglican kọ́ ni èyí tí ó jẹ́ òtítọ́.

Kété lẹ́yìn náà, ní ìdáhùn sí àwọn àdúra àtọkànwá Màmá, Ìyáàfin Jackson, Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan, bẹ̀ wá wò. Fún nǹkan bíi wákàtí méjì, ó bá èmi àti Màmá sọ̀rọ̀, ní dídáhùn àwọn ìbéèrè wa láti inú Bibeli. Yàtọ̀ sí àwọn ohun mìíràn, inú wa dùn láti mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ darí àwọn àdúrà wa sí Jehofa Ọlọrun, Baba Jesu Kristi, kìí ṣe sí Mẹ́talọ́kan àdììtú kan. (Orin Dafidi 83:18; Johannu 20:17) Ṣùgbọ́n ní tèmi ìbéèrè mánigbàgbé kan tí Màmá béèrè ni èyí: “Kí ni ó túmọ̀sí láti wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?”​—⁠Matteu 6:⁠33.

Ìdáhùn náà tí a gbékarí Bibeli nípalórí ìgbésí-ayé wa lọ́nà jíjinlẹ̀. Láti ọ̀sẹ̀ yẹn gan-⁠an, a bẹ̀rẹ̀ síí lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti láti máa ṣàjọpín àwọn ohun tí a kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ó dá wa lójú pé a ti rí òtítọ́. Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní 1927, Màmá ṣe ìrìbọmi ní àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa, èmi pẹ̀lú sì ṣe ìrìbọmi ní 1930.

Wíwọnú Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà

Ìdílé wa ń lọ si Ìjọ Gillingham, èyí tí ó ní àwọn ènìyàn 25. Mélòókan nínú wọn jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí a ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà, gbogbo wọn sì ní ìrètí ti ọ̀run. (Filippi 3:​14, 20) Ìtara Kristian wọn ń ranni. Nígbà tí n kò tíì tó ọmọ ogún ọdún, mo ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún àkókò kúkúrú ní Belgium ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930. Èyí tanná ran ìfẹ́-ọkàn mi fún iṣẹ́-ìsìn Ìjọba síwájú síi. Ní àkókò yẹn a kópa nínú pípín ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé-kékeré náà The Kingdom, the Hope of the World fún gbogbó àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì.

Nígbà tí ó yá bàbá mi tako àwọn ìgbòkègbodò Kristian wa gidigidi, àti lọ́nà kan ṣáá nítorí èyí, mo ṣí lọ sí London ní 1932 láti lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì. Lẹ́yìn ìyẹn mo ṣiṣẹ́ olùkọ́ fún ọdún mẹ́rin mo sì ń darapọ̀ mọ́ Ìjọ Blackheath ní àkókò náà, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú ẹyọ mẹ́rin tí ó wà ní London nígbà yẹn. Nígbà náà ni a bẹ̀rẹ̀ síí gbọ́ àwọn ìròyìn nípa ìfinisẹ́wọ̀n àti ìjìyà àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin wa ní Germany ti Hitler nítorí pé wọn kọ̀ láti ṣètìlẹyìn fún àwọn ìsapá ológun ti Hitler.

Ní 1938, ní oṣù náà gan-⁠an tí mo parí sísan gbèsè fún àwọn ìwé tí mo ti rà, mo fi iṣẹ́ mi sílẹ̀ láti mú ìfẹ́-ọkàn mi láti di aṣáájú-ọ̀nà kan ṣẹ. Beryl, àbúrò mi obìnrin bẹ̀rẹ̀ síí ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní London ní àkókò kan-náà, ṣùgbọ́n ó ń gbé ní ilé aṣáájú-ọ̀nà kan tí ó yàtọ̀. Ẹni àkọ́kọ́ tí ó ṣìkejì mi nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni Mildred Willett, ẹni tí ó wá fẹ́ John Barr, tí ó jẹ́ mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nísinsìnyí. Àwa yóò gun kẹ̀kẹ́ pẹ̀lú àwọn mìíràn tí wọ́n wà nínú àwùjọ wa lọ sí ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ a ó sì wà níbẹ̀ títí ṣúlẹ̀, láìka òjò sí lọ́pọ̀ ìgbà.

Òjò ogun ti ń ṣú dẹ̀dẹ̀ sórí Europe. Àwọn ọlọ̀tọ̀ ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí ìlò àwọn ìbòjú nítorí afẹ́fẹ́ tajútajú, ìmúrasílẹ̀ sì ti bẹ̀rẹ̀ láti ṣí àwọn ọmọdé nípò lọ sí àrọ́ko ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tàbí àwọn ìlú kéékèèké bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ogun bẹ̀rẹ̀. Mo ní kìkì ìwọ̀nba owó tí ó tó láti ra bàtà kan, kò sì sí ṣíṣeéṣe kankan pé mo lè rí ìrànlọ́wọ́ owó gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí mi. Ṣùgbọ́n Jesu kò ha ti sọ pé, ‘Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín bí ẹ bá wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́’? (Matteu 6:33) Mo ní ìgbàgbọ́ kíkúnrẹ́rẹ́ pé Jehofa yóò pèsè gbogbo ohun tí mo ṣaláìní, ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá. Nígbà mìíràn lákòókò ogun mo máa ń fi àwọn ẹ̀fọ́ tí mo ṣà lójú títì lẹ́yìn tí àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tí ó ń gbé e lọ bá ti kọjá tán kún ìpèsè oúnjẹ kékeré mi. Mo sì sábàá máa ń rí oúnjẹ nípa fífi àwọn èso àti ẹ̀fọ́ pààrọ̀ ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.

A bi àbúrò mi obìnrin Sonia ní 1928. Ọmọ ọdún méje péré ni nígbà tí ó ya ìgbésí-ayé araarẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa. Sonia sọ pé ní ọjọ́ orí kékeré yẹn pàápàá, ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà ti di góńgó òun. Ní 1941, láìpẹ́ lẹ́yìn tí ó fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn nípa ìrìbọmi, góńgó yẹn ní ìmúṣẹ nígbà tí a yanṣẹ́ fún òun àti Màmá gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà láti lọ sí Caerphilly, Gúúsù Wales.

Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Wa ní Àwọn Ọdún Ogun

Ní September 1939, Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, àwọn Kristian arákùnrin ati arábìnrin wa ní Britain ni a sì fi sẹ́wọ̀n fún ìdí kan-náà tí a fi fi àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn sẹ́wọ̀n ní Nazi Germany​—⁠ìdúró àìdásí tọ̀tún-tòsì wọn níti ìlọ́wọ́sógun. Àwọn bọ́m̀bù jíjù láti England àti sínú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní agbedeméjì ọdún 1940. Ní alaalẹ́, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ àwọn ohun-ìjà náà ń dinilétí, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa ó ṣeéṣe fún wa láti ri oorun díẹ̀ sùn kí ara baà lè tù wá fún iṣẹ́ ìwàásù ní ọjọ́ kejì.

Ní ìgbà mìíràn àwa yóò lọ sí ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ ìwàásù wa kìkì láti ríi pé ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ilé náà ti di àwókù. Ní November, bọ́m̀bù kan jábọ́ níwọ̀nba ẹsẹ̀ bàtà díẹ̀ sí ilé tí díẹ̀ nínú wa ń gbé, ní fífọ́ àwọn wíndò wa pátápátá. Ilẹ̀kùn wíwúwo tí ó wà níwájú ilé ya lulẹ̀, ibi tí èéfín máa ń gbà jáde sì wó lulẹ̀. Lẹ́yìn lílo apá tí ó ṣẹ́kù kí ilẹ̀ mọ́ lábẹ́ ìbòrí kúrò lọ́wọ́ àwọn agbófuurufúṣọṣẹ́, a pínyà a sì lọ gbé ní ilé àwọn Ẹlẹ́rìí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Láìpẹ́ lẹ́yìn náà mó gba iṣẹ́-àyànfúnni lọ sí Croydon, ní Greater London. Aṣáájú-ọ̀nà tí ó ṣìkejì mi ni Ann Parkin, tí àbúrò rẹ̀ ọkùnrin Ron Parkin wá di olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lẹ́yìn náà ní Puerto Rico. Lẹ́yìn náà mo ṣí lọ sí Bridgend, Gúúsù Wales, níbi tí mo ti ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìṣó, ní gbígbé nínú ọkọ̀ àfẹṣinfà kan fún oṣù mẹ́fà. Láti ibẹ̀ ni a ti máa ń gun kẹ̀kẹ́ lọ sí ìjọ ńlá tí ó wà nítòsí, ní Port Talbot tí ó fi kìlómítà mẹ́fà jìn.

Ní àkókò yìí àwọn ènìyàn ti ń kógun tì wá gan-⁠an, ní pípè wà ní conchie (àwọn olùyọwọ́yọsẹ̀ nítorí ẹ̀rí-ọkàn). Èyí mú kí ó ṣòro fún wa láti rí ibùwọ̀, ṣùgbọ́n Jehofa bójútó wa gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.

Nígbà tí ó yá, a yan mẹ́jọ nínú wa lọ sí Swansea, ìlú èbúté-ọkọ̀ kan ní Gúúsù Wales gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Bí ọwọ́ ogun náà tí ń le síi, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ẹ̀tanú lòdìsí wa. Àwọn ọ̀rọ̀ náà “àwọn ẹni ìyọṣùtìsí” àti “àwọn ojo” ní a fi ọ̀dà kọ sára ògiri ilé aṣáájú-ọ̀nà wa. Ìkóguntini yìí ni ìròyìn àwọn ìwé-ìròyìn tí wọ́n dẹ́bi fún wa nítorí ìdúró àìdásítọ̀túntòsì wa ń rusókè ní ọ̀nà tí ó pọ̀ jùlọ. Ní àsẹ̀yìnwáàsẹ̀yìnbọ̀, méje nínú wa ní wọ́n rán lọ sẹ́wọ̀n lọ́kọ̀ọ̀kan. Mo lo oṣù kan ní ọgbà-ẹ̀wọ̀n Cardiff ní 1942, lẹ́yìn náà ni Beryl àbúrò mi obìnrin ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ pẹ̀lú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní púpọ̀ nípa ti ara tí a sì jìyà ìfiniṣẹlẹ́yà àti ẹ̀gàn, a lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí.

Láàárín àkókò náà, Màmá àti Sonia ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní Caerphilly wọ́n sì ń ní irú àwọn ìrírí kan-náà. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àkọ́kọ́ tí Sonia kọ́kọ́ darí jẹ́ pẹ̀lú obìnrin kan tí ó ṣètò láti bẹ̀wò ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday kan. Ó dá Sonia lójú pé Màmá yóò tẹ̀lé òun lọ, ṣùgbọ́n Màmá ṣàlàyé pé: “Mó ni àdéhùn mìíràn. Ìwọ ni ó ṣètò náà, nítorí náà ó wulẹ̀ níláti lọ ní ìwọ nìkan ni.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sonia jẹ́ ọmọ ọdún 13 péré, ó dá lọ fúnraarẹ̀, obìnrin náà tẹ̀síwájú dáradára nípa tẹ̀mí ó sì di Ẹlẹ́rìí olùṣèyàsímímọ́ kan lẹ́yìn náà.

Àwọn Ìgbòkègbodò Ẹ̀yìn Ogun​—⁠Lẹ́yìn náà Gileadi

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí ní 1945, mo ń ṣiṣẹ́ ní àgbègbè ìpínlẹ̀ àdádó kan ní Whaley Bridge, Derbyshire. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí wọ́n kéde ìdáwọ́-ìjà-dúró náà, a ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí ogun-jíjà ti tójúsú nítorí àwọn àbájáde rẹ̀​—⁠àwọn tí ó sọ di ọmọ òrukàn, opó, àti agépá-gésẹ̀, a sì tù wọ́n nínú.

Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, Society béèrè fún àwọn olùyọ̀nda ara-ẹni láti wàásù ní Ireland, Erékùṣù Emerald. Ní àkókò náà kìkì nǹkan bíi 140 àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ń bẹ ní erékùṣù náà, nítorí náà a kà á sí ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Láàárín ìwọ̀nba oṣù díẹ̀, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe bíi 40 ni a yàn síbẹ̀, mo sì wà lára wọn.

Lẹ́yìn tí mo ti ṣiṣẹ́ fún àkókò díẹ̀ ní Coleraine àti Cookstown ní àríwá, a yan èmi àti àwọn mẹ́ta mìíràn sí Drogheda ní ìlà-oòrùn bèbè-etíkun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́nà ti ẹ̀dá àwọn ọmọ ilẹ̀ Ireland lọ́yàyà wọ́n sì jẹ́ olùfẹ́-àlejò ṣíṣe, ẹ̀tanú ìsìn wọn ga. Nítorí bẹ́ẹ̀, ní odidi ọdún kan gbáko, ìwọ̀nba àwọn àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli díẹ̀ ní a lè fi sóde lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn (níti tòótọ́ ìwé kan àti àwọn ìwékékeré díẹ̀).

Nígbà tí a fi wà ní Drogheda, mo ń gun kẹ̀kẹ́ láti oko kan lọ sí òmíràn nígbà tí ọ̀dọ́ oníṣẹ́ oko kan bẹ́ sọ́nà lójijì láti inú igbó. Ó wo apá ọ̀tún àti apá òsì ojú-ọ̀nà náà, lẹ́yìn náà ni ó wá fi ohùn pẹ̀lẹ́ béèrè pé: “Ìwọ ha jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bí?” Nígbà tí mo fèsì pé mo jẹ́ ọkàn lára wọn, ó ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Mo ní àríyànjiyàn gbígbónájanjan kan pẹ̀lú àfẹ́sọ́nà mi nípa ẹ̀yin ọmọbìnrin wọ̀nyí lánàá, a sì fòpin sí àjọṣepọ̀ tí ó wà láàárín wa. Ó rinkinkin mọ́ ọn pé Kọmunist ni yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Katoliki àti àwọn ìwé-ìròyìn ti sọ, ṣùgbọ́n mo jiyàn pé kò lè jẹ́ òtítọ́, níwọ̀n bí ẹ tí ń lọ láti ilé dé ilé ní gbangba.”

Mo fún un ní ìwé-kékeré kan láti kà, èyí tí ó tọ́jú sínú àpò aṣọ rẹ̀, a sì ṣètò láti pàdé kí a baà lè sọ̀rọ̀ síi bí alẹ́ bá lẹ́, níwọ̀n bí ó ti sọ pé: “Bí wọ́n bá rí mi tí mó ń bá ọ sọ̀rọ̀, èmi yóò pàdánù iṣẹ́ mi.” Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn àwa méjì lọ bá a a sì dáhùn ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè rẹ̀. Ó jọ bí ẹni pé ó gbàgbọ́ pé èyí jẹ́ òtítọ́, ó sì ṣèlérí láti wá sí ilé wa ní alẹ́ ọjọ́ mìíràn láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ síi. Kò wá, nítorí náà a nímọ̀lára pé àwọn oníkẹ̀kẹ́ kan tí wọ́n kọjá lọ ní alẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ náà ti níláti dá a mọ̀ kí ó sì ti pàdánù iṣẹ́ rẹ̀. Nígbà gbogbo ni a máa ń ṣe kàyéfì bóyá ó di Ẹlẹ́rìí kan.

Lẹ́yìn lílọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè ní Brighton ní gúúsù bèbè-etíkun England ní 1949, mélòókan nínú wa rí àwọn ìkésíni gbà láti lọ sí Watchtower Bible School of Gilead ní Ìpínlẹ̀ New York. Àròpọ̀ 26 láti Britain lọ sí kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dógún, èyí tí ó kẹ́kọ̀ọ́yege ní July 30, 1950, nígbà àpéjọpọ̀ àgbáyé ní Pápá EréÌdárayá Yankee.

Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Wa ní Brazil

Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e a yàn mí sí São Paulo, Brazil, ọ̀kan nínú àwọn ìlú-ǹlá tí ń yára gòkè àgbà lágbàáyé. Ní àkókò náà kìkì ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa márùn-⁠ún péré ni ó ní, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 600! Ẹ wo bí ó ti yàtọ̀ tó ní ìfiwéra pẹ̀lú ṣíṣiṣẹ́ ní Ireland! Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ilé tí ń bẹ ní ìpínlẹ̀ ìṣiṣẹ́ wa ní São Paulo jẹ́ àwọn ilé ńláńlá, tí a fi àwọn ọgbà onírin yíká pẹ̀lú àwọn géètì ọlọ́nà tí a fi irin ṣe. Àwa yóò késí ẹni tí ó ni ilé tàbí ìránṣẹ́bìnrin nípa pípàtẹ́wọ́.

Bí ọdún ti ń gorí ọdún, a ń rí àwọn iṣẹ́-àyànfúnni titun gbà. Mo ní àǹfààní láti ṣèrànlọ́wọ́ láti dá àwọn ìjọ titun sílẹ̀ ní onírúurú àwọn apá inú lọ́hùn-⁠ún ní àwọn ìpínlẹ̀ São Paulo, títíkan ọ̀kan ní Jundiaí ní 1955 àti òmíràn ní Piracicaba ní 1958. Lẹ́yìn náà, ní 1960, Sonia, àbúrò mi di mísọ́nnárì tí ó ṣìkejì mi, a sì yàn wá sí Pôrto Alegre, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Rio Grande do Sul. Ìwọ lè ṣe kàyéfì pé, báwo ni ó ṣe dé Brazil?

Sonia ati Màmá jọ ń ba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ ní England lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì. Ṣùgbọ́n ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950, wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún Màmá nítorí àrùn káńsà èyí tí kò mú kí ara rẹ̀ gbékánkán tó láti lọ láti ilé dé ilé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeéṣe fún un láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kí ó sì kọ àwọn lẹ́tà. Sonia ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ, síbẹ̀ ó ń ṣèrànlọ́wọ́ láti bójútó Màmá. Ní 1959, Sonia ní àǹfààní láti lọ sí kíláàsì kẹtàlélọ́gbọ̀n ti Gileadi a sì yàn án sí Brazil. Láàárín àkókò yìí, Beryl ń bójútó Màmá títí tí ó fi kú ní 1962. Beryl ti wọlé ọkọ nígbà náà, òun àti ìdílé rẹ̀ sí ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sin Jehofa.

Ní Brazil, èmi àti Sonia ran àwọn ènìyàn mélòókan lọ́wọ́ tí wọ́n fi ṣe ìyàsímímọ́ ati ìrìbọmi. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Brazil kan ní jẹ́ fíforúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Nítorí ìṣòro tí ó wà nínú rírí ìkọ̀sílẹ̀ gbà ní Brazil, ó jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn tọkọtaya láti wulẹ̀ máa gbé papọ̀ láìsí àǹfààní ìgbéyàwó. Ní pàtàkì ni ọ̀ràn rí báyìí nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn alájọṣègbéyàwó náà bá pínyà kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó ti kọ́kọ́ bá ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin.

Ọmọbìnrin kan, tí ń jẹ́ Eva, wà nínú ipò yẹn nígbà tí mo kàn sí i. Ẹni tí ó bá ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin ti sálọ, nítorí náà kí a baà lè mọ ibi tí ó wà, wọ́n bá wa ṣe ìkéde lórí rédíò. Nígbà tí a rí ọkọ rẹ̀, mó tẹ̀lé e lọ sí ìlú mìíràn láti mú kí ó fọwọ́sí ìwé àkọsílẹ̀ kan tí yóò sọ obìnrin náà dòmìnira láti lè mú ìsopọ̀ṣọ̀kan rẹ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tí kò tíì láya tí ó ń bá gbé bófinmu. Nínú ìgbẹ́jọ́ náà níwájú adájọ́, ó béèrè pé kí èmi àti Eva ṣàlàyé ìdí tí ó fi fẹ́ láti ṣàtúnṣe ipò ọ̀ràn ìgbéyàwó rẹ̀. Adájọ́ náà fi ìyàlẹ́nu àti ìtẹ́lọ́rùn hàn nígbà tí a ṣàlàyé èyí fún un.

Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, mo bá ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mi lọ láti lọ ṣètò fún lọ́yà tí yóò bá a bójútó ọ̀ràn rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan síi ìwàásù dídára kan ni a fifúnni nípa ìgbéyàwó àti àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n ìwàrere ti Ọlọrun. Nínú àpẹẹrẹ yìí iye owó ìkọ̀sílẹ̀ náà ga débi pé àwọn tọkọtaya náà níláti ṣiṣẹ́ láti san owó náà. Ṣùgbọ́n lójú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli titun wọ̀nyí, ó yẹ fún ìsapá náà. Èmi àti Sonia ní àǹfààní ṣíṣẹlẹ́rìí ìgbéyàwó wọn, àti lẹ́yìn náà, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn mẹ́ta tí kò tíì pé ogún ọdún, a tẹ́tísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀-àsọyé Bibeli ṣókí kan nínú ilé wọn.

Ìgbésí-Ayé Dídọ́ṣọ̀, Tí Ó Lérè

Nígbà tí èmi ati Sonia ya ìgbésí-ayé wa sí mímọ́ fún Jehofa tí a sì di aṣáájú-ọ̀nà, a ní in lọ́kàn, bí ó bá ṣeéṣe pàápàá, pé iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún yóò jẹ́ iṣẹ́ ìgbésí-ayé wa. A kò ronú púpọ̀ lórí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tàbí bí àmódi tàbí àwọn ìṣòro ìnáwó bá ṣẹlẹ̀. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti ṣèlérí, a kò tíì kọ̀ wá sílẹ̀.​—⁠Heberu 13:⁠6.

Óò, bẹ́ẹ̀ni, àìsí owó ti jẹ́ ìṣòro ní àwọn ìgbà mìíràn. Ní àkókò kan, èmi àti ẹnìkejì mi jẹ kìkì búrẹ́dì tí a fi ewébẹ̀ há ní àárín fún odidi ọdún kan gbáko, ṣùgbọ́n a kò tíì jìyà lọ́wọ́ ebi rí, tàbí ṣaláìní àwọn ohun tí ó jẹ́ kòṣeémáàní.

Bí àwọn ọdún ti ń rékọjá lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni okun wa ń dínkù. Ní agbedeméjì àwọn ọdún 1980, wọ́n ṣe iṣẹ́-abẹ tí ó yọrísí àdánwò mímúná kan fún àwa méjèèjì, níwọ̀nbí ìgbòkègbodò ìwàásù wa ti dínkù jọjọ. Ní January 1987, a késí wa láti di mẹ́ḿbà ìdílé orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Brazil.

Ìdílé wa títóbi tí iye tí ó ju ẹgbẹ̀rún àwọn òjíṣẹ́ lọ wà múlé sí nǹkan bíi 140 kìlómítà lẹ́yìn òde São Paulo nínú àwọn àpapọ̀ ilé ẹlẹ́wà kan, níbi tí a ti ń tẹ àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fún Brazil àti àwọn apá ibòmíràn ní South America. Níbí ni a ti ń rí àbójútó onífẹ̀ẹ́ gbà láti ọwọ́ àwọn olùfọkànsìn ìránṣẹ́ Ọlọrun. Nígbà tí mo kọ́kọ́ dé Brazil ní 1951, nǹkan bíi 4,000 àwọn oníwàásù ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà ni ó wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsìnyí iye tí ó rékọjá 366,000 ni ó wà! Baba wa ọ̀run oníyọ̀ọ́nú ti fi ‘gbogbo àwọn nǹkan mìíràn’ kún un fún wa nítòótọ́ nítorí pé a ti wá Ìjọba rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.​—⁠Matteu 6:⁠33.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Olive pẹ̀lú Mildred Willett níwájú ọmọlanke ìsọfúnni kan, 1939

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Olive àti Sonia Springate

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́