Ìtàn Ìgbésí Ayé
Jèhófà Jẹ́ Kọ́wọ́ Mi Tẹ Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Tó Wù Mí Gan-an
Gẹ́gẹ́ bí Sheila Winfield da Conceição ṣe sọ ọ́
Nígbà kan, arábìnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà wá sí ìjọ wa. Ó sọ fún wa pé àwọn èèyàn máa ń gba òun tọwọ́tẹsẹ̀ tóun bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa. Mo wá sọ nínú ọkàn mi pé, ‘Á wù mí pé kí n lọ wàásù nírú ìpínlẹ̀ yẹn o!’ Ọ̀rọ̀ tá a jọ sọ yẹn jẹ́ kó wù mí láti di míṣọ́nnárì. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá péré ni mí nígbà yẹn.
ÀMỌ́ ìdílé wa ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ṣáájú ìgbà yẹn. Láàárọ̀ ọjọ́ kan lọ́dún 1939, àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ò dàgbà púpọ̀ tí wọ́n sì múra dáadáa, kanlẹ̀kùn ilé wa nílùú Hemel Hempstead. Ìlú yìí kò jìnnà sí ìlú tí wọ́n ń pè ní Greater London, ní England nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn ni wọ́n bí mi, nítorí náà, mi ò rántí ohun tó ṣẹlẹ̀. Màmá mi fẹ́ fọgbọ́n lé wọn lọ, ló bá sọ fún wọn pé ó ṣeé ṣe kí bàbá mi nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n fẹ́ sọ, àmọ́ á tó aago mẹ́sàn-án alẹ́ kó tó wọlé. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí yẹn padà wá lálẹ́ ọjọ́ yẹn gan-gan! Lẹ́yìn tí bàbá mi tó ń jẹ́ Henry Winfield, ti rí i pé wọn kì í ṣẹni tó ń lọ́wọ́ sí ìṣèlú àtàwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ti orílẹ̀-èdè, ó ní kí wọ́n wọlé ó sì gbà kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kíákíá ló sì tẹ̀ síwájú débi pé ó ṣèrìbọmi. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ni màmá mi tó ń jẹ́ Kathleen náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́. Òun náà sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1946.
Lọ́dún 1948, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. Mo ronú pé màá nílò aago ọwọ́ láti lè máa fi ka iye wákàtí tí mo bá lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, táwa ọmọ bá ṣe dáadáa, tá ò ṣàìgbọràn, àwọn òbí wa máa ń fún wa ní sísì (ìyẹn kọ́bọ̀ mẹ́fà) lọ́jọọjọ́ Sátidé, ká lè rówó ná. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjì tí mo fi ń fi owó yìí pa mọ́ kí n tó lè ra aago ọwọ́ tówó rẹ̀ kéré jù nígbà yẹn. Àmọ́, ńṣe ni Ray tó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ṣáà máa ń sọ pé tọ́rọ́ méjì ni kí Dádì fún òun, pé òun ò fẹ́ sísì tó jẹ́ odindi. Lọ́jọ́ kan, ó takú pé tọ́rọ́ méjì lòun fẹ́, débi pé inú bí Dádì. Ni Ray bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pé torí àṣírí kan tó wà láàárín òun àti Jèhófà lòun ṣe fẹ́ tọ́rọ́ méjì. Nígbà tó yá ló wá ṣàlàyé ìdí náà, ó sọ pé: “Mo fẹ́ fi ọ̀kan sínú àpótí ìdáwó, ọ̀kan yòókù sì jẹ́ tèmi.” Omijé ayọ̀ bọ́ lójú mọ́mì mi lọ́jọ́ yẹn, kíákíá ni Dádì sì wá ọ̀nà láti ṣẹ́ owó náà. Mo wá rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa fi owó wa ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.
Kò pẹ́ sí àkókò yìí ni Dádì ṣètò pé kí ìdílé wa ṣí lọ sí àgbègbè kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́dún 1949, ó ta oko rẹ̀ àti ilẹ̀ tó ti ń wa yanrìn àti òkúta wẹ́wẹ́ tó ń tà, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò wàásù. Lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù September ọdún 1950, mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Látìgbà yẹn, tá a bá ti wà ní ọlidé ọlọ́jọ́ gbọọrọ, mo máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò ìsinmi (tá a wà mọ̀ sí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ báyìí), mo sì máa ń lo ọgọ́rùn-ún wákàtí lóṣooṣù nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ lásán nìyẹn. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí gan-an láti túbọ̀ ti ìjọsìn mímọ́ lẹ́yìn.
Ó Wù Mí Láti Di Míṣọ́nnárì
Lọ́dún 1951, wọ́n ní kí Dádì lọ máa wàásù ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Bideford, lágbègbè North Devon. Kò pẹ́ tá a débẹ̀ ni míṣọ́nnárì tó ń sìn nílẹ̀ Áfíríkà tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ yẹn wá sí ìjọ wa. Látìgbà náà lọ, ìfẹ́ tí mo ní láti di míṣọ́nnárì ló wá ń darí gbogbo ìpinnu tí mò ń ṣe. Àwọn olùkọ́ mi níléèwé mọ̀ nípa ohun tí mo ní lọ́kàn láti ṣe yìí, kò sì sí ohun tí wọn ò ṣe tán kí n lè yí èrò mi padà, wọ́n fẹ́ kí n máa lépa iṣẹ́ ayé. Àmọ́ lọ́jọ́ tí mo lò kẹ́yìn níléèwé, mo lọ sí yàrá àwọn olùkọ́ láti lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn kí n sì sọ fún wọn pé ó dìgbóṣe, ni ọ̀kan lára wọn bá sọ fún mi pé: “O káre láé! Ìwọ nìkan ni akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ ohun tó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe. Kí Ọlọ́run jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ ohun tó wù ọ́ yìí.”
Mi ò fàkókò ṣòfò rárá, kíá ni mo wá iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ kan, nígbà tó sì di ọjọ́ kìíní oṣù December ọdún 1955, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá, màmá mi àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin náà di aṣáájú-ọ̀nà. Bí gbogbo ìdílé wa ṣe wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún fún ọdún bíi mélòó kan nìyẹn.
Mo Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Ireland
Ọdún kan lẹ́yìn èyí ni mo gba lẹ́tà pé kí n lọ máa sìn nílẹ̀ Ireland. Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ kan tó máa jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ ohun tí mò ń lé, ìyẹn iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Lóṣù February ọdún 1957, èmi àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì mìíràn táwọn náà jẹ́ ọ̀dọ́, ìyẹn June Napier àti Beryl Barker gúnlẹ̀ sílùú Cork, ní gúúsù ilẹ̀ Ireland.
Kò rọrùn rárá láti wàásù nílẹ̀ Ireland. Ìjọ Kátólíìkì máa ń ta kò wá gan-an lákòókò náà. Nígbà tá a bá wọ inú ilé ńlá kan tàbí ọgbà ńlá kan táwọn ilé pọ̀ sí, a máa ń rí i dájú pé a mọ ọ̀nà tá a máa gbà jáde bó bá ṣẹlẹ̀ pé a ní láti tètè sá lọ. Ibi tá a máa ń gbé kẹ̀kẹ́ wa pa mọ́ sí máa ń jìnnà díẹ̀ síbi tá a bá wà, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà lẹnì kan á rí i, tá a sì fi nǹkan gé táyà àwọn kẹ̀kẹ́ náà tàbí kó jo táyà wọn.
Nígbà kan témi àti Beryl lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń gbénú àwọn ilé tó wà nínú ọgbà ńlá kan, àwọn ọmọ kan bẹ̀rẹ̀ sí í bú wa wọ́n sì ń sọ̀kò lù wá. La bá kó sínú ṣọ́ọ̀bù kan tí wọ́n kọ́ mọ́ ara ilé ẹnì kan níbi tí wọ́n ti ń ta mílíìkì. Báwọn èèyànkéèyàn kan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kóra jọ síta nìyẹn. Nítorí pé Beryl fẹ́ràn mílíìkì gan-an, ó mu kọ́ọ̀pù méjì sí mẹ́ta díẹ̀díẹ̀, pẹ̀lú èrò pé àwọn èèyànkéèyàn yẹn á túká. Àmọ́ wọn ò lọ. Bí àlùfáà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣe wọnú ṣọ́ọ̀bù náà nìyẹn. Ó rò pé àlejò ni wá tá a wá wo bí ibẹ̀ ṣe rí, ló bá lòun á mú wa rìn yí ibẹ̀ ká, ká lè wo bó ṣe rí. Àmọ́ ó kọ́kọ́ mú wa lọ sínú yàrá mìíràn nínú ilé náà. Bá a ṣe rọra jókòó láìsọ̀rọ̀, ó ṣe ààtò ìkẹyìn fún bàbá arúgbó kan tó ti fẹ́ kú. Lẹ́yìn náà làwa àti àlùfáà náà jọ jáde nínú ilé náà. Báwọn èèyànkéèyàn tó kóra jọ yẹn ṣe rí àwa pẹ̀lú rẹ̀ tá a jọ ń sọ̀rọ̀ ni wọ́n bá túká.
Mo Lọ Sílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
Lọ́dún 1958, ètò Jèhófà ṣe ìpàdé àgbáyé kan tí wọ́n pe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Ìfẹ́ Àtọ̀runwá nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Dádì ń lọ, èmi náà sì fẹ́ lọ, àmọ́ mi ò lówó. Bí ìyá bàbá mi ṣe kú lójijì nìyẹn tí mo sì jogún igba ó lé ọgọ́rin [280] dọ́là. Iye tó sì máa gbé mi lọ sí àpéjọ yẹn jẹ́ ọgọ́sàn-án [180] dọ́là, ni mo bá yára lọ sanwó sílẹ̀ fún ọkọ̀ òfuurufú tí mo máa wọ̀.
Kò pẹ́ sí àkókò yìí ni aṣojú kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá sọ́dọ̀ wa. Ó ní kí gbogbo àwa aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tá a máa lọ sí àpéjọ náà gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa jẹ́ ká di míṣọ́nnárì. Bí àlá ló rí lójú mi! Àmọ́ nígbà tó fún gbogbo àwọn yòókù ní fọ́ọ̀mù, kò fún mi. Ó ní mo ṣì kéré láti lọ sílé ẹ̀kọ́ náà. Mo wá sọ fún un pé kó jọ̀ọ́ kó fún èmi náà ní fọ́ọ̀mù, pé mo ti fi orílẹ̀-èdè mi sílẹ̀, mi ò sì yàtọ̀ sẹ́ni tó wà lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Nígbà tó rí i pé ó wù mí gan-an láti lọ, ló bá fún mi ní fọ́ọ̀mù kan. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà gan-an pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n pè mí! Kíá lèsì dé, wọ́n sì pè mí láti wá sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì.
Inú mi dùn gan-an pé wọ́n pé mí sí kíláàsì Kẹtàlélọ́gbọ̀n ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Èmi àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà mọ́kànlélọ́gọ́rin mìíràn láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlá la wà ní kíláàsì náà. Kíákíá loṣù márùn-ún tá a fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà pé. Nígbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ń parí lọ, Arákùnrin Nathan H. Knorr bá wa sọ ọ̀rọ̀ kan tó fakíki, wákàtí mẹ́rin ni àsọyé náà gbà. Ó fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ wà láìní ọkọ tàbí aya níṣìírí pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 7:37, 38) Àmọ́ ní ti àwa tó wù láti ṣègbéyàwó lọ́jọ́ kan, ó dámọ̀ràn pé ká ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ànímọ́ tá a fẹ́ kẹ́ni tá a máa fi ṣe ọkọ tàbí ṣe aya ní. Nípa bẹ́ẹ̀, tí ẹnì kan bá yọjú, ohun tá a kọ sílẹ̀ yẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ àwa àti ẹni náà bára mu.
Lára àwọn ohun tí mo kọ sílẹ̀ nípa ẹni tó máa jẹ́ ọkọ mi nìwọ̀nyí: Ó ní láti jẹ́ míṣọ́nnárì bíi tèmi kó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó gbọ́dọ̀ lóye Bíbélì jù mí lọ, kó sì gbà pé òun ò ní bímọ kí Amágẹ́dọ́nì tó dé ká lè máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún lọ. Ó tún gbọ́dọ̀ lè sọ èdè òyìnbó dáadáa, ó sì ní láti dàgbà jù mí lọ. Àkọsílẹ̀ yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an, torí pé ọmọ ogún ọdún péré ni mí nígbà náà tí mo sì fẹ́ lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ní ọ̀nà jíjìn.
Mo Lọ Sílẹ̀ Brazil
Lọ́jọ́ Sunday ọjọ́ kejì oṣù August ọdún 1959, a kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n sì sọ ibi tá a ti máa lọ ṣe iṣẹ́ ìsìn fún wa. Wọ́n yan èmi àtàwọn kan sí ilẹ̀ Brazil. Àwọn ẹni náà ni: Vehanouch Yazedjian, Sarah Greco, Ray àti Inger Hatfield tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya, àti Sonia Springate, pẹ̀lú Doreen Hines. Inú wa dùn gan-an. Gbogbo èrò ọkàn mi bá a ṣe ń lọ ni pé igbó kìjikìji, igi rọ́bà, ejò, àtàwọn ọmọ ìbílẹ̀ Íńdíà ni mo máa rí níbẹ̀. Àmọ́ nígbà tá a débẹ̀, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi! Dípò kí n rí igbó kìjikìji tí wọ́n ń pè ní igbó Amazon, ìlú Rio de Janeiro tó jẹ́ ìlú òde òní, tí oòrùn ti máa ń ràn gan-an, tó sì jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Brazil nígbà náà ni mo rí.
Ìṣòro tá a kọ́kọ́ bójú tó ni kíkọ́ èdè Potogí. Lóṣù àkọ́kọ́ tá a débẹ̀, wákàtí mọ́kànlá la fi ń kọ́ èdè náà lójoojúmọ́. Lẹ́yìn tí mo wàásù nílùú Rio, tí mo sì gbé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ fúngbà díẹ̀, wọ́n ní kí n lọ máa gbé nílé àwọn míṣọ́nnárì tó wà nílùú Piracicaba, ní Ìpínlẹ̀ São Paulo. Nígbà tó yá, mo tún lọ ń gbé ilé àwọn míṣọ́nnárì tó wà nílùú Porto Alegre, ní Ìpínlẹ̀ Rio Grande do Sul.
Nígbà tó wá di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1963, wọ́n ní kí n lọ máa ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìtúmọ̀ Èdè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Floriano Ignez da Conceição tó kọ́ wa lédè Potogí nígbà tá a kọ́kọ́ dé ilẹ̀ Brazil ni alábòójútó Ẹ̀ka Ìtúmọ̀ Èdè yìí. Ọdún 1944, nígbà tí gbogbo Ẹlẹ́rìí tó wà nílẹ̀ Brazil kò ju ọ̀ọ́dúnrún lọ ló kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kíláàsì Kejìlélógún nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ló sì lọ. Lọ́jọ́ kan, lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí mo débẹ̀, Arákùnrin Conceição sọ pé kí n dúró díẹ̀ lẹ́yìn tíṣẹ́ àárọ̀ bá parí, pé òun fẹ́ bá mi sọ nǹkan kan. Àyà mi kọ́kọ́ ń já. Àbí mo ti ṣẹ̀ ni? Nígbà tí aago oúnjẹ ọ̀sán jàjà dún, mo lọ bá a pé kí ló fẹ́ bá mi sọ. Ló bá bi mí pé, “Ṣé wàá fẹ́ mi?” Mi ò mọ èsì tí mo lè fún un rárá. Mo ní kó fún mi láyè díẹ̀ kí n fi lọ ronú lórí ohun tó sọ náà, mo sì yára lọ síbi tá a ti fẹ́ jẹ oúnjẹ ọ̀sán.
Floriano kọ́ ni arákùnrin tó máa kọ́kọ́ sọ fún mi pé òun fẹ́ fẹ́ mi. Àmọ́ títí dìgbà tó bá mi sọ̀rọ̀ yẹn, kò tíì sẹ́nì tó kúnjú ìwọ̀n ohun tí mo kọ sílẹ̀ nípa ẹni tí mo fẹ́ fẹ́. Mo gbà pé àkọsílẹ̀ mi yẹn ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe fẹ́ ẹni tí kò yẹ. Àmọ́ ẹni tó wá bá mi yìí yàtọ̀. Irú ẹni tí mo fẹ́ gan-an ni Floriano jẹ́! A sì ṣègbéyàwó ní May 15, 1965.
Bá A Ṣe Kojú Ìṣòro Àìsàn
Èmi àti Floriano gbádùn ìgbéyàwó wa gan-an láìka àwọn ìṣòro tá a dojú kọ sí. Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro náà ni àìsàn tó ń ṣe Floriano, èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ ká ṣègbéyàwó. Lọ́dún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, ẹ̀dọ̀fóró apá òsì Floriano kò ṣiṣẹ́ mọ́, àwọn nǹkan tí èyí dá sílẹ̀ sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í yọ ọ́ lẹ́nu. Nípa bẹ́ẹ̀, a kúrò ní Bẹ́tẹ́lì wọ́n sì ní ká lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú kan tó ń jẹ́ Teresópolis tó jẹ́ àgbègbè olókè ní Ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro. Ìdí tá a fi lọ síbẹ̀ ni pé a lérò pé bí ojú ọjọ́ ṣe rí níbẹ̀ á jẹ́ kí ara Floriano yá.
Yàtọ̀ sí ìṣòro yìí, ní December ọdún 1965, wọ́n ránṣẹ́ sí mi pé ara màmá mi kò yá rárá, pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń kọ lẹ́tà síra wa nígbà gbogbo, ó ti lé lọ́dún méje tí mo ti rí màmá mi kẹ́yìn nígbà yẹn. Ni màmá mi bá san owó tó máa gbé wa dé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ká lè wá wo òun. Wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún màmá mi, àmọ́ àwọn dókítà kò lè mú àrùn jẹjẹrẹ náà kúrò lára rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn náà le débi pé kò lè dìde nílẹ̀ mọ́, síbẹ̀ kò fọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù ṣeré rárá. Ó ní ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan nínú yàrá rẹ̀ kó bàa lè máa pe lẹ́tà kí wọ́n sì máa bá a tẹ̀ ẹ́. Ó tún máa ń wàásù níwọ̀nba fáwọn tó bá wá kí i. Ó kú lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù November ọdún 1966. Lóṣù yẹn, wákàtí mẹ́wàá ló fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye àkókò tó fi wàásù! Bàbá mi ń bá iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà lọ títí tóun náà fi kú lọ́dún 1979.
Lẹ́yìn tí màmá mi kú, èmi àti Floriano padà sílẹ̀ Brazil, níbi tá a ti ń sìn títí dòní ní Ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro. Wọ́n kọ́kọ́ yàn wá sẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká ní olú ìlú ìpínlẹ̀ náà, àmọ́ a ò gbádùn iṣẹ́ yìí lọ títí, torí pé ńṣe ni àìsàn Floriano tún bẹ̀rẹ̀, ó sì le gan-an. Bá a tún ṣe padà sí ìlú Teresópolis nìyẹn, tá a lọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.
Lọ́dún 1974, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Floriano ti ń gba ìtọ́jú tó ń mú kó jẹ̀rora gan-an, àwọn dókítà yọ ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ apá òsì kúrò. Lákòókò yẹn, kò lè ṣe alága àwọn alábòójútó mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mọ́. Àmọ́ ó máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lákòókò táwọn èèyàn fi máa ń wá wo àwọn aláìsàn nílé ìwòsàn. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ni ọkùnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ ará Amẹ́ríkà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bob, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n sì fi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bob tẹ́wọ́ gba òtítọ́ ó sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn náà. Díẹ̀díẹ̀, ara Floriano yá, ó sì ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé látìgbà náà.
Jèhófà Bù Kún Iṣẹ́ Ìsìn Mi
Láti ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe bọ̀, Jèhófà sì ti bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Nílùú Teresópolis, àwọn èèyàn tí mo láǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti ràn lọ́wọ́ tí wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lé ní ọgọ́ta. Ọ̀kan lára wọn ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Jupira, tí mo tún kọ́ láti mọ̀wé kà. Nígbà tó yá, mo kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́jọ tí wọ́n ti dàgbà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lé ní ogún èèyàn lára àwọn tó jẹ́ ẹbí Jupira tí wọ́n ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lónìí. Ọ̀kan nínú wọn jẹ́ alàgbà, àwọn mẹ́ta jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn méjì sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
Mo ti rí i pé kò yẹ kéèyàn máa fojú di ẹnì kankan pé kò lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Nígbà kan, bí mo ṣe ń kọ́ obìnrin kan tí kò dàgbà púpọ̀ tó ń jẹ́ Alzemira lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́, lọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Antônio bá sọ pé òun á dẹ ajá ńlá méjì sí mi bí mi ò bá tètè jáde nínú ilé àwọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń rí Alzemira títí nǹkan bí ọdún méje lẹ́yìn náà, tó wá ṣeé ṣe fún mi láti gba àṣẹ Antônio láti tún padà máa kọ́ Alzemira lẹ́kọ̀ọ́. Síbẹ̀, Antônio sọ fún mi pé kí n má ṣe bá òun sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì rárá. Àmọ́ lọ́jọ́ kan tójò ń rọ̀, mo pe Antônio pé kó wá ká jọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Mo wá rí i pé ìṣòro rẹ̀ ni pé kò lè kàwé. Látigbà náà, ọkọ mi àtàwọn mìíràn wá ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ wọ́n sì tún ń kọ́ ọ láti mọ̀wé kà. Lónìí, Alzemira àti Antônio ti ṣèrìbọmi. Antônio ń ṣèrànwọ́ gan-an nínú ìjọ, ó máa ń bá àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.
Díẹ̀ lèyí jẹ́ lára àwọn ìrírí tá a ní láàárín ohun tó lé lógún ọdún tá a fi sìn nílùú Teresópolis. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1988, wọ́n gbé wa lọ síbòmíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ ìsìn, ìyẹn ìlú Niterói, níbi tá a ti sìn fún ọdún márùn-ún ká tó ṣí lọ sílùú Santo Aleixo. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún gbé wa lọ sí ìjọ Japuíba, tó wà nílùú kan tó gbajúmọ̀ ní ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro, a sì láǹfààní láti dá ìjọ Ribeira sílẹ̀ níbẹ̀.
Mo Jẹ́ Kójú Mi Mú Ọ̀nà Kan Mo sì Rí Èrè Rẹpẹtẹ
Látìgbà tá a ti ń bá a bọ̀, èmi àti Floriano ti láǹfààní láti ran àwọn èèyàn tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300] lọ́wọ́ láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn kan lára wọn ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, àwọn kan jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, alàgbà làwọn mìíràn, nígbà táwọn kan sì jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Mo dúpẹ́ mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó lò wá láti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́wọ́!—Máàkù 10:29, 30.
Òótọ́ ni pé Floriano ti fara da àwọn àìsàn tó le gan-an. Àmọ́ láìka àwọn ìṣòro wọ̀nyí sí, kò yẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, ó máa ń láyọ̀, ó sì gbọ́kàn lé Jèhófà. Ó sábà máa ń sọ gbólóhùn kan pé: “Kéèyàn ṣaláì ní ìṣòro kọ́ lohun tó ń fúnni láyọ̀ lónìí. Ohun tó ń fúnni láyọ̀ ni kí Jèhófà máa ranni lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro tá a bá ní.”—Sáàmù 34:19.
Lọ́dún 2003, àwọn dókítà rí àrùn jẹjẹrẹ nínú ojú mi òsì. Wọ́n sì ṣiṣẹ́ abẹ fún mi, wọ́n fi ojú oníke rọ́pò rẹ̀, èyí tí mo ní láti máa nù lọ́pọ̀ ìgbà lójúmọ́. Síbẹ̀, Jèhófà ń fún mi lókun kí n lè máa sìn ín nìṣó gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.
Tá a bá ní ká sọ nípa ohun ìní ti ara, mo jẹ́ kí ojú mi mú ọ̀nà kan. Àmọ́ Jèhófà ti bù kún mi gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn mi, ó jẹ́ kí n lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. Bí arábìnrin tó jẹ́ míṣọ́nnárì yẹn ṣe sọ pé iṣẹ́ ìwàásù rí nílẹ̀ Áfíríkà gẹ́lẹ́ ni iṣẹ́ ìsìn wa nílẹ̀ Brazil rí. Láìsí àní-àní, Jèhófà ti jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó wù mí gan-an!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Èmi àti ìdílé mi lọ́dún 1953
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọdún 1957, nígbà tí mò ń wàásù lórílẹ̀-èdè Ireland
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìgbà témi àtàwọn tá a jọ jẹ́ míṣọ́nnárì dé sórílẹ̀-èdè Brazil lọ́dún 1959. Láti apá òsì: Èmi, Inger Hatfield, Doreen Hines, àti Sonia Springate
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Èmi àti ọkọ mi