ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 9/1 ojú ìwé 9
  • Ṣé Owó Ni Orísun Ayọ̀ Tòótọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Owó Ni Orísun Ayọ̀ Tòótọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ti Wá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Tí A Ń Pọ́n Lójú Yóò Ha Ní Àlàáfíà Láé Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ṣé Wàá Túbọ̀ Máa Kìlọ̀ Fáwọn Èèyàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Òfin Ìfẹ́ Tá a Kọ Sínú Ọkàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 9/1 ojú ìwé 9

Ṣé Owó Ni Orísun Ayọ̀ Tòótọ́?

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Sípéènì ni wọ́n ti bí Sonia. Nígbà tó wà lọ́mọdé, ó máa ń tẹ̀ lé màmá ẹ̀ lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ nígbà tó dàgbà, ó lọ sílùú London nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nílé iṣẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń wá fowó dókòwò.

Sonia fẹ́ràn iṣẹ́ ẹ̀ gan-an. Owó tó ń wọlé fún un kì í ṣe kékeré, ó sì ń pawó tó pọ̀ fáwọn oníbàárà iṣẹ́ náà. Iṣẹ́ yẹn gbádùn mọ́ ọn, ó sì ń ṣàṣeyọrí nídìí ẹ̀. Wákàtí méjìdínlógún [18] ni Sonia fi ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́, láwọn ìgbà míì sì rèé, kì í sùn ju oorun wákàtí méjì sí mẹ́ta lọ lóru mọ́jú. Iṣẹ́ tó ń ṣe gbà á lọ́kàn gan-an ni. Àmọ́ lójijì ni ìgbésí ayé ẹ̀ yí pa dà. Sonia rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iṣẹ́ àṣekúdórógbó tó ń ṣe ló fà á. Kò sì tíì ju ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún lọ.

Apá kan ara Sonia ló rọ, kò sì dá àwọn dókítà lójú pé Sonia máa lè sọ̀rọ̀ mọ́. Ni màmá Sonia bá lọ bá a nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kó lè lọ tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Sonia sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn díẹ̀díẹ̀, màmá ẹ̀ sọ fún un pé, “Mò ń lọ sípàdé, o sì ní láti bá mi lọ torí mi ò lè fi ìwọ nìkan sílé.” Sonia gbà láti lọ. Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

Sonia rántí pé, “Òótọ́ ni gbogbo nǹkan tí mo gbọ́ nípàdé yẹn. Ó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni. Inú mi dùn láti gbà pé kí ọ̀kan lára àwọn tó kí mi nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ mi ló pa mí tì, àmọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi tuntun yìí lọ́yàyà, wọ́n sì bìkítà.”

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Sonia bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó sì tẹ̀ síwájú gan-an nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Láàárín ọdún kan, ó ṣèrìbọmi. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ Sonia ló máa ń fi àkókò púpọ̀ wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì rí bí wọ́n ṣe máa ń láyọ̀. Sonia wá sọ pé, ‘Ó wù mí láti dà bíi wọn. Mo fẹ́ fi gbogbo okun mi sin Jèhófà!’ Ní báyìí, Sonia náà ti wà lára àwọn tó ń fi àkókò tó pọ̀ wàásù.

Kí ni Sonia kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí? Ó ní, “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó tó ń wọlé fún mi kì í ṣe kékeré, ìdààmú àti ewu tó wà nídìí iṣẹ́ yìí kì í jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, n kì í sì í láyọ̀. Ó ti wá yé mi báyìí pé àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà Baba wa ọ̀run ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé mi. Mo ti wá láyọ̀ tòótọ́.”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:10) Sonia lè jẹ́rìí sí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́