ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 4/15 ojú ìwé 3
  • Àwọn Tí A Ń Pọ́n Lójú Yóò Ha Ní Àlàáfíà Láé Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Tí A Ń Pọ́n Lójú Yóò Ha Ní Àlàáfíà Láé Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọlọ́run Àlàáfíà” Bìkítà fún Àwọn Tí A Ń Pọ́n Lójú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ṣé Owó Ni Orísun Ayọ̀ Tòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Èèyàn Kì Í Dàgbà Jù Láti Sin Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • A Ti Wá Ìjọba náà Lákọ̀ọ́kọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 4/15 ojú ìwé 3

Àwọn Tí A Ń Pọ́n Lójú Yóò Ha Ní Àlàáfíà Láé Bí?

ÌWỌ yóò ha fẹ́ láti rí i kí ìyà wá sópin, kì í ṣe fún ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n fún gbogbo aráyé? Gbé àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò:

Sonia ti jìyà púpọ̀.a Lákọ̀ọ́kọ́, ó rí i pé ọkọ òun ti ń bá ẹnì kan dálè fún ọdún mẹ́wàá. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀ tí ó kéré jù lọ kó kòkòrò àrùn HIV, àrùn AIDS sì pa á. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà ni ọmọkùnrin rẹ̀ kejì dùbúlẹ̀ àìsàn, kò pẹ́ kò jìnnà, àrùn AIDS pa òun náà. Sonia rántí pé: “Apá tí ó gbẹ̀yìn nínú àrùn náà wà fún ìgbà pípẹ́. Ó sorí kọ́ gidigidi, irun rẹ̀ re jẹ, kò sì ríran dáradára mọ́. Ó bani nínú jẹ́ púpọ̀.”

Fabiana, akẹ́kọ̀ọ́ yunifásítì kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil, dàníyàn nípa àìsídàájọ́ òdodo nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà lágbàáyé. Lẹ́yìn náà, ìbànújẹ́ bá ìgbésí ayé òun alára. Arákùnrin rẹ̀, tí ó sorí kọ́, pa ara rẹ̀. Nígbà tí Fabiana pàdánù iṣẹ́ rẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan gbà á nímọ̀ràn pé kí ó kàn sí pai-de-santo (babaláwo), ní rírò pé kí Fabiana tó lè ko irú àgbákò bẹ́ẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ẹnì kan ti sà sí i! Ṣùgbọ́n pai-de-santo kò fún un ní ìtura kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, Fabiana nímọ̀lára pé a ń dá òun lóró, ìdààmú ọkàn rẹ̀ kò jẹ́ kí ó rí oorun sùn.

Ìpọ́njú Ana bẹ̀rẹ̀ ní kùtùkùtù ìgbésí ayé rẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún kan, màmá mi já mi jù sílẹ̀, nítorí náà, ìyá mi àgbà ni ó tọ́jú mi.” Lẹ́yìn náà, nígbà tí Ana jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta péré, ìyá rẹ̀ àgbà kú. A fi Ana sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn ní Rio de Janeiro, níbi tí ó wà títí tí ó fi pé ọmọ ọdún 13. Ó sọ pé: “Ìwà burúkú gbáà ni wọ́n ń hù sí wa níbẹ̀, mo sì di ọlọ̀tẹ̀. Bí mo ṣe ń dàgbà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni mo ń jà lé lórí.”

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé, lọ́nà kan tàbí òmíràn, ìpọ́njú ń nípa lórí ìgbésí ayé gbogbo ẹ̀dá ènìyàn. Ní tòótọ́, ojoojúmọ́ ni a ń bá ìtàn nípa ọ̀ràn ìbànújẹ́ ẹ̀dá ènìyàn pàdé—nígbàkígbà tí a bá ka ìròyìn, tí a bá tẹ́tí sí i, tàbí tí a bá wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n. Ọ̀mọ̀wé Mary Sykes Wylie kọ̀wé pé: “Ní . . . sànmánì wa ti ẹlẹ́rọ ìbánisọ̀rọ̀ yí, ni yíyọ lọ́wọ́ dída ìròyìn búburú bóni léraléra tó di ohun tí kò ṣeé ṣe mọ́. Ogun, ìjábá ti ìṣẹ̀dá, àjálù ti ilé iṣẹ́, ìjàǹbá ọ̀nà márosẹ̀, ìwà ọ̀daràn, ìkópayàbáni, ìfìbálòpọ̀-ṣeni-níkà, ìfipá-bánilòpọ̀, ìwà ipá abẹ́lé—gbogbo rẹ̀ mú kí hílàhílo jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ ojoojúmọ́ ti ọ̀rúndún ogún yìí, tí ń kó jìnnìjìnnì báni.” Láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàkópọ̀ ìrírí ẹ̀dá ènìyàn ní sísọ pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora papọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora papọ̀.”—Róòmù 8:22.

Ìwọ ńkọ́? A ha ń pọ́n ọ lójú bí? Ìtura wo ni o lè retí? Ọwọ́ rẹ yóò ha tẹ àlàáfíà tòótọ́ láé bí? Sonia, Fabiana, àti Ana rí ojúlówó ìtùnú àti àlàáfíà tòótọ́ gan-an! Ìwọ lè kà nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ tí ń bẹ nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́