Ìtàn Ìgbésí Ayé
Ìdí Tí Sísọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn Fi Ń múnú Mi Dùn
Gẹ́gẹ́ bí Pamela Moseley ṣe sọ ọ́
Ogun ń jà kíkankíkan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1941, àkókò yẹn sì ni màmá mi mú mi lọ sí ìpàdé àgbègbè kan tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí tó wáyé nílùú Leicester. Arákùnrin Albert Schroeder sọ àkànṣe àsọyé kan níbẹ̀, tó dá lórí àwọn ọmọdé. Nígbà tí èmi àti màmá mi ṣèrìbọmi nípàdé àgbègbè yẹn, mo ṣàkíyèsí pé inú àwọn tó ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run dùn gan-an. Nígbà yẹn, mi ò tíì mọ bí ayọ̀ téèyàn máa ń rí nínú sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ṣe máa ń pọ̀ tó.
ỌDÚN kan ṣáájú ìgbà yẹn la bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ láti di ọmọ ẹ̀yìn. Mo ṣì rántí ọjọ́ yẹn lóṣù September ọdún 1939 tẹ́rù bà wá gan-an, ìyẹn ọjọ́ tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Mo rí i tí omi ń dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú màmá mi bó ti ń béèrè pé, “Kí ló dé, kí ló dé tí ayé ò lé ní àlàáfíà?” Àwọn òbí mi méjèèjì ló ṣiṣẹ́ ológun nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n sì rí gbogbo aburú tí ogun yẹn fà. Bí màmá mi ṣe lọ bá àlùfáà ìjọ Áńgílíkà kan nílùú Bristol nìyẹn tó sì béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ rẹ̀. Èsì tí àlùfáà yìí kàn fún un ni pé: “Ó pẹ́ tógun ti ń jà, ogun ò sì ní yéé jà.”
Àmọ́ kò pẹ́ sí àkókò yìí ni obìnrin kan tó jẹ́ àgbàlagbà wá sílé wa. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Ni màmá mi bá tún bi í ní ìbéèrè tó bi àlùfáà yẹn, ó ní: “Kí ló dé tí ayé yìí kò lè ní àlàáfíà?” Ẹlẹ́rìí náà ṣàlàyé pé àwọn ogun tó ń jà jẹ́ ara àmì tó fi hàn pé àkókò òpin ètò àwọn nǹkan yìí tó kún fún ìwà ipá là wà yìí. (Mátíù 24:3-14) Kò pẹ́ sígbà náà lọmọ rẹ̀ obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n wà lára àwọn tó ń wò wá tínú wọn sì dùn gan-an nígbà tá a ṣèrìbọmi. Kí nìdí tí sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ṣe máa ń fún àwọn Kristẹni láyọ̀ gan-an? Nígbà tó yá, mo wá mọ̀dí rẹ̀. Jẹ́ kí n sọ díẹ̀ lára ohun tí mo ti kọ́ ní ohun tó lé lọ́dún márùnlélọ́gọ́ta tí mo ti ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.
Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Rí Ayọ̀ Tó Wà Nínú Kíkọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́
Ọmọ ọdún mọ́kànlá ni mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run nílùú Bristol. Arákùnrin kan gbé ẹ̀rọ giramafóònù kan fún mi, ó sì tún fún mi ní káàdì ìjẹ́rìí kan, ó wá sọ pé: “Ó yá, lọ sí òpópónà yẹn kí o sì wàásù ní gbogbo ilé tó wà lápá ibẹ̀ yẹn.” Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn o, èmi nìkan sì ni. Àmọ́ ẹ̀rù bà mí gan-an. Mò ń lo ẹ̀rọ giramafóònù yẹn láti gbé àsọyé Bíbélì tí wọ́n ti gbà sílẹ̀ jáde fáwọn èèyàn gbọ́, lẹ́yìn náà ni màá wá fi kádìí ìjẹ́rìí náà han wọ́n, èyí tó ń rọ àwọn èèyàn láti gba ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ní àwọn ọdún 1950, ètò Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ ọn pé, tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé, ká máa ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ jáde látinú Bíbélì fáwọn èèyàn. Ó kọ́kọ́ ṣòro fún mi níbẹ̀rẹ̀ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ kí n sì ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì fún wọn nítorí pé mo jẹ́ ẹni tó máa ń tijú. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀rù ò bá mí mọ́. Ìgbà yẹn gan-an ni mo sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ojú tàwétàwé làwọn kan fi máa ń wò wá tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tá a wá ń ka ẹsẹ Bíbélì fún wọn tá a sì ń ṣàlàyé rẹ̀, wọ́n wá rí i pé olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wá. Mò ń gbádùn iṣẹ́ yìí gan-an débi pé mo fẹ́ láti lo àkókò púpọ̀ sí i láti fi wàásù. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tó di oṣù September ọdún 1955, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, ìyẹn iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
Mo Rí Èrè Nítorí Pé Mi Ò Jáwọ́
Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ tí mo kọ́kọ́ kọ́ ni pé, téèyàn bá jẹ́ kí ìfẹ́ sún òun láti máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láìjáwọ́, ó máa ń mú èrè wá. Nígbà kan, mo fún obìnrin kan tó ń jẹ́ Violet Morice ní ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Nígbà tí mo padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ṣílẹ̀kùn rẹ̀ gbayawu, ó káwọ́ mọ́yà, ó sì tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa bí mo ti ń ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún un. Gbogbo ìgbà tí mo bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ló jọ pé ó nífẹ̀ẹ́ gan-an sóhun tí mò ń bá a sọ. Àmọ́ nígbà tí mo sọ fún un pé kó jẹ́ ká máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ó dá mi lóhùn pé: “Rárá. Táwọn ọmọ mi bá dàgbà, màá máa ṣèyẹn.” Èsì tó fún mi yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi gan-an! Àmọ́ Bíbélì sọ nípa “ìgbà wíwá àti ìgbà gbígbà pé ó ti sọnù.” (Oníwàásù 3:6) Mo pinnu pé mi ò ní jáwọ́.
Mo padà lọ sọ́dọ̀ Violet ní oṣù kan lẹ́yìn ìgbà náà mo sì tún bá a jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ díẹ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ kí n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀. Ló bá sọ fún mi lọ́jọ́ kan pé: “Mo rò pé ó yẹ kó o máa wọlé báyìí, àbí o kò rò bẹ́ẹ̀?” Violet di olùjọ́sìn Jèhófà tó ń ṣe dáadáa gan-an ó sì di ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́! Bẹ́ẹ̀ ni, Violet ṣèrìbọmi, ó sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Lọ́jọ́ kan, ó ya Violet lẹ́nu gan-an láti rí i pé ọkọ òun ti ta ilé àwọn, ó sì ti já òun sílẹ̀. Àmọ́ inú wa dùn pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa, ó rí ilé mìíràn lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn gangan. Láti fi ẹ̀mí ìmoore rẹ̀ hàn sí Jèhófà, ó pinnu láti lo gbogbo ìyókù ayé rẹ̀ nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tí mo rí i bí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe jẹ́ kó nítara gan-an fún ìjọsìn tòótọ́, mo wá mọ ìdí tí sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ṣe máa ń múni láyọ̀ gan-an. Mo pinnu pé àní sẹ́, iṣẹ́ tí màá fi gbogbo ìgbésí ayé mi ṣe nìyẹn!
Lọ́dún 1957, wọ́n yan èmi àti Mary Robinson pé ká lọ máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ládùúgbò kan tó ń jẹ́ Rutherglen níbi tí iléeṣẹ́ pọ̀ sí, nílùú Glasgow, lórílẹ̀-èdè Scotland. Kò sígbà tá a kì í wàásù. A máa ń wàásù nígbà tí kùrukùru bá bolẹ̀, nínú ẹ̀fúùfù, nínú òjò, kódà lásìkò tí yìnyín bá ń rọ̀ sílẹ̀ pàápàá, àmọ́ ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lọ́jọ́ kan, mo bá obìnrin kan pàdé tó ń jẹ́ Jessie. Mò ń gbádùn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ ọ. Àmọ́ alátìlẹyìn ìjọba Kọ́múníìsì lọkọ rẹ̀, kò sí fẹ́ kí n wàásù fóun rárá. Nígbà tí ọkùnrin yìí wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì rí i pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú àwọn ipò tó dára wá fún ìran èèyàn, inú rẹ̀ dùn gan-an. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn méjèèjì dẹni tó ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.
Ọ̀nà Tẹ́nì Kan Kọ́kọ́ Gbà Hùwà Lè Tanni Jẹ
Nígbà tó yá, wọ́n tún yàn wá síbòmíràn, ìyẹn ìlú kan tó ń jẹ́ Paisley, lórílẹ̀-èdè Scotland. Nígbà tí mò ń wàásù níbẹ̀ lọ́jọ́ kan, lobìnrin kan bá tilẹ̀kùn rẹ̀ gbàà, kí n má bàa bá a sọ̀rọ̀. Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló bẹ̀rẹ̀ sí í wá mi kiri láti bẹ̀ mí. Nígbà tí mo padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé Ọlọ́run ni mo tilẹ̀kùn mọ́ lójú. Mo sì rí i pé mo ní láti wá ẹ rí.” Pearl lorúkọ obìnrin yìí. Ó sọ fún mi pé àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí ti já òun kulẹ̀ gan-an débi pé òun gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kóun lè rí ọ̀rẹ́ gidi. Ó wá sọ pé: “Kò pẹ́ sígbà náà lo wá sẹ́nu ọ̀nà mi yẹn. Mo ti wá rí i báyìí pé ìwọ ni ọ̀rẹ́ gidi náà.”
Kò rọrùn rárá láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Pearl. Orí òkè kan tó ga fíofío nilé rẹ̀ wà, ẹsẹ̀ ni mo sì fi máa ń rìn débẹ̀. Nígbà tí mo lọ síbẹ̀ láti lọ mú un wá sípàdé tó máa kọ́kọ́ lọ, afẹ́fẹ́ àti òjò fẹ́rẹ̀ẹ́ gbé mi lọ. Mo ní láti sọ agbòjò mi dà nù nígbà tó fàya. Oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn tí Pearl tilẹ̀kùn rẹ̀ gbàà yẹn ló ṣèrìbọmi láti fi hàn pé òun ti ya ìgbésí ayé òun sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà lọkọ rẹ̀ náà sọ pé òun fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ sígbà náà lèmi pẹ̀lú rẹ̀ jọ lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Bí òjò tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ bó ti máa ń rọ̀ nìyẹn. Ló bá sọ fún mi pé: “Má dáàmù nípa mi o. Mo máa ń dúró nínú irú òjò yìí fún ọ̀pọ̀ wákàtí láti wo eré bọ́ọ̀lù, kò sì sóhun tó ní kí n má lè ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà.” Ó pẹ́ tí ẹ̀mí ìforítì àwọn ará Scotland ti máa ń jọ mí lójú.
Ayọ̀ ńláǹlà ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo padà sáwọn àgbègbè yìí lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí mo sì rí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kò yẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́! Irú ayọ̀ téèyàn máa ń rí nìyẹn nínú sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (1 Tẹsalóníkà 2:17-20) Lọ́dún 1966, lẹ́yìn tí mo ti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílẹ̀ Scotland fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́jọ, wọ́n pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead kí n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti di míṣọ́nnárì.
Mo Lọ Sìn Nílẹ̀ Òkèèrè
Orílẹ̀-èdè Bolivia ni wọ́n yàn mí sí, ní ìlú kan tó ń jẹ́ Santa Cruz, tí ooru tí máa ń mú gan-an. Ìjọ kan ló wà níbẹ̀, àwọn bí àádọ́ta ló sì máa ń wá sípàdé. Ìlú yẹn rán mi létí bí àgbègbè kan tó ń jẹ́ Wild West nínú àwọn fíìmù kan tí mo wò ṣe rí. Tí n bá ronú padà sẹ́yìn, ó dà bíi pé míṣọ́nnárì tèmi yàtọ̀ sí táwọn tó kù. Ọ̀nì kò gé mi jẹ rí, àwọn èèyànkéèyàn kò gbéjà kò mí rí, bẹ́ẹ̀ ni mi ò sọnù nínú aṣálẹ̀ rí tàbí kí ọkọ̀ rì mí sínú òkun. Iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ iṣẹ́ tó ń múnú mi dùn gan-an.
Antonia lorúkọ ọ̀kan lára àwọn obìnrin tí mo kọ́kọ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílùú Santa Cruz. Kò rọrùn fún mi rárá láti fi èdè Sípéènì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà kan, ọmọ Antonia kékeré tó jẹ́ ọkùnrin tiẹ̀ sọ fún màmá rẹ̀ pé: “Mọ́mì, ṣé ńṣe lobìnrin yìí ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣi ọ̀rọ̀ sọ ká bàa lè máa rẹ́rìn-ín?” Antonia di ọmọ ẹ̀yìn níkẹyìn, àtọmọ rẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Yolanda. Yolanda yìí ní ọ̀rẹ́ kan tó ń kọ́ nípa ìmọ̀ òfin nílé ẹ̀kọ́ Yunifásítì, Dito lorúkọ ìnagijẹ ọkùnrin náà. Òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ó sì máa ń wá sípàdé. Mo kọ́ ohun kan lára Dito nípa iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tí mo kọ́ ni pé, nígbà míì, àwọn èèyàn nílò ká bá wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.
Nígbà tí Dito bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ jẹ, mo sọ fún un pé: “Dítò, Jèhófà kò fipá mú ẹ láti ti Ìjọba rẹ̀ lẹ́yìn o. Ọ̀kan lo máa mú.” Nígbà tó fèsì pé òun fẹ́ sin Ọlọ́run, mo bá sọ fún un pé: “Àwòrán ẹni tó fẹ́ gbàjọba ló kúnnú ilé rẹ yìí. Ǹjẹ́ àlejò tó bá rí àwọn àwòrán yìí á gbà pé o ti yàn láti ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn?” Ìwọ̀nba òótọ́ ọ̀rọ̀ tó nílò nìyẹn.
Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ni wàhálà kan ṣẹlẹ̀ níléèwé rẹ̀, tí àwọn ọmọ Yunifásítì náà àtàwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn síra wọn. Ni Dito bá kígbe mọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Jẹ́ ká jáde kúrò níbí yìí!” Ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí sọ pé: “Rárá o! Ọjọ́ ńlá tá a ti ń dúró dè nìyí,” bó ṣe ki ìbọn kan mọ́lẹ̀ nìyẹn tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sáré lọ sórí òrùlé Yunifásítì náà. Ó wà lára àwọn mẹ́jọ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Dito tí wọ́n kú lọ́jọ́ yẹn. Ǹjẹ́ ẹ mọ bínú mi ti máa ń dùn tó tí mo bá ti rí Dito, ẹni tó jẹ́ pé ì bá ti kú ká ní kò pinnu láti di Kristẹni tòótọ́ ni?
Mo Rí Bí Ẹ̀mí Jèhófà Ṣe Ń Ṣiṣẹ́
Lọ́jọ́ kan, mò ń kọjá lọ níwájú ilé kan, èrò mi ni pé a ti wàásù nínú ilé náà. Bí obìnrin tó ń gbénú ilé náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í pè mí nìyẹn. Ignacia lórúkọ rẹ̀. Ó ti mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀, àmọ́ inúnibíni tó le gan-an tí ọkọ rẹ̀ tó síngbọnlẹ̀ tó sì jẹ́ ọlọ́pàá ń ṣe sí i, kò jẹ́ kó lè tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Adalberto lorúkọ ọkọ rẹ̀ yìí. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì ni kò yé Ignacia, bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ pinnu láti dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe náà dúró, mo wá wá ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ mìíràn. Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dọ̀rẹ́ nìyẹn.
Ẹ wo bí ayọ̀ mi ṣe pọ̀ tó nígbà tí Ignacia di ara wa nínú ìjọ tó sì ń ṣe dáadáa gan-an, tó ń ṣèrànwọ́ tẹ̀mí àti tara fún ọ̀pọ̀ àwọn tó nílò ìtùnú. Nígbà tó yá, mẹ́ta lára àwọn ọmọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ náà di Ẹlẹ́rìí. Àní sẹ́, nígbà tí ìhìn rere náà yé Adalberto tán, ó padà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá ó sì bá àwọn tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀ tìtaratìtara débi pé, ó gba àsansílẹ̀ owó Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó jẹ́ igba [200] lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá náà.
Jèhófà Ń Mú Kó Dàgbà
Lẹ́yìn tí mo sìn nílùú Santa Cruz fún ọdún mẹ́fà, wọ́n ní kí n lọ máa sìn nílùú La Paz, tó jẹ́ ìlú pàtàkì kan nílẹ̀ Bolivia, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni mo sì lò níbẹ̀. Níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni méjìlá ló ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú La Paz. Bí iṣẹ́ ìwàásù ti ń tẹ̀ síwájú, tí èyí sì ń béèrè pé ká ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó túbọ̀ tóbi sí i, wọ́n wá kọ́ tuntun sílùú Santa Cruz tó jẹ́ ìlú tó ń tóbi sí i lójoojúmọ́. Ọdún 1998 ni wọ́n kó ẹ̀ka iléeṣẹ́ lọ síbẹ̀, wọ́n sì ní kí n wá di ara àwọn tó ń sìn níbẹ̀, a sì ti lé ní àádọ́ta báyìí.
Ìjọ kan ṣoṣo tó wà nílùú Santa Cruz lọ́dún 1966 ti di èyí tó lé ní àádọ́ta báyìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta [640] ní gbogbo ilẹ̀ Bolivia nígbà yẹn sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún báyìí!
Inú mi dùn gan-an pé iṣẹ́ ìsìn mi nílẹ̀ Bolivia ti sèso gan-an. Àmọ́, jíjẹ́ táwọn Kristẹni bíi tèmi níbi gbogbo jẹ́ olóòótọ́ máa ń fún mi níṣìírí ní gbogbo ìgbà. Gbogbo wa ni inú wa ń dùn bá a ti ń rí ìbùkún Jèhófà lórí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí à ń ṣe. Dájúdájú, inú mi ń dùn gan-an pé mo lè kópa nínú iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 28:19, 20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìgbà tí mò ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Scotland
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Mò ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Bolivia; (fọ́tò kékeré inú àkámọ́) ìgbà ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì Kejìlélógójì Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì