ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/22 ojú ìwé 19-23
  • Mo Gba Okun Láti Kojú Àwọn Àdánwò Níwájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo Gba Okun Láti Kojú Àwọn Àdánwò Níwájú
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpinnu Kan àti Àwọn Àbájáde Rẹ̀
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí Mo Kọ́ Láti Inú Àwọn Àdánwò
  • Gbígba Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Lórí Iṣẹ́ Ìgbésí Ayé Mi
  • Ìbẹ̀rẹ̀ Kékeré, Onírúkèrúdò
  • Ẹnì Kejì Mi Olùṣòtítọ́
  • Onírúurú Iṣẹ́ Àyànfúnni
  • Ìgbésí Ayé Aláyọ̀ ti Ṣíṣiṣẹ́ Sin Àwọn Ẹlòmíràn
  • Ẹ̀bẹ̀ Òṣìṣẹ́ Amúdàájọ́ṣẹ Kan
    Jí!—1998
  • Ìdí Tí Sísọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn Fi Ń múnú Mi Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Mi Ò Ṣi Iṣẹ́ Tí Màá Ṣe Láyé Mi Yàn
    Jí!—2007
  • Pípa Gbogbo Àfiyèsí Pọ̀ Sórí Ẹ̀bùn náà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Jí!—1996
g96 12/22 ojú ìwé 19-23

Mo Gba Okun Láti Kojú Àwọn Àdánwò Níwájú

GẸ́GẸ́ BÍ EDWARD MICHALEC ṢE SỌ

Inú bí òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ ìlú ńlá Wharton, Texas, U.S.A., gidigidi. Bí ó ti ń mú mi lọ sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀kẹrin, ó kọ kàrá pé: “Kí ló ṣe tí ìwọ kì í ṣègbọràn sí àṣẹ?”

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo dáhùn pé: “Mo ní ẹ̀tọ́ kíkún láti ṣe èyí.” Èyí túbọ̀ bí òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ náà nínú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í nà mí ní kòbókò. Àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n ń fi ìdí ìbọn wọn lù mí.

ÌYẸ́N ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 60 ọdún sẹ́yìn báyìí. Ní bíbojú wẹ̀yìn, mo lè rí i pé Jèhófà Ọlọ́run lò irú ipò bẹ́ẹ̀ láti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, kí n lè kojú ìpèníjà ti jíjẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì péré tí ó wà ní Bolivia, orílẹ̀-èdè Gúúsù America kan tí ó tóbi bákan náà pẹ̀lú ilẹ̀ Faransé. Ìrírí mi lè jẹ́ kí o rí bí Jèhófà ṣe lè fún ọ lókun nígbà tí o bá ń kojú onírúurú àdánwò.

Lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní 1936, bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ṣọ́ọ̀bù kan tí a ti ń tún rédíò ṣe ní Boling, Texas, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ kan tí Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà, sọ lórí afẹ́fẹ́. Ọ̀rọ̀ náà dá lórí àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá fún aráyé onígbọràn. Ó wọ̀ mí lọ́kan gidigidi. (Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 21:3, 4) Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìwé mélòó kan tí Rutherford kọ níbi ìkówèésí tiwa, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà wọ́n.

Ọkàn-ìfẹ́ mi nínú ohun tí ìyàwó bàbá mi pè ní “gbogbo àwọn ògbólógbòó ìwé ìsìn wọ̀nyẹn” dá a níjì. Ó kó wọn pa mọ́, ó sì halẹ̀ pé òun yóò dáná sun wọ́n. Nígbà tí mo kọ̀wé sí Watch Tower Society láti máa gba Ilé Ìṣọ́ àti The Golden Age, ọ̀kan nínú àwọn orúkọ tí a fi ń pe Jí! tẹ́lẹ̀, Society darí William Harper, láti Ìjọ Wharton tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nígbà náà, láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ mi. Láìpẹ́, èmi, ìyàwó bàbá mi, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, àti ọbàkan mi ọkùnrin kékeré lápapọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Arákùnrin Harper. Láìpẹ́, gbogbo wá ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wa fún Jèhófà nípa ìrìbọmi.

Ní 1938, Shield Toutjian, arìnrìn àjò aṣojú Society, ṣèbẹ̀wò sí ilé wa ní Boling, ó sì sọ àsọyé Bíbélì kan. Èró kún iyàrá ìgbàlejò wa fọ́fọ́—àwọn ènìyán tilẹ̀ dúró sí àwọn ẹnu ọ̀nà àbáwọyàrá tí ó yọ sí iyàrá ìgbàlejò náà. Arákùnrin Toutjian sọ̀rọ̀ nípa ìfaradà wòlíì Jeremáyà ní wíwàásù fún àwọn ènìyàn ní àkókò tirẹ̀ láìka àtakò sí. (Jeremáyà 1:19; 6:10; 15:15, 20; 20:8) Nípasẹ̀ irú àwọn àwíyé bẹ́ẹ̀, Jèhófà ń fún wa lókun de àwọn àdánwò tí a óò dojú kọ.

Ìpinnu Kan àti Àwọn Àbájáde Rẹ̀

Láìpẹ́, mo rí i pé mo ní láti ṣe ìpinnu kan. Ṣáájú, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ òwò, mo sì ti ń wá ọ̀nà láti di olókìkí láwùjọ ìṣòwò. Mo ní ilé iṣẹ́ òwò títa rédíò àti títún rédíò ṣe kan, mo sì ń ṣiṣẹ́ fún ilé iṣẹ́ tẹlifóònù kan, tí ń ṣàgbékalẹ̀ ẹ̀rọ tẹlifóònù. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mọrírì rẹ̀ pé àṣeyọrí tòótọ́ nínú ìgbésí ayé wé mọ́ wíwu Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run. Nítorí náà, mo kásẹ̀ òwò mi nílẹ̀, mo sì ṣàtúnṣe ilé alágbèérìnká kan. Nígbà tí ó fi di January 1, 1939, mo ti dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn aṣáájú ọ̀nà, àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan, nítòsí ìlú Three Rivers, ní Àrọko Karnes, Texas.

Ní September 1939, Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀ ní Europe. Àwọn alátakò lo àǹfààní náà láti ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́. Wọ́n sọ pé ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ abẹ́lẹ̀, tàbí amí la jẹ́ fún Agbára Àjọṣepọ̀. Ọ̀pọ̀ ènìyán gba irú ìfẹ̀sùnkanni bẹ́ẹ̀ gbọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í yọ wá lẹ́nu. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940, a fi mí sẹ́wọ̀n nígbà mẹ́sàn-án tàbí mẹ́wàá, pa pọ̀ pẹ̀lú èyí tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀, nígbà tí òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ yẹn àti àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ fi lù mí lálùbolẹ̀. Ọ̀ràn mí gba ìtọ́jú ìṣègùn lẹ́yìn náà.

Ó ṣẹlẹ̀ pé, òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ kan náà yìí gbà láti má ṣe fìyà jẹ ọkùnrin kan tí a fi ẹ̀sùn tẹ́tẹ́ títa láìbófinmu kàn lórí àdéhùn kan—kí ọkùnrin náà, òṣìṣẹ́ ibi ìwakùsà epò kan tí ó ṣe fìrìgbọ̀n, lù mí bolẹ̀. Ní ìyọrísí rẹ̀, bí mo ṣe ń fi ìwé ìròyìn lọni ní òpópónà lọ́jọ́ kan, ọkùnrin náà yọ ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n kan tì mí! Àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ díẹ̀ débẹ̀, ṣùgbọ́n kàkà kí wọ́n mú un, wọ́n lọ tì mí mọ́lé! Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹni tí ó gbéjà kò mí náà wáá sọ ohun tí ó fa ìgbéjàkò láìnídìí náà fún mi, ó sì tọrọ àforíjì.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí Mo Kọ́ Láti Inú Àwọn Àdánwò

Kíkojú irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ fún ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run lókun ní ti gidi. Fún ohun kan, n kò rántí ìrora tí mo ní nígbà tí a ń lù mí, ṣùgbọ́n mo rántí ìparọ́rọ́ àti àlàáfíà tí mo ní lẹ́yìn náà dáradára. (Ìṣe 5:40-42) Nípa bẹ́ẹ̀, mo kọ́ láti ṣe bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gbani níyànjú pé: “Ẹ . . . yọ ayọ̀ àṣeyọrí nígbà tí [ẹ] bá wà nínú ìpọ́njú, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá.” (Róòmù 5:3) Lẹ́yìn ìgbà náà, tí mo bá rántí lílù tí a lù mí, ó ń mú kí n pinnu pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, láti má ṣe jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn aṣojú Sátánì pa mí lẹ́nu mọ́.

Ní àfikún sí i, mo kọ́ ẹ̀kọ́ oníyebíye mìíràn. Ọ̀rọ̀ mi tí ó ṣe ṣàkó pé, “Mo ní ẹ̀tọ́ kíkún láti ṣe èyí,” ti mú kínú bí òṣìṣẹ́ amúdàájọ́ṣẹ náà. Lẹ́yìn náà, ó tún kò mi lójú lẹ́ẹ̀kan sí i, inú ń bí i lọ́tẹ̀ yìí nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí kò lọ́wọ́ sí ogun. (Aísáyà 2:4) Nínú ìgbìyànjú láti mú mi bínú, ó béèrè pé: “Bí a bá ké sí ọ láti ṣiṣẹ́ sin orílẹ̀-èdè rẹ, ṣé ìwọ yóò lọ?”

Nísinsìnyí tí mo ti kọ́ láti máa lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, mo fèsì pé: “Bí ó bá dá mi lójú pé ìfẹ́ inú Jèhófà ni, dájúdájú, n óò lọ.” Ìdáhùn yìí tú ìbínú rẹ̀ ká, ohunkóhun kò sì tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.

Gbígba Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Lórí Iṣẹ́ Ìgbésí Ayé Mi

Kókó pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé mi ni wíwà lára kíláàsì kẹta Watchtower Bible School of Gilead, ní 1944. Ilé ẹ̀kọ́ yìí ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ olóṣù márùn-ún fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Kí n tóó lọ sílé ẹ̀kọ́ yìí, ẹ̀rù máa ń bà mí láti bá àwùjọ sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n ohun tí ó ràn mí lọ́wọ́ gidigidi ni pé mo máa ń ní láti bá nǹkan bí ọgọ́rùn-ún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ̀rọ̀, tí ó sábà máa ń jẹ́ ní gbangba gbàgede kan. Maxwell Friend, tí ó dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa sísọ̀rọ̀ ní gbangba, máa ń já lu ọ̀rọ̀ mi, yóò sì kígbe pé: “Arákùnrin Michalec, n kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ!” Nípa títẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀, mo wáá mọ̀ pé mo ní ohùn tí ó lágbára gan-an.

Lẹ́yìn tí Nathan H. Knorr, ààrẹ ilé ẹ̀kọ́ náà nígbà náà, kéde pé Bolivia ni a yàn mí sí gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì, mo rántí bí ó ṣe ń ṣí mi létí pé: “Ìwọ yóò rí ọ̀pọ̀ ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ níbẹ̀. Jẹ́ onífẹ̀ẹ́, onísùúrù, àti agbatẹnirò pẹ̀lú wọn.” Nítorí pé Ogun Àgbáyé Kejì ṣì ń lọ lọ́wọ́ nígbà náà, a ní láti dúró fún ìgbà díẹ̀ kí a tóó gbéra lọ sí ibi iṣẹ́ àyànfúnni wa. Níkẹyìn, ní October 25, 1945, èmi àti Harold Morris—tí a jọ jẹ́ ọmọ kíláàsì kan náà—gúnlẹ̀ sí Pápákọ̀ Òfuurufú El Alto, kété lẹ́yìn òde ìlú ńlá La Paz, olú ìlú Bolivia. Nípa bẹ́ẹ̀, a di Ẹlẹ́rìí méjì péré tí ó wà ní orílẹ̀-èdè títóbi jù lọ ṣìkẹ́ta ní Gúúsù America.

A wọ bọ́ọ̀sì kan láti pápákọ̀ òfuurufú náà, tí ó fi 4,100 mítà ga ju ìtẹ́jú òkun lọ, lọ sí olú ìlú náà, La Paz, tí ó tàn ká ìsàlẹ̀ àti ẹ̀gbẹ́ àfonífojì olómi ńlá kan. Mímú ara bá ìgbésí ayé níbi tí ó ga ju ìtẹ́jú òkún lọ ní kìlómítà mẹ́ta jẹ́ ìpèníjà kan.

Ìbẹ̀rẹ̀ Kékeré, Onírúkèrúdò

Lọ́gán, a bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ àwọn ènìyàn wò láti ilé dé ilé. Wọ́n jẹ́ onínúure àti onísùúrù sí wa bí a ṣe ń tiraka láti sọ ìwọ̀nba tí a mọ̀ nínú èdè Spanish. Láìpẹ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan wá ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 18 sí 20 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú àwọn ilé. Ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, ní April 16, 1946, àwùjọ ènìyàn kékeré, aláyọ̀ kán, pàdé pọ̀ pẹ̀lú wa fún ayẹyẹ ọdọọdún ìrántí ikú Kristi. Láìpẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege mẹ́rin sí i láti Gilead dé, lára wọn sì ni Elizabeth Hollins, tí ó wáá di aya mi lẹ́yìn náà.

Láìpẹ́, èmi àti Arákùnrin Morris bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìlú ńlá mìíràn, títí kan Cochabamba àti Oruro, tí wọ́n jẹ́ ìlú ńlá títóbi jù lọ ṣìkejì àti ṣìkẹ́ta ní Bolivia nígbà náà. Nígbà tí mo ròyìn ọkàn-ìfẹ́ tí a rí àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a fi sóde, fún Arákùnrin Knorr, ó dábàá pé kí a máa bẹ àwọn ìlú ńláńlá wọ̀nyí wò ní nǹkan bí oṣù mẹ́tamẹ́ta láti ran àwọn tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn oníwà bí ọ̀rẹ́, ẹlẹ́mìí aájò àlejò wọ̀nyí wáá di Ẹlẹ́rìí Jehofa lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Níwọ̀n bí Ogun Àgbáyé Kejì ti ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ní ọdún kan ṣáájú, Bolivia ń fojú winá rúkèrúdò ìṣèlú. Ìbánidíje ìṣèlú àti ìbẹ̀rù ìtúnyọríjáde ẹgbẹ́ Nazi ní Gúúsù America yọrí sí ìwọ́de oníwà ipá ní àwọn òpópónà àti ìyọ́kẹ́lẹ́pani. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1946, wọ́n pa ààrẹ orílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ kọ́ òpó iná tí ó dojú kọ ààfin ààrẹ. Nígbà míràn, ìwà ipá náà kì í jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn láti jáde kúrò nínú ilé wọn.

Bí Elizabeth ṣe ń wọ bọ́ọ̀sì kọjá lọ ní gbàgede ìlú lọ́jọ́ kan, ó rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́ta tí wọ́n gbé kọ́ orí òpó. Pẹ̀lú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀, ó pariwo díẹ̀. Ẹnì kan tí wọ́n jọ wọkọ̀ ní: “Bí o kò bá fẹ́ràn ohun tí o ń rí, pajú rẹ dà.” Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tẹ àìní náà láti gbára lé Jèhófà pátápátá mọ́ wa lọ́kàn.

Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín ìdàrúdàpọ̀ náà, òtítọ́ Bíbélì ń ta gbòǹgbò nínú àwọn ọkàn onírẹ̀lẹ̀. Ní September 1946, a dá ọ́fíìsì ẹ̀ka kan sílẹ̀ ní La Paz, a sì yàn mí ní alábòójútó ẹ̀ka. Ilé kan tí a háyà, tí a ń lò bí ọ́fíìsì, ni a tún ń lò bí ibùgbé àwọn míṣọ́nnárì. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí a dá ìjọ àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní Bolivia, ilé kan náà yìí ni a ti ń ṣe àwọn ìpàdé.

Ní 1946, a bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwíyé fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú. A gba gbọ̀ngàn Ibi Ìkówèésí Ìlú ní agbègbè ìṣòwò ìlú La Paz fún ti àkọ́kọ́. Ará Yugoslavia, oníwà bí ọ̀rẹ́ kan, tí ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wa, sanwó fún ìpolongo àwíyé náà nínú ìwé agbéròyìnjáde àdúgbò. Gbọ̀ngàn náà kún fọ́fọ́. Mo ṣojora púpọ̀ nípa bí n ó ṣe sọ àwíyé yẹn níwọ̀n bí n kò ì tí ì gbọ́ èdè Spanish yanjú. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, ìpàdé náà kẹ́sẹ járí. Ó wáá já sí pé èyí ni àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ àwíyé mẹ́rin tí a sọ nínú gbọ̀ngàn náà.

Ní 1947 àwọn míṣọ́nnárì mẹ́fà dé sí i láti Gilead, mẹ́rin mìíràn sì dé láfikún sí i ní 1948. Àwọn ilé tí a lè háyà kò ní àwọn ohun amáyédẹrùn tàbí nǹkan fàájì òde òní nínú tó bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ sí bíbójú tó ìlànà iṣẹ́ wa tí ó kún fọ́fọ́, àwa míṣọ́nnárì ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ní láti ṣe àbọ̀ṣẹ́, kí a lè rí owó pààrọ̀ àwọn aṣọ wa tí ń gbó. Títi ìlú kan dé òmíràn jẹ́ ìpèníjà kan pẹ̀lú. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo rìnrìn àjò la ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ àárín àwọn òkè ńláńlá olótùútù já ní jíjókòó lẹ́yìn ọkọ̀ tí kò nílé lórí. Ṣùgbọ́n Jèhófà ń fún wa níṣìírí afúnni lókun nìṣó nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀.

Ní March 1949, Arákùnrin Knorr àti akọ̀wé rẹ̀, Milton Henschel, wá láti New York, wọ́n sì ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibùgbé míṣọ́nnárì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a ń lò ní La Paz, Cochabamba, àti Oruro. Ẹ wo bí ó ti ń fúnni níṣìírí tó láti gbọ́ nípa ìbísí aláìlẹ́gbẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, kí a sì gbọ́ nípa Ilé Bẹ́tẹ́lì àti ilé ìlò ìtẹ̀wé tuntun tí a ń kọ́ lọ́wọ́ ní orílé iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn! Arákùnrin Knorr dábàá pé kí a ní ibùgbé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ní ibi tí ó túbọ̀ bọ́ sí àárín gbùngbùn ìlú ńlá La Paz. Ó tún sọ fún wa pé a óò ní ọ̀pọ̀ míṣọ́nnárì sí i.

Lẹ́yìn náà ní 1949, a ṣe ìpàdé àyíká wa àkọ́kọ́, ní ìlú Oruro. Ó wú àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa tuntun lórí láti pàdé ara wọn fún ìgbà àkọ́kọ́. Nígbà yẹn, Bolivia ti dé góńgó àwọn olùpòkìkí Ìjọba 48, ó sì ní ìjọ mẹ́ta.

Ẹnì Kejì Mi Olùṣòtítọ́

Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí jíjùmọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, èmi àti Elizabeth wáá mọ ara wa, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa. Níkẹyìn, ní 1953, a ṣègbéyàwó. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà ní January 1939, tí èmi náà bẹ̀rẹ̀. Àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wọ̀nyẹn kò rọrùn fún òun náà pẹ̀lú. Nítorí ìgbòkègbodò ìwàásù onígboyà rẹ̀, wọ́n ti fi òun náà sẹ́wọ̀n rí, tí wọ́n mú un la òpópónà ìlú já bí ọ̀daràn kan lásán.

Elizabeth jẹ́wọ́ pé ẹ̀rú ba òun nígbà tí òún kópa nínú gbígbé ìsọfúnni káàkiri àti nínú síso àwọn ìwé ìsọfúnni fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tí ó kà pé: “Ìsín Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó” mọ́ra. Ṣùgbọ́n ó ṣe ohun tí ètò àjọ Jèhófà fún wa ní ìtọ́ni láti ṣe nígbà náà. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ó ṣe é fún Jèhófà. Àwọn ìrírí wọ̀nyẹ́n fún un lókun de àwọn àdánwò tí ó fara dà ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wọ̀nyẹn ní Bolivia.

Onírúurú Iṣẹ́ Àyànfúnni

Fún ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, a lo ọ̀pọ̀ àkókò wa nínú iṣẹ́ arìnrìn àjò. Kì í ṣe àwọn ìjọ mẹ́rin tí ń bẹ ní Bolivia nìkan ni a bẹ̀ wò, a tún bẹ àwọn àwùjọ àdádó ti àwọn olùfìfẹ́hàn àti gbogbo ìlú tí ó ní iye olùgbé tí ó ju 4,000 lọ wò. Ète wa ni láti ṣàwárí àwọn ènìyàn tí ń gbé ibi wọ̀nyẹn, kí a sì bomi rin ọkàn-ìfẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá ní nínú òtítọ́ Bíbélì. Ó mú ọkàn wa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láti rí i pé, nígbà tí ó fi máa di àwọn ọdún àárín 1960, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìlú kéékèèké tí a ti bẹ̀ wò ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ṣáájú ni àwọn ìjọ́ ti wà.

Láàárín àkókò náà, mo ní àwọn àìlera tí ibi gíga ti La Paz ń mú kí ó burú sí i. Nítorí náà, ní 1957, arákùnrin mìíràn gba ẹrù iṣẹ́ àbójútó ẹ̀ka, a sì yan èmi àti Elizabeth síṣẹ́ ní ibùgbé àwọn míṣọ́nnárì ní Cochabamba, ìlú àfonífojì tí ó túbọ̀ rẹlẹ̀ kan. Ní ìpàdé wa àkọ́kọ́, àwọn míṣọ́nnárì mélòó kan ló pésẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ọmọ ìbílẹ̀ Bolivia kankan. Nígbà tí a óò fi kúrò ní Cochabamba ní ọdún 15 lẹ́yìn náà, ní 1972, ìjọ méjì ló wà níbẹ̀. Nísinsìnyí, ìjọ 35 pẹ̀lú iye olùpòkìkí Ìjọba tí ó lé ní 2,600 ni ó wà ní àfonífojì Cochabamba!

Ní 1972, a gbé wa lọ sí Santa Cruz, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ilẹ̀ olóoru kan. A ṣì ń gbé níhìn-ín nínú iyàrá mélòó kan tí ó wà lókè Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Nígbà tí a dé ibí, ìjọ méjì ní ń bẹ ní Santa Cruz pẹ̀lú, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, wọ́n lé ní 45, pẹ̀lú iye akéde tí ó lé ní 3,600, tí ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.

Ẹ wo bí inú wá ti dùn tó pé a wà lẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì wa fún àwọn ọdún tí ó lé ní 50 wọ̀nyí, tí a rí ìkójọpọ̀ nǹkan bí 12,300 àwọn ènìyàn Jèhófà ní orílẹ̀-èdè yìí! Ní tòótọ́, wíwúlò fún àwọn ẹni ọ̀wọ́n wọ̀nyí ti dùn mọ́ wa nínú.

Ìgbésí Ayé Aláyọ̀ ti Ṣíṣiṣẹ́ Sin Àwọn Ẹlòmíràn

Kí n tóó lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì mi, olùdámọ̀ràn ọ̀ràn òfin fún Watch Tower Society, Hayden C. Covington, ará Texas bíi tèmi, sọ pé: “Ed, a ní àyè láti máa yan fanda ní Texas. Ṣùgbọ́n ní ibùgbé àwọn míṣọ́nnárì, ìwọ àti àwọn mìíràn yóò há pọ̀. Yóò túmọ̀ sí ṣíṣe àwọn ìyípadà.” Ó tọ̀nà. Gbígbé pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ìpèníjà kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ẹyọ kan péré nínú ọ̀pọ̀ ìpèníjà tí Kristẹni kan tí ó jẹ́ míṣọ́nnárì ń dojú kọ.

Nítorí náà, bí o bá ní láti ronú kíkúrò nílé láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ní àgbègbè míràn, rántí pé ìgbésí ayé ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ ti Kristi jẹ́ ti ṣíṣiṣẹ́ sin àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 20:28) Nítorí náà, míṣọ́nnárì kan ní láti múra sílẹ̀ ní ti èrò orí láti tẹ́wọ́ gba ìgbésí ayé ìṣẹ́raẹni. Àwọn kán lè máa ronú pé àwọn yóò ta yọ lọ́lá. Bóyá wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀—nígbà tí wọ́n bá ń dá gbére fún àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn ẹbí nílé. Ṣùgbọ́n ìyẹn ń pòórá nígbà tí ẹnì kán bá dé ìlú kékeré tàbí agbègbè ìlú ńlá tí kò lọ́rọ̀, tí yóò jẹ́ ibi iṣẹ́ àyàfúnni rẹ̀. Kí ni ìmọ̀ràn mi?

Bí o bá pàdé àwọn ìṣòro, bí àìlera, ìmọ̀lára wíwà ní àdádó kúrò lọ́dọ̀ ìdílé rẹ, tàbí bóyá ìṣòro àìlèjùmọ̀ ṣe pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ nínú iṣẹ́ àyànfúnni kan, tẹ́wọ́ gba gbogbo rẹ̀ bí apá kan ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ. Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò san ọ́ lẹ́san láìpẹ́, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pétérù ṣe kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo . . . yóò fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, òun yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in, yóò mú yín lókunlágbára.”—Pétérù Kìíní 5:10.

Edward Michalec kú ní July 7, 1996, nígbà tí a ṣì ń ṣe àṣeparí iṣẹ́ lórí títẹ àpilẹ̀kọ yìí jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ní Bolivia ní 1947

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

A sábà máa ń ṣe àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ sísọ̀rọ̀ ní gbangba ní ìta, bí a ṣe fi hàn nínú àwòrán gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá tí a yà lẹ́yìn náà yìí ní Gilead

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Pẹ̀lú aya mi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́