Edé—Nǹkan Aládùn Láti Odò Ìdọ́sìn Kan Ni Bí?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ECUADOR
BẸ́Ẹ̀ ni, ẹran òkun aládùn tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń gbádùn yìí sábà máa ń wá láti odò ìdọ́sìn kan. Síbẹ̀, àwọn tí ń jẹ ẹ́ lè ṣàìmọ èyí, nítorí bí ìyàtọ̀ bá wà rárá láàárín edé tí a fi dọ́sìn àti èyí tí a wulẹ̀ kó nínú agbami òkun, ó ní láti kéré gan-an. Ní gidi, ọ̀pọ̀ odò edé ní Ecuador kún fún àwọn ọmọ edé tí a kó ní tààràtà láti inú agbami òkun.
Àwọn apẹja tí a ń pè ní larveros ń fi àwọ̀n kó àwọn kògbókògbó edé tí kò ju ṣẹ̀ǹtímítà kan ààbọ̀ lọ wọ̀nyí ní àwọn ẹnu odò tí ó ní àwọn igi ẹ̀gbà léteetí ní bèbè etíkun tàbí nínú ìgbì òkun tí ń di ìfóófòó. Wọ́n wáá ń kó wọn lọ sínú odò edé láti dàgbà. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò lè gba ọ̀nà yìí rí edé púpọ̀ tó. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ odò ìdọ́sìn edé ló gbára lé àwọn ibi ìpamọsí tí ó ní àwọn ọ̀nà ṣíṣe ọ̀sìn ẹran omi ti ìgbàlódé láti pèsè ọmọ edé fún odò edé wọn. Ẹ jẹ́ kí á ṣàyẹ̀wó fínnífínní nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn odò ìdọ́sìn edé.
Ìbẹ̀wò Síbi Ìpamọsí Kan
Ibi ìpamọsí tí a bẹ̀ wò wà ní etíkun ẹlẹ́wà kan ní Bèbè Etíkun Pacific. A gbọ́dọ̀ fìdí ibi ìpamọsí edé sọlẹ̀ sítòsí ìwọ́jọpọ̀ omi oníyọ̀ ńlá kan, kí a lè rí omi púpọ̀ tó fún ìgbékalẹ̀ ìpínkiri omi rẹ̀ ẹlẹ́ka púpọ̀. A ń fa omi wọlé láti inú agbami òkun náà, a ń sẹ́ ẹ, a ń gbé e gbóná bí ó bá ṣe yẹ, a sì ń fi ránṣẹ́ sínú onírúurú àgbá omi tí ó wà nínú ilé.
Àwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè inú òkun, àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ, àti àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn kan, tí wọ́n jẹ́ oníwà bí ọ̀rẹ́, tí wọ́n kàn múra ṣákálá ṣáá, ló wáá pàdé wa. Iyàrá ìdàgbà ni a kọ́kọ́ wọ̀. Níhìn-ín, a kó àwọn edé tí a kò fi dọ́sìn, tí ó ti dàgbà dáadáa sínú àwọn àgbá ìdàgbà onílítà 17,000. Afinimọ̀nà wá ṣàlàyé pé: “Àwọn edé wọ̀nyí kì í ṣe jíjẹ. Wọ́n ti dàgbà dáadáa kí a tóó kó wọn wá síbí fún mímú irú ọmọ jáde.”
Ìṣètò iná títàn tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni wọ́n ń tẹ̀ lé ní iyàrá ìdàgbà. Láàárín aago 3:00 ọ̀sán àti ọ̀gànjọ́ òru—sáà tí wọ́n máa ń gùn—wọ́n ń pa àwọn iná tí kì í mọ́lẹ̀ rokoṣo náà, àwọn òṣìṣẹ́ sì ń lo tọ́ọ̀ṣì láti fi ṣàwárí àwọn abo tí wọ́n ti múra tán láti yín ẹyin. Àwọn abo irú ọ̀wọ́ Penaeus vannemei rọrùn láti dá mọ̀, nítorí pé akọ́ máa ń lẹ àpò àtọ̀ kan mọ́ ibi ikùn wọn. Ní gbàrà tí àwọn òṣìṣẹ́ bá ti rí abo tí ó ti gbọlẹ̀ kan, wọ́n á yára mú un lọ sínú àgbá kékeré onílítà 260 kan, tí wọ́n ń yín ẹyin sí.
Níbẹ̀ ni a ti ń fi abo tí ó ti gbọlẹ̀ náà sórí pèpéle kan létí àgbá onídìí rogodo kan—abo kan fún àgbá kan—títí tí yóò fi yín 180,000 ẹyin rẹ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bí ó ṣe ń ti àwọn ẹyin náà jáde ni wọ́n ń dọ́mọ bí wọ́n ṣe ń fara kan awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ìdì àtọ̀ náà. Lẹ́yìn náà, a ń sẹ́ àwọn ẹyin àti omi náà gba ìdí àgbá náà tí ó dà bí àrọ. Àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ń ṣàkọsílẹ̀ iye ẹyin tí ọ̀kọ̀ọ̀kán yín.
Ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn pípamọ, a ń kó àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀pa náà, níwọ̀n iye tí a pààlà sí, lọ sínú ohun tí a mọ̀ sí àgbá ìwòdàgbà. Ìwọ̀nyí rí bí ọpọ́n ìwẹ̀ ńlá, wọ́n sì ń gba nǹkan bí 11,000 lítà omi. Fún 20 ọjọ́ sí ọjọ́ 25 tí ó tẹ̀ lé e, àwọn àgbá wọ̀nyí ni yóò jẹ́ bí ilé fún àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀pa tí ń dàgbà náà, tí ń jẹ àwọn èèhọ̀n àti àwọn ẹran òkun gbígbẹ.
Ibi Tí Edé Ti Ń Dàgbà
A ń kó àwọn edé tí ó ti kúrò ní àṣẹ̀ṣẹ̀pa nísinsìnyí náà lọ sínú odò ìdọ́sìn. Ní gbàrà tí wọ́n bá ti débẹ̀, irú ìtọ́jú kan náà ni ó wà fún àwọn tí a pa níbi ìpamọsí àti àwọn tí a kó lágbami òkun. A ń kó wọn sí àwọn adágún omi kéékèèké láti lè ṣàkóso bí wọ́n ṣe ń mú ara wọn bá ìdíwọ̀n ooru ara tuntun náà àti ìwọ̀n iyọ̀ inú omi náà mu. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, wọ́n ti tóó kó lọ sínú adágún omi ńláńlá. Àwọn adágún àtọwọ́dá wọ̀nyí máa ń wà nítòsí ọ̀nà omi àtọwọ́dá kan tí ń gba omi dúró. A máa ń fa omi sínú ọ̀nà omi àtọwọ́dá yìí déédéé láti inú agbami òkun tàbí ẹnu odò náà. Àwọn adágún omi tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ń tóbi to nǹkan bíi hẹ́kítà márùn-ún sí mẹ́wàá. Fún oṣù mẹ́ta sí márùn-ún, wọ́n máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ edé wọ̀nyí máa dàgbà nínú adágún wọ̀nyí.
Láàárín àkókò ìdàgbà náà, a máa ń díwọ̀n bí afẹ́fẹ́ oxygen ṣe pọ̀ tó nínú àwọn omi adágún náà lójoojúmọ́. Bákan náà ni a ń ṣàyẹ̀wò ìwọ̀n ìdàgbà àwọn edé náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí a lè ṣàtúnṣebọ̀sípò ìṣètò oúnjẹ wọn. A ń sapá láti rí sí i pé wọ́n ń tẹ̀wọ̀n sí i ní ìwọ̀n gíráàmù 1 sí 2 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Ìgbà Ìkórè
Nígbà ìkórè, tí a bá ń jo omi odò náà gbẹ, a óò fi àwọ̀n kó àwọn edé náà tàbí kí a fà wọ́n yọ bí wọ́n ti ń sún mọ́ ẹnu odò náà. A óò wáá ṣan àwọn edé tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kórè náà, a óò sì da omi dídì lé wọ́n lórí láti kó wọn lọ sí ibi tí a ti ń dì wọ́n lọ́gán. Bí kò bá jẹ́ pé ẹni tí ó rà wọ́n pa àṣẹ mìíràn, níbẹ̀ ni a ti máa ń gé orí edé kúrò, ṣùgbọ́n a kì í bó ìrù wọn. A óò wáá fọ àwọn edé náà, a óò sì ṣà wọ́n jọ ní bí wọ́n ṣe tóbi sí, lẹ́yìn èyí ni a óò dì wọ́n, tí a óò sì kó wọn sí yìnyín láti dì wọ́n sọ́kọ̀, ó sì sábà máa ń jẹ́ nínú àpótí oníwọ̀n 2.27 kìlógíráàmù.
Nítorí náà, nígbà míràn tí o bá ń jẹ edé, o lè rántí pé ó ṣeé ṣe kí a ti dọ́sìn ẹran òkun aládùn yìí ní odò edé kan ní irú ibì kan bíi Latin America tàbí Éṣíà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Bí edé ṣe ń tóbi tó nígbà ìkórè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn apẹja tí ń fi àwọ̀n kó kògbókògbó edé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn àgbá ìwòdàgbà níbi ìpamọsí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Fífọ edé níbi tí a ti ń dì í
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Dídi edé ní bí wọ́n ṣe tóbi tó