ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 14-15
  • Coral—Ewu Ń Wu Ú, Ó sì Ń Kú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Coral—Ewu Ń Wu Ú, Ó sì Ń Kú
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìkarawun Bíbó Tí Kò Ní Ohun Alààyè Nínú
  • Kí Ni A Lè Ṣe Láti Dáàbò Bo Àwọn Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun?
    Jí!—1996
  • Àwọn Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun Tí Ń kú—Ẹ̀dá Ènìyàn Ló Ṣokùnfà Rẹ̀ Bí?
    Jí!—1996
  • Àyíká Òkìtì Ẹ̀dá Omi Abìlẹ̀kẹ̀ Jíjojúnígbèsè
    Jí!—1997
  • Òkè Ẹfun Gàgàrà Lójú Òfuurufú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 14-15

Coral—Ewu Ń Wu Ú, Ó sì Ń Kú

ÌSÀLẸ̀ òkun ṣeé rí kedere jù lọ ní Ilẹ̀ Olóoru. Ó mọ́ gaara. Omi rẹ̀ mọ́ kedere. Ilẹ̀ oníyanrìn funfun tí ó jìn tó mítà 15 nísàlẹ̀ rẹ̀ dà bí ohun tí ó sún mọ́ ọ débi pé o lè fọwọ́ bà á! Ṣáà wulẹ̀ gbé lẹbẹ ìlúwẹ̀ẹ́ àti agọ̀ ìbòjú wọ̀. Tún àwọn ọ̀pá àfimí rẹ ṣe bí o ti ń kó sínú omi lílọ́ wọ́ọ́wọ́ọ́ náà, tí àwọn ìsọpùtù omi sì ń dí ọ lọ́wọ́ láti ríran fún ìgbà díẹ̀. Lẹ́yìn náà, wo ìsàlẹ̀. Wo ibẹ̀ yẹn! Wo ẹja parrot aláwọ̀ pupa òun òféfèé tí ń gé coral jẹ, tí ó sì ń tu ìjàǹjá rẹ̀, tí ń di ara ìsàlẹ̀ oníyanrìn náà, sílẹ̀. Lójijì, ọ̀pọ̀ ẹja ilẹ̀ olóoru pẹ̀lú oríṣiríṣi àwọ̀ wọn—pupa, oníyeyè, aró, olómi ọsàn, elésè àlùkò—ń kọjá lọ. Àwọn ohun alààyè ń lọ, wọ́n ń bọ̀ níbi gbogbo. Ó gba àfiyèsí gbogbo agbára ìmọ̀lára rẹ pátápátá.

Igbó coral nìyí. Ó ń yọrí láti inú ilẹ̀ oníyanrìn nísàlẹ̀, ó sì ń na ẹgbẹẹgbẹ̀rún ohun tí a lè fi wé ọwọ́ ohun abẹ̀mí jáde. Kété níwájú ni ìdí coral onírìísí ìwo ẹranko elk kíkàmàmà kan wà, tí gíga rẹ̀ lé ní mítà mẹ́fà, tí fífẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bẹ́ẹ̀. Ní nǹkan bíi mítà 23 síwájú ni coral onírìísí ìwo àgbọ̀nrín wà, ó kéré sí onírìísí ìwo ẹranko elk, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tín-ínrín tí ó gba gbogbo àdúgbò náà bí igbó kan. Ẹ wo bí orúkọ tí a sọ àwọn coral wọ̀nyí ṣe bá wọn mu tó—ní kedere, wọ́n máa ń rí bí ìwo ẹranko! Àwọn ẹja àti àwọn ohun alààyè inú òkun mìíràn ń rí oúnjẹ àti ibùgbé lábẹ́ àwọn ẹ̀ka wọn.

Nígbà kan rí, a ti rò pé ewéko ni coral, ṣùgbọ́n a ti wáá mọ̀ nísinsìnyí pé, ìkójọpọ̀ òkúta ẹfun tí àwùjọ àwọn ẹran kan tí ń jẹ́ polyp ṣe ni. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn polyp kéré, wọn kò tó sẹ̀ǹtímítà 2.5 ní ìwọn ìdábùú òbírí. Polyp alára múlọ́múlọ́ ara coral náà ń so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ aládùúgbò rẹ̀ pẹ̀lú ẹran ara tí ohun ayọ̀gbọ̀lọ̀ kan bò. Coral máa ń dà bí òkúta lójú ọ̀sán, nítorí pé àwọn polyp máa ń wọnú ìkarawun wọn. Ṣùgbọ́n ó máa ń yíra padà lálẹ́, bí àwọn ẹ̀mú wọn ṣe ń mì lẹ̀ǹgbẹ̀, tí wọ́n sì ń fún òkìtì abẹ́ òkun náà ní ìrísí ẹlẹgẹ́, lílọ́lù. “Igi” olókùúta tí àwọn polyp náà ń ṣàjọpín rẹ̀ ni àkópọ̀ ìkarawun wọn tí èròjà calcium carbonate láti inú omi òkun náà ń lẹ̀ pọ̀ mọ́ra.

Oríṣi àwùjọ coral kọ̀ọ̀kan ń mú irú ìrísí ìkarawun aláìlẹ́gbẹ́ tirẹ̀ jáde. Kárí ayé, ó lé ní 350 oríṣi coral ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ìrísí, ìtóbi, àti àwọ̀ wọn ń ṣeni ní kàyéfì. Àwọn orúkọ wọn tí ó wọ́pọ̀ ń rán ọ létí àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀—àwọn coral igi, ọwọ̀n, tábìlì, tàbí agboòrùn—tàbí ti ewéko—àwọn coral òdòdó carnation, ewébẹ̀ lettuce, èso strawberry, tàbí olú. Ǹjẹ́ o rí coral ọpọlọ ńlá yẹn? Ó rọrùn láti mọ bí o ṣe gba orúkọ rẹ̀!

Igbó abẹ́ omi yìí ní ọ̀pọ̀ ohun alààyè nínú, láti orí àwọn ewéko àti ẹranko tí kò ṣeé fojú lásán rí, sí orí àwọn ẹja ray, ekurá, moray eel ńláńlá, àti àwọn ìjàpá. Àwọn ẹja kan tí ó ṣeé ṣe kí o máà tí ì gbọ́ nípa wọn rí wà níbí pẹ̀lú—ẹja clown aláwọ̀ ìyeyè títàn, Beau Gregories tí ó ní àwọ̀ elésè àlùkò, àwọn Moorish idol aláwọ̀ dúdú àti funfun, ẹja trumpet aláwọ̀ omi ọsàn, ẹja surgeon aláwọ̀ aró kíki, hamlet aláwọ̀ ẹ̀lú, tàbí ẹja lion aládàlù àwọ̀ ilẹ̀ òun àwọ̀ ilẹ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú. Àwọn edé barbershop, ọ̀kàsà tí a kùn lọ́dà, tàbí ẹja hawk aláwọ̀ rírẹ̀ dòdò ńkọ́? Gbogbo àwọ̀, gbogbo ìtóbi, gbogbo ìrísí. Àwọn kan rẹwà, àwọn kan kò gún gẹ́gẹ́—ṣùgbọ́n gbogbo wọn fani lọ́kàn mọ́ra. Wò ó, ẹja octopus kan ní ń fara pamọ́ sẹ́yìn coral ọwọ̀n yẹn! Ó ń jẹ clam kan tí ó ṣí. Bí ó ti máa ń rí nínú àwọn igbó orí ilẹ̀, oríṣiríṣi àgbàyanu ohun alààyè ni ìwàláàyè wọn so kọ́ra nínú àyíká abẹ́ òkun yìí, tí gbogbo wọn sì sinmi lórí ìjónírúurú rẹ̀. A ti ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé lórí ọ̀nà tí coral ń gbà mú irú jáde àti agbára ìṣe rẹ̀ láti bá ìṣàn omi òkun rìn, kí ó sì ṣàgbékalẹ̀ àwùjọ òkìtì tuntun nínú ìtẹ̀jáde Jí!, June 8, 1991 (Gẹ̀ẹ́sì).

Àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun ni àwọn ìgbékalẹ̀ ohun alààyè títóbi jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀kan lára ìwọ̀nyí, òkìtì Great Barrier Reef, níbi etíkun Australia gùn tó 2,010 kìlómítà, ó sì kó agbègbè ilẹ̀ tí ó pọ̀ tó ìtóbi àpapọ̀ England àti Scotland mọ́ra. Coral kan lè wọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ tọ́ọ̀nù, kí ó sì ga ju mítà mẹ́sàn-án lọ, láti abẹ́ òkun. Àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun máa ń wà nínú gbogbo omi tí kò jinlẹ̀ ní ilẹ̀ olóoru, ní ibi tí ó jìn tó 60 mítà. Wọ́n ní àwọn àmì ànímọ́ yíyàtọ̀ láti ibì kan dé ibòmíràn, débi pé nípa ṣíṣe àyẹ̀wò ègé coral kan, àwọn ògbógi lè mọ ìyàtọ̀ òkun àti omi àdúgbò tí ó ti wá pàápàá. Àyíká tí coral ti máa ń yọrí jẹ́ ọ̀kan tí ó ní oúnjẹ tí ó mọ níwọ̀n nínú omi, èyí tí ó ṣàlàyé ìdí tí òkun fi máa ń mọ́ rekete lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ní agbègbè tí wọ́n bá wà. Àwọn èèhọ̀n (tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ ní zooxanthellae), tí ń gbé ara polyp, tí ó ṣeé rí láti òdì kejì, ní ń pèsè oúnjẹ fún coral, àwọn ẹranko tí kò ṣeé fojú lásán rí tí wọ́n há sí àárín ẹ̀mú ti coral pẹ̀lú ń pèsè oúnjẹ fún un. Àbájáde gbogbo rẹ̀ ni òkìtì coral abẹ́ òkun kan, tí ó jẹ́ ibùgbé àdánidá fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún irú ọ̀wọ́ ohun alààyè inú òkun níbi tí òkun kì bá tí ní ibùgbé fún wọn láìsí coral.

Nínú gbogbo ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè inú òkun pẹ̀lú àyíká wọn, àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun ní ń mú irú jáde jù lọ. Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí pé: “Àwọn òkìtì abẹ́ òkun ni alábàádọ́gba àwọn ẹgàn ilẹ̀ olóoru, tí ń ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ohun alààyè nínú: àwọn abẹ̀bẹ̀ òkun àti pàṣán òkun gbágungbàgun, àwọn crinoid fífúyẹ́, àwọn ẹja onítànṣán ìdànǹdán àti àwọn sponge, edé, ọ̀kàsà àti ẹja oníràwọ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ekurá bíbani lẹ́rù, àti àwọn òmìrán moray eel. Gbogbo wọn gbára lé ìmújáde coral tí ń bá a lọ fún ibùgbé àdánidá wọn.” Àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun tún máa ń gbé ìwàláàyè ró lórí ilẹ̀ nípa pípèsè ìdènà kan láàárín ìgbì omi ńlá àti ààlà omi òun ilẹ̀, àti nípa fífi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn erékùṣù ilẹ̀ olóoru.

Coral tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá máa ń ní àwọ̀ ilẹ̀, àwọ̀ ewé, àwọ̀ pupa, àwọ̀ aró, tàbí àwọ̀ ìyeyè, tí ó sinmi lórí irú èèhọ̀n tí ń gbé inú polyp tí òdì kejì rẹ̀ ṣeé rí, tí coral náà rọ̀ mọ́. Àwọn ewéko aláìṣeéfojúlásánrí tí ń bẹ nínú èèhọ̀n náà ń lo ìtànṣán oòrùn tí ń gba ara ẹran alájọgbé wọn wọlé, wọ́n sì ń gba àwọn ohun tí kò wúlò fún polyp náà, irú bí afẹ́fẹ́ carbon dioxide, fún oúnjẹ wọn. Lọ́nà ìsanpadà, nípasẹ̀ ìpèsè ṣúgà inú ọ̀gbìn, àwọn èèhọ̀n ń pèsè afẹ́fẹ́ oxygen, oúnjẹ, àti okun fún àwọn iṣu ẹran coral náà. Àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn èèhọ̀n yìí ń mú kí coral lè yára pọ̀ sí i, kí ó sì máa wà láàyè nìṣó nínú àwọn omi ilẹ̀ olóoru tí kò ní oúnjẹ púpọ̀ nínú. Àwọn méjèèjì ń gbádùn ìgbésí ayé dídára jù lọ fún ewéko àti ẹranko. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìṣètò aláìlẹ́gbẹ́ àti ọlọgbọ́n tó!

Àwọn Ìkarawun Bíbó Tí Kò Ní Ohun Alààyè Nínú

Abájọ tí ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò fi ń lọ nísàlẹ̀! Wò ó, kí nìyẹn? Àwọn ìkarawun bíbó tí kò ní ohun alààyè nínú. Àwọn ẹ̀ka ń ya dà nù, wọ́n sì ń wó. Àwọn kán ti rà mọ́lẹ̀. Apá yìí lára igbó coral ti kú, tàbí, ó ń kú lọ. Kò sí ẹja. Kò sí edé. Kò sí ọ̀kàsà. Kò sí nǹkan kan. Aṣálẹ̀ abẹ́ omi ni. Ó yà ọ́ lẹ́nu. Ẹ wo bí ó ti múni gbọ̀n rìrì tó! Ó ba ìrírí gbígbádùn mọ́ni rẹ jẹ́. Kódà, nígbà tí o bá padà wọkọ̀, o ṣì ní àwọn ìbéèrè tí ń dà ọ́ láàmú. Kí ní lè ti fa ìsọdahoro yìí? Ìjàm̀bá ni bí? Àrùn ni bí? Àwọn okùnfà àdánidá ni bí? O ń fẹ́ ìdáhùn.

Bí ó tilẹ̀ jọ pé coral olókùúta lera gbagidi, ó ṣe ẹlẹgẹ́ púpọ̀ jù. Bí ẹ̀dá ènìyàn bá fọwọ́ kàn án lásán, ó lè bà jẹ́, nítorí náà, àwọn ọlọgbọ́n amòòkùn ń yẹra fún fífọwọ́ kàn án, àwọn atukọ̀ oníṣọ̀ọ́ra sì ń yẹra fún dídá ọkọ̀ ró sórí rẹ̀. Àwọn ewú mìíràn lórí coral ni ìbàjẹ́ oníkẹ́míkà, ìtúdànù epo, ìpalẹ̀ ẹ̀gbin mọ́, gígé gẹdú, àwọn oògùn tí ń ṣàn dà nù sínú omi láti oko, odò gbígbẹ́, kíkó pàǹtírí dà sómi, àti fífipá kó wọ omi aláìníyọ̀. Fífara kan ọ̀pá abẹ́ ọkọ̀ ojú omi ní tààràtà ń ṣe ìjàm̀bá púpọ̀. Ojú ọjọ́ gbígbóná jù sì lè ṣèpalára fún coral, kí ó sì pa á. Bí másùnmáwo bá bá a, coral máa ń tú èèhọ̀n rẹ̀ dà nù nínú ìkuukùu dídì, àwọn ẹja sì máa ń yára jẹ ẹ́. Bí ipò másùnmáwo bá ń bá a lọ fún ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù púpọ̀, coral máa ń bó, ó sì ń kú. Nígbà tí coral bá sì kú, àyíká òkìtì abẹ́ òkun náà kú nìyẹn. Àyíká tí ń gbé oríṣiríṣi ìwàláàyè ró fọ́n ká, ó sì pòórá.

Bíbó rẹ̀ ti wáá gbalẹ̀ ní gbogbo agbami òkun ilẹ̀ olóoru. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde rẹ̀, ìdágìrì ti bá àwùjọ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa òkun kárí ayé. Nígbà tí bíbó náà bá ṣẹlẹ̀ lọ́nà gbígbòòrò, ìbàjẹ́ náà kì í ṣeé tún ṣe. Lọ́nà tí ó káni lára, ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ jákèjádò àwọn òkun ilẹ̀ olóoru ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ ti wáá pe àfiyèsí ayé sí bí bíbó coral àti ikú rẹ̀ ṣe gbòòrò tó. Nígbà tí a ti ń rí bíbó coral látìgbà dégbà àti ní ìwọ̀n kéréje fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ kò ní àfijọ ìṣáájú kankan ní ti bí wọ́n ṣe le tó, wọ́n sì ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé. Ohun kan ti ń gbógun ti ọ̀pọ̀ jù lọ irú ọ̀wọ́ àwọn alààyè coral kárí ayé, tí ó sì ń fa ìwólulẹ̀ àyíká òkìtì abẹ́ òkun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́