ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 18-20
  • Kí Ni A Lè Ṣe Láti Dáàbò Bo Àwọn Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni A Lè Ṣe Láti Dáàbò Bo Àwọn Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yóò Ha Dara Pọ̀ Nínú Ìsapá Náà Bí?
  • Coral—Ewu Ń Wu Ú, Ó sì Ń Kú
    Jí!—1996
  • Àwọn Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun Tí Ń kú—Ẹ̀dá Ènìyàn Ló Ṣokùnfà Rẹ̀ Bí?
    Jí!—1996
  • Àyíká Òkìtì Ẹ̀dá Omi Abìlẹ̀kẹ̀ Jíjojúnígbèsè
    Jí!—1997
  • Òkun
    Jí!—2023
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 18-20

Kí Ni A Lè Ṣe Láti Dáàbò Bo Àwọn Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun?

Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kárí ayé gbà gbọ́ pé ìlọ́wọ́ọ́rọ́ àgbáyé ń nípa lórí ẹ̀dá ènìyàn, yóò sì máa burú sí i bí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìdàgbàsókè iṣẹ́ ẹ̀rọ. Lọ́dọọdún, nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́ta tọ́ọ̀nù òṣùwọ̀n metric afẹ́fẹ́ carbon dioxide (CO2) ni a ń tú jáde sínú afẹ́fẹ́ àyíká nípa sísun àwọn ohun ìdáná, irú bí èédú, epo, àti igi, láti mú iná wá, àti nípa dídáná sungbó. Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ṣe sọ, ohun tí a ń pè ní ìyọrísí iṣẹ́ ilé ewéko, tí ó jẹ́ ìyọrísí àwọn gáàsì tí ń wá láti inú sísun epo, ń wu ilẹ̀ ayé léwu ìmúmóoru ìwọ̀n 2 sí 4 lórí òṣùwọ̀n Celsius nígbà tí ó bá fi di ìlàjì ọ̀rúndún tí ń bọ̀. Ìlọsókè yìí yóò ṣokùnfà ikú fún àwọn coral àti àgbájọ àwọn ohun alààyè inú òkìtì abẹ́ òkun.

Ṣùgbọ́n ikú àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun yóò tún kan àwọn ohun alààyè orí ilẹ̀ lọ́nà tí kò bára dé. Ìwé ìròyìn Natural History sọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun fúnra wọn jẹ́ ìdí abájọ pàtàkì kan nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìyọrísí iṣẹ́ ilé ewéko, ó sì lè ṣe pàtàkì tó àwọn ẹgàn ilẹ̀ olóoru nínú dídín àwọn gáàsì ìyọrísí iṣẹ́ ilé ewéko kù. Bí wọ́n ṣe ń gbá èròjà calcium carbonate jọ pọ̀ fún ìkarawun wọn, àwọn coral ń gbá ọ̀pọ̀ afẹ́fẹ́ CO2 kúrò nínú agbami òkun. Láìsí èèhọ̀n zooxanthellae [èèhọ̀n tí coral ń bá gbé pọ̀ láti wà láàyè], ìwọ̀n carbon dioxide tí coral ń lò dín kù gan-an. Ó jẹ́ ẹ̀dà ọ̀rọ̀ pé bíba ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè abẹ́ omi yìí pẹ̀lú àyíká wọn jẹ́ lè mú kí ìgbésẹ̀ náà gan-an tí ń mú ikú rẹ̀ yá túbọ̀ yára kánkán.”

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà gbọ́ pé àwọn gáàsì míràn tí sísun nǹkan tú sílẹ̀ ń dá kún ìyọrísí iṣẹ́ ilé ewéko. Afẹ́fẹ́ nitrous oxide jẹ́ ọ̀kan, afẹ́fẹ́ chlorofluorocarbons (CFC) sì jẹ́ òmíràn. Ní ti gidi, molecule afẹ́fẹ́ CFC kọ̀ọ̀kan lágbára láti fa ooru mọ́ra ní ìlọ́po 20,000 bí molecule afẹ́fẹ́ CO2 kọ̀ọ̀kan ṣe lè ṣe. A tún ti dájú sọ àwọn afẹ́fẹ́ CFC gẹ́gẹ́ bíi kókó okùnfà sísọ ìpele ozone tí ń ṣíji bo àwọn ohun alààyè lọ́wọ́ ìtànṣán ultraviolet aṣèpalára di fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́. Afẹ́fẹ́ ozone Igun Àríwá àti ti Igun Gúúsù ti fẹ́lẹ́ tó láti lu ihò. Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú gbáà ni ìyẹn jẹ́ fún coral. Àwọn àyẹ̀wò tí ń ṣí ìwọ̀n kékeré òkìtì coral abẹ́ òkun tí omi lílọ́ wọ́ọ́rọ́ ti mú rọ tẹ́lẹ̀ payá sí ìwọ̀n àfikún ìmọ́lẹ̀ ultraviolet kékeré mú kí bíbó pọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn Scientific American kédàárò pé: “Kódà bí ìtújáde afẹ́fẹ́ chlorofluorocarbon bá tilẹ̀ dáwọ́ dúró lónìí, àwọn ìyípadà oníkẹ́míkà tí ń fa ìsọdìbàjẹ́ afẹ́fẹ́ ozone inú afẹ́fẹ́ àyíká ayé yóò máa bá a lọ fún ọ̀rúndún kan, ó kéré tán. Èrèdí rẹ̀ rọrùn: àwọn afẹ́fẹ́ náà ń wà pẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú afẹ́fẹ́ àyíká, wọn yóò sì máa bá a lọ ní fífọ́n ká láti ibi ìkójọ ìpele àkọ́kọ́ nínú afẹ́fẹ́ àyíká fún àkókò gígùn lẹ́yìn tí ìtújáde náà bá ti kásẹ̀ nílẹ̀.”

Ní ìpele ti ara ẹni, olúkúlùkù lè hùwà lọ́nà ìtóótun nípa ṣíṣàìfi pàǹtírí tàbí ohun ìbàyíkájẹ́ ba àwọn agbami òkun tàbí agbègbè etíkun jẹ́. Bí o bá ṣèbẹ̀wò sí òkìtì abẹ́ òkun, tẹ̀ lé ìkìlọ̀ láti má fọwọ́ kàn tàbí dúró lórí coral. Má ṣe mú tàbí ra àwọn ohun ìrántí tí a fi coral ṣe. Bí o bá ń wa ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ nítòsí òkìtì abẹ́ òkun ilẹ̀ olóoru, fi ìdákọ̀ró sọlẹ̀ sórí iyanrìn tàbí okùn ìdákọ̀ró tí àwọn aláṣẹ òkun ń pèsè. Má ṣe sáré àsápajúdé tàbí kí o fi apá ayíbírí ọkọ̀ rẹ rú ìsàlẹ̀ omi. Má ṣe da ẹ̀gbin inú ọkọ̀ sínú agbami òkun; wá àpápá tàbí èbúté tí yóò gbà á. Bill Causey, alábòójútó Looe Key National Marine Sanctuary (Florida, U.S.A.), sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ènìyàn ní ń dá ìṣòro tí ń fa àìbáradọ́gba náà sílẹ̀. Ó yẹ kí a máa fìrònú kíyè sí i kárí ayé. Bí a bá ń bá a lọ láti mú kí gbogbogbòò mọ̀ nípa ewu tí ó wà nínú pípàdánù ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pàtàkì kan pẹ̀lú àyíká wọn, bóyá, nígbà náà, a óò lè yí àwọn nǹkan padà.”

Ní ìpele ẹlẹ́kùnjẹkùn, a ti ń gbé àwọn òfin tí ń dáàbò bo àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun kalẹ̀, a sì ń mú wọn ṣẹ. Ìpínlẹ̀ Florida ń pe àwọn tí ó ni àwọn ọkọ̀ òkun tí ń ba òkìtì abẹ́ òkun rẹ̀ jẹ́ lẹ́jọ́. Àwọn tó ni ọkọ̀ òkun akẹ́rù kan tí ó hú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ saarè coral dà nù nígbà tí ó ń gúnlẹ̀ ti san mílíọ̀nù 6 dọ́là bí owó ìtanràn. Wọ́n lo apá kan lára owó náà láti tún dá ibùgbé abẹ́ òkun náà padà sípò. Ní báyìí, nípa lílo àwọn ohun alẹǹkanpọ̀ àrà ọ̀tọ̀, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè ń gbìyànjú láti tún lẹ coral tí ọkọ̀ òkun kan bà jẹ́ ní 1994 pọ̀ mọ́ra. Wọ́n ti tún bu owó ìtanràn, tí ó jẹ́ mílíọ̀nù 3.2 dọ́là míràn, fún ilé iṣẹ́ kan nítorí ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ òkun akẹ́rù rẹ̀ ba òkìtì abẹ́ òkun kan jẹ́ ní Florida. Àwọn orílẹ̀-èdè míràn ti ń ṣe irú òfin kan náà. Àwọn ibi ìmòòkùn gbígbajúmọ̀, irú bí Erékùṣù Cayman ní òkun Caribbean, ní àwọn ibi tí a ti gba ìmòòkùn láyè tí a pààlà sí. Australia ṣàgbékalẹ̀ Ọgbà Ohun Alààyè Abẹ́ Òkun ti Òkìtì Great Barrier Reef rẹ̀ láti bójú tó àwọn ìgbòkègbodò tí ń lọ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n bí gbogbo wa ti ṣe rí i, bí àwọn amòòkùn bá ṣe pọ̀ tó ni àwọn òkìtì abẹ́ òkun ṣe ń bà jẹ́ tó.

Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yóò Ha Dara Pọ̀ Nínú Ìsapá Náà Bí?

Ní ìpele kárí ayé, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn aṣáájú tí ọ̀ràn náà ń dá níjì parí èrò sí pé ojútùú náà kọjá agbára orílẹ̀-èdè kan tàbí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè kan. Ìbàyíkájẹ́ ń lọ kárí àgbáyé nípa ìgbì afẹ́fẹ́ àti omi tí ń yí po, ó sì ń nípa lórí àwọn òkìtì abẹ́ òkun náà. Àwọn orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan kò ní agbára kọjá orí omi tí ó wà ní ààlà ilẹ̀ wọn. Àwọn ohun abàyíkájẹ́ tí a dà sínú omi òkun gbalasa ń gúnlẹ̀ sí etíkun nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. A nílò ìsapá kárí ayé àti ojútùú àpawọ́pọ̀ ṣe.

Kò sí iyè méjì pé àwọn ènìyàn ọlọ́kàn rere tí wọ́n sì tóótun lágbàáyé yóò máa sapá nìṣó láti dáàbò bo àgbàyanu àwọn ohun àmúṣọrọ̀ coral ilẹ̀ ayé. Ó ṣe kedere pé a nílò ìjọba ayé kan tí ń dàníyàn, tí ó sì ń bìkítà nípa àyíká ilẹ̀ ayé gan-an. Ó múni láyọ̀ pé Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ yóò dá àyíká àgbáyé nídè. Nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn kíní, ó wí pé: “Kí wọn kí ó sì jọba lórí ẹja [àti gbogbo ohun alààyè inú omi] òkun.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Níwọ̀n bí Ọlọ́run kò ti fìyà jẹ àwọn ohun alààyè inú òkun, tí kò sì kó wọn nífà, aṣẹ rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ túmọ̀ sí pé kí ènìyàn bójú tó àyíká àgbáyé. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọ̀run tuntun [Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run] àti ilẹ̀ ayé tuntun kan wà tí àwá ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú àwọn wọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (Pétérù Kejì 3:13) Lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, ìṣàkóso ọ̀run yẹn yóò fọ ilẹ̀ ayé tí a ti sọ dìbàjẹ́ yìí mọ́ tónítóní, títí kan àwọn agbami òkun rẹ̀. Nígbà náà, àwọn olùgbé inú Ìjọba Ọlọ́run yóò bìkítà fún àwọn agbami òkun rírẹwà àti àwọn olùgbé inú wọn, wọn yóò sì gbádùn wọn ni kíkún.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwòrán apá ẹ̀yìn: Òkìtì coral abẹ́ òkun rírẹwà kan ní Òkun Ńlá Pacific, nítòsí Fiji

Àkìbọnú: 1. Àwòrán ẹja clown kan tí a sún mọ́ lábẹ́ omi, 2. àwòrán coral tí ó rí bíi tábìlì, 3. edé kan lórí coral

[Credit Line]

Àwòrán apá ẹ̀yìn ojú ìwé 18: Fiji Visitors Bureau

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́