Àyíká Òkìtì Ẹ̀dá Omi Abìlẹ̀kẹ̀ Jíjojúnígbèsè
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ PAPUA NEW GUINEA
ÀWỌN òkìtì ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ bo etíkun Papua New Guinea pátápátá. Látijọ́, ewu lásán ni àwọn awakọ̀ òkun kà wọ́n sí. Àmọ́ sí àwọn tí ń yẹ omi tó yí wọn ká wò kiri, àwọn òkìtì ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ jẹ́ ọ̀nà àbáwọlé sí àyíká ẹwà kíkọyọyọ, àwọ̀, àti ìtòròmini—ohun èlò kaleidoscope abẹ́ omi!
Ìgbìyànjú láti ya fọ́tò àyíká abẹ́ omi yìí ṣòro gan-an. Ohun kan ni pé, àwọn ohun tí ó wà lábẹ́ omi máa ń dà bí èyí tí ó jìnnà ní ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin bí wọ́n ṣe jìnnà sí ní gidi; nítorí náà, fífojú sùn wọ́n ṣòro. Omi máa ń gba ìmọ́lẹ̀ sára, ó máa ń fọ́n ọn ká, kì í sì í jẹ́ kí ó lọ tààrà. Àwọn àwọ̀ tún lè yàtọ̀ lọ́nà gíga ní ìbámu pẹ̀lú ojú ọjọ́, igun tí oòrùn wà, bóyà èèhọ̀n àti àwọn ohun alààyè ojú omi wà, jíjìn omi náà, àti ìrísí irú àwọ̀ tí ìsàlẹ̀ òkun náà ní. Borí gbogbo rẹ̀, omi náà, ohun tí a yà fọ́tò rẹ̀, àti ẹni tó ya fọ́tò náà kò dúró sójú kan!
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ayafọ́tò kan ti ṣàṣeyọrí díẹ̀ nínú ọ̀ràn yí. Ìgbà ìrìn àjò lábẹ́ omi ni a ya àwọn àwòrán tí ẹ rí níhìn-ín yìí. Ẹ jẹ́ kí a fi mẹ́rin lára àwọn ẹ̀dá fífanimọ́ra tí a ya fọ́tò wọn lábẹ́ ìgbì omi hàn yín.
Fọ́tò 1 fi olùgbé rírẹwà inú omi kan hàn tí ń jẹ́ tiger cowry (Cypraea tigris). Orúkọ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ níti pé àmì tóótòòtó ni bátànì ara ìkarawun rẹ̀ kíkọyọyọ ní, kì í ṣe ìlà. Ìhín ni a ti ń rí tiger cowry náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ àti àwọn sponge ni ó ń jẹ. Ó wu àwọn ará China ìgbàanì gan-an débi pé wọ́n ná ìkarawun rẹ̀ bí owó. Níhìn-ín ní Papua New Guinea, a ṣì ń fi ìkarawun cowry ṣe ṣẹ́ńjì ní àwọn ọjà ìbílẹ̀ kéékèèké kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, fún apá tí ó pọ̀ jù lọ, àwọn olùgbé ibẹ̀ ń kó wọn jọ kìkì nítorí ẹwà wọn dídán gbinrin.
Fọ́tò 2 ni ekòló oníhò aláwọ̀ rírẹwà (Spirobranchus giganteus). Ó lè máa jẹ òkú ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ tàbí kí ó gbẹ́ ihò sára ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ tí ó wà láàyè. Bí ó bá ń sinmi, ó máa ń dà bí òdòdó. Àmọ́ tí ebi bá ń pa á, ó máa ń lọ́ àwọn ẹ̀mú rẹ̀ pọ̀ roboto ṣe “àwọ̀n” tí yóò fi mú àwọn oúnjẹ tí ń kọjá lọ kíákíá. Pẹ̀lú àwọn ẹ̀mú rẹ̀ oníyẹ̀ẹ́ tí kò dúró lójú kan, ó dà bí ìlà àwọn oníjó tí ń ju àwọn abẹ̀bẹ̀ wọn. Ẹ̀dá yìí jẹ́ mìlímítà mẹ́wàá péré ní fífẹ̀. Àmọ́ ayàwòrán náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ó má baà mira lójijì. Bí wọ́n bá ti rí òye ewu àkọ́kọ́ pẹ́nrẹ́n, ní kíámọ́sá, àwọn ẹ̀dá rírẹwà wọ̀nyí ń ta bọ́n-ún wọ ilé wọn.
Fọ́tò 3 ni sponge. Ó jọ kànrìnkàn tí ń léfòó nínú agbada ìwẹ̀ rẹ níwọ̀nba. Ní gidi, sponge kan jẹ́ alààyè ẹranko kan, kì í ṣe ewéko. Ó jẹ́ ìṣùjọ oníhò ti àwọn sẹ́ẹ̀lì tí ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lọ́nà kan tí ó ní ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ jù lọ. Ìwé náà, The Undersea, sọ pé, ìṣètò àwọn sẹ́ẹ̀lì sponge náà kò sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbára lé ara wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, bí a bá ya sponge kan tí kò tí ì kú sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, apá kọ̀ọ̀kan yóò wá di sponge tuntun kan. Kódà bí a bá ya sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n ń lọ́ pọ̀ bí àwọn amoeba títí wọn óò fi pa pọ̀, tí wọn óò sì tún gbára jọ lẹ́ẹ̀kan sí i di àwọn sponge.”
Láìdàbí ewéko, tí ń ṣẹ̀dá oúnjẹ rẹ̀ fúnra rẹ̀, sponge “ń dọdẹ” wá oúnjẹ tirẹ̀ ni. Ó máa ń fa omi àyíká rẹ̀, yóò sì sẹ́ ẹ láti rí àwọn ohun ìṣẹ̀fọ́-ìṣẹran. Bíi ti ẹranko mìíràn, ó ń da oúnjẹ rẹ̀ nínú, ó sì ń yàgbẹ́. Ìwọ yóò rí àwọn sponge tí ó so mọ́ àwọn àpáta tàbí àwọn ìkarawun ní ìsàlẹ̀ òkun.
Níkẹyìn, nínú fọ́tò 4 ni clam tí a kò kà sí wà. Ó máa ń wà lójú kan, a sì lè tètè rí i nínú àwọn àpáta ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ tàbí kí ó wulẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ òkun. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ń jẹun nípa sísẹ́ àwọn ohun alààyè ojú omi kúrò nínú omi. A pe clam ní ẹran abìkarawun onídèérí méjì nítorí pé ó ní ìkarawun tàbí ìdérí méjì. Ìdè kan ló wà wọ́n pọ̀, àwọn iṣan lílágbára méjì kan sì ń ṣí i wọ́n sì ń bò ó. Bí clam kan bá ní láti gbéra, ó máa ń ṣíra payá, ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó ki fún ẹran yóò sì jáde síta níwọ̀nba. Ṣùgbọ́n bí ọ̀tá kan bá ń bọ̀, yóò kó wọnú ìkarawun rẹ̀!
Àwọn àwòrán wọ̀nyí wulẹ̀ fún wa ní ìran fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ológo tí a lè rí nínú àwọn òkun tí ó ní ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ nínú ni—ó tún jẹ́ ibòmíràn tí a ti fi ọgbọ́n ìṣẹ̀dá Jèhófà hàn.—Róòmù 1:20.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
1. A ṣì ń ná “tiger cowry” bí owó
2. Aràn oníhò ni àwọn “òdòdó” wọ̀nyí ní tòótọ́
3. Ẹranko ni “sponge,” kì í ṣe ewéko
4. Àwọn ohun alààyè ojú omi ni “clam” ń jẹ (a fi ẹnu rẹ̀ hàn)