Àwọn Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun Tí Ń kú—Ẹ̀dá Ènìyàn Ló Ṣokùnfà Rẹ̀ Bí?
ÀPÉRÒ Àgbáyé Lórí Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun ní 1992 sọ pé, ní tààrà tàbí láìṣe tààrà, àwọn ènìyàn ti fa ikú ìpín 5 sí 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òkìtì ohun alààyè abẹ́ òkun lágbàáyé, tí ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún mìíràn sì lè run láàárín 20 ọdún sí 40 ọdún tí ń bọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Clive Wilkinson ti Ẹ̀ka Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Òkun Ilẹ̀ Australia ṣe sọ, kìkì àwọn òkìtì abẹ́ òkun agbègbè àrọko ni ara wọn dá níwọ̀nba. Ìwé agbéròyìnjáde USA Today sọ pé àwọn agbègbè tí ìbàjẹ́ ti bá “àwọn òkìtì abẹ́ òkun ní Japan, Taiwan, Philippines, Indonesia, Singapore, Sri Lanka, àti Íńdíà ní Éṣíà; Kenya, Tanzania, Mòsáḿbíìkì, àti Madagascar ní Áfíríkà; àti ilẹ̀ Olómìnira Dominican, Haiti, Cuba, Jàmáíkà, Trinidad àti Tobago, àti Florida ní America nínú. Àwọn ohun tí ń fa ìmújooro náà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń gbé àwọn etíkun àti ìdàgbàsókè àwọn etíkun lọ́nà lílé kenkà jẹ́ àwọn kókó abájọ tí gbogbo wọn jùmọ̀ ní.”
Àwọn òkítì coral abẹ́ òkun sábà máa ń gbèrú nínú omi òkun tí ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù rẹ̀ wà láàárín ìwọ̀n 25 sí 29 lórí òṣùwọ̀n Celsius, ní sísinmi lórí ibi tí wọ́n wà. Ṣùgbọ́n ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù aláàlà tí coral tí ara rẹ̀ dá ní sún mọ́ ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù tí ń ṣekú pa a pẹ́kípẹ́kí. Ìlọsókè sí ìwọ̀n kan tàbí méjì kọjá ìwọ̀n gíga jù lọ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lè ṣokùnfà ikú. Nígbà tí a lè tọ́ka sí onírúurú okùnfà bíbó coral ládùúgbò kan àtí ikú rẹ̀ tí ń tẹ̀ lé e, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fura pé ìlọ́wọ́ọ́rọ́ àgbáyé lè jẹ́ okùnfà kan tí ó wọ́pọ̀ kárí ayé. Nípa ìparí èrò yìí, ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “Àwọn ìròyìn nípa bíbó coral ní 1987 ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú ìdàníyàn tí ń ga sí i nípa ìlọ́wọ́ọ́rọ́ àgbáyé. Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mélòó kan àti àwọn olùṣàkíyèsí mìíràn dé ìparí èrò pé àwọn òkìtì coral bára dọ́gba pẹ̀lú ẹyẹ ìbákà níbi ìwakùsà èédú—ìtọ́ka àkọ́kọ́ pé ìwọ̀n ooru inú agbami òkun àgbáyé ń lọ sókè. Bí ó tilẹ̀ jọ pé ìwọ̀n ooru omi òkun àdúgbò tí ń lọ sókè ń fa bíbó coral, síso àbájáde yìí pọ̀ mọ́ ìlọ́wọ́ọ́rọ́ àgbáyé kò tí ì lè jẹ́ ìparí èrò ní báyìí ná.”
Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ ní òkun Caribbean ti ṣètìlẹ́yìn fún àbá pé agbami òkun tí ó gbóná sódì ló fà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́.” Thomas J. Goreau, tí ń ṣolórí Ẹgbẹ́ Alájọṣe Nípa Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun Lágbàáyé, ṣàfiwéra ìṣòro àwọn òkìtì náà pẹ̀lú ẹgàn Amazon tí ń pa rẹ́ lọ lọ́nà àìní ìfojúsọ́nà fún rere. Ó sọ pé: “Àwọn ẹgàn díẹ̀ yóò ṣì wà ní àádọ́ta ọdún sí i, ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n tí àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun fi ń kú báyìí, wọn kò lè wà pẹ́ tó bẹ́ẹ̀.”
Ìparun Kárí Ayé—Okùnfà Jaburata
Ní àwọn Etíkun Pacific ti Àárín Gbùngbùn America, iye tí ó tó ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún coral rẹ̀ kú ní 1983. Bíbó tí ó jọra, ṣùgbọ́n tí kò ṣèparun tó bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní àkókò kan náà ní àárín gbùngbùn àti ìhà ìwọ̀ oòrùn Pacific. Bíbó kíkàmàmà ṣẹlẹ̀ ní òkìtì Great Barrier Reef ti Australia àti àwọn agbègbè agbami òkun Pacific àti Íńdíà. Ìròyìn ìbàjẹ́ tún wá láti Thailand, Indonesia, àti àwọn Erékùṣù Galápagos. Lẹ́yìn náà, bíbó lọ́pọ̀ yanturu ṣẹlẹ̀ nítòsí Bahamas, Colombia, Jàmáíkà, àti Puerto Rico pa pọ̀ mọ́ ìhà gúúsù Texas àti Florida, ní U.S.A.
Ọ̀nà kan tí àwọn òkìtì abẹ́ òkun kárí ayé ń gbà pa run bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú. Ìwé ìròyìn Natural History sọ pé: “Láàárín ìwọ̀n àkókò kúkúrú tí a ti fi ṣèwádìí nípa ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn bí ó ṣe kan àwọn òkìtì abẹ́ òkun, a kò tí ì rí bíbó tí ìwọ̀n rẹ̀ tó ti lọ́ọ́lọ́ọ́. Peter Glynn, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè ní Yunifásítì Miami, ti ṣàyẹ̀wò àwọn coral tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ 400 ọdún ní ìhà ìlà oòrùn Pacific tí ó bó lọ́nà kíkàmàmà, kò sì rí ẹ̀rí pé irú ìjábá bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Bíbó kíkàmàmà náà tọ́ka sí i pé ìmóoru rẹpẹtẹ láàárín àwọn ọdún 1980 lè ti ní ipa lílé kenkà lórí àwọn òkìtì coral abẹ́ òkun, wọ́n sì lè ti máa sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn òkìtì abẹ́ òkun lọ́jọ́ iwájú, bí ìyọrísí iṣẹ́ ilé ewéko bá tún yọrí sí ìwọ̀n ooru púpọ̀ sí i. Ó bani nínú jẹ́ pé ìlọ́wọ́ọ́rọ́ àgbáyé àti ìbàjẹ́ ìwúlò àyíká yóò máa bá a lọ, yóò sì túbọ̀ burú sí i, ní mímú kí ìṣẹ̀lẹ̀ bíbó rẹ̀ lágbàáyé túbọ̀ máa ṣe lemọ́lemọ́ sí i.”
Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report tọ́ka sí ohun tí ó tún lè jẹ́ okùnfà míràn pé: “Sísọ tí a ń sọ ìpele ozone tí ń ṣíji bo àwọn ohun alààyè lọ́wọ́ ìtànṣán ultraviolet di fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tún lè gba díẹ̀ lára ẹ̀bi ìparun àwọn òkìtì abẹ́ òkun tí ó ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́.”
Ní àwọn agbègbè etíkun, níbi tí iye tí ó lé ní ìdajì ènìyàn àgbáyé ń gbé, àìtóótun ẹ̀dá ènìyàn ti mú ipò nǹkan burú sí i gidigidi fún àwọn òkìtì abẹ́ òkun. Ìwádìí kan tí Àjọ Ìdáàbòbò Lágbàáyé àti Ètò Àbójútó Àyíká ti Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe rí i pé àwọn ènìyàn ti ṣèpalára fún ọ̀pọ̀ òkìtì abẹ́ òkun ní orílẹ̀-èdè 93 tàbí wọ́n tilẹ̀ ti pa wọ́n run. Ọ̀pọ̀ àwọn agbègbè tí ń gbèrú ń ṣan àwọn ìdọ̀tí tí a kò ṣètọ́jú dà sínú agbami òkun, tí ń kó èérí bá a.
A ti ń gé àwọn igi tí ń gbilẹ̀ nínú omi oníyọ̀, tí wọ́n sì ń sẹ́ èérí kúrò, a ń fi wọ́n ṣe gẹdú àti igi ìdáná. A ń fa àwọn òkìtì abẹ́ òkun ya, a sì ń wa kùsà wọn, fún àwọn ohun èèlò ìkọ́lé. Ní Sri Lanka àti Íńdíà, àwọn apá mélòó kan lára àwọn òkìtì abẹ́ òkun ni a ti lọ̀ fi ṣe sìmẹ́ńtì. Àwọn ọkọ̀ ojú omi ńláńlá àti àwọn kéékèèké ń ju ìdákọ̀ró sórí òkìtì abẹ́ òkun tàbí kí wọ́n dúró lé wọn lórí, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́.
Ìwé ìròyìn National Geographic ṣàpèjúwe ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní Ọgbà Òkìtì Coral Abẹ́ Òkun John Pennekamp ti Orílẹ̀-Èdè ní Florida pé: “Àwọn ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ wọn ń ba omi náà àti gbogbo ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀ jẹ́ pẹ̀lú àwọn ohun àṣemújáde epo rọ̀bì àti ẹ̀gbin tí wọ́n ń kó dà nù. Àwọn afẹ̀rọṣiṣẹ́ tí kò péjú owó ń rọ́ lu àwọn òkìtì abẹ́ òkun. Wọ́n ń fi àwọn ife oníke, agolo aláyọ́, gíláàsì, àpò oníke, ìgò, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn okùn ìpẹja tí a tò lọ rẹrẹẹrẹ dọ̀tí òkun náà. Pàǹtírí yìí kì í lọ—ní kedere, ilẹ̀ rẹ̀ kò ṣeé pa mọ́.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda onínúure Australian International Public Relations
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]
Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda onínúure Bahamas Ministry of Tourism