Ìrírí Agbonijìgì Tí Maggy Ní àti Ìbùkún Mi
Tuesday, May 2, 1995, ni a bí ọmọbìnrin mi, tí ìyàwó mí sì kú. Ó bani nínú jẹ́ pé Maggy kò rí ojú ọmọ rẹ̀ rí. Ìrètí mi nísinsìnyí ni láti fi Tamara han ìyá rẹ̀ nígbà tí ó bá jíǹde.
LẸ́YÌN ọdún 16 tí a ti ṣègbéyàwó, dókítà ìyàwó mi, Maggy, sọ fún un pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú, kò sì lè wà láàyè ju ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ lọ. Ìyẹ́n jẹ́ ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn. Ọpẹ́ ni pé Maggy lè gbé ìgbésí ayé bí ó ṣe yẹ kí ó rí láàárín àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀ wọ̀nyẹn. Kìkì nígbà tí òpin náà dé tán ni ìrora náà di èyí tí kò ṣeé mú mọ́ra mọ́.
Nítorí bí àrùn ọmú rẹ̀ ṣe gbilẹ̀ tó, àwọn dókítà sọ pé àǹfààní tí ó ní láti lóyún kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Nítorí náà, o lè wo bí ó ti múni gbọ̀n rìrì tó nígbà tí wọ́n rí ọmọ kan nínú ilé ọlẹ̀ rẹ̀ ní àkókò àyẹ̀wò àtìgbàdégbà onílànà ìró ultrasound kan láti mọ bí àwọn ìwúlé àrùn jẹjẹrẹ náà ti ṣe sí! Ọmọbìnrin ni. Oyún náà ti di oṣù mẹ́rin àti ààbọ̀ níkùn Maggy. Ó kún fún ìdùnnú pẹ̀lú ìrètí dídi ìyá kan fún ìgbà àkọ́kọ́.
Maggy ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láìkù síbì kan láti rí i dájú pé ọmọ tí òun yóò bí náà ní ìlera. Ó ṣọ́ oúnjẹ jẹ, kódà láàárín ọ̀sẹ̀ méjì tí ó kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, nígbà tí ìrora náà di aronigógó, ìgbà tí kò bá lè pa á mọ́ra mọ́ nìkan ni ó ń lo àwọn egbòogi apàrora.
A Bù Kún Wa Pẹ̀lú Abarapá Ọmọ Kan
Ní Saturday, April 29, ọkàn-àyà Maggy ń yára lù kìkì lóolelóole, ó sì wí pé: “Mo rò pé n óò kú.” Mo dúró tì í ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn tí mo tẹ dókítà láago ní Monday, mo gbé e lọ sílé ìwòsàn ní Montreal, Kánádà, tí kò jìnnà sílé wa ní St. Jérôme, lọ́gán.
Ní nǹkan bí agogo 5:30 òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, nọ́ọ̀sì kán kọjá lẹ́nu ọ̀nà iyàrá Maggy, ó sì rí i pé ó ń jẹ̀rora. Ó ṣe kedere pé ó ní ìkọlù àrùn ọkàn-àyà. Wọ́n ké sí dókítà kan láti iyàrá tí ó gbè é. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Maggy kú, ó ṣeé ṣe fún agbo àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn náà láti gba ọmọ wa là. A bí Tamara nígbà tí ó ku oṣù méjì àti ààbọ̀ kí oṣù rẹ̀ pé, ó sì wọn kìkì kìlógíráàmù 1.1.
Níwọ̀n bí ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ ara Tamara ti kéré, àwọn dókítà ń fẹ́ láti fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Bí ó ti wù kí ó rí, a fún wọn níṣìírí láti lo omi ìsúnniṣe àtọwọ́dá erythropoietin. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà tí lílo àṣemújáde yìí sì kẹ́sẹ járí ní mímú kí ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ lọ sókè, nọ́ọ̀sì kán wí pé: “Wọn kò ṣe máa lo ìyẹn fún gbogbo àwọn ọmọdé?”
Tamara kojú àwọn ìṣòro mìíràn tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ tí oṣù wọn kò pé, ṣùgbọ́n gbogbo ìwọ̀nyí yanjú. Ní tòótọ́, nígbà tí Dókítà Watters, onímọ̀ nípa ètò ìgbékalẹ̀ àti àrùn iṣan ara kán, yẹ̀ ẹ́ wò lẹ́yìn náà, ó sọ fún nọ́ọ̀sì náà pé: “Mo rò pé o ṣi ọmọ gbé fún mi láti yẹ̀ wò; kò sí ohun kankan tí ó ṣe eléyìí bí mo ṣe rí i yìí.”
Kíkojú Ikú àti Mímú Ara Bá Ipò Mu Lẹ́yìn-Ọ̀-Rẹyìn
Kò rọrùn fún mi láti máa wo Maggy bí ó ṣe ń kú lọ. Mo nímọ̀lára àìnírànwọ́. Ó ṣòro fún mi gan-an láti sọ̀rọ̀ nípa ikú Maggy. Síbẹ̀, mo ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mí wá sílé ìwòsàn. Díẹ̀díẹ̀, ìrora náà ń lọ sílẹ̀ bí mo ti ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tó. Nígbàkigbà tí mo bá ka àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tí ó kàn mí ní pàtàkì, mo máa ń fi sí ẹ̀gbẹ́ kan ní ìhà kékeré kan tí ó jẹ́ ti ara ẹni níbi ìkówèésí mi, tí mo sì máa ń mú un jáde, tí mo sì máa ń kà á nígbà tí mo bá rí i pé mo nílò rẹ̀.
Ìṣòro gbígbàfiyèsí mìíràn ni wíwá sínú ilé ṣíṣófo kan. Kò rọrùn láti kojú ìdánìkanwà. Mo ṣì ń ní ìmọ̀lára yìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ń jàǹfààní ìkẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni tí ń gbéni ró. Èmi àti Maggy jọ máa ń ṣe gbogbo nǹkan pọ̀ tẹ́lẹ̀ ni, a sì jíròrò ìṣòro tí mo lè ní pẹ̀lú ìdánìkanwà. Ó fẹ́ kí n tún gbéyàwó. Síbẹ̀, nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn.
Ìtìlẹ́yìn Àwọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ́ Mi
N kò mọ bí ǹ bá ti ṣe é, ká ní kò sí ìtìlẹ́yìn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí Maggy kú, Ẹlẹ́rìí kan tí ó ní ìmọ̀ gidigidi lára Ìgbìmọ̀ HLC wà níbẹ̀, nílé ìwòsàn, ó sì pèsè ìrànwọ́ tí mo nílò fún mi.
Ìrànwọ́ tí ìjọ Kristẹni wa ní St. Jérôme àti àwọn ìjọ mìíràn ní àdúgbò náà ṣe fún mi jọ àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà lójú. Ní alẹ́ tí wọ́n kéde ikú Maggy ní ìpàdé Kristẹni wa, ó lé ní 20 àwọn ará ọ̀wọ́n tí wọ́n dáhùn padà nípa ṣíṣe ìrànlọ́wọ́. Ìtìlẹ́yìn náà kọ yọyọ ní gidi.
Àwọn ará gbọ́únjẹ fún mi; àyè ibi ìmúǹkandì nínú fìríìjì mí kún bámúbámú fún ọ̀pọ̀ oṣù. Ìdílé mi àti àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin tilẹ̀ bójú tó pípèsè aṣọ fún ọmọbìnrin mi pẹ̀lú. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ nǹkan wá fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí n kò ní ibi tí mo lè pa gbogbo wọn mọ́ sí tán.
Ìmọ̀lára Ìtẹ́lọ́rùn Nísinsìnyí àti Lọ́jọ́ Iwájú
Tamara ń jẹ́ kí n lè máa gbọ́kàn fo àdánù mi. Ó ti gba gbogbo ìfẹ́ àti ìfẹ́ni ọkàn-àyà mi pátápátá. Lójoojúmọ́, tí mo bá kí i “káàárọ̀” tẹ̀rín-tọyàyà, òun náà yóò rẹ́rìn-ín padà, yóò bẹ̀rẹ̀ sí í “sọ̀rọ̀,” yóò sì máa jupá-jusẹ̀, tìdùnnútìdùnnú.
Gẹ́gẹ́ bí afìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ṣènàjú kan, mo ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí n óò gbé Tamara sẹ́sẹ̀ mi, kí ó lè fi awò awọ̀nàjíjìn mi wo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wá, Jèhófà, ṣe sí ojú ọ̀run. Ríronú nípa ìwàláàyè láìlópin nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ orísun tòótọ́ fún ìtùnú. Láti mọ̀ pé èyí ni ìrètí tí ń bẹ níwájú Tamara ń fún mi ní àfikún ìmọ̀lára ìtẹ́lọ́rùn.—Orin Dáfídì 37:9-11, 29.
Ní ríronú padà lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún márùn-ún tí ó kọjá yìí, mo lè júwe wọn dáradára jù lọ gẹ́gẹ́ bí adanilọ́kànrú àti onídùnnú. Mo ti kọ́ ohun púpọ̀ nípa ara mi àti ìgbésí ayé fúnra rẹ̀. Mo ń fi ìháragàgà dúró de ọjọ́ iwájú náà, nígbà tí “ikú kì yóò . . . sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́,” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe júwe rẹ̀.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Nígbà náà, nígbà àjíǹde, Maggy yóò lè mí délẹ̀ láìsí ìrora. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìrètí àti ìfẹ́ ọkàn mi tí ó fìdí múlẹ̀ gbọnyingbọnyin jù lọ ni láti wà níbẹ̀, kí n sì fi Tamara han Maggy, kí ó lè rí ọmọbìnrin kékeré náà, tí òún ti ṣe ohun ribiribi tó bẹ́ẹ̀ nítorí rẹ̀.—Gẹ́gẹ́ bí Lorne Wilkins ṣe sọ ọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Pẹ̀lú aya mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọmọbìnrin wa, Tamara