ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 12/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jíjínigbé ní Latin America
  • Níní Ẹ̀mí Nǹkan Yóò Dára Lè Gbé Ìlera Lárugẹ
  • Àwọn Ọmọdé Tí Ó Tẹ̀wọ̀n Jù
  • Afẹ́fẹ́ Búburú
  • Ìbẹ́sílẹ̀ Àrùn Lọ́rùnlọ́rùn Níhà Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà
  • A Kò Fòfin De Ohun Abúgbàù Abẹ́lẹ̀
  • Ìyáradipúpọ̀ Àwọn Ìlú Ńlá
  • “Ìṣẹ̀dá Ló Mọ̀ Ọ́n Ṣe Jù Lọ”
  • Fífi Ọkọ̀ Ojú Omi Sáré Àsápajúdé
  • A Rí I—Ọkọ̀ Ojú Omi Tí Ó Pẹ́ Tó 2,000 Ọdún
  • Mímú Ìdàgbàsókè Bí Ó Ṣe Yẹ Dájú
  • Bí Ogun Ṣe Ń ṣe Àwọn Ọmọdé Níṣekúṣe
    Jí!—1997
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Òwò Àwọn Apanilẹ́kún-Jayé
    Jí!—2000
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Ǹjẹ́ Ojútùú Kan Tiẹ̀ Wà?
    Jí!—2000
  • Ìbẹ̀rù—Ó Wọ́ Pọ̀ Nísinsìnyí Ṣùgbọ́n Kì Yóò Jẹ́ Títí Láé!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 12/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Jíjínigbé ní Latin America

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Argentina náà, Ámbito Financiero, ṣe wí, jíjínigbé ti di òwò tí ń mówó rẹpẹtẹ wọlé ní Latin America. Láàárín ọdún 1995, a ròyìn nǹkan bí 6,000 ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé níbẹ̀. Ìwádìí kan tí a ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé Colombia ni ó ní iye tí ó pọ̀ jù lọ pẹ̀lú níní iye tí ó jẹ́ 1,060 ìjínigbé láàárín ọdún 1995, tẹ̀ lé e ni Mexico, Brazil, àti Peru, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìṣẹ̀lẹ̀ láàárín sáà kan náà. Lọ́dọọdún, àwọn ajínigbé ará Colombia ń gba nǹkan bí 300 mílíọ̀nù dọ́là bí owó ìràpadà. Ní Brazil, owó tí wọ́n san fún àwọn ajínigbé di ìlọ́po mẹ́ta láàárín ọdún 1995, ó dé àròpọ̀ nǹkan bíi bílíọ̀nù kan dọ́là. Àwọn tí wọ́n ń jí gbé lè jẹ́ olówó tí ó sì lókìkí tàbí wọ́n lè jẹ́ kòlàkòṣagbe arìnrìn àjò afẹ́ tàbí àwọn ìyàwó ilé láti àwọn ìdílé tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn ajínigbé máa ń ṣe tán láti gba owó ìràpadà náà díẹ̀díẹ̀. Nígbà míràn, nítorí ìbẹ̀rù pé wọ́n lè tún jí wọn gbé, àwọn tí wọ́n jí gbé náà kì í ṣíwọ́ sísan owó ìràpadà náà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti dá wọn sílẹ̀.

Níní Ẹ̀mí Nǹkan Yóò Dára Lè Gbé Ìlera Lárugẹ

Ìwádìí kan tí a ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ní Finland tún fìdí ìgbàgbọ́ náà múlẹ̀ pé àìlẹ́mìí nǹkan yóò dára lè dá kún àìlera ti èrò orí àti ti ara ìyára, nígbà tí níní ẹ̀mí nǹkan yóò dára lè gbé ìlera lárugẹ. Nǹkan bí 2,500 ọkùnrin, tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún 42 sí 60, ni a fi ṣe àyẹ̀wò tí ó gba ọdún 4 sí 10 náà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Science News ṣe wí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ròyìn pé àwọn ọkùnrin tí ó ní “àìnírètí níwọ̀nba àti lọ́pọ̀lọpọ̀ ń kú . . . ní ìwọ̀n ìlọ́po méjì tàbí mẹ́ta àwọn tí ó ní ìwọ̀n ìrètí díẹ̀ tàbí tí kò ṣaláìnírètí; àwọn ti ìṣáájú tún ní àrùn jẹjẹrẹ àti ìkọlù àrùn ọkàn-àyà tí ó túbọ̀ ṣe lemọ́lemọ́.”

Àwọn Ọmọdé Tí Ó Tẹ̀wọ̀n Jù

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Weekend Australian ṣe wí, Dókítà Philip Harvey, onímọ̀ nípa oúnjẹ tí ń dá kún ìlera àwọn aráàlú, kéde láìpẹ́ yìí pé “àwọn ọmọdé ilẹ̀ Australia ń sanra sí i, wọ́n sì ń yára kánkán sanra sí i ni.” Ó gbé ìdàníyàn rẹ̀ karí ìwádìí kan tí a ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́, tí ó fi hàn pé ìpíndọ́gba àwọn ọmọdé tí ó tẹ̀wọ̀n jù ní Australia ti di ìlọ́po méjì láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá. Nǹkan bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún 9 sí 15 nílò ìtọ́jú ìṣègùn nítorí ìṣòro ìtẹ̀wọ̀n wọn. Dókítà Harvey gbà gbọ́ pé ìwọ̀n ìpín ọ̀rún àwọn ọmọdé tí wọ́n tẹ̀wọ̀n jù tún lè di ìlọ́po méjì láàárín ọdún mẹ́wàá tí ń bọ̀. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé, bí ó ṣe rí láàárín àwọn àgbàlagbà, kókó ìpìlẹ̀ fún sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ láàárín àwọn ọmọdé ni àìmáaṣeré ìmárale, jíjẹ àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá púpọ̀ sì tún jẹ́ kókó abájọ kan.

Afẹ́fẹ́ Búburú

Àjọ Abójútó Àwọn Ohun Alààyè Tí A Kò Fi Dọ́sìn Lágbàáyé (WWF) ti parí èrò sí pé èròjà benzene abafẹ́fẹ́jẹ́, tí àwọn ohun ìrìnnà máa ń tú jáde, tí a fura sí pé ó máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ, ti ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́ ní Róòmù. Àwọn olùṣèwádìí tí àjọ WWF ń lò múra fún àwọn 400 ọ̀dọ́ olùyọ̀nda ara ẹni tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún 8 sí 18 pẹ̀lú àwọn ìhùmọ̀ tí ń dá èròjà benzene mọ. Ìwádìí náà fi hàn pé ní Róòmù, “ìpíndọ́gba máíkírógíráàmù 23.3 èròjà benzene wà nínú afẹ́fẹ́ ìwọ̀n gígùn, òró àti ìbú mítà kan [ẹsẹ̀ bàtà 35]” kọ̀ọ̀kan, iye tí ó pọ̀ púpọ̀ ju òòté máíkírógíráàmù 15 tí ó bófin mu fún ìwọ̀n gígùn, òró àti ìbú mítà kọ̀ọ̀kan. Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Ítálì náà, La Repubblica, ròyìn pé lórí ìwádìí yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàlàyé pé wíwulẹ̀ mí èémí afẹ́fẹ́ búburú ní Róòmù fún ọjọ́ kan dọ́gba pẹ̀lú mímu sìgá 13.

Ìbẹ́sílẹ̀ Àrùn Lọ́rùnlọ́rùn Níhà Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà

Ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ròyìn pé ó lé ní 100,000 ènìyàn tí ó ti daláìsàn nínú ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbẹ́sílẹ̀ àrùn àkóràn tí ó burú jù lọ ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, iye ènìyàn tí ó lé ní 10,000 sì ti kú. Àrùn lọ́rùnlọ́rùn tí bakteria ń fà ti jà gan-an ní ẹkùn ilẹ̀ eléruku, tí ó wà ní ìhà gúúsù Aṣálẹ̀ Sàhárà, níbi tí àwọn àrùn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú èémí ti wọ́pọ̀. Àrùn náà máa ń fa ìwúlé nínú awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí ó bo ọpọlọ àti nínú okùn ògooro ẹ̀yìn. Afẹ́fẹ́ ní ń tàn án kálẹ̀—wíwúkọ́ tàbí sísín lẹ́ẹ̀kán lè tàn án ká. A lè fi abẹ́rẹ́ àjẹsára dènà àrùn náà, a sì lè fi oògùn agbógunti kòkòrò àrùn wò ó sàn, ní pàtàkì, nígbà tí ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Agbẹnusọ kan fún Àjọ Àwọn Dókítà Tí Kò Láàlà Ìpínlẹ̀ sọ pé: “Àjàkálẹ̀ àrùn lọ́rùnlọ́rùn tí ó ṣẹlẹ̀ ní 1996 ni ó tí ì burú jù lọ ní apá ìsàlẹ̀ Sàhárà ilẹ̀ Áfíríkà.” Ó fi kún un pé: “Iye àwọn tí ń kú wulẹ̀ ń pọ̀ sí i ni.”

A Kò Fòfin De Ohun Abúgbàù Abẹ́lẹ̀

Lẹ́yìn ìjíròrò ọlọ́dún méjì ní Geneva, Switzerland, àwọn olùyanjú ọ̀ràn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdé kùnà láti fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìfòfin de ohun abúgbàù abẹ́lẹ̀ lágbàáyé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pinnu láti fòfin de àwọn oríṣi ohun abúgbàù kan, a kò tún níí jíròrò ìfòfindè pátápátá lórí àwọn ohun abúgbàù, títí di ìgbà ìpàdé ìjíròrò ìṣàtúnyẹ̀wò tí ń bọ̀, tí wọ́n dájọ́ rẹ̀ sí ọdún 2001. Ní báyìí ná, gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé kan ṣe fi hàn, láàárín àkókò ọdún márùn-ún náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ohun abúgbàù abẹ́lẹ̀ pa 50,000 ènìyàn míràn, kí ó sì sọ 80,000—tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n jẹ́ ará ìlú lásán—di aláàbọ̀ ara. Ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Washington Post kédàárò lórí ìpinnu náà, ó wí pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ohun abúgbàù nípamọ́ ka àwọn ohun ìjà wọ̀nyí sí ohun wíwuni lọ́nà gíga jù lọ, láìka iye àwọn ará ìlú rẹpẹtẹ tí ó sì ń pọ̀ sí i tí wọ́n ń pa lẹ́yìn tí àwọn ìforígbárí tí a tìtorí wọn rì wọ́n mọ́lẹ̀ bá ti parí sí.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìdíyelé kan tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdé ṣe, nǹkan bí 100 mílíọ̀nù àwọn ohun abúgbàù ni a rì mọ́lẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè 68 lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.

Ìyáradipúpọ̀ Àwọn Ìlú Ńlá

Ìtẹ̀jáde The State of World Population 1996, ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ròyìn pé, àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ń kó lọ sí àwọn ìlú ńláńlá. Láàárín ọdún mẹ́wàá sí i, àwọn tí ń gbé ìlú ńláńlá lágbàáyé yóò pé bílíọ̀nù 3.3, tí ó jẹ́ nǹkan bí ìdajì 6.59 bílíọ̀nù ènìyàn tí a fojú bù pé yóò wà lágbàáyé nígbà náà. Ní 1950, iye àwọn ìlú ńláńlá tí ó ní iye ènìyàn tí ó lé ní mílíọ̀nù kan jẹ́ 83. Lónìí, wọ́n lé ní 280, iye kan tí a retí pé yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po méjì nígbà tí ó bá fi máa di ọdún 2015. Ní 1950, New York City nìkan ni àwọn olùgbé rẹ̀ lé ní mílíọ̀nù 10; lónìí, irú àwọn ìlú ńláńlá bẹ́ẹ̀ 14 ló wà, tí Tokyo sì ní èrò púpọ̀ jù lọ, mílíọ̀nù 26.5.

“Ìṣẹ̀dá Ló Mọ̀ Ọ́n Ṣe Jù Lọ”

Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé: “Ìṣẹ̀dá ló mọ ilẹ̀ pa mọ́ jù lọ nígbà tí epó bá tú dà sómi.” Àwọn alágbàwí ààbò ẹ̀dá bẹ̀rù ìṣẹ̀lẹ̀ aburú nípa àyíká ní 1978, nígbà tí ọkọ̀ epo tí ń jẹ́ Amoco Cadiz fọ́ ní ìhà etíkun Brittany, ní àríwá ilẹ̀ Faransé. Àwọn aláṣẹ àdúgbò lo oṣù mẹ́fà láti kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún tọ́ọ̀nù ẹrọ̀fọ̀ àti ilẹ̀ àfọ̀ tí epó ti sọ di eléèérí kúrò ní àdúgbò kan. Àdúgbò míràn tí ó di eléèérí lọ́nà gígadabú wà níbẹ̀ láìsí àtúnṣe. Ṣíṣe ìfiwéra àwọn méjèèjì nísinsìnyí fi hàn pé àwọn àwùjọ tí ó ṣe iṣẹ́ àtúnṣe náà kó ọ̀pọ̀ ẹrọ̀fọ̀ àti ilẹ̀ àfọ̀ kúrò tó bẹ́ẹ̀ tí èyí tí ó tó ìpín 39 nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ àfọ̀ kò lè hu koríko mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àdúgbò tí a kò fọwọ́ kàn náà, ìgbì omi òkún ti wẹ ẹrọ̀fọ̀ náà mọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí àfikún ìpín 21 nínú ọgọ́rùn-ún ewéko fi tún ń gbilẹ̀ sí i nísinsìnyí ju bí ó ṣe wà ṣáájú ìtúdànù epo náà lọ. Ilẹ̀ àfọ̀ náà yí i dá pátápátá, a kò sì rí àmì pé epó ti tú dà síbẹ̀ rí mọ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún wá.

Fífi Ọkọ̀ Ojú Omi Sáré Àsápajúdé

Àwọn ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ ojú omi tí a mọ̀ sí kẹ̀kẹ́ ológeere ojú omí túbọ̀ ń lókìkí sí i ní United States. Àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké wọ̀nyí lè sáré tó 100 kìlómítà ní wákàtí kan, wọ́n sì ṣeé darí bí alùpùpù. Ohun tí ń fa àníyàn gidigidi ni iye àwọn ìjàm̀bá eléwu tí ń pọ̀ sí i, tí ń ṣekú pani nígbà míràn, tí ń kan àwọn ọkọ̀ ojú omi wọ̀nyí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal ṣe sọ, a fojú díwọ̀n pé “àwọn aláyàálò ní ń fa iye tí ó pọ̀ tó ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìjàm̀bá náà.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń wọ ọkọ̀ náà ní ń wọ ẹ̀wù amúniléfòó gẹ́gẹ́ bí òfín ṣe là á sílẹ̀, púpọ̀ nínú wọn kò nírìírí púpọ̀ nínú ìlànà ìṣe títu ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì ń fi àwọn ọkọ̀ náà sáré àsápajúdé. Ẹ̀ṣọ́ Etíkun kán ṣàlàyé pé, “nígbà tí ẹnì kan bá ń tukọ̀ ojú omi náà lọ lórí eré 80 kìlómítà láàárín wákàtí kan, ipá tí ó ń ní nígbà tí ó bá lu omí dà bíi ti alùpùpù tí ń sáré bákan náà, tí ó forí sọ ilé kan.”

A Rí I—Ọkọ̀ Ojú Omi Tí Ó Pẹ́ Tó 2,000 Ọdún

Omi Òkun Gálílì tí ó gbẹ ju ti ìgbàkigbà rí lọ ní 1986 fi ọkọ̀ ojú omi kan tí ó ti wà láti ìgbà ayé Jésù hàn. Láti ìgbà náà, ọkọ̀ náà ti mù sínú ohun kan tí ó dáàbò bò ó láti mú kí ìbàjẹ́ rẹ̀ falẹ̀. Ìwé ìròyìn National Geographic ròyìn pé, ní báyìí, a ti gbé e kúrò nínú ohun tí kò jẹ́ kí ó tètè bà jẹ́ náà, a sì ti pàtẹ rẹ̀ fún àfihàn lẹ́bàá ìlú Magdala. Shelley Wachsmann, tí ó jẹ́ aṣáájú fún àwọn tí ó lọ hú u jáde, ṣàlàyé pé: “Ó gùn ní nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà 27 [mítà 8], pẹ̀lú àwọ̀n ìpẹja ńlá kan, yóò sì ti nílò atukọ̀ mẹ́rin àti olùdarí ọkọ̀ kan.” Ó fi kún un pé: “Ó kéré tán, oríṣi igi méje la fi gbẹ́ ẹ, títí kan àwọn àfọ́kù láti ara àwọn ọkọ̀ tí ó ti pẹ́ jù ú lọ. Bóyá nítorí pé igí ṣọ̀wọ́n tàbí nítorí pé ẹni tí ó ni ín tálákà púpọ̀.”

Mímú Ìdàgbàsókè Bí Ó Ṣe Yẹ Dájú

Ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde Jornal do Brasil sọ pé ohun tí ń nípa lórí ìdàgbàsókè ọmọ kán ju ànímọ́ àjogúnbá lọ. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Oúnjẹ dídára ni ìdánilójú pàtàkì jù lọ pé ìdàgbàsókè yíyẹ yóò ṣẹlẹ̀,” pẹ̀lú àfikún pé àìdára oúnjẹ wọ́pọ̀ láàárín àwọn ìdílé kòlàkòṣagbe pàápàá. Amélio Godoy Matos, ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ nípa ẹṣẹ́ tí ń tú àwọn èròjà ara sínú ẹ̀jẹ̀, sọ pé: “Ohun mìíràn tí ń gbé ìdàgbàsókè ga ni ṣíṣe eré ìmárale déédéé.” Ó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ọmọ́ sùn láìsí ìdílọ́wọ́, nítorí pé, omi ìsúnniṣe ìdàgbàsókè máa ń tú jáde nígbà tí ọmọ́ bá wà lójú oorun nìkan.” Bákan náà, àwọn ìṣòro tí ó kan èrò ìmọ̀lára lè mú kí ìdàgbàsókè ọmọ kán falẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Walmir Coutinho, tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹṣẹ́ tí ń tú àwọn èròjà ara sínú ẹ̀jẹ̀, ṣe sọ, “wíwo tẹlifíṣọ̀n láìpajúdà fún wákàtí púpọ̀ léwu fún oorun ọmọdé, ní pàtàkì, bí ó bá ń wo àwọn fíìmù oníwà ipá, ó sì lè dabarú ìdàgbàsókè tó gbámúṣé.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́