Ìbẹ̀rù—Ó Wọ́ Pọ̀ Nísinsìnyí Ṣùgbọ́n Kì Yóò Jẹ́ Títí Láé!
ÀWỌN akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò ṣe kàyéfì pé ìbẹ̀rù wọ́ pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti polongo lọ́nà gbígbòòrò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, ẹ̀rí tí ó pọ̀ yanturu wà pé a ń gbé ní àkókò kan tí a ti sàmì sí nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. O mọ̀ pé ìbẹ̀rù tí ó gbalé gbòde ti sàmì sí i. Ṣùgbọ́n tipẹ́tipẹ́ ni Jesu ti sàmí sí tàbí tọ́ka sí àkókò tiwa. Ó ń dáhùn padà sí ìbéèrè àwọn aposteli nípa wíwà níhìn-ín rẹ̀ àti òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan, tàbí ‘òpin ayé.’—Matteu 24:3.
Ìwọ̀nyí ni apá kan lára àwọn ohun tí Jesu sọ tẹ́lẹ̀:
“Orílẹ̀-èdè yoo dìde sí orílẹ̀-èdè, ati ìjọba sí ìjọba; ìmìtìtì-ilẹ̀ ńláǹlà yoo sì wà, ati awọn àjàkálẹ̀ àrùn ati àìtó oúnjẹ lati ibi kan dé ibòmíràn; awọn ohun ìran akúnfúnbẹ̀rù yoo sì wà ati awọn àmì ńláǹlà lati ọ̀run.”—Luku 21:10‚ 11.
O ha kíyè sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa “ìran akúnfúnbẹ̀rù” bí? Lẹ́yìn náà, nínú ìdáhùn kan náà, Jesu ṣe àkíyèsí pàtàkì mìíràn nípa ìbẹ̀rù tí ó lè kàn ọ́ ní tààràtà, tí ìyọrísí rẹ̀ ní kedere sì lè nípa lórí rẹ àti àwọn tí o nífẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n kí a tó pe àfiyèsí sí ìyẹn, jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn àfikún ẹ̀rí pé a ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ní ṣókí.—2 Timoteu 3:1.
Ìbẹ̀rù Ogun Tí A Dá Láre
Ìforígbárí àwọn ológun ti sọ ibi púpọ̀ ní ayé dahoro. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Geo pe àwọn kànga bẹtiróò tí a fi sílẹ̀ kí ó máa jó lẹ́yìn ìforígbárí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Middle East láìpẹ́ yìí ní “àjálù àyíká tí ó ga jù lọ tí ẹ̀dá ènìyàn tíì fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà rí.” Ogun ti pa, ó sì ti sọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá àwọn ènìyàn di aláàbọ̀ ara. Ní àfikún sí ikú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ológun àti ará ìlú nínú Ogun Àgbáyé I, mílíọ̀nù 55 ni a pa nínú Ogun Àgbáyé II. Rántí pé gẹ́gẹ́ bí apá kan àmì pé òpin ayé ti sún mọ́lé, Jesu sọ pé, “orílẹ̀-èdè yoo dìde sí orílẹ̀-èdè, ati ìjọba sí ìjọba.”
A kò tún lè gbójú fo ìgbìyànjú ènìyàn láti pa ẹ̀ya ìran run—pípa odindi ìran tàbí àwọn ènìyàn run. Ikú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará Armenia, Cambodia, àwọn Júù, àwọn ará Rwanda, Ukraine, àti àwọn mìíràn ti dá kún ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tí ó múni ṣe kàyéfì tí aráyé ti jẹ ní ọ̀rúndún ogún. Ìpakúpa náà ń bá a lọ ní àwọn ilẹ̀ tí àwọn agbawèrèmẹ́sìn ti ń ṣètìlẹyìn fún ìkórìíra ẹ̀yà ìran. Bẹ́ẹ̀ ni, ogun ṣì ń mú kí ilẹ̀ ayé rin gbingbin fún ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn.
Àwọn ogun òde òní ń bá a lọ láti máa pa ọ̀pọ̀ ènìyàn àní lẹ́yìn tí ìjà náà bá ti parí pàápàá. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn ohun abúgbàù tí a rì mọ́lẹ̀ láìbìkítà. Ní ìbámu pẹ̀lú ìròyìn kan tí ètò àjọ ìwádìí Wíwo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ṣe, “nǹkan bí 100 mílíọ̀nù àwọn ohun abúgbàù ní ń wu àwọn ará ilú léwu.” Irú àwọn ohun abúgbàù bẹ́ẹ̀ ń bá a lọ láti máa jẹ́ ewu fún àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ fún àkókò gígùn lẹ́yìn tí ogun tí a lò wọ́n fún ti parí. Ó sọ pé ní oṣù kọ̀ọ̀kan ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni àwọn ohun abúgbàù inú ilẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lé ní 60 ń sọ di abirùn tàbí ṣekú pa. Èé ṣe tí a kò fi mú ohun tí ń wu ìwàláàyè léwu, tí ó sì lè fa ìpalára púpọ̀ yìí kúrò pátápátá? Ìwé ìròyìn The New York Times ṣàkíyèsí pé: “Ohun abúgbàù tí ó pọ̀ gan-an ju èyí tí ètò ìpalẹ̀mọ́ ohun abúgbàù lè kápá, ni a ń rì mọ́lẹ̀ lójoojúmọ́, nítorí náà iye àwọn tí ń jìyà rẹ̀ ń pọ̀ sí i láìdáwọ́ dúró.”
Ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ inú ìwé agbéròyìnjáde náà, ní 1993, ròyìn pé títa àwọn ohun abúgbàù wọ̀nyí ti di òwò tí “ń mú iye tí ó tó 200 mílíọ̀nù dọ́là wọlé lọ́dọọdún.” Ó ní “àwọn ilé iṣẹ́ tí ó tó nǹkan bí 100 àti àwọn aṣojú ìjọba ní orílẹ̀-èdè 48” tí wọ́n “ń kó 340 oríṣiríṣi” àwọn ohun abúgbàù “ránṣẹ́ sí òkèèrè” nínú. Ní ọ̀nà tí ó burú jáì, àwọn ohun abúgbàù kan ni a ṣe ní ìrísí ohun ìṣeré ọmọdé, kí ó baà lè dùn ún wò fún àwọn ọmọdé! Wò ó ná, wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ fojú sun àwọn ọmọdé tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ láti sọ wọ́n di abirùn, kí wọ́n sì pa wọ́n run! Ọ̀rọ̀ olóòtú kan tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “100 Mílíọ̀nù Àwọn Bọ́m̀bù” jẹ́wọ́ pé, àwọn ohun abúgbàù ti “pa tàbí sọ àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i di abirùn ju ohun tí ìbàjẹ́ afẹ́fẹ́, oògùn olóró tí a fín sí ewéko, àti ohun èlò ogun átọ́míìkì ti pa lọ.”
Ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun abúgbàù nìkan ni ohun èlò tí ó lè ṣekú pani tí a ń tà ní ọjà àgbáyé. Àwọn ọ̀kánjúà oníṣòwò ohun ìjà ogun kárí ayé ń ṣòwò tí ó lè mú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là wá. Ìwé ìròyìn The Defense Monitor, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Ibùdó Ìsọfúnni Lórí Ààbò Ìlú, ròyìn pé: “Jálẹ̀ ẹ̀wádún tí ó kọjá [orílẹ̀-èdè kan tí ó yọrí ọlá] kó àwọn ohun ìjà ogun tí owó rẹ̀ tó 135 Bílíọ̀nù dọ́là kọjá sí ilẹ̀ òkèèrè.” Orílẹ̀-èdè alágbára yìí tún “fọwọ́ sí títa ohun ìjà ogun, ṣíṣe àwọn ohun ìjà ogun, àti fífún 142 orílẹ̀-èdè ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, tí iye owó rẹ̀ tí ó tó 63 Bílíọ̀nù dọ́là múni ta gìrì.” Wọ́n ń tipa báyìí fúnrúgbìn tí yóò yọrí sí ogun àti ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn ní ọjọ́ iwájú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Defense Monitor ti sọ, ní “1990 nìkan, ogun mú kí mílíọ̀nù 5 àwọn ènìyàn kọ́ láti lo ohun ìjà ogun láti jagun, ó náni ní iye tí ó ju 50 Bílíọ̀nù dọ́là lọ, ó sì pa ìdá mẹ́rin mílíọ̀nù àwọn ènìyàn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn jẹ́ ará ìlú.” Dájúdájú, o lè ronú nípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ogun tí ó ti jà láti ọdún náà wá, tí ń mú ìbẹ̀rù àti ikú wá fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn púpọ̀ síi!
Títúbọ̀ Pa Ilẹ̀ Ayé àti Ohun Abẹ̀mí Rẹ̀ Run
Ọ̀jọ̀gbọ́n Barry Commoner kìlọ̀ pé: “Mo gbàgbọ́ pé bí a kò bá ṣe ohunkóhun sí ìbàyíkájẹ́ ilẹ̀ ayé tí ń bá a lọ, yóò pa pílánẹ́ẹ̀tì yìí run, ní sísọ ọ́ di ibi tí kò yẹ fún ẹ̀dá ènìyàn láti gbé, nígbẹ̀yìngbẹ́yín.” Ó ń bá a lọ ní sísọ pé ìṣòrò náà kì í ṣe àìmọ̀kan, ṣùgbọ́n ìwọ̀ra àmọ̀ọ́mọ̀ṣe. Ìwọ ha lérò pé Ọlọrun wa olódodo àti onífẹ̀ẹ́ yóò fàyè gba ipò yìí títí láé, kí ó sì fi wá sílẹ̀ fún ìbẹ̀rù ìbàyíkájẹ́ tí ń pọ̀ sí i bí? Bíbà tí a ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́ ń béèrè fún ìjíhìn àwọn tí ń bà á jẹ́ àti àtúnṣe àtọ̀runwá fún pílánẹ́ẹ̀tì náà. Èyí jẹ́ apá kan àwọn ohun tí Jesu sọ̀rọ̀ lé lórí nínú èsì rẹ̀ sí àwọn aposteli nípa ‘òpin ayé.’
Ṣáájú kí a tó ṣàgbéyẹ̀wò bí Ọlọrun yóò ṣe mú ìjíhìn náà wá, jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ènìyàn síwájú sí i. Àkọsílẹ̀ níwọ̀nba nípa bíba ipò ìjẹ́mímọ́ jẹ́ pàápàá bani nínú jẹ́: òjò omiró àti fífi ìwọra bẹ́gi tí ń pa gbogbo igbó run; dída àwọn átọ́míìkì tí kò wúlò mọ́, kẹ́míkà onímájèlé, àti ògidì ẹ̀gbin sílẹ̀ láìbìkítà; dídín agbára ìdáàbòbò ìpele afẹ́fẹ́ àyíká adáàbòboni kù; àti lílo oògùn apagi àti apakòkòrò ní ìlòkulò.
Ìfẹ́ ọkàn nínú òwò láti baà lè rí èrè jẹ ti sọ ilẹ̀ ayé di ìbàjẹ́. Ọ̀pọ̀ tọ́ọ̀nù àwọn ohun tí kò wúlò fún àwọn ilé iṣẹ́ ni a ń dà sínú odò, òkun, afẹ́fẹ́, àti ilẹ̀ ní ojoojúmọ́. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń dọ̀tí ojú ọ̀run pẹ̀lú àwọn páńdukú tí wọ́n fi sílẹ̀ ní gbalasa òfuurufú, láìpa ilẹ̀ mọ́ lẹ́yìn náà, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ilẹ̀ ayé ni a ń fi ìdọ̀tí gègèrè yí po ní kíákíá. Tí kì í bá ṣe ọ̀nà ti àdánidá tí Ọlọrun gbà ṣe ilẹ̀ ayé pé kí ó máa ṣàtúnṣe ara rẹ̀ ni, ilé ilẹ̀ ayé wa kì bá tí ṣe é gbé, orí kunkun ènìyàn ni ì bá sì ti ṣeé ṣe kí ó ti ṣekú pa á tipẹ́tipẹ́.
Ènìyàn tilẹ̀ ń ba ara rẹ̀ jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, wo tábà àti àwọn ìlòkulò oògùn mìíràn. Ní United States, irú ìlo àwọn nǹkan báyìí ní ìlòkulò ni a ti fún ní orúkọ náà “ìṣòrò ìlera tí ó tóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà.” Ó ń ná orílẹ̀-èdè náà ní bílíọ̀nù 238 dọ́là lọ́dọọdún, nínú èyí tí a ń lo bílíọ̀nù 34 dọ́là sórí “ìtọ́jú ìlera tí kò pọndandan [ìyẹn ni, tí ó ṣeé yẹ̀ sílẹ̀].” Èló ni o rò pé tábà ń náni ní ti owó àti ìwàláàyè níbi tí ìwọ ń gbé?
Ìgbésí ayé onígbọ̀jẹ̀gẹ́ àti oníyapa, tí ọ̀pọ̀ lè takú pé ó dára, ti so èso bíbani lẹ́rù èyí tí àrùn tí ìbálòpọ̀ takọtabo tí ń ṣekú pani ń mú wá, tí ń rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní sàréè ní rèwerèwe. A ti ṣàkíyèsí pé abala ìkéde òkú nínú ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn ní àwọn ìlú ńlá, ń fi hàn nísinsìnyí pé àwọn ẹni 30 ọdún sí 40 ọdún tí ń kú ti ń pọ̀ sí i. Èé ṣe? Lọ́pọ̀ ìgbà, nítorí pé wọ́n ń fàyè gba ìwà burúkú láti borí wọn. Irú ìlọsókè bíbani nínú jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú àrùn ìbálòpọ̀ àti àwọn àrùn mìíràn tún bá àsọtẹ́lẹ̀ Jesu mu gẹ́ẹ́, nítorí ó sọ pé “awọn àjàkálẹ̀ àrùn . . . lati ibi kan dé ibòmíràn” yóò wà.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìbàyíkájẹ́ tí ó burú jù lọ, ni ti èrò inú àti tẹ̀mí, tàbí ti ìṣarasíhùwà ẹ̀dá ènìyàn. Bí o bá ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo ọ̀nà ìbàjẹ́ tí a ti mẹ́nu kan títí di ìsinsìnyí, kì í ha í ṣe òtítọ́ pé, èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára wọn jẹ́ ìyọrísí èrò inú tí a ti sọ dìbàjẹ́ bí? Ṣàgbéyẹ̀wò ọṣẹ́ tí èrò inú tí ń ṣàárẹ̀ ń dá sílẹ̀ ní ọ̀nà ìpànìyàn, ìfipábánilòpọ̀, ìdigunjalè, àti onírúurú àwọn ìwà ipá mìíràn tí ẹnì kan ń ṣe sí ẹlòmíràn. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ń mọ̀ pé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìṣẹ́yún tí a ń ṣe lọ́dọọdún jẹ́ àmi ìbàjẹ́ èrò orí àti tẹ̀mí.
A ń rí púpọ̀ sí i nínú ìṣarasíhùwà àwọn ọ̀dọ́. Àìbọ̀wọ̀ fún àwọn òbí àti àwọn aláṣẹ mìíràn ń dá kún ìwópalẹ̀ ìdílé àti ìtàpá sí òfin àti àṣẹ. Àìní ìbẹ̀rù tí ó gbámúṣé fún aláṣẹ yìí ni a so pọ̀ ní tààràtà mọ́ àìjẹ́ ẹni tẹ̀mí àwọn ọ̀dọ́. Nítorí náà, àwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ẹ̀kọ́ àìgbọlọ́rungbọ́, àti àwọn àbá èrò orí mìíràn tí ń ba ìgbàgbọ́ jẹ́ kọ́ni, jẹ̀bi tí ó pọ̀. Àwọn tí wọ́n tún jẹ̀bi ni ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, tí wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, nínú ìsapá wọn láti di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó bóde mu, tí ó sì “rọ́ọ̀ọ́kán.” Àwọn àti àwọn mìíràn tí wọ́n ti jingíri sínú ọgbọ́n ayé ń kọ́ni ní ọgbọ́n èrò orí ẹ̀dá ènìyàn títakora.
Àwọn ìyọrísí rẹ̀ ṣe kedere lónìí. Kì í ṣe ìfẹ́ fún Ọlọrun àti àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn ní ń sún àwọn ènìyàn, bí kò ṣe ìwọra àti ìkórìíra. Èso búburú rẹ̀ ni ìwà pálapàla, ìwà ipá, àti àìnírètí tí ó gbalé gbòde. Ó bani nínú jẹ́ pé, èyí ń mú kí àwọn ènìyàn aláìlábòsí ọkàn máa bẹ̀rù, títí kan ìbẹ̀rù pé ènìyàn yóò pa ara rẹ̀ àti pílánẹ́ẹ̀tì run.
Yóò Ha Burú Tàbí Sunwọ̀n Sí i Bí?
Kí ni ọjọ́ ọ̀la tí ó sún mọ́lé ní ní ìpamọ́ ní ti ọ̀ràn ìbẹ̀rù? Ìbẹ̀rù yóò ha máa bá a nìṣó láti máa pọ̀ sí i, tàbí a óò ha kápá rẹ̀ bí? Lẹ́ẹ̀kan sí i, ẹ jẹ́ kí a ṣàkíyèsí ohun tí Jesu sọ fún àwọn aposteli rẹ̀.
Ó tọ́ka sí ohun kan tí ó wà ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà—ìpọ́njú ńlá. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọrọ̀ rẹ̀: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú awọn ọjọ́ wọnnì oòrùn yoo ṣókùnkùn, òṣùpá kì yoo sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, awọn ìràwọ̀ yoo sì jábọ́ lati ọ̀run, awọn agbára awọn ọ̀run ni a óò sì mì. Nígbà naa sì ni àmì Ọmọkùnrin ènìyàn yoo farahàn ní ọ̀run, nígbà naa sì ni gbogbo awọn ẹ̀yà ilẹ̀-ayé yoo lu ara wọn ninu ìdárò, wọn yoo sì rí Ọmọkùnrin ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹlu agbára ati ògo ńlá.”—Matteu 24:29‚ 30.
Nítorí náà, a lè retí pé ìpọ́njú ńlá náà yóò bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli mìíràn tọ́ka sí i pé apá àkọ́kọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ìgbẹ̀san lára ìsìn èké káàkiri àgbáyé. Lẹ́yìn náà ni ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun tí ń múni ta gìrì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tọ́ka sí lókè yìí yóò ṣẹlẹ̀, tí yóò ní ìfarahàn àwọn nǹkan mériyìírí ti òkè ọ̀run nínú. Kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀ lórí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn?
Tóò, ṣàkíyèsí àkọsílẹ̀ tí ó dọ́gba nínú ìdáhùn Jesu, níbi tí a ti rí àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú ṣe kedere sí i:
“Awọn àmì yoo wà ninu oòrùn ati òṣùpá ati awọn ìràwọ̀, ati lórí ilẹ̀-ayé làásìgbò awọn orílẹ̀-èdè, láìmọ ọ̀nà àbájáde nitori ìpariwo omi òkun ati ìrugùdù rẹ̀, nígbà tí awọn ènìyàn yoo máa kúsára lati inú ìbẹ̀rù ati ìfojúsọ́nà fún awọn ohun tí ń bọ̀ wá sórí ilẹ̀-ayé tí a ń gbé; nitori awọn agbára awọn ọ̀run ni a óò mì.”—Luku 21:25‚ 26.
Ìyẹn wà níwájú wa. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni yóò ní irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀, tí yóò mú wọn kú sára. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jesu sọ pé: “Bí awọn nǹkan wọnyi bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nàró ṣánṣán kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nitori pé ìdáǹdè yín ń súnmọ́lé.”—Luku 21:28.
Ó sọ àwọn ọrọ̀ afúnniníṣìírí wọ̀nyẹn fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́. Dípò kí wọ́n jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú wọn kú sára tàbí sọ wọ́n di aláìṣiṣẹ́ mọ́, wọn yóò ní ìdí láti gbé orí wọn sókè láìbẹ̀rù, àní bí wọ́n tilẹ̀ mọ̀ pé ògógóró ìpọ́njú ńlá náà ti wà nítòsí. Èé ṣe tí wọn kò fi ní bẹ̀rù?
Nítorí pé Bibeli sọ ní kedere pé àwọn olùla gbogbo “ìpọ́njú ńlá” náà já yóò wà. (Ìṣípayá 7:14) Àkọsílẹ̀ ìlérí yìí sọ pé, bí a bá wà lára àwọn olùlàájá náà, a lè gbádùn àwọn ìbùkún aláìlẹ́gbẹ́ láti ọwọ́ Ọlọrun. Ó parí pẹ̀lú ìdánilójú náà pé Jesu “yoo sì máa fi wọ́n mọ̀nà lọ sí awọn ìsun omi ìyè. Ọlọrun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.”—Ìṣípayá 7:16, 17.
Àwọn wọnnì—àwa pẹ̀lú sì lè wà lára wọn—tí ń gbádùn irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ kì yóò ní ìbẹ̀rù tí ń yọ àwọn ènìyàn lẹ́nu lónìí. Síbẹ̀, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé wọ́n kì yóò ní ìbẹ̀rù kankan rárá, nítorí Bibeli fi hàn pé ìbẹ̀rù tí ó dára, tí ó sì gbámúṣé wà. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí èyí jẹ́, àti bí ó ṣe yẹ kí ó nípa lórí wa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn olùjọsìn Jehofa ń fayọ̀ retí ayé tuntun tí ń bọ̀ náà
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìbàyíkájẹ́: Fọ́tò: Godo-Foto; rọ́kẹ́ẹ̀tì: Fọ́tò U.S. Army; àwọn igi tí ń jó: Richard Bierregaard, Smithsonian Institution