O Ha Ti Sunmọ Ju Bi O Ti Rò Lọ Bí?
ỌJỌ́ mẹta ṣaaju ikú rẹ̀, Jesu ni ọwọ́ rẹ̀ dí lati owurọ titi di àṣálẹ́ ni Jerusalẹmu, ọjọ́ kan ti o jasi eyi ti o ṣe pataki julọ fun awọn Kristian ti wọn ngbe nisinsinyi. Oun kọni ninu tẹmpili, ni yíyí ọpọlọpọ awọn ibeere ẹlẹtan eyi ti awọn aṣaaju onisin Juu gbiyanju lati fi kẹ́dẹ mú un dà. Nikẹhin, o dari ifibu mimuna sí awọn akọwe ati Farisi ti o sami sí wọn gẹgẹ bi agabagebe ati ejo paramọlẹ tí wọn forile Gẹhẹna.—Matiu, ori 22, 23.
Bi oun ti nfi agbegbe tẹmpili silẹ, ọkan lara awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun un pe: “Olukọni, wo irú okuta ati irú ile tí ó wa nihin-in yii!” Jesu, ẹni ti a ko wu lori, wi fun un pe: “Iwọ ri ile nla wọnyi? Ki yoo sí okuta kan ti a o fi silẹ lori ekeji, ti a ki yoo wó lulẹ.” (Maaku 13:1, 2) Lẹhin naa Jesu fi tẹmpili naa silẹ fun igba ikẹhin, o sọkalẹ sí Afonifoji Kidroni, o rekọja, o si gun ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Oke Olifi.
Bi oun ti jokoo ninu oorun irọlẹ tí ó tàn rokoṣo síi lara nibẹ lori oke, pẹlu tẹmpili naa ni ibi ti a ti lè ríi lori Oke Moraya lodikeji afonifoji naa, Peteru, Jakọbu, Johanu, ati Anderu wá sọdọ rẹ̀ nikọkọ. Awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti o sọ jade nipa iwolulẹ tẹmpili naa wúwo lọkan wọn. Wọn beere pe: “Sọ fun wa, nigba wo ni nǹkan wọnyi yoo ṣẹ, ki ni yoo si ṣe ami wíwàníhìn-ín rẹ ati ti ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan?” (Matiu 24:3, (NW); Maaku 13:3, 4) Idahun ti oun fi fun ibeere wọn ni ọsan ọjọ yẹn lori Oke Olifi ṣe pataki gidi fun wa. O lè pa wa mọ kuro ninu diduro fun ìgbà pípẹ́ ki a to bẹrẹ sii ronu nipa “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.”
Ibeere wọn jẹ́ alapa meji. Apakan jẹ́ nipa opin tẹmpili ati eto igbekalẹ awọn Juu; ekeji niiṣe pẹlu wíwàníhìn-ín ọjọ-ọla Jesu gẹgẹ bi Ọba ati ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi. Awọn ibeere mejeeji wọnyi ni Jesu kárí ninu idahun rẹ̀, gẹgẹ bi a ti fifunni ninu Matiu 24 ati 25, Maaku 13, ati Luuku 21. (Tun wo Iṣipaya 6:1-8.) Nipa ipari ayé isinsinyi, tabi eto-igbekalẹ awọn nǹkan, Jesu ṣapejuwe awọn apa iha oniruuru ti o jẹ pe, bi a ba mu wọn papọ, yoo jẹ́ ami alapa pupọ ti nfi ikẹhin awọn ọjọ́ han. Njẹ ami alapa pupọ yẹn nni imuṣẹ bí? O ha fi wa sí ikẹhin ọjọ́ tí a sọrọ nipa rẹ̀ ninu Bibeli bí? Njẹ imuṣẹ rẹ̀ ha kilọ fun wa pe o lé ti sunmọ ju bi a ti ro lọ bí?
Apa iha kan ninu ami alapa pupọ Jesu ni: “Orilẹ-ede, yoo dide sí orilẹ-ede ati ilẹ ọba sí ilẹ ọba.” (Matiu 24:7) Ni 1914, ogun agbaye kìn-ínní bẹrẹ. Lọgan awọn Ẹlẹrii Jehofa ti ẹwadun yẹn ti wa lojufo. Eesitiṣe? Ni December 1879, nǹkan bíi 35 ọdún ṣaaju, ni gbigbe e kari kika akoko Bibeli, iwe irohin Watch Tower ti wipe 1914 yoo jẹ́ ọdún pataki julọ ninu itan ẹda eniyan. Njẹ ogun yii, ogun akọkọ tí o gbooro kari aye nitootọ, ninu eyi ti orilẹ-ede 28 ti kópa ti a si pa 14 aadọta ọkẹ eniyan, ha le jẹ́ ibẹrẹ awọn iṣẹlẹ ti nmu ami alapa pupọ Jesu ti opin ṣẹ bí? Awọn apa iha miiran ti ami naa yoo ha tẹle e bí?
Ninu “ifihan ti Jesu Kristi,” ipaniyan rẹpẹtẹ kan naa yi ni a sọ asọtẹlẹ rẹ̀. Níhìn-ín ni ẹṣin pupa kan ati ẹni ti o gùn ún “gba alaafia kuro lori ilẹ-aye.” (Iṣipaya 1:1; 6:4) Dajudaju iyẹn ṣẹlẹ lati 1914 sí 1918. Ogun Agbaye Kìn-ínní si wulẹ jẹ́ ibẹrẹ ni. Ni 1939, Ogun Agbaye Keji tẹle e. Orilẹ-ede mọkandinlọgọta ni a fa sinu iforigbari yẹn, awọn eniyan tí wọn tó 50 aadọta ọkẹ ni a sì pa. Laaarin 45 ọdun ti o tẹle Ogun Agbaye Keji, ohun ti o ju 125 ogun ni a ti ja, ti o pa ohun ti o ju 20 aadọta ọkẹ eniyan.
Apa iha miiran ti ami naa ni: “Àìtó ounjẹ yoo sì wà.” (Matiu 24:7, NW) Ìyàn ti o gbalẹ̀kan lakooko ati lẹhin Ogun Agbaye Kìn-ínní wà. Irohin kan ṣakọsilẹ lẹsẹẹsẹ ohun ti ó ju 60 ìyàn nlanla lati 1914, tí ó gba araadọta ọkẹ ẹ̀mí. Ju bẹẹ lọ, ani nisinsinyi paapaa 40,000 awọn ọmọ ńkú lojoojumọ lati inú àìjẹunre kánú ati awọn àrun tí a lè ṣediwọ fun.
‘Isẹlẹ nla yoo sì wà.’ (Luuku 21:11) Wọn mi ilẹ-aye tìtì lẹhin ti Ogun Agbaye Kìn-ínní bẹrẹ. Ni 1915 isẹlẹ gba 32,610 ẹ̀mí ni Italy; ni 1920 omiran pa 200,000 ni China; ni 1923 ni Japan, 99,300 kú; ni 1935 nibi ti a mọ̀ sí Pakistan nisinsinyi, 25,000 sọ ẹ̀mí wọn nù; ni 1939 ni Turkey, 32,700 parun; ni 1970 ni Peru, 66,800 ni a pa; ni 1976 ni China, 240,000 (awọn miiran sọ pe 800,000) kú; ni 1988 ní Armenia, 25,000 sọ ẹmi wọn nù. Dajudaju, awọn isẹlẹ nla ti wà lati 1914!
‘Ajakalẹ arun yoo wa kaakiri.’ (Luuku 21:11) Laaarin 1918 ati 1919, awọn eniyan tí wọn tó 1,000,000,000 ṣaisan pẹlu àrùn gágá, ohun ti o si ju 20,000,000 kú. Ṣugbọn iyẹn wulẹ jẹ́ ibẹrẹ ni. Ní apa aye tí ó ṣẹṣẹ ngoke àgbà, ibà, àrùn ìtọ̀ ẹ̀jẹ̀, river blindness, ìgbẹ́ gbuuru tí ó légbákan, ati awọn ailera miiran nbaa lọ lati sọ awọn eniyan di alaiwulo tí o si npa ọgọrọọrun lọna araadọta ọkẹ. Ni afikun, aisan ọkan-aya ati káńsà ngba araadọta ọkẹ ẹmi síi. Awọn òkùnrùn ti a nta látagbà nipaṣẹ ibalopọ takọtabo nfi araye ṣofo. Eyi ti nko ipaya ba ọkan lonii ni ijiya aṣekupani ti AIDS, ti a diyele pe o nran ojiya ipalara titun ni iṣẹju kọọkan, laisi iwosan kankan ni ojutaye.
‘Ẹṣẹ ndi pupọ.’ (Matiu 24:12) Iwa ailofin ti hùyẹ́ lati 1914, lonii o si ti búkẹ̀mù. Awọn iṣikapaniyan, ifipa bobinrin lopọ, idigunjale, ogun ìpàǹpá—ní wọn jẹ́ awọn kókó iwe irohin ati irohin kika ori redio ati tẹlifiṣọn. Iwa-ipa alainitumọ ngbilẹ lọ laidawọduro. Ni United States, ọkunrin oníbọn kan rọ̀jò ọta ọgọrun-un ẹ̀kì lati inú ibọn ráífù ayìn léraléra saarin ogunlọgọ awọn ọmọ ile-iwe—5 kú, 29 sì farapa. Ní England ọkunrin ayírí kan pa awọn eniyan 16 pẹlu ibọn ráífù ti a fi ńgbéjà koni AK-47. Ni Canada ọkunrin kan ti o koriira awọn obinrin lọ si Yunifasiti Montreal o sì pa 14 ninu wọn. Irú awọn eniyan bẹẹ dà bí ikooko, kinniun, ẹranko ẹhanna, ẹran alainironu ti a bi lati kẹ́dẹ mú ki a si parun.—Fiwe Esekiẹli 22:27; Sẹfanaya 3:3; 2 Peteru 2:12.
“Àyà awọn eniyan yoo maa já fun ibẹru, ati fun ireti nǹkan wọnni tí nbọ sori ayé.” (Luuku 21:26) Ní kété lẹhin ìbúgbàù bọmbu atọmiki akọkọ, onimọ ijinlẹ atọmiki Harold C. Urey sọ nipa ẹhin ọla pe: “Awa yoo jẹun ninu ẹ̀rù, sùn ninu ẹ̀rù, gbé ninu ẹ̀rù, a o sì kú ninu ẹ̀rù.” Ni afikun si ibẹru ogun àgbá atọmiki ni iwa-ọdaran, ìyàn, eto iṣunna owó tí kò duro soju kan, iwolulẹ iwarere, ijẹrabajẹ idile, isọdeeri ilẹ-aye. Nitootọ, akoko buburu ti awọn iwe-irohin ati irohin orí tẹlifiṣọn ngbe jade yẹyẹyẹ fun wa ntan ibẹru ká ibi gbogbo.
Apọsteli Pọọlu tun kọwe nipa awọn ipo ti yoo gbodekan ni awọn ikẹhin ọjọ eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii. Nṣe ni kika awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí kika irohin ojumọ. Oun kọwe pe, “Ṣugbọn eyi ni ki o mọ, pe ni ikẹhin ọjọ́ igba ewu yoo de. Nitori awọn eniyan yoo jẹ́ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owó, afúnnu, agberaga, asọrọ buburu, aṣaigbọran sí òbí, alailọpẹ, aláìmọ́, alainifẹẹ, alaile darijini, abanijẹ́, alaile kora wọn nijaanu, onroro, alainifẹẹ oun rere, onikupani, alagidi, ọlọkan giga, olufẹ fàájì ju olufẹ Ọlọrun lọ; awọn ti wọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn tí wọn sẹ́ agbara rẹ̀: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyii pẹlu.”—2 Timoti 3:1-5.
Ohun Gbogbo Nbaa Niṣo “Gẹgẹ Bii Lati Ibẹrẹ Iṣẹda”?
Apọsteli Peteru sọ asọtẹlẹ apa iha miiran ti ikẹhin ọjọ́ pe: “Ni awọn ọjọ́ ikẹhin awọn ẹlẹgan yoo dé pẹlu ẹgan wọn, wọn yoo maa tẹsiwaju pẹlu ifẹ ọkan araawọn wọn yoo si maa wipe: ‘Nibo ni ileri yii ti wíwàníhìn-ín rẹ̀ gbé wà? Họ́wù, lati ọjọ́ tí awọn baba wa ti sùn [ninu ikú], ohun gbogbo nbaa niṣo ni deedee gẹgẹ bii lati ibẹrẹ iṣẹda.’”—2 Peteru 3:3, 4, NW.
Lonii, nigba ti koko ọ̀rọ̀ nipa awọn ọjọ ikẹhin wáyé, ọpọlọpọ awọn eniyan mú awọn ọ̀rọ̀ alaṣọtẹlẹ Peteru ṣẹ nipa rirẹrin-in ẹlẹya ati wiwi pe: ‘Óò, gbogbo awọn nǹkan wọnyẹn ti ṣẹlẹ rí. Itan wulẹ ntun ara rẹ̀ sọ ni.’ Nitori naa wọn rọ́ awọn ikilọ naa tì ṣẹgbẹẹkan wọn si nbaa lọ ‘ni titẹsiwaju pẹlu ifẹ ọkan araawọn.’ Ó jẹ́ “gẹgẹ bi ifẹ inu wọn” ni wọn fi ṣaifiyesi imuṣẹ awọn asọtẹlẹ tí o fi awọn ọjọ́ ikẹhin han kedere.—2 Peteru 3:5, NW.
Laika eyiini sí, awọn apa iha ọtọọtọ ti ami alapa pupọ ti Jesu sọtẹlẹ ko tii ni imuṣẹ papọ ri ní irú sáà akoko kukuru bẹẹ ati ni iru ọna ti o rinlẹ ti o si ni irú awọn abajade gbigbooro bẹẹ. (Fun apẹẹrẹ, ṣatunyẹwo Matiu 24:3-12; Maaku 13:3-8; Luuku 21:10, 11, 25, 26.) Awa yoo si tun fẹ́ lati fa afiyesi rẹ sí apa iha miiran nipa awọn ọjọ́ ikẹhin ti a ti sọtẹlẹ, eyi ti a ṣapejuwe ninu Iṣipaya.
Ẹ jẹ́ kí a yijusi Iṣipaya 11:18 (NW). O sọ pe nigba ti Ijọba Kristi bá bẹrẹ iṣakoso tí awọn orilẹ-ede sì binu tí akoko fun idajọ sì dé, nigba naa Jehofa yoo “mú awọn wọnni tí npa ilẹ-aye run wá sí iparun.” Biba ayika jẹ́ kò ha npa ayika run lonii bí? Nitootọ, awọn eniyan ti lo awọn ohun àmúṣọrọ̀ ilẹ-aye nigba gbogbo lati sọ araawọn di ọlọ́rọ̀. Ṣugbọn ní ṣiṣe bẹẹ, wọn kò tíì fi igba kan wà ni ipo lati pa á run gẹgẹ bi planẹti kan tí ó ṣeé gbé. Nisinsinyi, nitori ọgbọ́n ẹ̀rọ ìmọ̀ ijinlẹ tí a ti mugberu lati 1914, awọn eniyan ti wá ní agbara yẹn, ati nipa fifi iwọra jíjàdù fun ọrọ̀, nitootọ ni wọn npa ilẹ-aye run, wọn nba ayika jẹ́ wọn sì nfi agbara ilẹ-aye lati gbé iwalaaye ró sabẹ ewu.
Awujọ eniyan oníwọ̀ra, onifẹẹ ọrọ-alumọọni nṣe eyi nisinsinyi pẹlu ìyára ti nbanilẹru. Diẹ lara awọn ipo buburu jai ti nyọrisi nitii: òjò omi kíkan, imooru yika aye, iho lara ìbòrí afẹfẹ ozone, akunya pantiri, awọn ààtàn olóró, awọn oogun apagi ati apakokoro tí ó lewu, pantiri atọmiki, itudasilẹ epo, dida adalu omi ìgbẹ́ si ayika, iwulewu oriṣiriṣi ẹ̀yà iṣẹda, awọn adágún omi alaini ohun alaaye mọ́, omi abẹ ilẹ̀ ti a ti kó èérí bá, iparun igbo ẹgan, ilẹ ti a ti kó èérí bá, ipadanu ilẹ ẹlẹ́tùlójú, ati eefin dúdú ti ńba awọn igi ati ohun ọ̀gbìn jẹ́ ti o si ńba ilera eniyan jẹ́ pẹlu.
Ọjọgbọn Barry Commoner wipe: “Mo gbagbọ pe sisọ ilẹ-aye dèérí ti nbaa lọ, bi a kò ba da a duro, ni asẹhinwa asẹhinbọ yoo pa planẹti yii run ni sisọ ọ di alaiyẹ gẹgẹ bi ibi ti ẹda eniyan lè gbé. . . . Iṣoro naa kò sí ninu aimọkan niti imọ ijinlẹ, ṣugbọn ninu iwọra àmọ̀ọ́mọ̀ṣe.” Iwe naa State of the World 1987 wi ni oju-iwe 5 pe: “Ibi ti igbokegbodo ẹda eniyan ga de ti bẹrẹ si halẹmọ ṣíṣeégbé ilẹ-aye funraarẹ.” Ọ̀wọ́ awọn itolẹsẹẹsẹ tẹlifiṣọn fun gbogbo ilu ti a gbé si afẹ́fẹ́ ni United States ni 1990 ni a fun ni akọle naa “Eré Sisa Lati Gba Planẹti Wa Là.”
Eniyan kì yoo dáwọ́ biba ayika jẹ duro lae; Ọlọrun yoo ṣe bẹẹ nigba ti o ba run awọn wọnni tí wọn nrun ilẹ-aye. Ọlọrun ati Ọgagun Àgbà rẹ ti ọrun, Jesu Kristi, yoo ṣe eyi nipa mimu idajọ ṣẹ lori awọn orilẹ-ede onifẹẹ ọrọ̀ alumọọni nigba ogun ikẹhin ti Amagẹdọni.—Iṣipaya 16:14, 16; 19:11-21.
Nikẹhin, kiyesi apa iha titayọ ti o tẹle asọtẹlẹ Jesu nipa awọn ikẹhin ọjọ́: “A o . . . waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo aye.” (Matiu 24:14) Ihinrere yii sọ fun wa pe Ijọba Ọlọrun ti nṣakoso nisinsinyi ninu awọn ọ̀run yoo sì gbegbeesẹ lati pa eto buburu yii run laipẹ ti yoo sì mú Paradise padabọsipo si ilẹ-aye. Ihinrere naa ni a ti waasu rẹ ṣaaju ṣugbọn kò kari gbogbo ilẹ-aye ti a ngbe nigba kankan rí. Bi o ti wu ki o ri, lati 1914, awọn Ẹlẹrii Jehofa ti ṣe iyẹn, laika inunibini ti Jesu sọtẹlẹ si—awọn ìfòfindè lati ọ̀dọ̀ Ijọba, iwa-ipa awujọ eniyankeniyan, ifisẹwọn, idaloro, ati ọpọlọpọ ikú.
Ni 1919 awọn 4,000 Ẹlẹrii Jehofa ni wọn wà ti wọn nwaasu ihinrere yii. Iye wọn ti nbaa lọ lati pọ sii, ti ó fi jẹ́ pé ni ọdún tí ó kọja iye tí ó ju 4,000,000 nwaasu ni awọn ilẹ 212, ni nǹkan bii èdè 200, ni pinpin ọgọrọọrun lọna araadọta ọkẹ Bibeli, iwe ikẹkọọ, iwe irohin, tí wọn ndari araadọta ọkẹ awọn ikẹkọọ Bibeli ninu ile awọn eniyan, tí wọn sì nṣe awọn apejọpọ ninu awọn pápá iṣere titobi nla ní apa ibi gbogbo lagbaaye. A kò ba ti lè ṣe ìwọ̀n bàǹtàbanta iwaasu ihinrere yii ṣaaju 1914. Aṣeyọri rẹ̀ dé iwọn tí a ti báa dé beere fun ẹ̀rọ itẹwe ayára-bí-àṣá ti ode oni, awọn ohun lílò fun ìrìrìn àjò, awọn ẹ̀rọ kọmputa, ẹrọ ifiweranṣẹ ayára-bí-àṣá (fax) ati pẹlu ipese ìkẹ́rù ranṣẹ ati ibanisọrọpọ tí ó wà larọọwọto ni akoko wa nikanṣoṣo.
Jerusalẹmu ti ọjọ́ Jeremaya ni a kilọ iparun rẹ̀ tí nbọ fun; awọn olugbe rẹ̀ wulẹ rẹrin-in ẹlẹya, ṣugbọn ó sunmọ ju bí wọn ti rò lọ. Lonii, ikilọ titobi ju ti iparun Amagẹdoni ni a npolongo, pẹlu ẹ̀rí itilẹhin ti o pọ jaburata. (Iṣipaya 14:6, 7, 17-20) Araadọta ọkẹ kọ etí ikún síi. Ṣugbọn akoko ntan lọ; o ti sunmọ ju bi wọn ti rò lọ. O ha ti sunmọ ju bí iwọ ti rò lọ bí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ni ọjọ́ Jeremaya ó ti sunmọ ju bí wọn ti rò lọ