Bí Ogun Ṣe Ń ṣe Àwọn Ọmọdé Níṣekúṣe
OGUN náà, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ogun abẹ́lé tí ń jà ní Sierra Leone, bẹ́ sílẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ 1995. Nígbà tí ogun parí, Tenneh ọmọ ọdún mẹ́rin, tí àwọn òbí rẹ̀ ti kú sínú ogun náà, fara pa. Ọta kan ti há sínú orí rẹ̀, lẹ́yìn ojú rẹ̀ ọ̀tún, ewu sì wà pé ọta náà yóò fa àkóràn àrùn tí yóò ràn dé inú ọpọlọ rẹ̀, tí yóò sì pa á.
Ní oṣù 16 lẹ́yìn náà, tọkọtaya ará Britain kan ṣètò pé kí wọ́n gbé Tenneh wá sí England fún iṣẹ́ abẹ. Agbo àwọn oníṣẹ́ abẹ kan yọ ọta náà, àwọn ènìyàn sì yọ̀ pé iṣẹ́ abẹ náà kẹ́sẹ járí, pé a ti gba ẹ̀mí ọmọdé kan là. Síbẹ̀, mímọ̀ pé Tenneh jẹ́ ọmọ aláìlóbìí kan tí wọn ì bá má ti yìnbọn fún rárá sọ ayọ̀ náà di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Àwọn Ohun Ìjà, Ebi, àti Àrùn
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọta kan ló ṣèèṣì ba Tenneh, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ni kì í ṣe pé ọta ṣèèṣì bà, àmọ́ tó jẹ́ pé àwọn gangan ni a dojú ìbọn kọ. Nígbà tí gbọ́nmisi-omi-ò-to ẹ̀yà ìran bá bẹ́ sílẹ̀, pípa àwọn àgbàlagbà kì í tó; a máa ń wo àwọn ọmọ ọ̀tá gẹ́gẹ́ bí àwọn tí yóò wá di ọ̀tá lọ́jọ́ ọ̀la. Alálàyé kan nípa ìṣèlú ní Rwanda sọ nínú ètò orí rédíò kan ní 1994 pé: “Láti lè pa àwọn eku ńláńlá, o gbọ́dọ̀ pa àwọn eku kéékèèké.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé tí ń kú nígbà ogun ni kì í ṣe bọ́ǹbù tàbí ọta ló ń pa wọ́n, àmọ́ ebi àti àìsàn ló ń pa wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, nínú àwọn ogun Áfíríkà, àìsí ìpèsè oúnjẹ àti ìtọ́jú lọ́nà ti ìṣègùn ti pa àwọn ènìyàn tí iye wọn fi nǹkan bí ìlọ́po 20 pọ̀ ju àwọn tí ìjà gidi náà ti pa lọ. Dídínà ìpèsè àwọn ohun kòṣeémánìí jẹ́ ọgbọ́n ìwéwèé ogun tí a ń fi àìláàánú ṣàmúlò lóde òní. Àwọn ẹgbẹ́ ológun ti ri àwọn ohun abúgbàù mọ́ àwọn ilẹ̀ títóbi tí ń mú oúnjẹ jáde, wọ́n ti ba àwọn àká ọkà àti àwọn ìpèsè omi jẹ́, wọ́n sì ti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìpèsè ìrànlọ́wọ́. Wọ́n tún ti wó àwọn ilé ìwòsàn palẹ̀, wọ́n sì ti tú àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn ká.
Irú àwọn ọgbọ́n ìwéwèé bẹ́ẹ̀ ń ṣèpalára púpọ̀ fún àwọn ọmọdé. Fún àpẹẹrẹ, láàárín 1980 sí 1988, àwọn ọmọ tí àwọn ohun tó tan mọ́ ogun pa pọ̀ tó 330,000 ní Angola àti 490,000 ní Mòsáḿbíìkì.
Kò Sí Ilé, Kò Sí Ìdílé
Ogun ń sọ àwọn ọmọ di aláìlóbìí nípa pípa àwọn òbí wọn, àmọ́ ó tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa títú àwọn ìdílé ká. Jákèjádò ayé, nǹkan bíi mílíọ̀nù 53 ènìyàn ló ti sá kúrò ní ilé wọn lábẹ́ ìhalẹ̀mọ́ni ìwà ipá. Ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ẹnì kan nínú ènìyàn 115 lórí ilẹ̀ ayé! Ó kéré tán, àwọn ọmọdé ni ìdajì lára wọn. Pẹ̀lú jìnnìjìnnì àtisálọ, àwọn ọmọ kì í sábà wà pẹ̀lú àwọn òbí wọn.
Ní àbáyọrí ìforígbárí tó ṣẹlẹ̀ ní Rwanda, àwọn 114,000 ọmọdé ni kò sí lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn nígbà tí ọdún 1994 parí. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ṣe ní 1995 ti fi hàn, ọmọ kan nínú 5 ti ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀ ní Angola. Fún àwọn ọmọdé púpọ̀, ní pàtàkì àwọn tí wọ́n kéré gan-an, ìṣòro èrò orí tí wọ́n máa ń ní ní ti pé wọn kò sí lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn túbọ̀ ń kó ìrora ọkàn bá wọn ju pákáǹleke tí ogun pàápàá ń fà lọ.
Ohun Abúgbàù Àrìmọ́lẹ̀ Ń Pa Wọ́n
Jákèjádò ayé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọdé ni wọ́n lọ ṣeré, ni wọ́n daran lọ, ni wọ́n lọ ṣẹ́gi ìdáná, tàbí tí wọ́n lọ gbin nǹkan, kìkì láti di ẹni tí àwọn ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ fọ́ yángá. Àwọn ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ ń pa 800 ènìyàn lóṣooṣù. Àròpọ̀ nǹkan bí 110 mílíọ̀nù ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ ló wà ní àwọn orílẹ̀-èdè 64. Nǹkan bíi mílíọ̀nù méje irú àwọn ohun abúgbàù bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rì mọ́lẹ̀ ní Cambodia nìkan, tí ó jẹ́ méjì fún ọmọ kọ̀ọ̀kan.
Ó lé ní 40 orílẹ̀-èdè tí ń ṣe oríṣi ohun abúgbàù tí ó tó 340 ní onírúurú ìrísí àti àwọ̀. Àwọn kan rí bí òkúta, àwọn mìíràn rí bí ọ̀pẹ̀yìnbó, àwọn mìíràn sì rí bí àwọn labalábá kéékèèké tí ó láwọ̀ ewé, tí ó máa ń rọra fò sórí ilẹ̀ láti inú hẹlíkọ́pítà, láìbúgbàù. Àwọn ìròyìn fi hàn pé àwọn ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ kan, tí a ṣe láti rí bí ohun ìṣeré ọmọdé, ni wọ́n ti gbé sítòsí àwọn ilé ẹ̀kọ́ àti ibi ìṣeré tí àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ti lè rí wọn.
Nǹkan bíi dọ́là 3 péré ló ń náni láti ṣe ohun abúgbàù kan tí ó jẹ́ fún ṣíṣèpalára fún àwọn ẹgbẹ́ ológun, àmọ́ láti mọ ibi tí ohun abúgbàù kan wà, kí a sì hú u jáde nínú ilẹ̀ ń náni ní iye tí ó tó 300 sí 1,000 dọ́là. Ní 1993, nǹkan bí 100,000 ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ ni a hú kúrò nílẹ̀, àmọ́ mílíọ̀nù méjì míràn ni a rì mọ́lẹ̀ lọ́tun. Gbogbo wọn jẹ́ panipani onísùúrù, tí kì í sùn, tí kò mọ̀yàtọ̀ láàárín sójà àti ọmọdé, tí kò mọ àdéhùn àlàáfíà kankan, ó sì ń gbéṣẹ́ fún ohun tí ó tó 50 ọdún.
Ní May 1996, lẹ́yìn ìjíròrò fún ọdún méjì ní Geneva, Switzerland, àwọn aṣàdéhùn àgbáyé kò lè fòfin de ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ káàkiri ayé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ irú àwọn ohun abúgbàù kan di aláìbófinmu tí wọ́n sì pààlà sí lílo àwọn mìíràn, a kì yóò tún ronú nípa fífòfinde ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ pátápátá títí di ìgbà àpérò fún àtúnyẹ̀wò tí ń bọ̀, tí yóò wáyé ní ọdún 2001. Láti ìsinsìnyí sí ìgbà náà, àwọn ohun abúgbàù àrìmọ́lẹ̀ yóò pa àwọn 50,000 ènìyàn míràn, yóò sì sọ 80,000 ènìyàn di aláàbọ̀ ara. Ọ̀pọ̀ lára wọn yóò jẹ́ ọmọdé.
Ìdálóró àti Ìfipábáni-Lòpọ̀
Nínú àwọn ogun tó jà láìpẹ́ yìí, a ti dá àwọn ọmọdé lóró, yálà láti fìyà jẹ àwọn òbí wọn tàbí láti fipá gba ìsọfúnni nípa àwọn òbí wọn. Nígbà míràn, nínú ipò àyíká ìforígbárí ẹlẹ́hànnà, a kò nílò okùnfà kankan, dídá àwọn ọmọdé lóró sì ń ṣẹlẹ̀ kìkì fún ìdánilárayá.
Ìwà ipá ìbálòpọ̀, títí kan ìfipábáni-lòpọ̀, wọ́pọ̀ nígbà ogun. Nígbà ogun tó ṣẹlẹ̀ ní àgbègbè Balkan, ó jẹ́ àṣà pàtó kan láti fipá bá àwọn ọ̀dọ́langba ọmọdébìnrin lò pọ̀ àti láti fipá mú wọn láti bímọ fún àwọn ọ̀tá wọn. Bákan náà, ní Rwanda, àwọn sójà lo ìfipábáni-lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣọṣẹ́ láti ba ìdè ìdílé jẹ́. Ní àwọn ìgbà kan tí wọ́n lọ digun kó àwọn ènìyàn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọ̀dọ́langba ọmọdébìnrin tí ó bọ́ lọ́wọ́ ìkọlù ẹgbẹ́ ológun ni wọ́n fipá bá lò pọ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n lóyún ni àwọn ìdílé àti ẹgbẹ́ àwùjọ wọ́n kọ̀. Àwọn ọmọdébìnrin kan gbé àwọn ọmọ wọn jù sílẹ̀; àwọn mìíràn pa ara wọn.
Ìrora Ti Èrò Ìmọ̀lára
Àwọn ọmọdé tí wọ́n wà nínú ogun sábà máa ń fara da àwọn ìrírí tí ó túbọ̀ le koko ju ìmọ̀lára ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ó burú jù lọ tí ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ń ní. Fún àpẹẹrẹ, ní Sarajevo, ìwádìí kan, nínú èyí tí a ti lo 1,505 ọmọdé, fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n ti nírìírí lílo ohun ìjà. Ó ju ìdajì lára wọn tó ti fara gbọta, ìdáméjì nínú mẹ́ta lára wọn sì ti wà nínú ipò tí wọ́n ti retí pé a óò pa àwọn.
Ìwádìí kan tí a ti lo àwọn 3,000 ọmọdé ilẹ̀ Rwanda fi hàn pé ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ni wọ́n ti rí ìwà ipá àti ìpànìyàn nígbà ìpalápalù ẹ̀yà náà, àti pé àwọn tí iye wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún ni wọ́n pàdánù àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámẹ́ta lára wọn tó ti rí ìfipábáni-lòpọ̀ tàbí ìbáni-ṣèṣekúṣe, ó sì lé ní ìdámẹ́ta lára wọn tó ti rí i tí àwọn ọmọdé mìíràn ń lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn tàbí ìluni. Irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ ń ba èrò inú àti ọkàn àyà àwọn ọmọdé jẹ́. Ìròyìn kan láti Yugoslavia, tí ó dá lórí àwọn ọmọdé tí a kó hílàhílo bá, sọ pé: “Wọ́n ṣì ń rántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà . . . èyí sì ń fa ìmọ̀lára ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ lílégbákan; rírántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ adanilórírú tí a kò retí, tí ń wá lójijì lójoojúmọ́; ìbẹ̀rù; àìláàbò àti ìbìnújẹ́ kíkorò.” Lẹ́yìn ìpalápalù ẹ̀yà tí ó wáyé ní Rwanda, afìṣemọ̀rònú kan ní Ibùdó Ìkọ́fẹpadà Nínú Hílàhílo ní Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Ìmọ̀lára ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀, ìṣòro ìpọkànpọ̀, ìsoríkọ́ àti èrò àìnírètí nípa ọjọ́ ọ̀la wà lára àwọn àmì tí ó máa ń hàn lára àwọn ọmọdé.”
Báwo Ni A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́?
Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèwádìí gbà gbọ́ pé hílàhílo kì í lọ nígbà tí àwọn ọmọdé bá bo ìmọ̀lára àti ohun tí wọ́n ń rántí mọ́ra. Ìwòsàn sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ọmọdé kan bá gbéjà ko àwọn ohun búburú tí ó ń rántí nípa bíbá àgbàlagbà olóye kan, tí ó sì ń gba tẹni rò, sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà sọ pé: “Èyí tí ó jẹ́ ìdajì lára ìjàkadì náà ni mímú kí àwọn ọmọ tí ìdààmú bá ní gidi ṣí ọkàn payá, ki wọ́n sì sọ̀rọ̀ fàlàlà.”
Àrànṣe pàtàkì míràn nínú wíwo ìdààmú ti èrò ìmọ̀lára náà sàn ni ìṣọ̀kan àti ìtìlẹ́yìn tí ó lágbára láti ọ̀dọ̀ ìdílé àti ẹgbẹ́ àwùjọ. Bíi gbogbo ọmọdé, àwọn òjìyà ìpalára ogun nílò ìfẹ́, òye, àti ìgbatẹnirò. Síbẹ̀, ìdí kan ha wà ní gidi láti gbà gbọ́ pé ìrètí wà fún gbogbo ọmọdé láti gbádùn ọjọ́ ọ̀la amọ́kànyọ̀ bí?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ó Rí Bíi Bọ́ọ̀lù
Ní Laos, ọmọdébìnrin kan àti arákùnrin rẹ̀ ń lọ mú ẹfọ̀n jẹko. Ọmọdébìnrin náà rí nǹkan kan tí ó jọ bọ́ọ̀lù nínú ihò kan. Ó mú un, ó sì jù ú sí arákùnrin rẹ̀. Nǹkan náà bọ́ sílẹ̀, ó bú gbàù, ó sì pa ọmọdékùnrin náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọ̀kanṣoṣo Lára Ẹgbẹẹgbẹ̀rún
Nígbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀ ní àgbègbè ibi tí Maria, ọmọ ọdún 12 kan, tí kò lóbìí, ń gbé ní Angola, wọ́n fipá bá a lò pọ̀, ó sì lóyún. Nígbà tí ogun náà ń le sí i, Maria sá lọ, ó sì rin 300 kìlómítà lọ sí ibì kan tí kò séwu, níbi tí ó ti wọ ibùdó ìtọ́jú àwọn ọmọ tí kò nílé. Nítorí pé ó kéré gan-an, ó tètè rọbí, ó sì bímọ tí oṣù rẹ̀ kò pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro. Ọ̀sẹ̀ méjì péré ni ọmọ tó bí náà fi gbé ayé. Maria kú ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà. Maria jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọdé tí wọ́n ti dá lóró, tí wọ́n sì fipá bá lò pọ̀ nígbà àwọn ogun tó ń ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Èrò Inú àti Ọkàn Àyà Tí Wọ́n Ṣe Níṣekúṣe
A fi bí ìwà ipá ṣe ń nípa lórí àwọn ọmọdé lọ́pọ̀ ìgbà hàn kedere nínú ọ̀ràn ti Shabana, ọmọ ọdún mẹ́jọ, láti Íńdíà. Ó wà níbẹ̀ nígbà tí ẹgbẹ́ àwọn akọluni kan lu bàbá rẹ̀ pa, tí wọ́n sì bẹ́ ìyá rẹ̀ lórí. Èrò inú àti ọkàn àyà rẹ̀ dòkú, ní títagọ̀ bo ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ àti àdánù náà. Ó sọ̀rọ̀ ní ṣàkó, láìsí ìmọ̀lára pé: “Àárò àwọn òbí mi kò sọ mí. N kò ronú nípa wọn.”