ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 12/8 ojú ìwé 6-9
  • Kíkẹ́ Lọmọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkẹ́ Lọmọ
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Onírúurú Ọ̀nà Ni Wọ́n Ń Gbà Hùwà Àìdáa Sáwọn Ọmọdé
  • Àwọn Tó Yẹ Ká fún Ní Àkànṣe Àfiyèsí
  • Ibùdó Ìgbàlà fún Àwọn Ọmọdé
  • A Ṣì Ń Wá Ojútùú Gidi
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ojútùú náà Rèé O, Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
    Jí!—2000
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 12/8 ojú ìwé 6-9

Kíkẹ́ Lọmọ

“FÌFẸ́ díẹ̀ hàn sí ọmọdé, òun yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an.” Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, John Ruskin, tí í ṣe òǹkọ̀wé àti olùṣelámèyítọ́ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ló kọ ọ̀rọ̀ yẹn. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ òbí gbà pé àǹfààní wà nínú ká nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹni, kì í ṣe kìkì nítorí ìfẹ́ táwọn náà á fi hàn sí wa, ṣùgbọ́n ní pàtàkì jù lọ, nítorí ipa rere tí ìfẹ́ yìí yóò ní lórí wọn.

Fún àpẹẹrẹ, ìwé Love and Its Place in Nature sọ pé láìsí ìfẹ́, “ó jọ pé ńṣe làwọn ọmọdé máa ń kú.” Ashley Montagu, tí wọ́n bí sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó sì jẹ́ olókìkí nínú ìmọ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, sọ pé: “Ìṣesí, ìgbòkègbodò, àti ìrònú òun ìhùwà ọmọ tí wọn kò fìfẹ́ hàn sí máa ń yàtọ̀ sí ti èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́. Bí ọmọ tí wọn kò nífẹ̀ẹ́ ṣe ń dàgbà tilẹ̀ máa ń yàtọ̀ sí ti èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́.”

Ìwé ìròyìn Toronto Star sọ nípa ìwádìí kan tí àbájáde rẹ̀ fi ohun tó jọ èyí hàn. Ó sọ pé: “Ara àwọn ọmọ tí a tọ́ dàgbà, tí a kì í gbá mọ́ra déédéé, tí a kì í fọwọ́ pa lára . . . kì í balẹ̀ rárá.” Ní ti gidi, pípa ọmọ tì nígbà tó ṣì jẹ́ ọmọ ọwọ́ “lè mú kí agbára ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àti agbára ìrántí rẹ̀ lábùkù fúngbà pípẹ́.”

Àwọn ìwádìí yìí fi ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí àwọn òbí àti ọmọ máa wà pa pọ̀ hàn. Àbí báwo ni ìdè tó lágbára ṣe lè wà láàárín òbí àti ọmọ? Ṣùgbọ́n ó bani nínú jẹ́ pé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ lágbàáyé pàápàá, ohun tí wọ́n ń ṣe nísinsìnyí ni pé kí wọ́n sáà ti pèsè àwọn ohun tí ọmọ kan nílò fún un bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ kò sí nítòsí. Wọ́n máa ń rán àwọn ọmọ lọ sí ilé ìwé, wọ́n máa ń ní kí wọ́n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi, wọ́n máa ń ní kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́, wọ́n máa ń ní kí wọ́n lọ sí àwọn òde ẹgbẹ́, wọ́n sì máa ń fún wọn lówó pé kí wọ́n ṣeré lọ. Bí ìgbà tí wọ́n ta àwọn ọmọ wọ̀nyí nù kúrò nínú ìdílé ló rí, àti pé gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ wọ̀nyí wá mọ̀—bóyá wọ́n sì rò bẹ́ẹ̀ ni o—pé a pa àwọn tì, a kò fẹ́ àwọn, àti pé a kò nífẹ̀ẹ́ àwọn, pé àwọn àgbàlagbà tí kò fẹ́ rí wọn sójú ló yí àwọn ká. Irú èrò tó wọ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn ọmọdé lè jẹ́ ìdí kan tí àwọn ọmọ asùnta tí wọ́n pọ̀ tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] fi sábà máa ń fi ẹ̀hónú hàn ní Berlin. Àpẹẹrẹ kan ni Micha, tí ó sọ pé: “Kò sẹ́ni tó fẹ́ mi mọ́.” Ọmọdékùnrin ọlọ́dún mẹ́sàn-án kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì sì fìbínú sọ bákan náà pé: “Ajá wá sàn jù mí lọ.”

Onírúurú Ọ̀nà Ni Wọ́n Ń Gbà Hùwà Àìdáa Sáwọn Ọmọdé

Pípa ọmọ tì jẹ́ ọ̀kan lára ìwà àìdáa tó ń fi hàn pé àwọn èèyàn kò ní ànímọ́ tí Bíbélì pè ní “ìfẹ́ni àdánidá.” (Róòmù 1:31; 2 Tímótì 3:3) Ó sì lè ṣamọ̀nà sí híhu àwọn ìwà àìdáa tó tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Fún àpẹẹrẹ, láti ìgbà tí wọ́n ti ṣe Ọdún Àwọn Ọmọdé ní Àgbáyé ní ọdún 1979 ni wọ́n ti túbọ̀ ń pe àfiyèsí sórí ìṣòro fífi ìyà jẹ àwọn ọmọdé àti bíbá wọn ṣèṣekúṣe. Lóòótọ́, ó ṣòro láti mọ bó ṣe pọ̀ tó gẹ́lẹ́, bí wọ́n sì ṣe ń ṣẹlẹ̀ níbì kan yàtọ̀ sí òmíràn. Ṣùgbọ́n kò sí iyè méjì pé ẹ̀dùn ọkàn tí ń bá àwọn ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe fínra láti kékeré títí wọn yóò fi dàgbà ṣòro láti wò sàn.

Láìka irú ìwà àìdáa tí wọ́n hù sí àwọn ọmọdé sí, ohun tó ń gbìn sí wọn lọ́kàn ni pé a ò nífẹ̀ẹ́ wọn, a ò sì fẹ́ rí wọn sójú. Ó sì jọ pé ńṣe ni ìṣòro yìí ń pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà Die Welt ti sọ, “púpọ̀ púpọ̀ àwọn ọmọdé ló ń dàgbà di ẹni tí kò tẹ́gbẹ́ láwùjọ.” Ó tún sọ pé: “A kò fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọdé mọ́ ní ilé. Gẹ́gẹ́ bí [Gerd Romeike, ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ kan tó ń rí sí ọ̀ràn títọ́ àwọn ọmọdé sọ́nà ní Hamburg], ti sọ, ìdè ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn ọmọ àti àwọn òbí ti ń dẹ̀, tàbí kó jẹ́ pé ìdè ọ̀hún ò sí níbẹ̀ rí ni ká kúkú wí. Irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ń lérò pé a pa àwọn tì ni, wọn kì í sì í rí ààbò tí wọ́n fẹ́.”

Àwọn ọmọ tí a fi ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ẹni tí a nífẹ̀ẹ́ dù lè ní ẹ̀mí ìkórìíra, kí wọ́n sì máa fi ìkanra mọ́ àwọn tó pa wọ́n tì tàbí mọ́ àwùjọ lódindi. Ó kéré tán, ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ìròyìn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe kan ní Kánádà ta àwọn ará ìlú lólobó pé ó yẹ kí wọ́n gbégbèésẹ̀ láìjáfara ká má bàa pàdánù odindi ìran ènìyàn kan “tí wọ́n rò pé àwùjọ kò bìkítà nípa àwọn.”

Àwọn ọ̀dọ́ tí a kò nífẹ̀ẹ́ lè gbèrò láti sá kúrò nílé láti mórí bọ́ nínú ìṣòro wọn, ṣùgbọ́n wọ́n á wá rí i pé ìṣòro náà túbọ̀ pọ̀ gan-an ní àwọn ìlú ńlá tí ìwà ọ̀daràn, ìjoògùnyó, àti ìwà pálapàla kún. Ní ti gidi, ní ohun tó lé ní ogún ọdún sẹ́yìn, àwọn ọlọ́pàá fojú díwọ̀n pé ọ̀kẹ́ kan àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún tó sá kúrò nílé ló ń dá gbé ní àgbègbè kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. A ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ tó ti yàyàkuyà nítorí pé ìdílé wọ́n ti tú ká àti nítorí ìwà òkú òǹrorò, tí àwọn òbí tó ya ọlọ́tí tàbí ajoògùnyó sábà máa ń hù. Wọ́n ti já sí ìgboro, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó jẹun, tó bá sì yá, tí àwọn abáṣẹ́wó-wóníbàárà wá lù wọ́n nílùkulù, tí wọ́n sì bọ́ṣọ iyì lára wọn, àwọn ọmọ wọ̀nyí á tún máa bẹ̀rù àtisá fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, nítorí pé tí wọ́n bá dán an wò, pásapàsa ìyà ni yóò jẹ wọ́n.” Ó bani nínú jẹ́ láti sọ pé lójú bí a ṣe ń fi òtítọ́ inú gbìyànjú láti yí ipò tí ń bani nínú jẹ́ yìí padà, kò kásẹ̀ nílẹ̀.

Àwọn ọmọ tí wọ́n dàgbà sínú irú ipò tí a ṣàpèjúwe lókè yìí kì í ní láárí tí wọ́n bá dàgbà, lọ́pọ̀ ìgbà wọn kì í lè tọ́ ọmọ tiwọn dáadáa. Níwọ̀n bí a kò ti nífẹ̀ẹ́ wọn, ọmọ bíi tiwọn náà ni wọ́n á máa bí jọ—àwọn ọmọ tó rí i pé a kò nífẹ̀ẹ́ àwọn. Láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀, òṣèlú kan ní ilẹ̀ Jámánì sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Bí àwọn ọmọ tí a kò nífẹ̀ẹ́ bá dàgbà, ìkórìíra ló máa kún inú wọn.”

Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òbí ló ń sa ipá wọn láti jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn. Wọn kì í kàn fẹnu lásán sọ bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n ń fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn nípa fífi ìfẹ́ bójú tó àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n sì ń fún wọn ní àfiyèsí tó tọ́ sí olúkúlùkù ọmọ. Ṣùgbọ́n ìṣòro ṣì ń wà—àwọn ìṣòro tí ẹ̀rí fi hàn kedere pé ó kọjá agbára òbí kọ̀ọ̀kan láti yanjú. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn apá ibì kan nínú ayé, ètò ọrọ̀ ajé àti ètò ìṣèlú tí àwọn ènìyàn aláìpé ń darí kò lè bójú tó ìlera àwọn ọmọdé, kò lè pèsè ẹ̀kọ́ tó yẹ, àti oúnjẹ tó pọ̀ tó, kò sì lè dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìyà tó ń tìdí kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ wá, kò sì lè gbà wọ́n lọ́wọ́ ipò òṣì tí wọ́n ń gbé. Bákan náà, lọ́pọ̀ ìgbà ohun tó máa ń mú kí àwọn ipò nǹkan burú sí i ni ìwọra, ìwà ìbàjẹ́, ìmọtara-ẹni-nìkan, àti àwọn àgbàlagbà tí kì í gba ti ọmọnìkejì wọn rò.

Kofi Annan, ọ̀gá àgbà àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ díẹ̀ lára àwọn lájorí ìṣòro táwọn ọmọdé ń ní lónìí nígbà tó kọ̀wé pé: “Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé ni kò sí nǹkan tí wọ́n lè ṣe bí kò ṣe pé kí wọ́n máa fara da ìṣẹ́ tó ń ṣẹ́ wọn; ẹgbàágbèje wọn ni àbájáde ogun àti ọrọ̀ ajé tó dojú dé ń hàn léèmọ̀; ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn ni ogun ti sọ dẹni tó ti gé lápá tàbí lẹ́sẹ̀; púpọ̀ wọn ló ti di ọmọ òrukàn, àrùn éèdì sì ń pa púpọ̀ nínú wọn.”

Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ìgbà ni nǹkan ń burú fún wọn! Àwọn àjọ tó jẹ́ apá kan àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, bí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF) àti Àjọ Ìlera Àgbáyé, ti sakun láti mú kí ipò àwọn ọmọdé sunwọ̀n sí i. Ọ̀gbẹ́ni Annan sọ pé: “Púpọ̀ ọmọ tí a ń bí ni ara wọn ń le, púpọ̀ wọn ni a sì ń fún lábẹ́rẹ́ àjẹsára; púpọ̀ wọn ló mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà; púpọ̀ wọn ló lómìnira láti kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n ṣeré, kí wọ́n sì máa gbé ìgbésí ayé wọn bí ọmọdé ju bí a ṣe lè rò pé kí ó rí ní ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn.” Àmọ́, ó tún kìlọ̀ pé: “Kò wá yẹ kí àwọn àṣeyọrí tí a ti ṣe mú ká fọwọ́ lẹ́rán o.”

Àwọn Tó Yẹ Ká fún Ní Àkànṣe Àfiyèsí

Ó yẹ ká fún àwọn ọmọ kan ní àkànṣe àfiyèsí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún ọdún 1960, ó ba aráyé lẹ́rù nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ìròyìn láti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ìròyìn náà sọ nípa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ tí wọ́n ń bí ní abirùn nítorí àwọn oògùn apanilọ́bọlọ̀. Bí àwọn obìnrin tó lóyún bá lo àwọn oògùn náà, ó máa ń di ìṣòro sí wọn lọ́rùn bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò retí pé kó fún àwọn níṣòro, ìyẹn ló sì máa ń mú kí wọ́n bí àwọn ọmọ tí ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọ́n rọ tàbí ọmọ tí kò lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀. Ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn á wá kéré gan-an.

Ogójì ọdún ti kọjá lọ, ohun tó tún lè máa gé àwọn ọmọdé lọ́wọ́ tàbí ẹsẹ̀ ni bọ́ǹbù tí wọ́n ń kẹ́ sílẹ̀.a Àwọn kan fojú bù ú pé nǹkan bí ọgọ́ta sí àádọ́fà mílíọ̀nù bọ́ǹbù tí wọ́n ti kẹ́ sílẹ̀ ló wà káàkiri ayé. Àròpọ̀ àwọn tí wọ́n ń pa àti àwọn tí wọ́n ń gé lọ́wọ́ tàbí lẹ́sẹ̀ lọ́dọọdún jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26,000]. Láti ọdún 1997, nígbà tí Jody Williams gba Ẹ̀bùn Nobel ti Àlàáfíà nítorí ìpolongo tó ṣe pé kí wọ́n fòfin de kíkẹ́ bọ́ǹbù sílẹ̀, ni wọ́n ti mú ọ̀ràn náà lọ́kùn-únkúndùn. Ṣùgbọ́n àwọn bọ́ǹbù tí wọ́n kẹ́ sílẹ̀ ṣì wà káàkiri. Òṣèlú ará Jámánì kan sọ nípa ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbìyànjú láti palẹ̀ àwọn bọ́ǹbù tí wọ́n kẹ́ sílẹ̀ mọ́ lágbàáyé, ohun tó sọ ni pé: “Ńṣe ló dà bíi fífi ṣíbí gbọ́nmi kúrò nínú àmù ńlá tí a kò sì yé dami sínú rẹ̀.”

Ọ̀wọ́ àwọn ọmọ mìíràn tí wọ́n ń fẹ́ àkànṣe àfiyèsí ni àwọn tí wọn kò ní òbí. Jèhófà Ọlọ́run, tí í ṣe Ẹlẹ́dàá ènìyàn, pète pé kí àwọn ọmọ dàgbà níbi tí ìyá àti bàbá ti ń bójú tó wọn tìfẹ́tìfẹ́. Ọmọ kan nílò irú àbójútó bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ ìyá àti bàbá, ó sì lẹ́tọ̀ọ́ sí i.

Àwọn ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀ràn gbígba ọmọ ẹlòmíràn ṣọmọ ló ń gbìyànjú láti gbọ́ bùkátà àwọn ọmọ tí kò ní ìyá àti bàbá. Ṣùgbọ́n ó bani nínú jẹ́ pé àwọn tó yẹ kí a gbà ṣọmọ gan-an lára àwọn òtòṣì ọmọ wọ̀nyí ni a ń pa tì jù—ìyẹn àwọn tí ara wọn kò le, tí ó ṣòro fún wọn láti kẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n jẹ́ abirùn tàbí tí àwọn òbí wọ́n jẹ́ àjèjì.

Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ ni wọ́n ti dá sílẹ̀ tí wọ́n fi ń rọ àwọn èèyàn láti máa dáwó déédéé kí wọ́n lè “gba” ọmọ kan tó ń gbé orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ “ṣọmọ.” Wọ́n á máa fi owó tí wọ́n ń dá náà rán ọmọ yẹn lọ sílé ìwé tàbí kí wọ́n máa fi gbọ́ bùkátà rẹ̀. Bí wọ́n bá fẹ́, wọ́n tilẹ̀ lè máa fi fọ́tò ránṣẹ́ síra wọn, kí wọ́n sì máa kọ̀wé síra wọn kí àjọṣe wọn lè lágbára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò yìí wúlò, kì í ṣe ojútùú tó pé tán ni.

Àpẹẹrẹ ohun mìíràn tó gbàfiyèsí tí wọ́n ti ṣe láti fi ran àwọn ọmọdé tí wọn kò lóbìí lọ́wọ́ ni ibùdó kan tí wọ́n ṣe àyájọ́ àádọ́ta ọdún rẹ̀ ní ọdún 1999.

Ibùdó Ìgbàlà fún Àwọn Ọmọdé

Ní ọdún 1949, Hermann Gmeiner ṣí ibùdó kan tó pè ní Ibùdó Ìgbàlà fún Àwọn Ọmọdé sílẹ̀ ní ìlú Imst, ní orílẹ̀-èdè Austria. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ibi kékeré bẹ̀rẹ̀, ní báyìí ó ti gbèrú, wọ́n sì ti ní iye tí ó sún mọ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ibùdó sí i, irú ibùdó bẹ́ẹ̀ sì ti wà ní ọ̀kàn lé ní àádóje orílẹ̀-èdè ní Áfíríkà, Amẹ́ríkà, Éṣíà, àti Yúróòpù.

Orí ohun mẹ́rin ni Gmeiner gbé ìlànà ohun tó dáwọ́ lé náà kà, àwọn ni ìyá, àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, ilé, àti abúlé. “Ìyá” ló jẹ́ ìpìlẹ̀ “ìdílé” tí wọ́n ti ní ọmọ márùn-ún tàbí mẹ́fà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ń gbé pọ̀ pẹ̀lú wọn, ó sì ń gbìyànjú láti fún wọn ní àfiyèsí àti ìfẹ́ tí a retí lọ́dọ̀ ìyá gidi. Àwọn ọmọ náà ń gbé pọ̀ nínú “ìdílé” kan náà pẹ̀lú “ìyá” kan náà títí di ìgbà tí wọn óò fi “ilé” sílẹ̀. Ọjọ́ orí àwọn ọmọ tó wà nínú “ìdílé” náà kò dọ́gba. Níwọ̀n bí àwọn ọmọ náà ti ní “ẹ̀gbọ́n” àti “àbúrò” lọ́kùnrin àti lóbìnrin, wọ́n ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣaájò ara wọn, èyí sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti má ṣe ya anìkànjọpọ́n. Wọ́n ń sapá láti mú àwọn ọmọ náà ṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí “ìdílé” kan nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Wọ́n máa ń fi àwọn tí òbí kan náà bí sínú “ìdílé” kan náà.

Nǹkan bí “ìdílé” mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló para pọ̀ di abúlé kan, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń gbé ilé tiwọn. Wọ́n ń kọ́ gbogbo àwọn ọmọ náà láti máa ran “ìyá” wọn lọ́wọ́ nípa ṣíṣe àwọn iṣẹ́ ilé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí bàbá níbẹ̀, wọ́n ṣètò pé kí àwọn ọkùnrin máa ṣèrànwọ́ láti máa gbà wọ́n nímọ̀ràn tó yẹ kí bàbá máa gbani, kí wọ́n sì bá wọn wí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ilé ìwé tó wà ládùúgbò ni àwọn ọmọ náà ń lọ. “Ìdílé” kọ̀ọ̀kan ń gba iye owó kan lóṣooṣù tí wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà. Àdúgbò wọn níbẹ̀ ni wọ́n ti ń ra oúnjẹ àti aṣọ. Ète rẹ̀ jẹ́ láti jẹ́ kí àwọn ọmọ náà máa gbé ìgbésí ayé wọn bí ìdílé ṣe ń ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣòro àti ayọ̀ tí ń bẹ nínú ìdílé, tí èyí sì ń jẹ́ kí wọ́n máa gbé ìgbésí ayé tó bójú mu bó ti lè ṣeé ṣe tó. Èyí ń múra wọn sílẹ̀ láti lè bójú tó ìdílé tiwọn tí wọ́n bá dàgbà.

A Ṣì Ń Wá Ojútùú Gidi

Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀ràn gbígba ọmọ ẹlòmíràn ṣọmọ, àwọn ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn, Ibùdó Ìgbàlà fún Àwọn Ọmọdé, àjọ UNICEF, àti àwọn àjọ àti ẹgbẹ́ tó dà bíi wọn ṣe dáadáa nípa gbígbìyànjú láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ tí òṣì ń ta. Ṣùgbọ́n kò sí ìkankan lára wọn tó lè sẹ́ òtítọ́ náà pé òṣì ń ta àwọn èèyàn kan. Láìka bí wọ́n ṣe fẹ́ láti ṣèrànwọ́ tó sí, wọn kò lè fún ọmọ tó yarọ lẹ́sẹ̀ tuntun, wọn kò lè mú abirùn ọmọ lára dá, wọn kò lè mú ọmọ tí àwọn òbí rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú wọn, bákan náà ni wọn kò lè mú òbí rẹ̀ tó ti dolóògbé padà wá fún un.

Bó ti wù kí ẹ̀dá ènìyàn sapá tó, kò lè ṣeé ṣe fún wọn láti rí ojútùú gidi sí ìṣòro tí àwọn ọmọdé ń ní. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣì ń bọ̀ wá ní ojútùú! Òtítọ́ ni, ìyẹn sì lè yá ju bí o ṣe rò lọ. Ṣùgbọ́n lọ́nà wo?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Land Mines—What Can Be Done?” tí ó jáde nínú ìtẹ̀jáde wa ti May 8, 2000, lédèe Gẹ̀ẹ́sì.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ọmọ kan nílò irú àbójútó bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ ìyá àti bàbá, ó sì lẹ́tọ̀ọ́ sí i

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́