Ojútùú náà Rèé O, Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
FOJÚ inú wo ayé kan tí olúkúlùkù ọmọ yóò ti jẹ́ ẹni ìkẹ́, ẹni ìgẹ̀, tí a sì fi àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n bìkítà jíǹkí, tí wọ́n ní ìfẹ́ àtọkànwá láti pèsè ìtọ́sọ́nà àti ìdarí tó dára jù lọ fún ọmọ wọn. Fojú inú wo ayé kan tí ara olúkúlùkù ọmọ ti le dáadáa, tí ọpọlọ wọ́n sì jí pépé, tí kò sí àwọn ọmọ asùnta níbẹ̀, tí a kò sì fi ẹ̀tọ́ ìgbà ọmọdé du àwọn ọmọ nítorí ipò ìṣúnná owó tó sọ ọ́ di dandan fún wọn láti máa ṣiṣẹ́!
Ṣé irú ibi tí a ń sọ yìí fani lọ́kàn mọ́ra? Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ó ṣeé gbà gbọ́? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rò bẹ́ẹ̀, ohun méjì ló sì mú kí wọ́n rò bẹ́ẹ̀.
Àwọn Òbí Lè Wá Díẹ̀ Lára Ojútùú Náà
Ó dájú pé ìwọ yóò gbà pé àwọn àgbàlagbà ní agbára láti yanjú díẹ̀ lára àwọn ìṣòro táwọn ọmọdé ń ní, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ dènà rẹ̀ nígbà mìíràn. Àmọ́ ṣá o, ìyẹn tí àwọn àgbàlagbà náà bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni, àwọn òbí fúnra wọn ní ọ̀kan lára ojútùú sí ìṣòro náà lọ́wọ́.
Fún àpẹẹrẹ, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé “kí aya má lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ . . . kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀” kì í bí àwọn ọmọ tí ìyà ń jẹ nítorí pé wọ́n ń gbé inú ilé tí ìkọ̀sílẹ̀ ti pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ.—1 Kọ́ríńtì 7:10, 11.
Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n fẹ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé “kí a máa rìn lọ́nà bíbójúmu, kì í ṣe nínú àwọn àríyá aláriwo àti mímu àmuyíràá,” kì í bí àwọn ọmọ tí ń ní ìrora ọkàn tí àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn jẹ́ ọ̀mùtípara tàbí ajoògùnyó ń ní.—Róòmù 13:13; Éfésù 5:18.
Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n fẹ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé “kí ẹ ta kété sí àgbèrè” ń ṣèdíwọ́ fún bíbímọ àìròtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ pé ẹyọ kan nínú òbí méjì tí í tọ́ ọmọ ni yóò tọ́ ọ dàgbà.—1 Tẹsalóníkà 4:3; Mátíù 19:9.
Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n fẹ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì pe, “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò,” tí wọ́n sì “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn” kò ní bí àwọn ọmọ tí ń jẹ̀rora tàbí tí ìdààmú ọkàn bá nítorí oríṣiríṣi ìwà àìdáa tí wọ́n hù sí wọn.—Kólósè 3:21; Títù 2:4.
Lákòópọ̀, bí gbogbo àwọn àgbàlagbà bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì tí Jésù fúnni sílò pé, “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn,” ṣé a óò rí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọ tí a kò fẹ́ tàbí tí a kò fìfẹ́ hàn sí?—Mátíù 7:12.
Ó dùn mọ́ni nínú pé ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ló ń fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí a tò sókè yìí. Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo wọn ló fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ibi tí ìṣòro náà sì wà nìyẹn. Àti pé àwọn tí wọ́n fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá ń rí i pé àìpé ẹ̀dá àti àwọn ohun tó le ju agbára wọn ń mú kí ìsapá àwọn forí ṣánpọ́n nígbà mìíràn. Àwọn èèyàn lè wá díẹ̀ lára àwọn ojútùú sí ìṣòro tí àwọn ọmọdé ń ní, àmọ́ ó hàn kedere pé wọn kò lè wá ojútùú sí gbogbo rẹ̀.
Ìjọba Ọ̀run Tí Yóò Wá Ojútùú sí Gbogbo Rẹ̀
Òǹkọ̀wé John Ruskin, tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, gbà tọkàntọkàn pé “lájorí ojúṣe Ìjọba kan ni láti rí i pé olúkúlùkù ọmọ tí a bí sí orílẹ̀-èdè wọn ní ilé gidi, aṣọ tó dára, oúnjẹ tó dára, kí wọ́n sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tó jíire, títí wọn yóò fi dàgbà di ẹni tó tójú bọ́.” Ṣùgbọ́n, Ruskin sọ pé, “láti lè [ṣàṣeparí] èyí, Ìjọba gbọ́dọ̀ ní àṣẹ lórí àwọn èèyàn tí a kò tilẹ̀ lè ronú kàn ní lọ́ọ́lọ́ọ́.”
Kìkì ìjọba tó ní ìtìlẹ́yìn àtọ̀runwá ló lè ní irú àṣẹ onínúure tí Ruskin sọ nípa rẹ̀ yẹn. Irú ìjọba yẹn gẹ́lẹ́ ni a sì ti ṣèlérí—èyí tí Jésù mẹ́nu kàn nínú Mátíù 6:9, 10. Gbàrà tí ìjọba yìí, tí Ọlọ́run yóò mú wá bá ti gba ìṣàkóso pátápátá lórí àwọn àlámọ̀rí ayé, yóò máa lo àṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ènìyàn, tí yóò máa pèsè ilé, aṣọ, oúnjẹ, tí yóò sì máa kọ́ gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, títí kan àwọn ọmọdé. (Aísáyà 65:17-25) Ṣùgbọ́n ìjọba pípé yìí yóò ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìjọba Ọlọ́run yóò mú àwọn ènìyàn padà bọ̀ sí ìjẹ́pípé, yóò sì jẹ́ kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ lọ́nà tó gbá múṣé. (Jóòbù 33:24-26) Wọn óò tọ́ àwọn ọmọ nínú ipò alálàáfíà àti ẹ̀mí ará níbi gbogbo, ipò dídára tí a là kalẹ̀ nínú Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọdé tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ṣe. (Sáàmù 46:8, 9) A kò tún ní nílò Ọdún Àwọn Ọmọdé ní Àgbáyé, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní nílò Àdéhùn Nípa Ẹ̀tọ́ Ọmọdé mọ́.
Fífún àwọn òbí àti àwọn abirùn ọmọ ní ìlera pípé yóò jẹ́ iṣẹ́ tó rọrùn fún Kristi Jésù, tí í ṣe Ọba ìjọba ọ̀run yìí. Àwọn iṣẹ́ ìyanu ìmúláradá tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé mú èyí dáni lójú. (Lúùkù 6:17-19; Jòhánù 5:3-9; 9:1-7) Kódà, jíjí àwọn ọmọdé àti àwọn òbí tó ti kú dìde pàápàá kò ní ju agbára rẹ̀ lọ láti ṣe!—Mátíù 9:18-25.
Ohun ìdùnnú gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé àkókò tí Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀ láti yanjú ìṣòro àwọn ọmọdé tó wà ní ayé ti sún mọ́lé!
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ìrànwọ́ fún Àwọn Ọ̀dọ́
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìfẹ́ gan-an nínú ríran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún ìṣòro àti láti fi hàn wọ́n bí wọ́n ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Nítorí náà, láti àwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n ti tẹ àwọn ìwé mélòó kan láti kájú àìní àwọn ọ̀dọ́—láti orí àwọn ọmọ jẹ́lé-ó-sinmi dé orí àwọn ọ̀dọ́langba. Lára àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ni ìwé náà, Iwe Itan Bibeli Mi àti Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ àti fídíò tó ní àkọlé náà, Young People Ask—How Can I Make Real Friends? O lè gba àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń gbé àdúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwa tí a ṣe ìwé ìròyìn yìí.
Ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn mọ̀ pé àwọn fẹ́ wọn àti pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn nípa jíjíròrò àwọn ìṣòro tí wọ́n ń ní pẹ̀lú wọn déédéé. Àwọn òbí sábà máa ń lo ìsọfúnni dáadáa tí a kọ sínú àwọn ìwé tí a ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́, tí a mẹ́nu kàn lókè gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ń tẹ̀ síwájú, tí wọ́n ń ṣe déédéé fún kíkọ́ ọ̀dọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Ìwọ alára lè fẹ́ láti lo irú ìlànà kan náà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ.