ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 1/8 ojú ìwé 20-22
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Ǹjẹ́ Ojútùú Kan Tiẹ̀ Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjí Èèyàn Gbé—Ǹjẹ́ Ojútùú Kan Tiẹ̀ Wà?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipá Tí Wọ́n Ti Sà
  • Àbá Pọ̀—Ṣùgbọ́n Ojútùú Ò Tó Nǹkan
  • Ojútùú Kan Wà
  • Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Tó Dára Ṣe Pàtàkì
  • Mímú Àwọn Oníwàkiwà Kúrò
  • Ayé Tuntun Òdodo
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Òwò Àwọn Apanilẹ́kún-Jayé
    Jí!—2000
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Lájorí Ohun Tó Ń Fà Á
    Jí!—2000
  • Jíjí Èèyàn Gbé Ti Di Òwò Tó Kárí Ayé
    Jí!—2000
  • A Rí Ọwọ́ Agbára Ọlọ́run Lára Wa
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 1/8 ojú ìwé 20-22

Jíjí Èèyàn Gbé—Ǹjẹ́ Ojútùú Kan Tiẹ̀ Wà?

“Ọ̀RÀN jíjí èèyàn gbé ti wá le débi tí ara gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè yìí ò gbà á mọ́ o, gbogbo wa pátá la ó sì gbógun ti ìwà ibi yìí,” igbe tí olórí orílẹ̀-èdè Chechnya fi bẹnu nìyẹn nígbà tó ń ṣèlérí pé òun á mú ìṣòro jíjí èèyàn gbé tó ń bá ìpínlẹ̀ rẹ̀ ní Rọ́ṣíà fínra kúrò.

Ṣé pé ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé ṣeé mú kúrò? Ì bá mà dára o, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ká bi wọ́n léèrè pé, Báwo ni wọn ó ti ṣe é?

Ipá Tí Wọ́n Ti Sà

Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Kòlóńbíà ti da ẹgbàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, agbẹjọ́rò ìjọba mẹ́rìnlélógún, àti àkànṣe olùṣekòkáárí ìgbógunti ìjínigbé síta nítorí àtigbógun ti jíjí èèyàn gbé. Ní ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro, ní Brazil, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún èèyàn ló tú síta tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn nítorí jíjí tí wọ́n ń jí àwọn èèyàn gbé lemọ́lemọ́ nílùú náà. Ní Brazil àti Kòlóńbíà, àwọn ẹgbẹ́ tí iṣẹ́ wọ́n jọ ti ológun pẹ̀lú ti ń lọ jí àwọn ẹbí àwọn ajínigbé náà gbé. Díẹ̀ lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Philippines sì ń dá ẹgbẹ́ ojúlalákàn-fi-ń-ṣọ́rí sílẹ̀ láti gbèjà ara wọn—wọ́n ń pa àwọn ajínigbé!

Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Guatemala ti gbé òfin kalẹ̀ pé pípa ni wọn yóò máa pa àwọn ajínigbé, ààrẹ ilẹ̀ náà sì ta àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jí láti dá àjàkálẹ̀ jíjí èèyàn gbé dúró. Ní Ítálì, ìjọba gbé àwọn òfin tó lágbára kalẹ̀ láti dènà jíjí èèyàn gbé, wọ́n fòfin de sísan owó ìtúsílẹ̀, wọ́n sì ń gbẹ́sẹ̀ lé owó àti dúkìá àwọn ẹbí ẹni tí wọ́n jí gbé kí wọ́n má bàa lọ san owó náà. Àwọn lọ́gàálọ́gàá ní Ítálì ń yangàn pé àwọn òfin wọ̀nyí ti dín ìṣẹ̀lẹ̀ jíjí èèyàn gbé kù. Àmọ́, àwọn olùṣelámèyítọ́ ń sọ pé ìyọrísí rẹ̀ ni pé àwọn ìdílé ẹni tí wọ́n jí gbé máa ń gbìyànjú láti yanjú ọ̀ràn náà ní bòókẹ́lẹ́ àti pé èyí ń dín iye ìjínigbé tí ìjọba gbọ́ nípa rẹ̀ kù. Àwọn ilé iṣẹ́ àdáni tí n ṣètò ààbò fojú díwọ̀n rẹ̀ pé iye àwọn èèyàn tí wọ́n ń jí gbé ní Ítálì ti di ìlọ́po méjì láti ọdún 1980 sí 1989.

Àbá Pọ̀—Ṣùgbọ́n Ojútùú Ò Tó Nǹkan

Lójú àwọn ìdílé ẹni tí a jí gbé, ojútùú kan ṣoṣo ló jọ pé ó gbéṣẹ́—láti fowó gba èèyàn wọn sílẹ̀ bó bá ṣe lè yá tó. Ṣùgbọ́n àwọn ògbógi kìlọ̀ pé bí owó ìtúsílẹ̀ náà bá pọ̀ tí wọ́n sì tètè san án, àwọn ajínigbé lè wá ka ìdílé náà sí èyí tó rọrùn láti halẹ̀ mọ́, wọ́n sì tún lè padà wá. Tàbí kí wọ́n béèrè owó ìtúsílẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì kí wọ́n tó tú ẹni tí wọ́n jí gbé sílẹ̀.

Àwọn ìdílé kan tilẹ̀ ti san owó ìtúsílẹ̀ gọbọi kí wọ́n tó wá mọ̀ pé ẹni tí wọ́n torí ẹ̀ sanwó náà ti kú. Nítorí náà, àwọn ògbógi sọ pé a kò gbọ́dọ̀ san owó ìtúsílẹ̀ tàbí ká máa bá wọn dúnàádúrà àyàfi tí a bá rí ẹ̀rí pé ẹni tí wọ́n jí gbé náà ṣì wà láàyè. Irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ìdáhùn sí ìbéèrè tó jẹ́ pé ẹni tí wọ́n jí gbé náà nìkan ló lè dáhùn rẹ̀. Àwọn ìdílé kan máa ń béèrè pé àwọn fẹ́ rí fọ́tò ẹni tí wọ́n jí gbé náà níbi tó ti mú ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ kan dání.

Ọ̀ràn ti fífi ipá gbà wọ́n sílẹ̀ ńkọ́? Ó sábà máa ń la ewu ńlá lọ. Brian Jenkins, tó jẹ́ ògbógi nínú bíbójútó ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé, sọ pé: “Ní Látìn Amẹ́ríkà, ìpín mọ́kàndínlọ́gọ́rin lára gbogbo ẹni tí wọ́n mú ní òǹdè ni wọ́n pa nígbà tí a gbégbèésẹ̀ àtifipá gbà wọ́n sílẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà míì, ìgbésẹ̀ ìfipá gbà wọ́n sílẹ̀ máa ń kẹ́sẹ járí.

Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára ojútùú tó wà ló dá lórí bí a kò ṣe ní jẹ́ kí wọ́n rí wa jí gbé. Kì í ṣe àwọn aṣojú ìjọba nìkan ló ń ṣiṣẹ́ lórí ọ̀ràn àtidènà jíjí èèyàn gbé. Àwọn oníwèé ìròyìn ń kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe lè ṣe é tí a kò ní jí wọn gbé, bí wọ́n ṣe lè bẹ́ jáde láti inú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó wà lórí eré, àti bí wọ́n ṣe lè lo agbárí fún àwọn ajínigbé. Àwọn tó ń kọ́ èèyàn ní ìjà bíi júdò àti kàréètì ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí a ṣe lè gba ara ẹni lọ́wọ́ ajínigbé. Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ẹ̀rọ tí ìró rẹ̀ ń tú nǹkan fó pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún dọ́là lórí rẹ̀, ẹ̀rọ kíkéré jọjọ náà ṣeé kì bọ eyín ọmọdé tí yóò jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá lè wá ọmọ tí wọ́n bá jí gbé kàn. Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ máa ń ṣe àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ “tí ń dènà ìjínigbé” fún ẹni tó bá lówó rẹ̀, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà máa ń ní àwọn ohun tó ń tú èéfín tajútajú sáfẹ́fẹ́, àwọn ojú ihò tí a lè gbà na ìbọn, àwọn gíláàsì ara ilẹ̀kùn ọkọ̀ tí ọta ò lè bà jẹ́, àwọn táyà tí kò ṣeé bẹ́, àti àwọn ohun tó ń tú ọ́ìlì sójú títì, kí ó lè máa yọ̀.

Ọ̀nà kan tí àwọn olówó ń gbà dènà rẹ̀ jẹ́ nípa gbígba àwọn gìrìpá tó ń ṣọ́ wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Francisco Gomez Lerma tó jẹ́ ògbógi nínú ọ̀ràn ààbò ń sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní Mexico, ó sọ pé: ‘Gbígba àwọn gìrìpá tó ń ṣọ́ èèyàn kò lè yanjú ọ̀ràn náà nítorí pé wọ́n máa ń gbàfiyèsí àwọn èèyàn, wọ́n tiẹ̀ lè lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ajínigbé.’

Ìṣòro jíjí èèyàn gbé náà díjú gan-an, ó sì ta gbòǹgbò tó pọ̀ gan-an débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí aráyé lè ṣe sí i tí yóò mú un kúrò. Ṣé kò wá sí ọ̀nà tí a lè gbà yanjú rẹ̀ ní gidi ni?

Ojútùú Kan Wà

Ìwé ìròyìn yìí ò fìgbà kan ṣíwọ́ títọ́ka sí ojútùú gidi kan ṣoṣo tó lè yanjú gbogbo irú ìṣòro báwọ̀nyí tó ń yọ aráyé lẹ́nu. Ojútùú yẹn ni èyí tí Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, tọ́ka sí nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọn yóò ṣe máa gbàdúrà, ó sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:10.

Ó hàn kedere pé a nílò ìjọba òdodo kan lágbàáyé, tí yóò bójú tó àlámọ̀rí onírúurú ènìyàn tó kún ayé—òótọ́ ni, Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù sọ nípa rẹ̀ ni. Níwọ̀n bí ẹ̀dá ènìyàn kò ti lè gbé irú ìjọba bẹ́ẹ̀ kalẹ̀, yóò bọ́gbọ́n mu ká yíjú sí Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run. Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀, sọ pé ó ti pète láti ṣe èyí láìpẹ́.—Sáàmù 83:18.

Wòlíì Dáníẹ́lì ṣàkọsílẹ̀ ète Jèhófà nígbà tó kọ̀wé pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. . . . Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Bíbélì ṣàpèjúwe bí ìjọba Ọlọ́run yìí yóò ṣe gbégbèésẹ̀ láti mú gbogbo ìwà ọ̀daràn kúrò, títí kan jíjí èèyàn gbé.

Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Tó Dára Ṣe Pàtàkì

Ó dájú pé ìwọ náà yóò gbà pẹ̀lú wa pé kíkọ́ àwọn èèyàn ní ìwà ọmọlúwàbí ṣe pàtàkì bí a bá fẹ́ yanjú ìṣòro jíjí èèyan gbé. Fún àpẹẹrẹ, ronú ipa tí yóò ní lórí àwùjọ ẹ̀dá ká ní gbogbo wa ṣègbọràn sí ìṣílétí tí a kọ sísàlẹ̀ yìí, tó wà nínú Bíbélì, pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Hébérù 13:5) “Kí ẹ má ṣe máa jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ẹyọ ohun kan, àyàfi láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 13:8.

O lè nímọ̀lára bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí bí o bá ronú lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn ní ọgbọ̀nlérúgba ilẹ̀ jákèjádò ayé. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ti ní ipa tó gbá múṣé lórí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ti jẹ́ oníwọra tàbí ọ̀daràn paraku tẹ́lẹ̀ rí. Ẹnì kan tó jẹ́ iṣẹ́ jíjí èèyàn gbé ló ń ṣe tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Ó wá yé mi pé láti mú inú Ọlọ́run dùn, mo ní láti bọ́ ìwà ògbólógbòó mi dà nù kí n sì gbé tuntun wọ̀—èyí tó jẹ́ onínútútù tó dà bíi ti Kristi Jésù.”

Bó ti wù kó rí, a mọ̀ pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó jíire kò lè yí gbogbo ọ̀daràn padà, ó tilẹ̀ lè máà yí èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn padà. Kí ló wá máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n kọ̀ láti yí padà?

Mímú Àwọn Oníwàkiwà Kúrò

A kò ní gba àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ hùwà kiwà láyè láti jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, . . . tàbí àwọn oníwọra, . . . tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé . . . Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.”—Òwe 2:21, 22.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Òfin Ọlọ́run láyé ìgbàanì, pípa ni wọ́n ń pa ajínigbé tí kò bá ronú pìwà dà. (Diutarónómì 24:7) Àwọn oníwọra, bí àwọn ajínigbé, kò ní sí nínú Ìjọba Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọ̀daràn tó wà lóde òní mórí bọ́ nínú ìdájọ́ ẹ̀dá, ṣùgbọ́n wọn ò lè mórí bọ́ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run. Oníwàkiwà èyíkéyìí tó bá fẹ́ gbé lábẹ́ ìṣàkóso òdodo Ìjọba Jèhófà gbọ́dọ̀ yí padà kúrò lọ́nà burúkú.

Ó ṣe kedere pé bí àwọn ipò tó ń sún èèyàn sí ìwà ọ̀daràn bá ṣì wà, ìwà ọ̀daràn á ṣì wà. Ṣùgbọ́n, Ìjọba Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀, nítorí Bíbélì ṣèlérí pé: “Ìjọba náà . . . Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú,” títí kan gbogbo àwọn tó ń hùwà kiwà. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yìí tún sọ pé Ìjọba Ọlọ́run yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin. (Dáníẹ́lì 2:44) Nǹkan á mà yàtọ̀ o!

Ayé Tuntun Òdodo

Ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn. Òun ni èyí tí ó ṣàpèjúwe ọjọ́ iwájú dáadáa báyìí pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Aísáyà 65:21, 22.

Ìjọba Ọlọ́run yóò sọ gbogbo ilẹ̀ ayé yìí dọ̀tun. Gbogbo ẹni tó bá wà láàyè yóò gbádùn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́, wọ́n á lo agbára àdánidá tí wọ́n ní nípa ṣíṣe iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ àti eré ìnàjú tó gbámúṣé. Ipò nǹkan jákèjádò ayé yóò dára débi tí ẹnikẹ́ni kò tiẹ̀ ní ronú jíjí ọmọnìkejì rẹ̀ gbé. Ìfọ̀kànbalẹ̀ yóò wà níbi gbogbo. (Míkà 4:4) Báyìí ni Ìjọba Ọlọ́run yóò sọ ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé tó ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ gbogbo ayé lónìí di ọ̀rọ̀ ìtàn tí ẹnikẹ́ni kò tiẹ̀ ní ronú kàn mọ́.—Aísáyà 65:17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

“Kì yóò . . . sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́