Jíjí Èèyàn Gbé—Lájorí Ohun Tó Ń Fà Á
JÍJÍ èèyàn gbé ti wá di nǹkan tó ń jà kálẹ̀ lóde òní. Àmọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ìpànìyàn, ìfipábáni-lòpọ̀, olè jíjà, híhùwà àìdáa sọ́mọdé, àti ìpẹ̀yàrun pàápàá ń jà kálẹ̀. Èé ṣe tí gbogbo ayé fi wá léwu tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn èèyàn fi máa ń bẹ̀rù láti jáde kúrò nílé wọn lálẹ́?
Lájorí ohun tó ń fa àjàkálẹ̀ ìwà ọ̀daràn, tí jíjí èèyàn gbé jẹ́ ọ̀kan lára rẹ̀, ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àléébù tó rinlẹ̀ láàárín àwùjọ ẹ̀dá. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn àkókò eléwu yìí? Jọ̀wọ́, ṣàyẹ̀wò ohun tó sọ tẹ́lẹ̀ nínú 2 Tímótì 3:2-5.
“Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.”
Àfàìmọ̀ kí o má gbà pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a ti kọ tipẹ́tipẹ́ ṣàpèjúwe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Nínú ayé wa yìí, àwọn àléébù tí ń gbèèràn láwùjọ ẹ̀dá ti búrẹ́kẹ. Ó yẹ fún àfiyèsí pé a bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe àwọn ìwà abaninínújẹ́ tí ẹ̀dá ń hù, tó wà lókè wọ̀nyẹn, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì wọ̀nyí: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín.” (2 Tímótì 3:1) Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò mẹ́ta péré lára àwọn àléébù pàtàkì láwùjọ tó fa àjàkálẹ̀ jíjí èèyàn gbé.
Ìṣòro Ti Àwọn Agbófinró
“Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.”—Oníwàásù 8:11.
Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá ni kò ní èlò tó láti fi kojú àjàkálẹ̀ ìwà ọ̀daràn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, òwò tó pé ni ìwà ọ̀daràn jíjí èèyàn gbé. Ní ọdún 1996, ìpín méjì péré nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo àwọn ajínigbé tó wà ní Kòlóńbíà la ṣẹjọ́ wọn. Ní Mexico, ó kéré tán, igba mílíọ̀nù dọ́là ni àwọn èèyàn san bí owó ìtúsílẹ̀ ní ọdún 1997. Àwọn ajínigbé kan ní Philippines tilẹ̀ ti gba sọ̀wédowó rí láti lè tú èèyàn sílẹ̀.
Ní àfikún, ìwà ìbàjẹ́ láàárín àwọn agbèfọ́ba tí ń gbófin ró máa ń mú kí ìgbéjàko ìwà ọ̀daràn lọ́nà tó gbéṣẹ́ forí ṣánpọ́n nígbà míì. A ti fẹ̀sùn jíjí èèyàn gbé kan àwọn ọ̀gá ẹgbẹ́ pàtàkì tí ń gbógun ti ìjínigbé ní Mexico, Kòlóńbíà, àti orílẹ̀-èdè olómìnira Soviet tẹ́lẹ̀ rí. Nínú ìwé ìròyìn Asiaweek, ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga ilẹ̀ Philippines, Blas Ople, sọ pé ìròyìn tó dọ́wọ́ ìjọba fi hàn pé ìpín méjìléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a jí gbé ní Philippines ni kò ṣẹ̀yìn àwọn tí wọ́n ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá àti iṣẹ́ ológun tàbí àwọn tó ti fẹ̀yìn tì. A gbọ́ pé ajínigbé kan tí òkìkí ẹ̀ kàn ní Mexico máa “ń sá di àwọn agbèfọ́ba nítorí ó ń fún àwọn ọlọ́pàá àdúgbò, àwọn ti ìpínlẹ̀ àti ti ìjọba àpapọ̀ àti àwọn agbẹjọ́rò ìjọba ní ẹ̀gúnjẹ.”
Ipò Òṣì àti Ìyannijẹ Láwùjọ
“Èmi alára sì padà, kí n lè rí gbogbo ìwà ìninilára tí a ń hù lábẹ́ oòrùn, sì wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà.”—Oníwàásù 4:1.
Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni ipò ọrọ̀ ajé àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ kò gbè, àwọn ni wọ́n sì máa ń lọ jí èèyàn gbé. Nítorí náà, nínú ayé tí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì ń pọ̀ sí i láìdábọ̀, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti rí owó láìṣàbòsí, òwò jíjí èèyàn gbé yóò ṣì máa fajú àwọn kan mọ́ra. Níwọ̀n bí a bá ṣì ń ni àwọn èèyàn lára, òwò jíjí èèyàn gbé yóò ṣì jẹ́ ọ̀nà ìjìjàgbara àti ọ̀nà àtipàfiyèsí sí ipò tí wọ́n gbà pé àwọn ò lè fara mọ́.
Ìwọra àti Àìsí Ìfẹ́
“Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” (1 Tímótì 6:10) “Nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”—Mátíù 24:12.
Látijọ́ táláyé ti dáyé ni ìfẹ́ owó ti ń mú kí àwọn èèyàn hùwà ibi. Bóyá ni ìwà ọ̀daràn mìíràn wà tó ń fi ohun tó ń fa làásìgbò, ìbànújẹ́, àti àìnírètí fún ẹ̀dá pawó tó òwò jíjí èèyàn gbé. Ohun tó ń sún ọ̀pọ̀ èèyàn sí i ni ìwọra—ìfẹ́ owó—tó ń mú kí wọ́n máa hùwà àìláàánú sí àjèjì, kí wọ́n sì dá a lóró, kí wọ́n sì kó ìdílé rẹ̀ sínú làásìgbò fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, ọ̀pọ̀ oṣù, àti nígbà mìíràn ọ̀pọ̀ ọdún.
Ó ṣe kedere pé nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀ tí kò dára rárá láwùjọ wa tó jẹ́ ọ̀rọ̀ owó ṣáá la máa ń sọ ṣùgbọ́n tí a ń gbé ìwà ọmọlúwàbí jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Láìsí àní-àní, ipò yìí ló ń fà á tí onírúurú ìwà ọ̀daràn, títí kan jíjí èèyàn gbé, fi ń ráyè gbilẹ̀.
Ṣé ohun tí a wá ń sọ ni pé àkókò wa yìí ni Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni èyí yóò túmọ̀ sí fún ilẹ̀ ayé àti àwa alára? Ǹjẹ́ ojútùú kan wà sí àwọn ìṣòro bíbanilẹ́rù, títí kan jíjí èèyàn gbé, tó ń bá aráyé fínra?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kì í Ṣe Tuntun
Ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ṣááju Sànmánì Tiwa, Òfin Mósè sọ pé pípa ni kí wọ́n pa ajínigbé. (Diutarónómì 24:7) Wọ́n jí Júlíọ́sì Késárì gbé ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n sì gba owó kí wọ́n tó tú u sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gbé Richard Kìíní, Aláyà-bíi-Kìnnìún, tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ní ọ̀rúndún kejìlá ní Sànmánì Tiwa. Ohun ìtúsílẹ̀ tó pọ̀ jù tí wọ́n tíì san rí ni tọ́ọ̀nù mẹ́rìnlélógún góòlù àti fàdákà tí àwọn Quechuan tí ń gbé Peru fún ajagunmólú ará Sípéènì náà, Francisco Pizarro, láti fi gba baálẹ̀ wọn, Atahuallpa, tí wọ́n jí gbé ní ọdún 1533. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn aṣẹ́gun náà fún un lọ́rùn pa ni.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Pẹ̀lú gbogbo ìsapá àwọn ọlọ́pàá, òwò jíjí èèyàn gbé ò kásẹ̀ ńlẹ̀