Jíjí Èèyàn Gbé—Òwò Àwọn Apanilẹ́kún-Jayé
“Ọ̀RÀN jíjí èèyàn gbé kò dà bíi jíjí ẹrù gbé. Ó jẹ́ ìwà láabi, ìwà ìkà àti àìlójú-àánú sí ìdílé, tó jẹ́ agbo tó ṣe pàtàkì jù lọ láwùjọ ẹ̀dá,” ni Mark Bles sọ nínú ìwé tó kọ, tó pè ní The Kidnap Business. Tí wọ́n bá jí ẹnì kan gbé, ńṣe ni pákáǹleke máa ń bá àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀. Ìṣẹ́jú kan ò ní lọ kí wọ́n máà jáyà pé bóyá ààyè ẹ̀ làwọ́n á rí tàbí òkú ẹ̀, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ wọ́n á tún máa ronú pé ẹ̀bi àwọn ni, inú á máa bí wọn, ọwọ́ wọn ò sì ní ran nǹkan kan. Wọ́n lè wà nínú ìpayà yìí fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, tàbí ọ̀sẹ̀, tàbí oṣù, tàbí nígbà míì, fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá.
Àwọn ajínigbé náà máa ń lo bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára ìdílé onítọ̀hún láti fi béèrè owó lọ́nàkọnà. Ẹgbẹ́ àwọn ajínigbé kan fipá mú ọkùnrin kan tí wọ́n jí gbé láti kọ ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí sínú lẹ́tà kan tó kọ sí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn, ó kọ̀wé pé: “Mo fún àwọn oníròyìn láṣẹ láti gbé ohun tí mo ń kọ yìí fáyé gbọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé bí ẹ̀mí mi bá lọ sí i, ẹ̀bi àwọn tó jí mi gbé ni ṣùgbọ́n ìdílé mi yóò pín nínú ẹ̀bi náà nítorí wọ́n fẹ́ràn owó jù mí lọ.” Àwọn tó ń jí èèyàn gbé ní Ítálì ti wá sọ ọ̀ràn gbígba owó ìtúsílẹ̀ di kàn-ńpá nípa gígé ẹ̀yà ara ẹni tí wọ́n jí gbé, wọ́n á wá fi ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí rẹ̀ tàbí àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n. Ajínigbé kan ní Mexico tilẹ̀ máa ń dá àwọn tó bá jí gbé lóró nígbà tó bá ń dúnàádúrà owó ìtúsílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìdílé ẹni náà lórí tẹlifóònù.
Ní ti àwọn ajínigbé mìíràn ẹ̀wẹ̀, wọ́n máa ń gbìyànjú láti wá ojúure àwọn tí wọ́n jí gbé. Fún àpẹẹrẹ, ní Philippines, àwọn tó jí ọkùnrin oníṣòwò kan gbé fi í sí òtẹ́ẹ̀lì ńlá kan ní Manila, wọ́n tọ́jú ẹ̀, wọ́n ra ọtí fún un, wọ́n sì kó àwọn aṣẹ́wó tì í láti máa fi tura títí wọ́n fi rí owó ìtúsílẹ̀ rẹ̀ gbà. Ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n ń jí gbé ni wọ́n máa ń tì mọ́lé, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa ìlera àwọn èèyàn náà. Ọ̀pọ̀ ni wọ́n máa ń dá lóró. Bó ti wù kó rí, ẹni tí wọ́n jí gbé kò lè ṣàìfi ojú winá ìpayà tí yóò mú kó máa ronú ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí òun.
Kíkojú Àìfararọ Tó Ń Fà
Kódà lẹ́yìn tí wọ́n bá tú ẹni tí wọ́n jí gbé sílẹ̀, ara irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè má tètè balẹ̀. Ọmọ ilẹ̀ Sweden kan tó jẹ́ nọ́ọ̀sì, tí wọ́n jí gbé ní Sòmálíà sọ èrò rẹ̀ pé: “Ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ. Òun ni pé kí o bá àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí sọ̀rọ̀, kí o sì wá ìrànlọ́wọ́ àwọn tó mọ̀ nípa ìṣòro rẹ dunjú tó bá pọndandan.”
Àwọn tí ń ṣètọ́jú àwọn tí a jí gbé ti ní ìlànà kan tí wọ́n fi ń tọ́jú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Wọ́n á máa ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn díẹ̀díẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ amọṣẹ́dunjú kó tó di pé wọ́n lọ bá ìdílé wọn, kí wọ́n sì tó máa bá ìgbésí ayé wọn lọ. Rigmor Gillberg, ọmọ ẹgbẹ́ Alágbèélébùú Pupa, tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú títọ́jú àwọn tó níṣòro ìmọ̀lára, sọ pé: “Ìtọ́jú tí a ń fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò ní jẹ́ kí ìṣòro náà máa wà lọ kánrin.”
Àwọn Ohun Mìíràn Tó Lè Ṣẹlẹ̀
Ẹni tí wọ́n jí gbé àti ìdílé rẹ̀ nìkan kọ́ ló ń fara gbá ìdààmú tó ń tìdí jíjínigbé wá. Ìbẹ̀rù pé a lè jíni gbé lè dí ìrìn àjò afẹ́ lọ́wọ́ kó sì ṣèdíwọ́ fún ìdókòwò; kì í tún jẹ́ kí ọkàn àwọn èèyàn balẹ̀. Láàárín oṣù díẹ̀ péré ní ọdún 1997, ilé iṣẹ́ ńlá mẹ́fà tí òwò wọn nasẹ̀ jákèjádò ayé ló kógbá wọn kúrò ní orílẹ̀-èdè Philippines nítorí ewu jíjí èèyàn gbé. Obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Philippines, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Aráàlú Tí Ń Gbógun Ti Ìwà Ọ̀daràn sọ pé: “Ọkàn wa ò balẹ̀ rárá.”
Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Arizona Republic sọ pé: “Ìbẹ̀rù jíjínigbé ń fa ṣìbáṣìbo lágbo àwọn lọ́gàálọ́gàá ní Mexico, kò sì lè ṣàìrí bẹ́ẹ̀.” Ìwé ìròyìn Brazil náà, Veja, sọ pé àwọn gbọ́mọgbọ́mọ àti àwọn ìgárá ọlọ́ṣà ti rọ́pò àwọn ológòmùgomù tó máa ń dẹ́rù ba àwọn ọmọdé ní Brazil. Ní Taiwan, wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ iléèwé lọ́gbọ́n tí gbọ́mọgbọ́mọ ò fi ní jí wọn gbé, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà pẹ̀lú, wọ́n ti gbé àwọn kámẹ́rà amóhùnmáwòrán tí ń ṣọ́ èèyàn sí ilé ìwé àwọn ògowẹẹrẹ kí àwọn gbọ́mọgbọ́mọ má bàa gbé wọn.
Ìjẹ Ni Fáwọn Òṣìṣẹ́ Elétò Ààbò
Ọ̀ràn jíjí àwọn èèyàn gbé tó ń pọ̀ sí i àti àwọn ọ̀nà ẹlẹgẹ́ tí a ń gbà yanjú rẹ̀ ti mú kí àwọn iléeṣẹ́ elétò ààbò máa rí ṣe. Ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta irú ilé iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tó wà ní ìlú Rio de Janeiro, lórílẹ̀-èdè Brazil, wọ́n sì ń pa iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù méjì dọ́là.
Àwọn ilé iṣẹ́ elétò ààbò tó ń pọ̀ sí i kárí ayé, ló ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́gbọ́n tí wọn ò fi ní kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé, wọ́n ń tẹ ìròyìn nípa àwọn àgbègbè tó léwu jáde, wọ́n sì ń dúnàádúrà fún ìtúsílẹ̀. Wọ́n máa ń gba àwọn ìdílé àti ilé iṣẹ́ nímọ̀ràn, nípa kíkọ́ wọn ní ọgbọ́n tí àwọn ajínigbé máa ń lò, wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè fọkàn balẹ̀. Àwọn ilé iṣẹ́ kan tilẹ̀ ń gbìyànjú láti mú àwọn tó ń jí èèyàn gbé kí wọ́n sì gba owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n san padà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti tú ẹni tí wọ́n jí gbé sílẹ̀. Àmọ́, ọ̀fẹ́ kọ́ ni wọ́n ń ṣe é.
Pẹ̀lú gbogbo ìsapá wọ̀nyí, ńṣe ni ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Nígbà tí Richard Johnson, tó jẹ́ igbákejì ọ̀gá pátápátá nílé iṣẹ́ Seitlin & Company ń sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí ní Látìn Amẹ́ríkà, ó sọ pé: “Kàkà kí ìwà jíjí èèyàn gbé dín kù, ṣe ni á túbọ̀ máa pọ̀ sí i.”
Ìdí Tí Ìṣẹ̀lẹ̀ Náà Fi Ń Pọ̀ Sí I
Àwọn ògbógi ṣàlàyé ìdí tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi pọ̀ sí i lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí. Ọ̀kan lára ìdí náà ni ipò ọrọ̀ ajé tó ń burú ní àwọn àgbègbè kan. Òṣìṣẹ́ kan tó máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tí àjálù dé bá, tó ń gbé ìlú Nal’chik, ní Rọ́ṣíà, sọ pé: “Ọ̀nà tó yá jù lọ, téèyàn lè tètè gbà rí owó ni ọ̀nà tó lókìkí yìí, ìyẹn ni jíjí èèyàn gbé.” Ní àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira kan tó wà lábẹ́ Soviet tẹ́lẹ̀ rí, a gbọ́ pé wọ́n ń fi owó tó ń wá láti inú jíjí èèyàn gbé ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun àdáni ti àwọn aláṣẹ ológun tí ń fipá ṣàkóso níbẹ̀.
Ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ń rìnrìn àjò nítorí àtilọ ṣòwò tàbí nítorí àtigbafẹ́, èyí sì ń ṣínà tuntun fún àwọn ajínigbé tí ń wá ẹni tí wọ́n fẹ́ gbé. Iye àwọn àjèjì tí wọ́n ń jí gbé ti di ìlọ́po méjì láàárín ọdún márùn-ún. Láàárín ọdún 1991 sí 1997, wọ́n jí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ gbé ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.
Ibo ni gbogbo àwọn tó ń jí èèyàn gbé wọ̀nyí ti ń wá? Àwọn ogun mélòó kan ti ń parí, èyí sì túmọ̀ sí pé àwọn sójà tẹ́lẹ̀ rí ò ní ríṣẹ́ ṣe mọ́, wọn ò sì ní lówó lọ́wọ́. Àwọn èèyàn yìí sì mọ gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n lè fi ṣe iṣẹ́ tó ń mówó wọlé yìí.
Bákan náà, lílo àwọn ọ̀nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ tó mú kó ṣòro láti ja báńkì lólè àti ṣíṣẹ́pá òwò oògùn olóró ti mú kí àwọn ọ̀daràn ṣí sí iṣẹ́ jíjí èèyàn gbé láti fi rọ́pò ọ̀nà tówó ń gbà wọlé fún wọn. Mike Ackerman, tó jẹ́ ògbógi nípa ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé, ṣàlàyé pé: “Bí a ti túbọ̀ ń dí ọ̀nà táwọn ọ̀daràn fi lè jí ohun ìní láwùjọ ni àwọn ọ̀daràn wá ń hùwà ipá sí èèyàn fúnra rẹ̀.” Pípolongo owó gọbọi tí a san fún ìràpadà pẹ̀lú lè sún àwọn kan láti fẹ́ ṣí sí iṣẹ́ jíjí èèyàn gbé.
Wọ́n Ní Èrò Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Owó ni ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí ń jí èèyàn gbé ń wá kì í ṣe nǹkan míì. Owó tí wọ́n máa ń béèrè máa ń yàtọ̀ síra, ó lè jẹ́ owó díẹ̀ tàbí èyí tó pọ̀, bíi ọgọ́ta mílíọ̀nù dọ́là tí àwọn kan gbà bí owó ìtúsílẹ̀ ọ̀gbẹ́ni ọlọ́rọ̀ jìngbìnnì kan, tó jẹ́ oníṣòwò ní Hong Kong, àmọ́ tí wọn kò tú sílẹ̀.
Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, àwọn kan tó ń jí èèyàn gbé máa ń lo ẹni tí wọ́n jí gbé láti jẹ́ kí àwọn ará ìlú lè mọ̀ nípa wọn, kí wọ́n lè rí oúnjẹ, oògùn, rédíò, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbà, kí a sì lè pèsè ilé ẹ̀kọ́ tuntun, ọ̀nà, àti ilé ìwòsàn fún wọn. Àwọn ajínigbé tú ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n jí gbé ní Éṣíà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n fún wọn ní aṣọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ àti àwọn bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀. Àwọn mìíràn máa ń lo ìjínigbé láti dẹ́rù ba àwọn olùdókòwò àti àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kí wọ́n sì kó wọn láyà jẹ, kí àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè yìí lè ṣíwọ́ fífi ilẹ̀ wọn àti ohun àmúṣọrọ̀ wọn ṣèjẹ.
Nítorí náà, wọ́n ní ète tó pọ̀, ọ̀nà àtiṣe é kò sì wọ́n wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tó ń ronú àtidi ajínigbé àti àwọn tí wọ́n máa jí gbé pọ̀ rẹpẹtẹ. Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ náà ni ojútùú ìṣòro náà pọ̀? Kí ni díẹ̀ lára ojútùú rẹ̀, àti pé ṣé wọ́n lè yanjú ìṣòro náà ní tòótọ́? Ká tó dáhùn irú ìbéèrè wọ̀nyẹn, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn okùnfà pàtàkì tó fara sin tó ń jẹ́ kí òwò jíjí èèyàn gbé máa gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
Bí Wọ́n Bá Jí Ọ Gbé
Àwọn tí wọ́n ti ṣèwádìí nípa ọ̀ràn yìí dá àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí fún àwọn tí wọ́n bá jí gbé.
• Ṣe ohun tí wọ́n bá ní kí o ṣe; má ṣagídí. Wọ́n sábà máa ń fojú àwọn òǹdè tó bá ń ṣagídí gbolẹ̀, wọ́n sì lè pa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n fi ìyà jẹ òun nìkan.
• Má ṣe páyà. Rántí pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tí a ń jí gbé ló ń là á já.
• Wá ohun kan tí wàá fi máa mọ àkókò.
• Gbìyànjú láti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ tóo lè máa tẹ̀ lé lójoojúmọ́.
• Máa ṣe eré ìmárale, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí o wà há.
• Fojú sílẹ̀; gbìyànjú láti há àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àti ìró nǹkan sórí, kí o sì rántí òórùn àwọn nǹkan. Mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn tó jí ọ gbé.
• Tó bá ṣeé ṣe, fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú wọn, kí o sì gbìyànjú láti bá wọn jíròrò. Bí àwọn ajínigbé náà bá wò ẹ́ gẹ́gẹ́ bí èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọ́n lè má ṣe ẹ́ léṣe tàbí kí wọ́n pa ọ́.
• Hùwà bí ọmọlúwàbí tí o bá fẹ́ béèrè ohun tí o nílò lọ́wọ́ wọn.
• Má ṣe gbìyànjú láti dúnàádúrà ìtúsílẹ̀ ara rẹ.
• Bó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n fẹ́ wá fipá gbà yín sílẹ̀, ńṣe ni kí o dọ̀bálẹ̀ láìmira kí o sì máa retí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìbánigbófò Ìjínigbé—Ọ̀ràn Tó Ń Fa Àríyànjiyàn
Ilé iṣẹ́ tó tún ń rí ṣe nídìí ọ̀ràn jíjí èèyàn gbé tó ń gbilẹ̀ sí i ni ilé iṣẹ́ ìbánigbófò. Owó tó ń wọlé fún ilé iṣẹ́ Lloyd’s of London lórí ọ̀ràn ìbánigbófò ìjínigbé lọ́dọọdún ti fi ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i láàárín ọdún 1990 sí 1999. Àwọn ilé iṣẹ́ púpọ̀ sí i ló ń fi irú ìbánigbófò yẹn lọni. Ìbánigbófò náà kan ríran ẹni tó ń dúnàádúrà lọ́wọ́, sísan owó ìtúsílẹ̀, àti nígbà mìíràn ìsapá àwọn amọṣẹ́dunjú láti gba owó ìtúsílẹ̀ náà padà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀ràn ti ìbánigbófò yìí ń fa awuyewuye gan-an.
Àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí òwò ìbánigbófò ìjínigbé ń sọ pé ó ń sọ ìwà ọ̀daràn náà di òwò ńlá ni àti pé kò bójú mu kí èèyàn máa fi ọ̀ràn ìjínigbé pawó. Wọ́n tún sọ pé ẹni tí wọ́n ń bá gbófò lè wá jọ̀gọ̀ nù kó máà mú ọ̀ràn ààbò rẹ̀ lógìírí mọ́ àti pé ìbánigbófò á túbọ̀ mú kí iṣẹ́ bíbéèrè tí àwọn ajínigbé ń béèrè owó máa rọrùn sí i ni, ìyẹn á sì jẹ́ kí ìwà ọ̀daràn yìí máa pọ̀ sí i. Àwọn kan tilẹ̀ ń bẹ̀rù pé bí ọ̀ràn ìbánigbófò bá wà, èyí lè mú kí àwọn èèyàn máa ṣètò pé kí a jí àwọn gbé kí àwọn lè rí owó ìbánigbófò gbà. Wọ́n fòfin de ìbánigbófò ìjínigbé ní Ítálì, Jámánì, àti Kòlóńbíà.
Àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òwò ìbánigbófò ìjínigbé sọ pé ó ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn san owó fún àdánù àwọn èèyàn kéréje bó ṣe rí ní ti àwọn ìbánigbófò mìíràn. Wọ́n ronú pé ìbánigbófò ń fọkàn èèyàn balẹ̀ dé àyè kan, níwọ̀n bí ó ti ń mú kí àwọn ìdílé àti ilé iṣẹ́ tí a mú wọnú ìṣètò náà lè sanwó fún ìrànlọ́wọ́ àwọn amọṣẹ́dunjú tó tóótun, tí wọ́n lè fọkàn ẹni balẹ̀, tí wọ́n lè dúnàádúrà owó ìtúsílẹ̀ tí kò pọ̀, tí wọ́n sì lè mú kó rọrùn láti gbá àwọn ajínigbé náà mú.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Rúkèrúdò ní Stockholm
Lọ́dún 1974, wọ́n jí Patty Hearst gbé, ọmọ bàbá olówó tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Randolph A. Hearst, tó ni iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn kan, àmọ́ ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ nígbà tí ọmọbìnrin náà wá gbè sẹ́yìn àwọn tó jí i gbé, tó sì bá ẹgbẹ́ náà lọ digun jalè. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, agbábọ́ọ̀lù kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sípéènì dárí ji àwọn tó jí i gbé, ó sì ṣàdúrà fún wọn pé wọ́n á ṣoríire.
Láàárín ọdún 1970 sí 1974, orúkọ tí wọ́n pe ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí yìí ni Rúkèrúdò ní Stockholm, ìdí tí wọ́n fi pè é bẹ́ẹ̀ ni jíjí tí wọ́n jí àwọn èèyàn gbé ní ọdún 1973 ní báńkì kan ní Stockholm, Sweden. Nígbà yẹn, àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jí gbé náà wá di ọ̀rẹ́ àwọn tó jí wọn gbé. Irú àjọṣe yẹn wá jẹ́ ààbò fún àwọn tí wọ́n ń jí gbé, gẹ́gẹ́ bí ìwé Criminal Behavior ṣe ṣàlàyé pé: “Bí àwọn tí a jí gbé àti àwọn tó jí wọn gbé bá ṣe wá mọ ara wọn dáadáa sí ni wọ́n á ṣe máa fẹ́ràn ara wọn sí i. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wá fi hàn pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, kò jọ pé ọ̀daràn náà máa ṣe ẹni tó jí gbé ní jàǹbá.”
Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tí wọ́n jí gbé ní Chechnya, tí wọ́n sì fipá bá lòpọ̀, sọ pé: “Mo mọ̀ pé nígbà tí ẹni tó ń ṣọ́ wa náà wá mọ irú ẹni tí a jẹ́, ó wá rí i pé kò dáa bí òun ṣe ń fipá bá mi lò. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, ó sì wá tọrọ àforíjì.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Jíjí ẹnì kan gbé ni ọ̀kan lára pákáǹleke tó máa ń dani lórí rú jù lọ tó lè bá ìdílé ẹni náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn tí a jí gbé nílò ìtùnú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tí wọ́n ń jí gbé ni wọ́n máa ń tì mọ́lé, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ bìkítà nípa ìlera wọn