ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 1/8 ojú ìwé 13
  • Jíjí Èèyàn Gbé Ti Di Òwò Tó Kárí Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jíjí Èèyàn Gbé Ti Di Òwò Tó Kárí Ayé
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Òwò Àwọn Apanilẹ́kún-Jayé
    Jí!—2000
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Ǹjẹ́ Ojútùú Kan Tiẹ̀ Wà?
    Jí!—2000
  • Jíjí Èèyàn Gbé—Lájorí Ohun Tó Ń Fà Á
    Jí!—2000
  • A Rí Ọwọ́ Agbára Ọlọ́run Lára Wa
    Jí!—2005
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 1/8 ojú ìwé 13

Jíjí Èèyàn Gbé Ti Di Òwò Tó Kárí Ayé

Ọ̀RÀN jíjí èèyàn gbé ṣẹlẹ̀ gan-an káàkiri ayé láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá. Ìròyìn kan sọ pé láàárín ọdún 1968 sí 1982, àwọn èèyàn tí iye wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún kan láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàléláàádọ́rin ní a mú ní òǹdè. Ṣùgbọ́n ní nǹkan bí ọdún 1997 sí 1999, nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] sí ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] èèyàn ni wọ́n ń jí gbé lọ́dọọdún.

Ó jọ pé òwò jíjí èèyàn gbé ló lòde báyìí láàárín àwọn ọ̀daràn lórígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé láti Rọ́ṣíà títí dé Philippines, tí kò sì sí ẹ̀dá táwọn ajínigbé ò lè jí gbé. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan, wọ́n jí ọmọ jòjòló tí kò tíì lò tó ọjọ́ kan láyé gbé. Ní Guatemala, wọ́n jí ìyá arúgbó tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin kan tó wà lórí àga aláìsàn gbé pamọ́ fún oṣù méjì. Ní Rio de Janeiro, àwọn ọmọọ̀ta kan bẹ̀rẹ̀ sí ki àwọn èèyàn mọ́lẹ̀ lójú pópó, wọ́n sì sọ pé àfi báa bá fún àwọn ní ọgọ́rùn-ún dọ́là péré làwọ́n máa tú àwọn èèyàn náà sílẹ̀.

Àwọn ẹran pàápàá ò ṣàìfara gbá nínú ọ̀ràn yìí. Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àwọn ọ̀daràn amójú-kuku kan ní Thailand jí erin kan tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ tó wọ̀n tó tọ́ọ̀nù mẹ́fà gbé, wọ́n wá ní àfi báa bá fún àwọn ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ dọ́là làwọ́n máa tú erin náà sílẹ̀. A gbọ́ pé àwọn ọ̀daràn ọmọọ̀ta ní Mexico ń rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn kéékèèké láti máa fi jíjí ẹran ọ̀sìn àti ẹran agbéléjẹ̀ dánra wò kí wọ́n lè nírìírí tó nígbà tí wọ́n bá fi máa lọ jí èèyàn gbé.

Nígbà kan, àwọn olówó làwọn tó ń jí èèyàn gbé ń ṣọdẹ kiri, ṣùgbọ́n ìlù ti yí padà báyìí. Ilé iṣẹ́ ìròyìn Reuters sọ pé: “Ojoojúmọ́ ayé yìí ni wọ́n ń jí èèyàn gbé ní Guatemala, níbi tí àwọn èèyàn ti ń rántí ìgbà táyé ṣì dáa, tó jẹ́ pé díẹ̀ lára àwọn oníṣòwò tó rí ṣe nìkan làwọn ajàjàgbara ń jí gbé. Láyé ìsinyìí, àtolówó àtòtòṣì, àtọmọdé àtàgbàlagbà làwọn ajínigbé ń kì mọ́lẹ̀.”

Èyí tó bá le gan-an la sábà máa ń gbọ́ nípa rẹ̀ nínú ìròyìn, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìṣẹ̀lẹ̀ jíjí èèyàn gbé ló máa ń yanjú láìsí ariwo. Kódà, àwọn orílẹ̀-èdè ti pinnu pé nítorí àwọn ìdí kan, “kò sí ohun tó ń ṣí àwọn lórí tí àwọn á fi máa pariwo ọ̀ràn ìjínigbé síta.” Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò gbé mélòó kan lára àwọn ìdí wọ̀nyẹn yẹ̀ wò.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

MEXICO

Bó ti jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún méjì èèyàn ni wọ́n ń jí gbé lọ́dọọdún, wọ́n ti wá fún òwò jíjínigbé ní orúkọ, orúkọ náà ni “iléeṣẹ́ kékeré.”

ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1990, iye àwọn tó wá ń ṣe ètò ìbánigbófò ní iléeṣẹ́ Lloyd’s of London, bó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ajínigbé jí wọn gbé, ti ń fi ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i lọ́dọọdún.

RỌ́ṢÍÀ

Ní àgbègbè Caucasus níhà gúúsù Rọ́ṣíà nìkan, iye àwọn tí a jí gbé pọ̀ sí i láti igba ó lé méjìléláàádọ́rin lọ́dún 1996 sí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ lọ́dún 1998.

PHILIPPINES

Ìwé ìròyìn “Asiaweek,” sọ pé, “ó jọ pé orílẹ̀-èdè Philippines ni ibùdó ìjínigbé ní Éṣíà.” Ẹgbẹ́ àwọn ajínigbé tó wà níbẹ̀ lé ní ogójì.

BRAZIL

Ní ọdún kan, a gbọ́ pé àwọn ajínigbé gba iye tó lé ní bílíọ̀nù kan dọ́là bí owó ìràpadà níbẹ̀.

KÒLÓŃBÍÀ

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n ń jí gbé lọ́dọọdún. Ní oṣù May 1999, àwọn aṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba jí ọgọ́rùn-ún olùreṣọ́ọ̀ṣì gbé nígbà kan tí wọ́n ń ṣayẹyẹ Máàsì.

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́