ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 166
  • Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Kí ni Bíbélì sọ nípa owó?
  • Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ká ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó?
  • Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ owó?
  • Owó
    Jí!—2014
  • Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
    Jí!—2015
  • Kí Lèrò Tó Tọ́ Kéèyàn Ní Nípa Owó?
    Jí!—2007
  • Báwo Lo Ṣe Lè Ní Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Owó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 166
Ọkùnrin kan ń wá bó ṣe máa ni owó tabua.

Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?

Ohun tí Bíbélì sọ

Rárá. Bíbélì kò sọ pé owó burú bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé owó ló ń ṣokùnfà gbogbo ohun búburú. Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé “owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo,” àmọ́ kì í ṣe bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ nìyẹn, ọ̀rọ̀ náà sì lè ṣí èèyàn lọ́nà. Ohun tí Bíbélì sọ ní ti gidi ni pé “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo.”a​—1 Tímótì 6:10, Bíbélì Mímọ́, àwa la kọ ọ̀rọ̀ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀.

  • Kí ni Bíbélì sọ nípa owó?

  • Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ká ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó?

  • Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ owó?

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa owó

Kí ni Bíbélì sọ nípa owó?

Bíbélì gbà pé owó wúlò, kódà tá a bá fi ọgbọ́n lò ó, ó lè jẹ́ “ààbò.” (Oníwàásù 7:12) Láfikún sí i, Bíbélì gbóríyìn fún àwọn tó lawọ́ sí àwọn míì, èyí tó lè gba pé kéèyàn fún ẹlòmíì ní ẹ̀bùn owó.—Òwe 11:25.

Àmọ́, Bíbélì kìlọ̀ pé kó dáa kéèyàn máa wá bó ṣe máa lówó lójú méjèèjì. Ó sọ pé: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.” (Hébérù 13:5) Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé, kò yẹ ká jẹ́ kí owó gbà wá lọ́kàn, ká má sì máa lépa ọrọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí àwọn ohun tá a nílò ní ti gidi bí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé tẹ́ wa lọ́rùn.—1 Tímótì 6:8

Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé ká ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó?

Àwọn olójúkòkòrò kò ní jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Éfésù 5:5) Lákọ̀ọ́kọ́ náà, lára ìbọ̀rìṣà tàbí ìjọsìn èké ni ojúkòkòrò jẹ́. (Kólósè 3:5) Ìkejì, torí pé àwọn olójúkòkòrò máa ń wá bí wọ́n ṣe máa di ọlọ́rọ̀ lọ́nàkọnà, wọ́n kì í sábà tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere. Òwe 28:20 sọ pé “ọwọ́ ẹni tó ń kánjú láti di olówó kò lè mọ́.” Ó tiẹ̀ lè tì wọ́n débí tí wọ́n á fi lọ́wọ́ nínú àwọn ìwàkiwà bí ìbanilórúkọjẹ́, lílu jìbìtì, ìkówójẹ, ìjínigbé tàbí ìpànìyàn pàápàá.

Ká tiẹ̀ sọ pé ìfẹ́ owó tẹ́nì kan ní kò mú kó hùwà búburú, síbẹ̀ àbàjáde rẹ̀ kì í bímọ re. Bíbélì sọ pé: “Àwọn tó pinnu pé àwọn fẹ́ di ọlọ́rọ̀ máa ń kó sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́ ọkàn tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì lè pani lára.”​—1 Tímótì 6:9.

Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ owó?

Tá ò bá ṣe àwọn ohun tá a mọ̀ pé kò dáa àtàwọn ohun tí Ọlọ́run kórìíra torí owó, a máa níyì lójú àwọn èèyàn, a sì máa rí ojúure Ọlọ́run àti ìtìlẹ́yìn rẹ̀. Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn tó bá ń sapá láti wù ú tọkàntọkàn, pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” (Hébérù 13:5, 6) Ó tún mú un dá wa lójú pé: “Olóòótọ́ èèyàn yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún.”​—Òwe 28:20.

Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Sọ̀rọ̀ Nípa Owó

Oníwàásù 7:12: ‘Owó jẹ́ ààbò.’

Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá fi ọgbọ́n náwó, ó máa ṣe wá láǹfààní torí ó lè dáàbò bò wá dé ìwọ̀n àyè kan.

Lúùkù 12:15: “Torí pé tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Owó kọ́ lohun tó ṣe pàtàkì jù ní ìgbésí ayé, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè fún èèyàn ní ìgbàlà.

1 Tímótì 6:10: “Ìfẹ́ owó ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú jàǹbá, àwọn kan tí wọ́n sì ní irú ìfẹ́ yìí ti ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Owó fúnra rẹ̀ kọ́ ló burú. Àmọ́, àwọn èèyàn tó ní ìfẹ́ owó tó sì jẹ́ pé owó nìkan ni wọ́n fi sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn máa ń fa ìṣòro fún ara wọn irú bí kí ìdílé wọn tú ká àti àìlera torí iṣẹ́ àṣekúdórógbó.

Hébérù 13:5: “Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Dípò tí a ó fi máa lépa ọrọ̀ ní gbogbo ọ̀nà, a máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú kìkì àwọn ohun tá a nílò nìkan.

Mátíù 19:24: “Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ pe ọ̀dọ́kùnrin kan tó lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé kó wa di ọmọlẹ́yìn òun ni. Ọ̀dọ́kùnrin náà kò gbà torí pé kò lè yááfì àwọn ohun ìní rẹ̀. Torí náà, Jésù kì wá nílọ̀ pé, ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ ju Ọlọ́run lọ ń fi ìyè àìnípẹ̀kun rẹ̀ ṣeré.

a Ìtumọ̀ Bíbélì míì tu ẹsẹ yẹn lọ́nà yìí: “Ìfẹ́ owó ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú jàǹbá.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́