ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/07 ojú ìwé 12-13
  • Kí Lèrò Tó Tọ́ Kéèyàn Ní Nípa Owó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Lèrò Tó Tọ́ Kéèyàn Ní Nípa Owó?
  • Jí!—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣọ́ra fún “Ìfẹ́ Owó”
  • Ohun Tó Ju Owó Lọ
  • Owó
    Jí!—2014
  • Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
    Jí!—2015
  • Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
Àwọn Míì
Jí!—2007
g 7/07 ojú ìwé 12-13

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Lèrò Tó Tọ́ Kéèyàn Ní Nípa Owó?

BÍBÉLÌ sọ pé: ‘Ìdáàbòbò ni owó wà fún.’ (Oníwàásù 7:12) A lè sọ pé owó máa ń dáàbò boni lọ́wọ́ ìnira tí òṣì máa ń fà, torí pé bí ò bá sówó, a ò lè ra oúnjẹ àti aṣọ, a ò sì ní í ríbi gbé. Àní sẹ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tówó ò lè rà. Oníwàásù 10:19 tiẹ̀ sọ pé ó “ń mú ìdáhùn wá nínú ohun gbogbo.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa ṣiṣẹ́ kára kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti gbọ́ bùkátà tara wa àti ti ìdílé wa. (1 Tímótì 5:8) Béèyàn bá ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ kára, ọkàn èèyàn á balẹ̀, kò sẹ́ni tó máa fèèyàn wọ́lẹ̀, ẹ̀rù àìlówó lọ́wọ́ ò sì ní máa bani.—Oníwàásù 3:12, 13.

Síwájú sí i, bá a bá ń ṣiṣẹ́ àṣekára, a máa rówó fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Jésù ṣáà sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) A lè nírú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fi owó wa ran àwọn aláìní lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́, pàápàá jù lọ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, tàbí tá a bá ra ẹ̀bùn fún ẹnì kan tá a fẹ́ràn.—2 Kọ́ríńtì 9:7; 1 Tímótì 6:17-19.

Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́, kì í wulẹ̀ ṣe lóòrèkóòrè, bí kò ṣe pé kí wọ́n jẹ́ kó mọ́ wọn lára láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ìyẹn ló fi sọ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà.” (Lúùkù 6:38) Ìlànà kan náà ló kan fífi owó tàbí ohun mìíràn ṣètìlẹ́yìn kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú. (Òwe 3:9) Ó dájú pé bá a bá ń hùwà ọ̀làwọ́ lọ́nà yìí, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti sọ ara wa di “ọ̀rẹ́” Jèhófà àti ọ̀rẹ́ Ọmọ rẹ̀.—Lúùkù 16:9.

Ṣọ́ra fún “Ìfẹ́ Owó”

Ahun gbáà làwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, bí wọ́n bá sì jàjà fún èèyàn ní nǹkan, a jẹ́ pé nǹkan kan wà nídìí ẹ̀ ni. Ohun tó sì fà á tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ìfẹ́ owó yìí kì í jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Abájọ tí 1 Tímótì 6:10 fi sọ pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” Kí ló wá fà á táwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó kì í fi í nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tó sì tún máa ń pa wọ́n lára?

Ohun kan ni pé, owó kì í tó oníwọra èèyàn. Ohun tí ìwé Oníwàásù 5:10 sì sọ gan-an nìyẹn, ó ní: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà.” Ìyẹn ló fà á táwọn olùfẹ́ owó fi máa ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjákulẹ̀ “gún ara wọn.” Ibi tó tún wá burú sí ni pé, ìwọra wọn kì í jẹ́ kí wọ́n rẹ́ni bá rìn, tẹbí tará á máa sá fún wọn, wọn kì í sì í lè sinmi tó. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Dídùn ni oorun ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.” (Oníwàásù 5:12) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìfẹ́ owó kì í jẹ́ kéèyàn rí ojú rere Ọlọ́run.—Jóòbù 31:24, 28.

Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ la lè rí nínú Bíbélì àti nínú àwọn ìwé ìtàn nípa àwọn èèyàn tí wọ́n tìtorí owó jalè, tí wọ́n yí ẹjọ́ po, tí wọ́n sọ ara wọn di aṣẹ́wó, tí wọ́n pààyàn, tí wọ́n dalẹ̀ àwọn míì, tí wọ́n sì purọ́. (Jóṣúà 7:1, 20-26; Míkà 3:11; Máàkù 14:10, 11; Jòhánù 12:6) Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó ké sí olùṣàkóso kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tó sì “ní ọrọ̀ gan-an” pé kó máa tọ òun lẹ́yìn. Ó ṣeni láàánú pé ọkùnrin náà ò jẹ́ ìpè Jésù nítorí pé ó rò pé ìpè yẹn máa pá ọrọ̀ òun lára. Ohun tó ṣe yìí ya Jésù lẹ́nu, ó si sọ pé: “Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n ní owó láti rí ọ̀nà wọ ìjọba Ọlọ́run!”—Lúùkù 18:23, 24.

Láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” tá à ń gbé yìí, ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn Kristẹni wà lójúfò nítorí pé bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò ti ya “olùfẹ́ owó.” (2 Tímótì 3:1, 2) Àwọn Kristẹni tòótọ́ tí ọ̀ràn ìjọsìn Ọlọ́run jẹ lọ́kàn kì í ṣe oníwọra, nítorí pé wọ́n ní ohun tó ju owó lọ fíìfíì.

Ohun Tó Ju Owó Lọ

Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba ń sọ pé owó lè jẹ́ ààbò, ó tún fi kún un pé, “ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò” nítorí pé ó “máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.” (Oníwàásù 7:12) Kí ló ní lọ́kàn? Ọgbọ́n tí Sólómọ́nì ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí yìí ni ọgbọ́n téèyàn ní nítorí pé ó lóye Ìwé Mímọ́ dunjú tó sì tún bẹ̀rù Ọlọ́run látọkànwá. Nítorí pé irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ ju owó lọ fíìfíì, ó lè dáàbò bo èèyàn lọ́wọ́ àìmọye ọ̀fìn téèyàn lè kó sí láyé, kódà ó lè gbani lọ́wọ́ ikú àìtọ́jọ́ pàápàá. Ọgbọ́n tòótọ́ sì tún dà bí adé nítorí pé ó máa ń gbé àwọn tó bá ní in ga, ó sì tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn. (Òwe 2:10-22; 4:5-9) Nítorí pé irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ sì máa ń mú kéèyàn rí ojú rere Ọlọ́run, Bíbélì tún pè é ní “igi ìyè.”—Òwe 3:18.

Gbogbo àwọn tó bá fi tọkàntọkàn fẹ́ irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì múra tán láti wá a rí, máa ń rí i pé ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ìyẹn ni Bíbélì fi sọ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ . . . bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an. Nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n; láti ẹnu rẹ̀ ni ìmọ̀ àti ìfòyemọ̀ ti ń wá.”—Òwe 2:1-6.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń wà ní àlàáfíà, wọ́n máa ń láyọ̀, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀ ju tàwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó lọ nítorí pé wọn ka ọgbọ́n sí ohun tó ṣe pàtàkì ju owó lọ. Hébérù 13:5 sọ pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí [Ọlọ́run] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’” Kò sí bí owó ṣe lè dá irú ààbò bẹ́ẹ̀ boni.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ọ̀nà wo ni owó ń gbà dáàbò boni?—Oníwàásù 7:12.

◼ Kí nìdí tí ọgbọ́n tó bá Ìwé Mímọ́ mu fi ju owó lọ fíìfíì?—Òwe 2:10-22; 3:13-18.

◼ Kí nìdí tó fi yẹ ká sá fún ìfẹ́ owó?—Máàkù 10:23, 25; Lúùkù 18:23, 24; 1 Tímótì 6:9, 10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́