ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • hf apá 4 1-2
  • Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
  • Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 1 Ẹ FARA BALẸ̀ ṢÈTÒ ÌNÁWÓ YÍN
  • 2 Ẹ MÁA FINÚ HAN ARA YÍN, Ẹ MÁ SÌ ṢE JU ARA YÍN LỌ
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
    Jí!—2015
  • Owó
    Jí!—2014
  • Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
hf apá 4 1-2
Tọkọtaya kan jọ ń ṣètò bí wọ́n á ṣe máa ṣọ́wó ná

APÁ KẸRIN

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

“Ìmọ̀ràn ni a fi ń fìdí àwọn ìwéwèé múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”​—Òwe 20:18

Gbogbo wa la nílò owó ká lè pèsè àwọn ohun tí ìdílé wa nílò. (Òwe 30:8) Ó ṣe tán, ‘owó jẹ́ fún ìdáàbòbò.’ (Oníwàásù 7:​12) Ó lè ṣòro fún tọkọtaya láti jọ máa sọ̀rọ̀ nípa owó, àmọ́ ẹ má ṣe jẹ́ kí owó dá wàhálà sílẹ̀ láàárín yín. (Éfésù 4:​32) Ó yẹ kí tọkọtaya fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì jọ máa pinnu bí wọ́n ṣe fẹ́ ná owó.

1 Ẹ FARA BALẸ̀ ṢÈTÒ ÌNÁWÓ YÍN

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ jọ máa ṣètò bí ẹ ṣe máa ná owó yín. (Ámósì 3:3) Ẹ jọ pinnu ohun tó yẹ kí ẹ rà àti iye tí ẹ máa lè ná. (Òwe 31:16) Má kàn máa ra ohun tí o bá rí torí pé owó wà lọ́wọ́ rẹ. Má ṣe tọrùn bọ gbèsè. Má ṣe ná ju owó tí o ní lọ.​—Òwe 21:5; 22:7.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Tí owó bá ṣẹ́ kù sí yín lọ́wọ́ ní ìparí oṣù, ẹ jọ pinnu ohun tí ẹ máa fi ṣe

  • Tí iye tí ẹ ná bá pọ̀ ju iye tó wọlé fún yín, ẹ ṣètò bí ẹ ṣe máa dín ìnáwó yín kù. Bí àpẹẹrẹ, ẹ máa se oúnjẹ fúnra yín dípò kí ẹ máa ra oúnjẹ jẹ

Tọkọtaya kan ń ronú nípa ìnáwó ńlá tó wà níwájú wọn

2 Ẹ MÁA FINÚ HAN ARA YÍN, Ẹ MÁ SÌ ṢE JU ARA YÍN LỌ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Máa fi òtítọ́ ṣe ohun gbogbo “kì í ṣe níwájú Jèhófà nìkan, ṣùgbọ́n níwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú.” (2 Kọ́ríńtì 8:​21) Ẹ má fi ohunkóhun pa mọ́ fún ara yín nípa iye tó ń wọlé fún yín àti bí ẹ ṣe ń náwó.

Rí i dájú pé ò ń fọ̀rọ̀ lọ ọkọ tàbí aya rẹ tí o bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì tó jẹ mọ́ ìnáwó. (Òwe 13:10) Àlàáfíà máa wà láàárín yín tí ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀ nípa ìnáwó yín. Ṣe ni kí o gbà pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ ni owó tó ń wọlé fún ẹ, kì í ṣe tìẹ nìkan.​—1 Tímótì 5:8.

Tọkọtaya kan lọ rajà, wọ́n wá ń wo ìwé tí wọ́n kọ ohun tí wọ́n fẹ́ rà sí

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Ẹ jọ fẹnu kò lórí iye tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín lè ná láìsọ fún ẹnì kejì

  • Ẹ má ṣe dúró dìgbà tí bùkátà bá délẹ̀ kí ẹ tó jọ sọ̀rọ̀ nípa owó

OJÚ TÓ YẸ KÍ Ẹ MÁA FI WO OWÓ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó ṣe pàtàkì, ẹ má ṣe jẹ́ kó dá wàhálà sílẹ̀ láàárín yín tàbí kó mú kí ẹ máa ṣàníyàn tí kò yẹ. ­(Mátíù 6:​25-​34) Kò dìgbà tí ẹ bá lówó rẹpẹtẹ kí ẹ tó lè gbádùn ara yín. Bíbélì sọ pé: “Ẹ . . . máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.” (Lúùkù 12:15) Kò sí nǹkan kan tí owó lè rà tó máa dà bí ọkọ tàbí aya rẹ. Torí náà, ẹ jẹ́ kí ohun tí ẹ ní tẹ́ yín lọ́rùn, ẹ má sì ṣe pa àjọṣe tí ẹ ní pẹ̀lú Ọlọ́run tì. Tí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìdílé yín máa láyọ̀, inú Jèhófà sì máa dùn sí yín.​—Hébérù 13:5.

BI ARA RẸ PÉ  . . .

  • Kí ni ìdílé wa lè ṣe tí a kò fi ní tọrùn bọ gbèsè?

  • Ìgbà wo ni èmi àti ọkọ tàbí aya mi jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn nípa ìnáwó wa láìfi ohunkóhun pa mọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́