Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Agbára Ìrántí Mo dúpẹ́ tọkàntọkàn fún àpilẹ̀kọ náà, “O Lè Mú Kí Agbára Ìrántí Rẹ Sunwọ̀n Sí I.” (April 8, 1996) Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo ti gbìyànjú láti máa rántí orúkọ gbogbo àwọn mẹ́ḿbà ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò tí mo ń dara pọ̀ mọ́—ṣùgbọ́n láìkẹ́sẹjárí. Ọ̀ràn náà gbàfiyèsí kánjúkánjú láìpẹ́ yìí, nígbà tí Watch Tower Society yàn mí láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn àjò. Àpilẹ̀kọ yìí dáhùn àdúrà mi! Nípa lílo àwọn ìdámọ̀ràn tí a fúnni, mo lè rántí orúkọ iye ènìyàn tí ó ju ìdajì àwọn tí mo bá pàdé ní ìjọ mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ.
C. E. U., Nàìjíríà
Rí Ọlọ́run Ẹ ṣeun púpọ̀ fún àpilẹ̀kọ náà, “Ọlọ́run Jẹ́ Kí A Rí Òun.” (March 22, 1996) Nígbà tí mo ń kà á, omijé ayọ̀ kún ojú mi fún Scott àti Steve Davis. Ìrírí wọ́n ti fún ìpinnu mi láti dáwọ́ lé iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìgbésí ayé mi lẹ́yìn tí mo bá jáde nílé ẹ̀kọ́ lókun.
G. G., Ítálì
N kò ka ìrírí àgbàyanu àti amọ́kànyọ̀ bí èyí rí! Dájúdájú, Jèhófà ti ní láti fi ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ hàn nígbà tí ó rí i tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin méjì wọ̀nyí ń tiraka láti ṣiṣẹ́ sìn ín. Iṣẹ́ ìsìn aláìmọtara-ẹni-nìkan wọn sí Ọlọ́run yẹ fún ìgboríyìn.
J. D., United States
Ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ nípa bí Scott àti Steve ṣe wá Ọlọ́run kiri ń gbéni ró ní tòótọ́. Èmi pẹ̀lú ti wá Ọlọ́run kiri onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n n kò rí ìtẹ́lọ́rùn. Mo fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run gan-an, ṣùgbọ́n n kò mọ bí mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ wo bí mo ti kún fún ọpẹ́ tó pé Jèhófà mọ ohun tí ọkàn mi ń yán hànhàn fún! Ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà ti gba ẹ̀mí mi la, ó sì ti fún mi ní àlàáfíà.
D. C., United States
Ààbò Àtọ̀runwá? Mo ní ìsoríkọ́ láìpẹ́ yìí, nítorí pé mo rò pé Jèhófà kì í gbọ́ àdúrà mi. Bí ó ti wù kí ó rí, àpilẹ̀kọ náà, “Ojú-Ìwòye Bibeli: Àwọn Kristian Tòótọ́ Ha Lè Retí Ààbò Àtọ̀runwá Bí?” (April 8, 1996) ti jẹ́ kí n lóye pé Ọlọ́run ń gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀, kì í sì í sábà ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú wa. Ǹjẹ́ kí Jèhófà máa bù kún yín bí ẹ ti ń kọ àwọn àpilẹ̀kọ tí ń jẹ́ kí a lè máa gbẹ́kẹ̀ wa lé e.
C. A. A., Brazil
Àlòkù Ọkọ̀ Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Bí O Ṣe Lè Ra Àlòkù Ọkọ̀.” (April 8, 1996) Èmi àti ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ra àlòkù ọkọ̀ kan. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ń ṣiṣẹ́ dáradára, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́fà, ọkọ̀ náà daṣẹ́ sílẹ̀ pátápátá. Bí a bá ti ní ìsọfúnni dáradára yìí ṣáájú ni, bóyá a kì bá tí ra òkú ọkọ̀ tí kò kúrò lójú kan sí ẹnu ọ̀nà ilé wa.
M. C., United States
Gẹ́gẹ́ bí amọṣẹ́dunjú onímọ̀ nípa ohun ìrìnnà kan, èmi yóò fẹ́ láti ṣàfikún kókó kan. Kí o tóó ra àlòkù ọkọ̀ kan, ṣàyẹ̀wò láti rí i pé nọ́ḿbà ẹ̀yà ara rẹ̀ àti ti ẹ̀rọ agbọ́kọ̀rìn rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú èyí tí ó wà lórí fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ rẹ̀. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, tàbí bí a bá ti pa wọ́n rẹ́, ó ṣeé ṣe kí ọkọ̀ náà jẹ́ èyí tí a ti jí gbé!
M. V., Ilẹ̀ Olómìnira Czech
A dúpẹ́ fún ìdámọ̀ràn wíwúlò náà.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Tábà Tí Kò Ní Èéfín Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Tábà Tí Kò Ní Èéfín—Ó Ha Léwu Bí?” (April 22, 1996) Àkọlé náà kò yé mi dáadáa tó, ìyẹn ló sì mú kí n ka àpilẹ̀kọ náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò tí ì bá ìṣòro yìí pàdé níhìn-ín ní Togo, àpilẹ̀kọ náà jẹ́ kí n mọ irú ìṣòro tí ń kan àwọn mìíràn ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé.
C. H., Togo
Mo máa ń fẹ́ láti ka gbogbo àpilẹ̀kọ yín, ṣùgbọ́n èyí ló dára jù lọ. Àwọn ọ̀dọ́ tí ń lo tábà tí kò ní èéfín wà níhìn-ín, ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ yìí kìlọ̀ nípa àwọn ewu rẹ̀. Èmi kì yóò lò ó láé.
P. H. W., Brazil